Datasets:
Tasks:
Multiple Choice
Modalities:
Text
Formats:
json
Sub-tasks:
multiple-choice-qa
Size:
< 1K
License:
[ | |
{ | |
"question": "Fẹ́ra kù' túmọ̀ sí", | |
"a": "lóyún", | |
"b": "rin ìrìn-àjò", | |
"c": "bímọ", | |
"d": "mo ọbẹ̀ í sè", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé Àṣàké ni ààyò Délé. Ọlọ́run kò tètè yọ̀nda. ọmọ fún un. l̀yáalé rẹ̀, Àjọ́kẹ́ ti bí ìsun, l̀yàwó tí Déié fẹ́ tẹ̀lé e, Àníkẹ́, náà ti bí ìwàlè. Àwọn méjèèjì a sì máa wo Àṣàké bi ọlọ́wọ́-ṣíbí tó kàn wá bá ọkọ wọn jẹun lásán. Gbogbo ìgbà ni Délé máa ń gbàdúrà kí Ọlọ́run tètè dá Àṣàkẹ́ lóhùn. Ìparí oṣù tí iṣé pàjáwìrì gbé Délé lọ sí Òkè-òkun ni Àṣàkẹ́ déédéé rí i pé òun ti fẹ́ra kù! Wéré lo tẹ ọkọ rẹ̀ láago láti fún un ní ìròyin ayọ̀ náà. Kàyéfí ni ó jẹ́ fún àwọn orogún rẹ láti rí i ní ipò tó wa, wọ́n sì ń fojú ìlara wò ó. Oṣù mẹ́fà ni Délé lò lẹ́yìn odi kí ó tó padà wá sílé. Oṣù kejì tó dé ni Àṣàkẹ́ bímọ, ọmọ náà si jọ Délé bí ìmumu. Ó sọ ọ́ ní Ọmọniyì. Àṣàkẹ́' sọ, ọ́ ní Olúwajùwá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Níbo ni Láyí kọ́kọ́ gbé?", | |
"a": "Ládépò", | |
"b": "Ìpólé", | |
"c": "Ìdọ̀gọ̀", | |
"d": "Kétu", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Nígbà ìwáṣẹ̀ bí ọmọkùnrin bá tó níyàwó, àwọn obí rẹ̀ yóò wáya fún un ṣùgbọ́n lóde òní. ojú awo ni awo fí ń gbọbẹ́. Èyí ni Láyí kò ṣe fi òjò Déwálé àti lyùnadé gbin ọkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fé kí Láyi ni irú láyé, bí i ti Démọ́lá àti Àkàndé, tí wọ́n bí sí Ìdọ̀gọ̀ níbi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí.\nLáyí tí ń dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ ará rẹ̀ nígbà tí Déwálé lọ dáko ẹgan ní Kétu ní ibi tí lyùnadé tí ń ṣiṣẹ́ olùkọ́.\n\nLádépò ni a ti bí Láyi ṣùgbọ́n Ìpólé ni ó ń gbé báyìí. Láti ìgbà tí ó ti di ọmọ òrukàn ni Déwálé àti Iyùnadé ti gbà á tọ́. Ní ìlú yìí kan náà ni ó ti ṣe alábàápàdé Fúnmilọ́lá, Ṣadé, Tọ́lá àti Yẹ́misí tí ó sì yan Fúnmilọ́lá, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyò. Èrò ọkàn àwọn alágbàtọ́ Láyí ni pé bí wọ́n ṣe fẹ́yàwó fún Àkàndé àti Démọ́lá tí gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò náà ni kí wọ́n ṣe fún un, ṣùgbọ́n ibi wọ́n fi ojú sí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ.\n\nÀsìkò tí Láyí gbéyàwó rọ̀ ọ́ lọ́rùn ju ti àwọn irò rẹ̀ tí ó fi ìkánjú lábẹ̀ gbígbóná. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí Délé tí ń wáṣẹ́ ló ti bá ọmọbìnrin kan pàdé. Wón ṣeré oge, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ di tọkọtaya ṣùgbọ́n ará ò rokùn, ará ò radìyẹ. Bákan náà ni Kínyọ fi afẹ́ ayé kojú sí bùkátà mọ́to kí ó tó to ilé rẹ̀, bùkátà wá wó lu ara wọn ṣùgbọ́n ti Láyí yàtọ̀ gédégédé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó Láyí, ó ríṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́ kan. Èyí ló mú un pinnu láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí Ayédáadé níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́. Lára àwọn ọmọ tí Olórun fi jíǹkí rẹ̀ ni Dékémi, tíi ṣe ọmọlójú rẹ̀. Nítorí l̀jáfárá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́., Láyí di ọ̀gá pátápátá láìpẹ́. Ó kọ́lẹ́, ó ra mọ́tò. l̀yàwó rẹ̀ náà sì di oníṣòwò ńlá tí àwọn aláròóbò ń ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Bádéjọ pinnu láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́-ìwé nítorí pé", | |
"a": "ó ní owó", | |
"b": "kò bímọ púpọ̀", | |
"c": "ó fẹ́ di bàbá alákọ̀wé", | |
"d": "l̀ya àìkàwé jẹ ẹ́", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Ọmọ bíbí ìlú Béyìíòṣe ni Ìṣọ̀lá. Òun àti àbúrò rẹ̀ Fọláhànmí, nìkan ni Bádéjọ, bàbá wọ́n bí. Àgbẹ̀ oníkòkó aládàáńlá ni Bádéjọ. Bọ́látitó, aya rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò obì. Bádéjọ kò kàwé ṣùgbọ́n ó pinnu láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjéèjì débi tí wọ́n bá lè kàwé dé láyé, nítorí pé ìya àìkàwé jẹ ẹ́ púpọ̀ nídi òwò tí ó ń ṣe.\n\nLẹ́yìn tí Ìṣọ̀lá parí ìwé mẹ́wàá ní ìlú l̀bòdì ni ó gba ìlú Arómisá lọ láti tẹ̀ síwáiú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní fásitì. Ìlú ọbá ni ó sì ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kejì nínú òfin. Ìṣọ̀lá padà sílúu Béyìíròṣe, ó sì di gbajúgbajà agbẹjọ́rò káàkiri agbègbè náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni olùkọ́?", | |
"a": "l̀yá Démọ́lá", | |
"b": "Ìyá Dékẹ́mi", | |
"c": "Kínyọ̀", | |
"d": "Délé", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Nígbà ìwáṣẹ̀ bí ọmọkùnrin bá tó níyàwó, àwọn obí rẹ̀ yóò wáya fún un ṣùgbọ́n lóde òní. ojú awo ni awo fí ń gbọbẹ́. Èyí ni Láyí kò ṣe fi òjò Déwálé àti lyùnadé gbin ọkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fé kí Láyi ni irú láyé, bí i ti Démọ́lá àti Àkàndé, tí wọ́n bí sí Ìdọ̀gọ̀ níbi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí.\nLáyí tí ń dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ ará rẹ̀ nígbà tí Déwálé lọ dáko ẹgan ní Kétu ní ibi tí lyùnadé tí ń ṣiṣẹ́ olùkọ́.\n\nLádépò ni a ti bí Láyi ṣùgbọ́n Ìpólé ni ó ń gbé báyìí. Láti ìgbà tí ó ti di ọmọ òrukàn ni Déwálé àti Iyùnadé ti gbà á tọ́. Ní ìlú yìí kan náà ni ó ti ṣe alábàápàdé Fúnmilọ́lá, Ṣadé, Tọ́lá àti Yẹ́misí tí ó sì yan Fúnmilọ́lá, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyò. Èrò ọkàn àwọn alágbàtọ́ Láyí ni pé bí wọ́n ṣe fẹ́yàwó fún Àkàndé àti Démọ́lá tí gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò náà ni kí wọ́n ṣe fún un, ṣùgbọ́n ibi wọ́n fi ojú sí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ.\n\nÀsìkò tí Láyí gbéyàwó rọ̀ ọ́ lọ́rùn ju ti àwọn irò rẹ̀ tí ó fi ìkánjú lábẹ̀ gbígbóná. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí Délé tí ń wáṣẹ́ ló ti bá ọmọbìnrin kan pàdé. Wón ṣeré oge, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ di tọkọtaya ṣùgbọ́n ará ò rokùn, ará ò radìyẹ. Bákan náà ni Kínyọ fi afẹ́ ayé kojú sí bùkátà mọ́to kí ó tó to ilé rẹ̀, bùkátà wá wó lu ara wọn ṣùgbọ́n ti Láyí yàtọ̀ gédégédé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó Láyí, ó ríṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́ kan. Èyí ló mú un pinnu láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí Ayédáadé níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́. Lára àwọn ọmọ tí Olórun fi jíǹkí rẹ̀ ni Dékémi, tíi ṣe ọmọlójú rẹ̀. Nítorí l̀jáfárá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́., Láyí di ọ̀gá pátápátá láìpẹ́. Ó kọ́lẹ́, ó ra mọ́tò. l̀yàwó rẹ̀ náà sì di oníṣòwò ńlá tí àwọn aláròóbò ń ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "kọlé tó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Ìfẹ́ láàárín Dékúnlé àti Fadékẹ́mi", | |
"b": "Fadékẹ́mi di apọnmità", | |
"c": "Bórí pẹ́ nílọ̀ á dire", | |
"d": "l̀yà tí ó ń jẹ ọmọ òrukàn", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Fadékẹ́mi jẹ́ ọmọ òrukàn tí ó sì rẹwà lóbinrin. Láti kékeré ni ó ti ń wẹ̀ nínú ìyà. Ó ń gbé lọ́dọ́ Adébáyọ̀, ábúrò babá rẹ̀, ẹni tí ó fi ìyà pá a lórí dọ́ba, títi tí ó fi sá kúrò níbẹ̀. Ìlú Arárọ̀mí tí ó sá lọ ni ó ti di aláàárù. Ó tún dan iṣẹ́ apọnmità wò, bẹ́ẹ̀ ló tún ṣiṣẹ́ ọmọọdọ̀ lọ́dọ̀ Àmọ̀pé Olóúnjẹ, ṣùgbọ́n kàkà kí ewé àgbọ́n rẹ rọ̀, fíle ló ń le sí i.\n\nÌdí iṣẹ́ bírísopé tí ó tún lọ ṣe ni Dékúnlé ọmọọbá ti pàdé rẹ̀, tí ẹwà rẹ̀ sí wọ̀ ọ́ lójú. Ó bá a sọ̀rọ̀, ọ̀rọ, wọ́n sì wọ̀. Dékúnlé wá bọ́ṣọ ìyà lára rẹ̀, ó sì sọ ọ́ dìyàwó. Báyìí ni orúkọ ro Fadékẹ́mi. Ó di ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó ọlọ́rọ̀ ìlú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yí nínú ọlá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Èwo Ió yàtò?", | |
"a": "Owóṣeéní", | |
"b": "Adégbọlá", | |
"c": "Akin", | |
"d": "Subúọlá", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Kò-là-kò-sagbe túmọ̀ sí ẹni tí ó", | |
"a": "lówó púpọ̀", | |
"b": "rí jẹ díẹ̀", | |
"c": "ń ṣàgbẹ̀ jẹun", | |
"d": "ń ṣowó ná", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Kò-là-kò-sagbe ni Yàyá ọmọ Ògúndìran. Atàpáta-dìde ni ọbàkan rẹ̀, Bísí, ó sì jẹ́ obìnrin. Iṣẹ́ káràkátà ni Yàyá ń ṣe kí ó tó dé ipò tí ó wà yìí. Yàyá ni àbúrò méjì, okùnrin ni àwọn méjèèjì. Àkókò wa ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni, èkejì náà wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama. \n\nYàyá ni ó ń gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ wọ̀nyí láti ìgbà tí ìyàwó wọn ti di olóògbé. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé Ògúndìran wà láyé bí aláìsí ni. Ẹ̀rù yìí pọ̀ fún un láti dá gbé ṣùgbọ́n nítorí pé Ṣọlá jáfáfá lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ, l̀jọba fi ẹ̀kọ́ dá a lọ́lá láti tẹ̀síwájú sí yunifásítì.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "\"ta epo si àlà\" túmọ́ sí", | |
"a": "pòkìkí", | |
"b": "dágunlá sí", | |
"c": "kó ìwọ̀sí bá", | |
"d": "kábàámọ̀", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ohun tí ó mú ẹ̀rù Ṣàngó ba àwọn ará ìlú ni pé ó", | |
"a": "fẹ́ ìyàwó mẹ́ta", | |
"b": "jẹ́ Ọba Ọ̀yọ́", | |
"c": "máa ń yọ iná lẹ́nu", | |
"d": "jẹ́ ọmọ Tápà", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.\n\nBí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "\"wọn\" tí a falà sí nídìí ń tọ́ka sí", | |
"a": "ọba", | |
"b": "ẹgbẹ́", | |
"c": "akọrin", | |
"d": "òǹwòran", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ohun gbogbo ló ni àsìkò tirẹ̀. Nígbà tí àsìkò tó fún àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ wọ̀nyí láti jó kí ọba ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wá ríran wò. Ṣé ní ti ẹgbẹ́, wọ́n pọ̀ lọ súà bí ọlá Ọlọ́run: Ìdáǹdè, Ọmọladé, Òmìnira, Ọmọ́yèiú, Bọ́bakẹyẹ, Ajagungbadé, Ọbatèkóbọ̀, Ọbaníbàṣírí, Bọ́bagúntẹ̀, àti bẹ́è bẹ́ẹ̀ lọ.\n\nTí a bá ní kí á máa to àwọn orúkọ ẹgbẹ́ wọ̀nyí bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, yóò gba odindin ojú-ìwé méjì níbi tí wọ́n pọ̀ dé. Bí oníkàlùkù wọn ti ń jáde lọ síwájú kábíyèsí pẹ̀lú ẹ̀bùn wọn lọ́wọ́ ni àwọn òṣèré wọn ń lù tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Músílíù ọmọ Hárúnà Ìṣọ̀lá kọ kísà lórin. Eléré ìbílẹ̀ kan tí wọn ń pè ní Ìdàgẹ̀rẹ̀ náà ko ségè lórin. Orí ẹṣin funfun ni Jẹnẹra Àyìnlá wà tó ń kọrin fún ẹgbẹ́ Ìdáǹdè.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ohun tí ó jẹ́ kí Báyọ̀ di ẹni ará rẹ̀ ni pé ó", | |
"a": "jẹ́ akíkanjú", | |
"b": "rí owó ṣòwò", | |
"c": "ṣiṣẹ́ ní òkè-òkun", | |
"d": "nífẹ́ẹ̀ àwọn àbúrò rẹ̀", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Báyọ̀ àti àwọn àbúrò rè méjèèjì jẹ́ ọmọ òrukàn, kò sí olùrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ní àforítì. Báyọ̀ ni ó gbọ́ bùkátà àtilọ sílé ẹ̀kọ́ ara rẹ̀ àti ìtọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ kárakára. Ó tiraka, ó jáde ìwé mẹ́wàá, ó sì ṣe àṣeyọrí. Èyí mú kí ìjọba fún un ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí ìlú òyìnbó. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí Báyọ̀ kúrò ni Ìtelè lọ sí òke òkun, ó gboyè ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣègùn. Ó ṣiṣẹ́ díẹ̀ fún ọdún kan láti lè rí owó tí yóò fi padà wálé nítorí àáyún àwọn àbúrò rẹ̀ ń yun ún.\n\nNí kété tí Báyọ̀ padà sí Nàìjíríà, ìlú l̀bàdàn ni ó ríṣẹ́ sí ní ilé-ìwòsàn ńlá kan. Láìpẹ̀ láìjìnà, ó ti di ìlúmọ̀ọ́ká nínú iṣẹ́ ìṣègùn. Lẹ́nu iṣẹ́ yìí ni ó ti ṣe alábàápádé Jọkẹ́, Ọlọ́run sì fi èso-inú mẹ́rin jíǹkín wọn.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ó mà tó ọjọ́ mẹ́ta kẹ̀\" máa ń' jẹyọ nínú lẹ́tà gẹ́gẹ́ bí", | |
"a": "àkọlẹ́", | |
"b": "ìkíni", | |
"c": "ìkádìí", | |
"d": "kókó lẹ́tà", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Báyọ̀ àti àwọn àbúrò rè méjèèjì jẹ́ ọmọ òrukàn, kò sí olùrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ní àforítì. Báyọ̀ ni ó gbọ́ bùkátà àtilọ sílé ẹ̀kọ́ ara rẹ̀ àti ìtọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ kárakára. Ó tiraka, ó jáde ìwé mẹ́wàá, ó sì ṣe àṣeyọrí. Èyí mú kí ìjọba fún un ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí ìlú òyìnbó. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí Báyọ̀ kúrò ni Ìtelè lọ sí òke òkun, ó gboyè ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣègùn. Ó ṣiṣẹ́ díẹ̀ fún ọdún kan láti lè rí owó tí yóò fi padà wálé nítorí àáyún àwọn àbúrò rẹ̀ ń yun ún.\n\nNí kété tí Báyọ̀ padà sí Nàìjíríà, ìlú l̀bàdàn ni ó ríṣẹ́ sí ní ilé-ìwòsàn ńlá kan. Láìpẹ̀ láìjìnà, ó ti di ìlúmọ̀ọ́ká nínú iṣẹ́ ìṣègùn. Lẹ́nu iṣẹ́ yìí ni ó ti ṣe alábàápádé Jọkẹ́, Ọlọ́run sì fi èso-inú mẹ́rin jíǹkín wọn.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "a ni ó fi àìjẹ̀bi sun àtìmọ́lé?", | |
"a": "Jẹ́jẹ́nìwà", | |
"b": "Jókòótadé", | |
"c": "Ìdògbé", | |
"d": "Mèmúnà", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Orí yeye ní mògún, tàìṣẹ̀ ló pọ̀. ìdògbé ọmọ Mẹ̀múnà ará Ìlórò, ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí. ó jókòó síta láti reti Jókòótadé ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀, tí ó rán ní àkàrà èyí tí yóò fi jẹ ẹ̀kọ.\n\nJẹ́jẹ́nìwà ni àbúrò bàbá Ìdògbé. Àti pínníṣín ni ó ti gba ìdògbé mọ́ra, tí ó sì fí sí ẹnu ìkọ́ṣẹ́ mẹkáníìkì nígbà tí ó pé ọmọ ọdún rnẹ́tàlá. l̀dògbé já fáfá lẹ́nu ìkọ́ṣẹ́, kì í pa ibí iṣẹ́ jẹ, tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀n. Ọmọ tó ṣeé mú yangàn ni. Ní ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí, jíjókòó tí l̀dògbé jókòó sí ìta pẹ̀lú aṣo iṣẹ́ rẹ̀, tí ó dọ̀tí kọjá ààlà, ni ó ṣokùnfà kíkó tí àwọn ọlọ́pàá kó o mọ́ àwọn ẹlẹ́gírí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní àdúgbò kejì. Kí á tó ṣẹ́jú pé, Ìdògbé ti bá ará rẹ̀ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àsìkò wo Ió yẹ kí ayeye bẹ̀rẹ̀?", | |
"a": "Àárọ̀", | |
"b": "Ọ̀sán", | |
"c": "Ìrọ̀lẹ́", | |
"d": "Alẹ́", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́", | |
"b": "Ìgbọ́ràn dára", | |
"c": "Àìmàsìkò ló ń dàmú ẹ̀dá", | |
"d": "Aláàárù Ọjàaba", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "\"Ẹ firun dúdú ṣiṣẹ́.\" Gbólóhún yìí ni bàbá àgbà, Adélabí, máa ń fi ṣí àwọn ọmọọmọ rẹ̀ létí ní gbogbo ìgbà. Ìgbà tí wọ́n bá wá kí i lábúlé Ológo ló máa ń ráyè ṣe èyí. Àyọ̀ká àti Gbénró kọ́kọ́ máa ń kọtí ọ̀gbọn-in sí àwọn ọ̀rọ ìṣítí wọ̀nyí ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ríi pé àwọn ẹ̀gbọ́n wọn, Ọlá àti Bíọ́dún, tó ń tẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ń mókè nínú ẹ̀kọ́ wọn, ni àwọn náà bá yára fara mọ́ ọ. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọláníkẹ̀ẹ́ ní tirẹ̀ kò já gbogbo rẹ̀ kúnra.\n\nNítorí ìdí èyí, kò wá yani lẹ́nu pé nígbà tí wọ́n dàgbà tán, gbogbo àwọn tó tẹ̀lé ọ̀rọ ìṣítí bàbá àgbà ló mókè: wọ́n di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ tí wọ́n yàn Iáàyò; wọ́n wá là, tí wọ́n sì lu. Ọláníkẹ̀ẹ́ ni tirẹ̀ wá gúnlẹ̀ sí Ọjàaba níbi tó ti ń gbàárù.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ẹ̀gbọ́n Tèmiladé ni", | |
"a": "Jídé", | |
"b": "Kọ́lájọ", | |
"c": "Kúnlé", | |
"d": "Ṣeun", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "\"Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!\" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.\n\nLáì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ìpinnu Ayọ̀kúnnú ni pé kí òun", | |
"a": "di oníṣòwò ńlá", | |
"b": "di adájọ́", | |
"c": "múra sí ẹ̀kọ́ òun", | |
"d": "máa ná owó òbí òun", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.\n\nTanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.\n\nNígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Adédọjà jẹ́", | |
"a": "oníṣòwò ńlá", | |
"b": "ọ̀gá-àgbà ilé-ẹ̀kọ́", | |
"c": "gbajúmọ̀ agbẹjọ́rò", | |
"d": "aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.\n\nTanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.\n\nNígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni ìyàwó tí Ṣàngó fẹ́ràn jù", | |
"a": "Ọbà", | |
"b": "Ọya", | |
"c": "Ọ̀ṣun", | |
"d": "Torosi", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.\n\nBí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Kíni a fi \"agbẹ̀du\" wé?", | |
"a": "Ẹja", | |
"b": "Àkùkọ", | |
"c": "Omi", | |
"d": "Ẹyìn", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọdún kelòó ni bàbá Awódélé ti kú?", | |
"a": "Kẹtàlá", | |
"b": "Kẹwàá", | |
"c": "Keje", | |
"d": "Kẹta", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Mọ́tọ̀ mẹ́fà ni Awódélé ní. Pijó kan, Mẹ́sídìsì méjì, Ìsúsù kan, Tòyótà kan àti Jíìpù kan. Mẹ́sídìsì ni ó máa ń gbé lọ síbi iṣẹ́. Tó bá fẹ́ rin ìrìnàjò pàtàkì, Jíìpù ló máa ń gbe lọ. Kàsálí awakọ̀ rẹ̀ ń wa kísà.\n\nỌmọ mẹ́rin ni Awódélé bí: Kọ́ládé làkọ́bí, Àdùkẹ́ làtẹ̀lé, Kọ́lájọ lọ́mọ, kẹta ń jẹ́, Yéwándé làbíkẹ́yìn wọn lénjélénje. Wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì. Gbogbo rẹ̀ sẹ wẹ́kú bí ìdodo ẹfọ̀n. Gbogbo ọmọ tí Ọmọ́yẹni bí fún Awódélé ló yàn tó yanjú. Àwọn àgbà ní \"Ojú tó ríbi tí kò fọ́, ire ló ń dúró dè\" kò sí ẹni tí ó lè rí Awódélé lónìí kó gbàgbọ́ wí pé alágbe ni bàbá rẹ̀. Ọdún kẹta gééré tí bàbá rẹ̀ kú ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹnu re fún un. Ó sì ti wa nínú yọ̀tọ̀mì yìí́ fún ọdún mẹ́wàá gbáko.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ló ta àwọn aráyé jí nípa bí ayé ṣe rí?", | |
"a": "Oníṣọ̀nà", | |
"b": "Géńdé", | |
"c": "Àgbà-ò-kọgbọ́n", | |
"d": "Adélébọ̀", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Òréré ayé, awo ojú\nẸ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó\nẸ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà\nẸ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun\nÀgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí\nỌmọ adáríhunrun sí sàkun ayé\nNítorí ojú làgbà á yá\nÀgbà kan kì í yánu\nẸmọ́ kú, ojú òpó dí\nOníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ\nBó bá wá rí bẹ́ẹ̀\nẸ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀\nÌdí abájọ táyé ò fi gún mọ́\nẸ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́\nÀkàṣù kò yó géńdé\nÀkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún\nÀṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́\nAyé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "ìgbé ayé Adépégà", | |
"b": "Ìrírí àwọn ọmo Adépégà", | |
"c": "Iṣẹ́, ajé", | |
"d": "ìkọ́ṣẹ́yege", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ọmọ mẹ́ta ni Bájọ bí. Adàrán ni àkọ́bí, Dáúdà ni ó tẹ̀le e: Adépégá sì ni àbíkẹ́yìn wọn. Ọjọ́ pẹ́ tí Adépégà ti bá Adàrán lọ sí Owódé lebàá Ìtamọ̀gán níbi ti ́Adàrán tí ń ṣiṣẹ́. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi í ṣẹ́nu ẹ̀kọ́ṣẹ́. Lẹ́yìn tí ó kọ́ṣẹ́ tí ó sì yege, ó kọjá sí Orímẹ̀dù nítòsí Lẹ́kí.\n\nÓ rọ́wọ́ mú níbẹ̀. Ibẹ̀ ni ó sì ti rí Fádékẹ́, ọmọ Fádípè tí ó wá fi ṣaya. Ọlọ́run fi ọ̀pọ̀ ọmọ kẹ́ wọn: Jẹ̀dá, Fẹ́mi, Elísá. Bọ́sẹ̀, Kọ̀yà àti Kọ́lá. Bí ibẹ̀ ṣe gbè é tó, kò gbàgbé ilé. Ó pinu láti padà sí Ìsòmù ìlú abínibí rẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ sì tẹ̀le e.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àyọkò yìí fihàn pé owó jẹ́ [MASK]", | |
"a": "agbéraga", | |
"b": "ọ̀gá", | |
"c": "ìráńṣẹ́", | |
"d": "onítara", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "wó ṣe pàtàkì, ó ṣe kókó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dámọ̀ràn kankan lẹ́yìn òun, síbẹ̀ a gbọdọ̀ mọ̀ pé ìráńṣẹ́ ló jẹ́. Kò yẹ kí ó di ọ̀gá fún ẹnikẹ́ni ti Ọba òkè bá fi ṣe búrùjí fún. Láyé àtijọ́, bí ẹnìkan bá ṣiṣẹ́ tó lówó láàárín ẹbí, gbogbo ẹbi ní yóò jàǹfàní rẹ̀. Ìmọ̀ wọn nípa owó pé kò niran, kò jẹ́ kí wọ́n di agbéraga. Bí àwọn bàbá wa ti ní ìtara iṣẹ́ ajé tó, wọn kì í sábà gbọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́í wá owó. Lóde òní, àwọn ènìyàn ń digunjalẹ̀. wọ́n ń ṣẹ́ṣó, wọ́n ń gbọ́mọ, wọ́n sì ń gbé kokéènì láti lówó.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Kíni ó mú kí ìrìn àjò parí sí èbúté lọ́jọ́ kejì?", | |
"a": "Yànmùyánmú dà wọ́n láàmú", | |
"b": "Epo tán nínú fìtílà", | |
"c": "Àárẹ̀ mú àwọn atukọ̀", | |
"d": "Àyìndé kò mọ̀ ọ́n wẹ̀", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Bọ́lájí kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí", | |
"a": "ó fẹ́ gbé àpótí l̀bò", | |
"b": "kò fẹ́ kówó jẹ", | |
"c": "owó oṣù rẹ̀ tí ó kéré", | |
"d": "kí ó lè ṣòwò kòkó", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ oníràwọ̀ kò ṣe ìpàdé ní gbọ̀ngán ìlú lọ́sàn-án mọ́. Òròoru niwọ́n ń ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní ìdíkọ̀ èrò ní Ajé báyìí. Bọ̀sún ní olórí wọn. Adélàjà ni àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ fà kalẹ̀ láti bá Bọ́lájí du ipò gómìnà nínú ìdìbò tó ń bọ̀. Àdùké faramọ́-ọn kí ẹgbẹ́ fa ọkọ òun sílẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó báálé rẹ̀ kejì ni kí ọkọ wọn yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àlàké so pé ní ìdúnta ni àwọn kan rán jàǹdùkú láti jó ilé àwọn tí ó wà ní Adágbó, ìlú ìyá ọkọ òun. Inú Adélàjà kò dùn sí ìmọ̀ràn aya rẹ̀ rárá. Ó ní kò lè fi juujuu bo òun lójú nítorí Bọ́lájí tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ṣé Àníkẹ́ tí ó dèjè lé Àlàkẹ́ lórí ni ẹ̀gbọ́n Bọ́lájí.\n\nÀwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí fún ipò gómìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló mọ̀ pé ó kówó jẹ níbí iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó fẹ̀yìn rẹ̀ tì. Àwọn àgbà wá fẹ́ kí Ògúnyè ti ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin fà kalẹ̀ bá Bọ́lájí díje. Èyí ló fàá tí àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́ fi ń forí gbárí. Ọwọ́ Alájé kò sì ká ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ sì ti já òwú dí etí, a á lo Adébáyò kó ran wọn mọ. Ọ̀rọ̀ yìí ti pín ẹgbẹ́ Oníràwọ̀ sí méjì, inú fùù, ẹ̀dọ̀ fùù ni gbogbo ẹgbẹ́ wà báyìí. Ìpòlongo ìbò ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí ọ̀rọ̀ Bọ́lájí àti Wàlé fẹ́ di iṣu a-tà-yàn-àn-yàn-àn. Ọbàkan Adélàjà ni Wálé tí ó jẹ́ ìgbákèjì olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin. Wálé náà ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣójà láì ní àbàwọ́n kankan. Òwò kòkó ni Bọ́lájí ń ṣe l'Ékòó báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ti ṣiṣẹ́ ọba rí. \n\nÓ bínú kọ̀wẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọ̀yà tasore tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà nígbà náà. Akùtupu hù lọ́jọ́ tí Bọ́lájí àti Wále pólongo ìbò dé Ajé. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjèèjì fi ìjá pẹ̀ẹ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àbá Onírù ni Adélàjà lọ fara pamọ́ sí. Ọ̀gbọ́n àyínìke ni Adégòkè fi pòórá níbi rògbòdìyàn náà. Ènìyàn méjọ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Ańbàlì, akọ̀wé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin-pẹ̀lú Adéyọ̀mí àbíkẹ́yìn Adélàjà wà lára àwọn tí wọ́n fi orí wọn fọ́ àgbọn rògbòdìyàn náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Kí ni ó bí òwe: orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo. .\" nínú àyọkà yìí", | |
"a": "Àìgbọràn Àlàó", | |
"b": "Bí Àlàó ṣe jẹ́ lọ́wọ́ l̀yá rẹ̀", | |
"c": "Májèlé tí Àlàó gbé jẹ́", | |
"d": "Àyẹ̀wò ara tí Àlàó lọ ṣe", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "\"Orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo, báa wi fọ́mọ ẹni a gbọ́\", èyí ni gbólóhùn tí ó jáde lẹ́nu Àkàndé tí i ṣe bàbá Àlàó, bí ọmọ rẹ̀ tí ń japoró ikú lóríbùsùn ní ilé-Ìwòsàn Márapé ní Dòho.\n\nÀlàó jẹ́ ọmọ ìlú Òkè-Ẹgàn. Láti kékeré ni l̀yápé, l̀yá Àlàó ti bà á jẹ́, nítorí pé ó jẹ́ ògúnná kanṣoṣo tí ó ní. Gbogbo akitiyan Àkàndé ní títọ́ Àlàó sọ́nà ló já sí pàbó. Àlàó jayé alákátá, ó gbé ìwà ìṣekúṣe wọ̀ bí ẹ̀wù. Bí dúdú ti ń wá, ni pupa ń wá sọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀, kódà ó fẹ́rè lè máa gbé wèrè ní àgbésùn. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe ni ó fi hàn pé ó ti kó àrùn-kògbóògùn.\n\nÀlàó gbà pé ikú yá ju ẹ̀sín, èyí ni ó mú un gbé májèlé jẹ, èyí tí ó sọ ọ́ di èró ilé-ìwòsàn.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ìtumọ 'ẹlẹ́gírí ni", | |
"a": "ọlọ́pàá", | |
"b": "olè", | |
"c": "mẹkánìkì", | |
"d": "alákàrà", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Orí yeye ní mògún, tàìṣẹ̀ ló pọ̀. ìdògbé ọmọ Mẹ̀múnà ará Ìlórò, ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí. ó jókòó síta láti reti Jókòótadé ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀, tí ó rán ní àkàrà èyí tí yóò fi jẹ ẹ̀kọ.\n\nJẹ́jẹ́nìwà ni àbúrò bàbá Ìdògbé. Àti pínníṣín ni ó ti gba ìdògbé mọ́ra, tí ó sì fí sí ẹnu ìkọ́ṣẹ́ mẹkáníìkì nígbà tí ó pé ọmọ ọdún rnẹ́tàlá. l̀dògbé já fáfá lẹ́nu ìkọ́ṣẹ́, kì í pa ibí iṣẹ́ jẹ, tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀n. Ọmọ tó ṣeé mú yangàn ni. Ní ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí, jíjókòó tí l̀dògbé jókòó sí ìta pẹ̀lú aṣo iṣẹ́ rẹ̀, tí ó dọ̀tí kọjá ààlà, ni ó ṣokùnfà kíkó tí àwọn ọlọ́pàá kó o mọ́ àwọn ẹlẹ́gírí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní àdúgbò kejì. Kí á tó ṣẹ́jú pé, Ìdògbé ti bá ará rẹ̀ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àwọn àgbà ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí nítorí ó", | |
"a": "ti jalè lẹ́nu iṣẹ́", | |
"b": "ní atìlẹyìn àwọn ọ̀dọ́", | |
"c": "ní ìyàwó púpọ̀", | |
"d": "dà rògbòdìyàn sílẹ̀", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ oníràwọ̀ kò ṣe ìpàdé ní gbọ̀ngán ìlú lọ́sàn-án mọ́. Òròoru niwọ́n ń ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní ìdíkọ̀ èrò ní Ajé báyìí. Bọ̀sún ní olórí wọn. Adélàjà ni àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ fà kalẹ̀ láti bá Bọ́lájí du ipò gómìnà nínú ìdìbò tó ń bọ̀. Àdùké faramọ́-ọn kí ẹgbẹ́ fa ọkọ òun sílẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó báálé rẹ̀ kejì ni kí ọkọ wọn yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àlàké so pé ní ìdúnta ni àwọn kan rán jàǹdùkú láti jó ilé àwọn tí ó wà ní Adágbó, ìlú ìyá ọkọ òun. Inú Adélàjà kò dùn sí ìmọ̀ràn aya rẹ̀ rárá. Ó ní kò lè fi juujuu bo òun lójú nítorí Bọ́lájí tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ṣé Àníkẹ́ tí ó dèjè lé Àlàkẹ́ lórí ni ẹ̀gbọ́n Bọ́lájí.\n\nÀwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí fún ipò gómìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló mọ̀ pé ó kówó jẹ níbí iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó fẹ̀yìn rẹ̀ tì. Àwọn àgbà wá fẹ́ kí Ògúnyè ti ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin fà kalẹ̀ bá Bọ́lájí díje. Èyí ló fàá tí àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́ fi ń forí gbárí. Ọwọ́ Alájé kò sì ká ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ sì ti já òwú dí etí, a á lo Adébáyò kó ran wọn mọ. Ọ̀rọ̀ yìí ti pín ẹgbẹ́ Oníràwọ̀ sí méjì, inú fùù, ẹ̀dọ̀ fùù ni gbogbo ẹgbẹ́ wà báyìí. Ìpòlongo ìbò ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí ọ̀rọ̀ Bọ́lájí àti Wàlé fẹ́ di iṣu a-tà-yàn-àn-yàn-àn. Ọbàkan Adélàjà ni Wálé tí ó jẹ́ ìgbákèjì olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin. Wálé náà ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣójà láì ní àbàwọ́n kankan. Òwò kòkó ni Bọ́lájí ń ṣe l'Ékòó báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ti ṣiṣẹ́ ọba rí. \n\nÓ bínú kọ̀wẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọ̀yà tasore tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà nígbà náà. Akùtupu hù lọ́jọ́ tí Bọ́lájí àti Wále pólongo ìbò dé Ajé. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjèèjì fi ìjá pẹ̀ẹ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àbá Onírù ni Adélàjà lọ fara pamọ́ sí. Ọ̀gbọ́n àyínìke ni Adégòkè fi pòórá níbi rògbòdìyàn náà. Ènìyàn méjọ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Ańbàlì, akọ̀wé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin-pẹ̀lú Adéyọ̀mí àbíkẹ́yìn Adélàjà wà lára àwọn tí wọ́n fi orí wọn fọ́ àgbọn rògbòdìyàn náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Níbo ní Bọ́lá tí ń ṣiṣẹ́?", | |
"a": "Ọlá", | |
"b": "Àpà", | |
"c": "Sọ̀bẹ", | |
"d": "Abraka", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ìlú Ọlá ni Ọláolú ń gbé; ibẹ̀ ló sì bí gbogbo ọmọ rẹ̀ sí. Gbogbo àwọn ọmọ wọ̀nyi ló kàwé dáadáa. Àwọn tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ni Tìjání tí ó jẹ́ akọ-níwájú-adájọ́. Bọ́lá ni adarí ilé iṣẹ́ mádàámidófò kan ní Sọ́bẹ. Lọ́ládé sì ni ọ̀gá àgbà pátápátá ní ilé-ìwòsàn ìjọba ni Àpà. Dáramájà, àkọ́ṣẹ́- igi Ọáolú, ni gííwá ilé okòwò kátàkárà ní ara rẹ̀ ni Sohó. Rẹ̀mí tíí ṣe abígbẹ̀yìn, nìkan ló kù ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ní Abraka. Dáramájà wòye pé ó yẹ kí àwọn yẹ́ bàbá àwọn sí fún iṣẹ́ takuntakun tí ó ṣe lórí ọmọ. Wọ́n fẹnu kò láti fi ayẹyẹ ọjọ́-ìbí yẹ bàbá sí.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ìbòdì ni", | |
"a": "a bí Ìṣọ̀lá sí", | |
"b": "Ìṣọ̀lá ti gboyè ẹlẹ́ẹ̀kejì", | |
"c": "Ìṣọ̀lá tí kàwé mẹ́wàá", | |
"d": "Ìṣọ̀lá ti ń ṣiṣẹ́ agbẹjọ́rò", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ọmọ bíbí ìlú Béyìíòṣe ni Ìṣọ̀lá. Òun àti àbúrò rẹ̀ Fọláhànmí, nìkan ni Bádéjọ, bàbá wọ́n bí. Àgbẹ̀ oníkòkó aládàáńlá ni Bádéjọ. Bọ́látitó, aya rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò obì. Bádéjọ kò kàwé ṣùgbọ́n ó pinnu láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjéèjì débi tí wọ́n bá lè kàwé dé láyé, nítorí pé ìya àìkàwé jẹ ẹ́ púpọ̀ nídi òwò tí ó ń ṣe.\n\nLẹ́yìn tí Ìṣọ̀lá parí ìwé mẹ́wàá ní ìlú l̀bòdì ni ó gba ìlú Arómisá lọ láti tẹ̀ síwáiú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní fásitì. Ìlú ọbá ni ó sì ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kejì nínú òfin. Ìṣọ̀lá padà sílúu Béyìíròṣe, ó sì di gbajúgbajà agbẹjọ́rò káàkiri agbègbè náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni ó ṣe agbátẹrù ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́.", | |
"a": "Ọ̀rẹ́wùmí", | |
"b": "Kọ́ládé", | |
"c": "Pẹ̀lúmi", | |
"d": "Mákànánjúọlá", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún\nsí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.\n\nInú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere\nláìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Tanímọ̀la ni ó di", | |
"a": "atọrọjẹ nígbẹ̀yìn", | |
"b": "aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́", | |
"c": "agbẹjọ́rò pàtàkì", | |
"d": "ọ̀gá-àgbà ilé-ẹ̀kọ́", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.\n\nTanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.\n\nNígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni ó dá oko igbó", | |
"a": "Adédùntán", | |
"b": "Adúlójù", | |
"c": "Ọláòṣéépín", | |
"d": "Ọlátẹ́jú", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ló féyàwó gbẹ̀yìn?", | |
"a": "Démọ́lá", | |
"b": "Délé", | |
"c": "Kínyọ", | |
"d": "Láyí", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Nígbà ìwáṣẹ̀ bí ọmọkùnrin bá tó níyàwó, àwọn obí rẹ̀ yóò wáya fún un ṣùgbọ́n lóde òní. ojú awo ni awo fí ń gbọbẹ́. Èyí ni Láyí kò ṣe fi òjò Déwálé àti lyùnadé gbin ọkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fé kí Láyi ni irú láyé, bí i ti Démọ́lá àti Àkàndé, tí wọ́n bí sí Ìdọ̀gọ̀ níbi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí.\nLáyí tí ń dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ ará rẹ̀ nígbà tí Déwálé lọ dáko ẹgan ní Kétu ní ibi tí lyùnadé tí ń ṣiṣẹ́ olùkọ́.\n\nLádépò ni a ti bí Láyi ṣùgbọ́n Ìpólé ni ó ń gbé báyìí. Láti ìgbà tí ó ti di ọmọ òrukàn ni Déwálé àti Iyùnadé ti gbà á tọ́. Ní ìlú yìí kan náà ni ó ti ṣe alábàápàdé Fúnmilọ́lá, Ṣadé, Tọ́lá àti Yẹ́misí tí ó sì yan Fúnmilọ́lá, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyò. Èrò ọkàn àwọn alágbàtọ́ Láyí ni pé bí wọ́n ṣe fẹ́yàwó fún Àkàndé àti Démọ́lá tí gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò náà ni kí wọ́n ṣe fún un, ṣùgbọ́n ibi wọ́n fi ojú sí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ.\n\nÀsìkò tí Láyí gbéyàwó rọ̀ ọ́ lọ́rùn ju ti àwọn irò rẹ̀ tí ó fi ìkánjú lábẹ̀ gbígbóná. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí Délé tí ń wáṣẹ́ ló ti bá ọmọbìnrin kan pàdé. Wón ṣeré oge, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ di tọkọtaya ṣùgbọ́n ará ò rokùn, ará ò radìyẹ. Bákan náà ni Kínyọ fi afẹ́ ayé kojú sí bùkátà mọ́to kí ó tó to ilé rẹ̀, bùkátà wá wó lu ara wọn ṣùgbọ́n ti Láyí yàtọ̀ gédégédé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó Láyí, ó ríṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́ kan. Èyí ló mú un pinnu láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí Ayédáadé níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́. Lára àwọn ọmọ tí Olórun fi jíǹkí rẹ̀ ni Dékémi, tíi ṣe ọmọlójú rẹ̀. Nítorí l̀jáfárá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́., Láyí di ọ̀gá pátápátá láìpẹ́. Ó kọ́lẹ́, ó ra mọ́tò. l̀yàwó rẹ̀ náà sì di oníṣòwò ńlá tí àwọn aláròóbò ń ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Ayẹyẹ jíjó-kí-ọba", | |
"b": "Bírà àwọn akọrin", | |
"c": "ljó àwọn Ẹgbẹ́", | |
"d": "Àwọn àlejò Kábíyèsí", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ohun gbogbo ló ni àsìkò tirẹ̀. Nígbà tí àsìkò tó fún àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ wọ̀nyí láti jó kí ọba ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wá ríran wò. Ṣé ní ti ẹgbẹ́, wọ́n pọ̀ lọ súà bí ọlá Ọlọ́run: Ìdáǹdè, Ọmọladé, Òmìnira, Ọmọ́yèiú, Bọ́bakẹyẹ, Ajagungbadé, Ọbatèkóbọ̀, Ọbaníbàṣírí, Bọ́bagúntẹ̀, àti bẹ́è bẹ́ẹ̀ lọ.\n\nTí a bá ní kí á máa to àwọn orúkọ ẹgbẹ́ wọ̀nyí bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, yóò gba odindin ojú-ìwé méjì níbi tí wọ́n pọ̀ dé. Bí oníkàlùkù wọn ti ń jáde lọ síwájú kábíyèsí pẹ̀lú ẹ̀bùn wọn lọ́wọ́ ni àwọn òṣèré wọn ń lù tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Músílíù ọmọ Hárúnà Ìṣọ̀lá kọ kísà lórin. Eléré ìbílẹ̀ kan tí wọn ń pè ní Ìdàgẹ̀rẹ̀ náà ko ségè lórin. Orí ẹṣin funfun ni Jẹnẹra Àyìnlá wà tó ń kọrin fún ẹgbẹ́ Ìdáǹdè.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọ̀mọ́ mélòó ni Bọ̀sún bí?", | |
"a": "méjì", | |
"b": "mẹ́tà", | |
"c": "mẹ́rìn", | |
"d": "márùn-ún", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Adékàńńbí ni ó", | |
"a": "ṣe àyẹ̀wò", | |
"b": "sá fún ọ̀rẹ́ rẹ̀", | |
"c": "dá oko", | |
"d": "jẹ̀ ìjẹ ẹ̀líírí", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Kò sí iṣẹ́ tí Ọdẹ́wálé, bàbá Ṣínà, kò lè ṣe. Bí ó tí ń dáko, ló ń dẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ló sì ń ṣe iṣẹ́ káràkátà. Síbẹ̀, ó kàn ń ṣiṣẹ́ bí erin ni, ìjẹ èlíírí ló ń jẹ! Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Tájù, Níyì àti Délé kò tilẹ̀ béèrè rẹ̀ mọ́.\n\nÌdí nìyí tí bàbá rẹ̀, Adékàńńbí, ṣe fééjì kẹ́ẹ̀ta tó gboko àwo lọ láti wádìí ohun tí òun lè ṣe kí ọmọ rẹ̀ lè lu àlùyọ. Babaláwo ló wá ṣí aṣọ lójú eégún nípa ohun tí ó fa sábàbí wàhálà tó ń bá Ọdẹ́wálé fínra. Gbogbo ohun tí babaláwo kà fún un bí ètùtù ni ó ṣe. Ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí dọ́gba fún Ọdẹ́wálé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lù àlùyọ, ọwọ́ rẹ̀ wá tẹ́nu.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Tolú jẹ́ [MASK]", | |
"a": "ẹ̀gbọ́n Tádé", | |
"b": "àbúrò Táyọ̀", | |
"c": "ọkọ Títí", | |
"d": "Dáúdù Akinadé", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "\"Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.\nÀbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.\n\nTádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà\nfi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Nípasẹ àṣà wo ni a fi so Yorùbá di \"ọmọ káàárọ̀-ò-jíire\"?", | |
"a": "Ìmúra", | |
"b": "Ìkíni", | |
"c": "ìpèsè oúnjẹ́", | |
"d": "Irun dídì", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.\n\nLóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!\n\nIrun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àlàkẹ́ fẹ́ kí ọkọ òun yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú nítorí kò", | |
"a": "fẹ́ kí wọ́n tún jó ilé àwọn", | |
"b": "fẹ́ kí ó di gómìnà", | |
"c": "pẹ́ tí ọkọ rẹ̀ fẹ̀yìn tì", | |
"d": "fẹ́ kí ọkọ rẹ̀ dí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ́wọ́", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ oníràwọ̀ kò ṣe ìpàdé ní gbọ̀ngán ìlú lọ́sàn-án mọ́. Òròoru niwọ́n ń ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní ìdíkọ̀ èrò ní Ajé báyìí. Bọ̀sún ní olórí wọn. Adélàjà ni àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ fà kalẹ̀ láti bá Bọ́lájí du ipò gómìnà nínú ìdìbò tó ń bọ̀. Àdùké faramọ́-ọn kí ẹgbẹ́ fa ọkọ òun sílẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó báálé rẹ̀ kejì ni kí ọkọ wọn yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àlàké so pé ní ìdúnta ni àwọn kan rán jàǹdùkú láti jó ilé àwọn tí ó wà ní Adágbó, ìlú ìyá ọkọ òun. Inú Adélàjà kò dùn sí ìmọ̀ràn aya rẹ̀ rárá. Ó ní kò lè fi juujuu bo òun lójú nítorí Bọ́lájí tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ṣé Àníkẹ́ tí ó dèjè lé Àlàkẹ́ lórí ni ẹ̀gbọ́n Bọ́lájí.\n\nÀwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí fún ipò gómìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló mọ̀ pé ó kówó jẹ níbí iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó fẹ̀yìn rẹ̀ tì. Àwọn àgbà wá fẹ́ kí Ògúnyè ti ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin fà kalẹ̀ bá Bọ́lájí díje. Èyí ló fàá tí àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́ fi ń forí gbárí. Ọwọ́ Alájé kò sì ká ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ sì ti já òwú dí etí, a á lo Adébáyò kó ran wọn mọ. Ọ̀rọ̀ yìí ti pín ẹgbẹ́ Oníràwọ̀ sí méjì, inú fùù, ẹ̀dọ̀ fùù ni gbogbo ẹgbẹ́ wà báyìí. Ìpòlongo ìbò ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí ọ̀rọ̀ Bọ́lájí àti Wàlé fẹ́ di iṣu a-tà-yàn-àn-yàn-àn. Ọbàkan Adélàjà ni Wálé tí ó jẹ́ ìgbákèjì olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin. Wálé náà ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣójà láì ní àbàwọ́n kankan. Òwò kòkó ni Bọ́lájí ń ṣe l'Ékòó báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ti ṣiṣẹ́ ọba rí. \n\nÓ bínú kọ̀wẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọ̀yà tasore tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà nígbà náà. Akùtupu hù lọ́jọ́ tí Bọ́lájí àti Wále pólongo ìbò dé Ajé. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjèèjì fi ìjá pẹ̀ẹ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àbá Onírù ni Adélàjà lọ fara pamọ́ sí. Ọ̀gbọ́n àyínìke ni Adégòkè fi pòórá níbi rògbòdìyàn náà. Ènìyàn méjọ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Ańbàlì, akọ̀wé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin-pẹ̀lú Adéyọ̀mí àbíkẹ́yìn Adélàjà wà lára àwọn tí wọ́n fi orí wọn fọ́ àgbọn rògbòdìyàn náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ẹni tí ó ṣokùnfà ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún Tanímọ̀la ni", | |
"a": "Adérọ̀gbà", | |
"b": "Moẹ́erere", | |
"c": "Ayọ̀kúnnú", | |
"d": "Adédọjà", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.\n\nTanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.\n\nNígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Kọ́lájọ ni ó", | |
"a": "sin orílẹ̀-èdè", | |
"b": "Ṣe òwò ọjà", | |
"c": "ṣe ìranù", | |
"d": "ríṣẹ́ tí ó dára", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "\"Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!\" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.\n\nLáì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ohun tó fi Àyìndé lọ́kàn balẹ̀ ni pé àwọn ẹnìkejì rẹ̀ yóò", | |
"a": "di olówó", | |
"b": "ràn án Iọ́wọ́", | |
"c": "gúnlẹ̀ sí èbúté", | |
"d": "rí ẹja pa", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọmọ́wùmi jẹ́ ọmọ [MASK]", | |
"a": "Bísọ́lá", | |
"b": "Ọ̀rẹ́wùmí", | |
"c": "Bánkẹ́", | |
"d": "Adéjọkẹ́", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún\nsí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.\n\nInú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere\nláìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ló máa ń kọrin fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé ẹ̀kọ́ dára?", | |
"a": "Ẹ̀gbọ́n wọn", | |
"b": "Òbí wọn", | |
"c": "Ọ̀rẹ́ wọn", | |
"d": "Tísà wọn", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "\"Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!\" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.\n\nLáì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ẹni tí ó ń sòrò fẹ́ kí àwọn tí a fi joyè jẹ́ awòkọ́ṣe fún àwọn tó", | |
"a": "rí jájẹ ní ìlú", | |
"b": "kù díẹ̀ káà-tó fún", | |
"c": "ń hùwà ìbàjẹ́", | |
"d": "ń bọ ògún ilé àti tìta", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọ̀rọ̀ tí a lè fi rọ́pò ‘dẹ̀gbẹ́’ ni", | |
"a": "da ẹmu", | |
"b": "kọ́ ebè", | |
"c": "ta ọjà", | |
"d": "ṣe ọdẹ", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Kò sí iṣẹ́ tí Ọdẹ́wálé, bàbá Ṣínà, kò lè ṣe. Bí ó tí ń dáko, ló ń dẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ló sì ń ṣe iṣẹ́ káràkátà. Síbẹ̀, ó kàn ń ṣiṣẹ́ bí erin ni, ìjẹ èlíírí ló ń jẹ! Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Tájù, Níyì àti Délé kò tilẹ̀ béèrè rẹ̀ mọ́.\n\nÌdí nìyí tí bàbá rẹ̀, Adékàńńbí, ṣe fééjì kẹ́ẹ̀ta tó gboko àwo lọ láti wádìí ohun tí òun lè ṣe kí ọmọ rẹ̀ lè lu àlùyọ. Babaláwo ló wá ṣí aṣọ lójú eégún nípa ohun tí ó fa sábàbí wàhálà tó ń bá Ọdẹ́wálé fínra. Gbogbo ohun tí babaláwo kà fún un bí ètùtù ni ó ṣe. Ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí dọ́gba fún Ọdẹ́wálé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lù àlùyọ, ọwọ́ rẹ̀ wá tẹ́nu.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àwọn ènìyàn péjọ láti", | |
"a": "bé ìdàgbàsókè ìlú láruge", | |
"b": "gbé ogun ti ìwà ìbàjẹ́", | |
"c": "ṣe ètùtù", | |
"d": "ṣe ayẹyẹ ìfinijoyè", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àmọ̀dá jẹ́ ọmọ ìlú", | |
"a": "Aperin", | |
"b": "Aṣaka", | |
"c": "Ọmọ́là", | |
"d": "Ìlọ̀kọ́", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Ẹlẹ́dàá fi jìnkí àwọn ará abúlé Aṣaka ló sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn di ẹni tí ajé ń bá jẹun. Ṣakaṣaka ni orúkọ baba ńlá wọn tí ó ti ìlú Aperin wa, lẹ́yìn tí ó ti kọ́kọ́ tẹ̀dó sí abúlé Ọmọ́là.\nIlẹ̀ abà yìí tí ó dára jẹ́ kí nǹkan oko wọ́n máa ṣe dáradára, ṣùgbọ́n àwọn olè kò jẹ́ kí wọn ó ri owó tí wọ́n pa ná. Àwọn ará abà yìí náà kò fọwọ́ lẹ́rán, àwọn géndé abà yìí pín ara wọn sí ẹgbẹẹgbẹ́ ojú-lalákan-fi-í -ṣọ́rí. Wọn a máa jáde ní òru, wọn a sì máa ṣọ́ ìlú.\n\nÀṣé Àmọ̀dá ni kòkòrò tí ó ń jẹ̀fọ́. Ìlú Ìlokọ́ ló ti sá wálé. Oko kòkó Kásúmù, baba rẹ̀ tí ó sì sọ pé òún wá jókòó ti férè run tán. Kò wá sí ẹni tí ó torí éyí fura sí i. Kúrá kìí lọ sí oko olè, àmó òun ló máa ń júwe ilé ẹni tí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ta irè-oko fún àwọn apamọlẹ́kún-jayé. Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ṣoṣo ni tolóhun. Ní òru ọjọ́ kan ọwọ́ tẹ díẹ̀ lára àwọn ìgárá náà, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé Àmọ̀dá jẹ́ ọ̀kan lára igi-lẹ́yìn-ọgbà àwọn. Lọ́gán ni wọ́n lọ mú u, tí wọ́n sì fa òun àti àwọn ọmọ-iṣẹ́ rẹ̀ lé ìjọba lọ́wọ́.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni wọ́n ṣe aájò fún", | |
"a": "Ajéwọlé", | |
"b": "Adáhunṣe", | |
"c": "Ọlọ́kùnrùn", | |
"d": "Alágẹmọ", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ọjọ́ kan ṣoṣo òjò a máa borí ọ̀dá. Láìpé Ajéwọlé gbàgbé pé ìgbà kan wà rí tí Tóórẹra ìyàwó òun jẹ́ àgàn tí ó ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ, tí o ń rọ́mọ lẹ́yìn adìe, tí ó bú puru sẹ́kún, tí àwọn ń fojoojúmọ́ ṣèránún ọmọ. Nígbà tí ó yá ọmọ wá pọ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbogbo sì dayọ̀. Ó ti kúrò nínú ò-lóńjẹ-nílé-fi-túlààsì-gbààwẹ̀. Kó máa rù hangogo bí alágẹmọ mọ́. Kó sì máa mì tíẹ́tíẹ́ bí ọlọ́kùnrùn mọ́. Ó kúrò nínú à-ń-mu-hàntúrú, à-ń-ya-ojúlé ààfáà àti adáhunṣe kiri. Adùn sì wá gbẹ̀yìn ewúro fún un.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Èwo ni òótọ́?", | |
"a": "Oníṣòwò ni Ajírọ́lá", | |
"b": "Akọ̀wé àgbà ni\nMobọ́lárìn", | |
"c": "Akin jẹ́ ọmọ Owóṣeéní", | |
"d": "Ajírọ́lá ṣe ayẹyẹ\nọjọ́ ìbí rẹ̀", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Adépìtàn ni ó", | |
"a": "fa màlúù kalẹ̀", | |
"b": "dá ilé-iṣẹ́ sílẹ̀", | |
"c": "gbàgbé ilé", | |
"d": "ṣèlérí aàbò", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Ọdún kejìlá rè é tí Adébáre, Adéyanjú àti Adéoyè ti wà ní Tòróńtò, ìlú ọba. Gbogbo wọn ló ti lówó. Adébáre nìkan ni ó pinnu láti wá dá ilé-iṣẹ́ sílẹ̀ ní Ajélàńwá, ìlú rẹ̀, nítorí pé ilé làbọ̀ ìsinmi oko. Ó sì tún rò pé yóò fún àwọn ará ìlú rẹ̀ ní àǹfààní láti ríṣẹ́ àti òwò ṣe.\n\nNí ọjọ́ ìṣílé-iṣẹ́ yìí, ìlú kún fọ́nfọ́n, ayé gbọ́ ọ̀rún sì mọ̀. Màlúù méjì ni ọba Àkànní, Alájé ti Ajélàńwá rà kalẹ̀ nítorí ìdùnnú tí ó ṣubú layọ̀ fún un pé àsìkò òun ni ilé-iṣẹ́ wọ̀lú. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Adébáre fún àìgbàgbé ilé. Ó sì ṣí ilé-iṣẹ́ náà nípa gígé aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ tí a ta sí ẹnu ọ̀nà.\n\nNínú ilé-iṣẹ́ yìí ni a ti rí oríṣiríṣi ẹ̀ka bíi aṣọ híhun, ike ṣíṣe, búrẹ́dì ṣíṣe, abọ́ ìjẹun ṣíṣe àti ṣíṣe omi amọ́lóló. Àdépìtàn tí ó jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá ní agbègbè yìí ṣèlérí ìpèse ààbò tó péye fún ilé-iṣẹ́ náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ilé ìfowópamọ́ wo ni àwọn ọlọ́ṣà náà bẹ́wọ̀ ṣìkejì?", | |
"a": "Afúyẹ́gẹgẹ", | |
"b": "Ọmọlèrè", | |
"c": "Owólòwò", | |
"d": "Tẹ́wọ́gbare", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.\n\nIlé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí\nAfúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.\n\nOwó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni Déwálé", | |
"a": "Awakọ̀", | |
"b": "Tíṣà", | |
"c": "Àgbẹ̀", | |
"d": "Onísòwò", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Nígbà ìwáṣẹ̀ bí ọmọkùnrin bá tó níyàwó, àwọn obí rẹ̀ yóò wáya fún un ṣùgbọ́n lóde òní. ojú awo ni awo fí ń gbọbẹ́. Èyí ni Láyí kò ṣe fi òjò Déwálé àti lyùnadé gbin ọkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fé kí Láyi ni irú láyé, bí i ti Démọ́lá àti Àkàndé, tí wọ́n bí sí Ìdọ̀gọ̀ níbi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí.\nLáyí tí ń dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ ará rẹ̀ nígbà tí Déwálé lọ dáko ẹgan ní Kétu ní ibi tí lyùnadé tí ń ṣiṣẹ́ olùkọ́.\n\nLádépò ni a ti bí Láyi ṣùgbọ́n Ìpólé ni ó ń gbé báyìí. Láti ìgbà tí ó ti di ọmọ òrukàn ni Déwálé àti Iyùnadé ti gbà á tọ́. Ní ìlú yìí kan náà ni ó ti ṣe alábàápàdé Fúnmilọ́lá, Ṣadé, Tọ́lá àti Yẹ́misí tí ó sì yan Fúnmilọ́lá, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyò. Èrò ọkàn àwọn alágbàtọ́ Láyí ni pé bí wọ́n ṣe fẹ́yàwó fún Àkàndé àti Démọ́lá tí gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò náà ni kí wọ́n ṣe fún un, ṣùgbọ́n ibi wọ́n fi ojú sí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ.\n\nÀsìkò tí Láyí gbéyàwó rọ̀ ọ́ lọ́rùn ju ti àwọn irò rẹ̀ tí ó fi ìkánjú lábẹ̀ gbígbóná. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí Délé tí ń wáṣẹ́ ló ti bá ọmọbìnrin kan pàdé. Wón ṣeré oge, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ di tọkọtaya ṣùgbọ́n ará ò rokùn, ará ò radìyẹ. Bákan náà ni Kínyọ fi afẹ́ ayé kojú sí bùkátà mọ́to kí ó tó to ilé rẹ̀, bùkátà wá wó lu ara wọn ṣùgbọ́n ti Láyí yàtọ̀ gédégédé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó Láyí, ó ríṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́ kan. Èyí ló mú un pinnu láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí Ayédáadé níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́. Lára àwọn ọmọ tí Olórun fi jíǹkí rẹ̀ ni Dékémi, tíi ṣe ọmọlójú rẹ̀. Nítorí l̀jáfárá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́., Láyí di ọ̀gá pátápátá láìpẹ́. Ó kọ́lẹ́, ó ra mọ́tò. l̀yàwó rẹ̀ náà sì di oníṣòwò ńlá tí àwọn aláròóbò ń ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ẹyẹ kú torí èso, 'èso' tọ́ka sí", | |
"a": "obìnrin", | |
"b": "àjẹ́", | |
"c": "ọlá", | |
"d": "ọmọ", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Háà Òyéfèsọ̀! Ibi tí ó wà parí àjò ayé rẹ̀ sì rèé. Gbogbo ẹbí ló bá ọ sọ̀rọ̀ pé ìwọ̀nba là ń jẹ lájá tó sínwín kú Àríkọ́gbọ́n ni irú rẹ̀ jẹ́ fún àwọn òróbìnrin-dórí.\n\nNítorí pé o bá ọlá nílé, ó sọ ará rẹ̀ di àkẹ́ra ọmọ, ó wá ń pààrọ̀ abo bí ẹni pààrọ̀ aṣọ. Èyí tó tílẹ̀ wá burú jù ni pé bí ó bá fẹ́ fẹ́ obìnrin, èwó ni ti l̀yàwó Ọláifá. O kò lóògùn ìrìndò, ò ń jẹ aáyán. Bàbá sọ lọ́jọ́ náà pé òun yóò fi àjùlọ hàn ọ́, àwa ni ò fura. Àjẹ́ ké lánàá, ọmọ kú lónìí, ta ni kò mọ̀ pé àjé àná ló pọmọ jẹ, Ohun tí ó ṣe òkùnfà ikú Òyéfẹ̀sọ̀ nìyí. Ẹyẹ, kú torí èso.\nÀjálù burúkú ni ikú Òyéfẹ̀sọ̀ jẹ́ fún Àjàní àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Àmọ̀kẹ́. Àtigbọ́ bùkátà l̀yàwọ́ méjì àti ọmọ márún-ún tí olóògbé fi sílẹ̀ wá di ti ìyá òkú àti Àjàní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ibo ni ìlú Adépégà?", | |
"a": "Owódé", | |
"b": "Ìsòmù", | |
"c": "Ìtamọ̀gán", | |
"d": "Orímẹdù", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ọmọ mẹ́ta ni Bájọ bí. Adàrán ni àkọ́bí, Dáúdà ni ó tẹ̀le e: Adépégá sì ni àbíkẹ́yìn wọn. Ọjọ́ pẹ́ tí Adépégà ti bá Adàrán lọ sí Owódé lebàá Ìtamọ̀gán níbi ti ́Adàrán tí ń ṣiṣẹ́. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi í ṣẹ́nu ẹ̀kọ́ṣẹ́. Lẹ́yìn tí ó kọ́ṣẹ́ tí ó sì yege, ó kọjá sí Orímẹ̀dù nítòsí Lẹ́kí.\n\nÓ rọ́wọ́ mú níbẹ̀. Ibẹ̀ ni ó sì ti rí Fádékẹ́, ọmọ Fádípè tí ó wá fi ṣaya. Ọlọ́run fi ọ̀pọ̀ ọmọ kẹ́ wọn: Jẹ̀dá, Fẹ́mi, Elísá. Bọ́sẹ̀, Kọ̀yà àti Kọ́lá. Bí ibẹ̀ ṣe gbè é tó, kò gbàgbé ilé. Ó pinu láti padà sí Ìsòmù ìlú abínibí rẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ sì tẹ̀le e.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni", | |
"a": "Fífi ara wé ẹlòmìíràn", | |
"b": "Níní ìfẹ́ owó jù", | |
"c": "Gbígbé ẹ̀bi fún aláre", | |
"d": "Kíki ọwọ́ bọ àpò alápò", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù\nỌgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò\nKò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù\nBá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́ \nBí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn \nBí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre \nBí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ \nBí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà\nWò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ \nMo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn \nÌfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀ \nAláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru\nÀwọn tí kìí fojú róhun olóhun\nAlágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó\nẸni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé\nẸyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò\nÈyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin\nỌ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni ó sọ pé ẹnu àgbà ń rùn?", | |
"a": "Àyọ̀ká", | |
"b": "Gbénró", | |
"c": "Ọláníkẹ̀ẹ́", | |
"d": "Bíọ́dún", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "\"Ẹ firun dúdú ṣiṣẹ́.\" Gbólóhún yìí ni bàbá àgbà, Adélabí, máa ń fi ṣí àwọn ọmọọmọ rẹ̀ létí ní gbogbo ìgbà. Ìgbà tí wọ́n bá wá kí i lábúlé Ológo ló máa ń ráyè ṣe èyí. Àyọ̀ká àti Gbénró kọ́kọ́ máa ń kọtí ọ̀gbọn-in sí àwọn ọ̀rọ ìṣítí wọ̀nyí ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ríi pé àwọn ẹ̀gbọ́n wọn, Ọlá àti Bíọ́dún, tó ń tẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ń mókè nínú ẹ̀kọ́ wọn, ni àwọn náà bá yára fara mọ́ ọ. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọláníkẹ̀ẹ́ ní tirẹ̀ kò já gbogbo rẹ̀ kúnra.\n\nNítorí ìdí èyí, kò wá yani lẹ́nu pé nígbà tí wọ́n dàgbà tán, gbogbo àwọn tó tẹ̀lé ọ̀rọ ìṣítí bàbá àgbà ló mókè: wọ́n di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ tí wọ́n yàn Iáàyò; wọ́n wá là, tí wọ́n sì lu. Ọláníkẹ̀ẹ́ ni tirẹ̀ wá gúnlẹ̀ sí Ọjàaba níbi tó ti ń gbàárù.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "tiraka’ nínú àyọkà yìí túmọ̀ sí", | |
"a": "rin ìrìnàjò", | |
"b": "fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run", | |
"c": "gbìyànjú", | |
"d": "ra mọ́tò", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ọjọ́ mánigbàgbé, ọjọ́ ayọ̀, lọjọ́ tí Adétutù gbé Adéagbo àti Ajíbíkẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó. Àwọn méjéèjì sì fọpẹ́ fún Ọlọ́run pé àwọ́n ti ipasẹ̀ ọmọ là. Wọn kò bá ọlá nílé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ náà sì kàwé yanjú.\n\nAkintọ̀mídé, àkọ́bí wọn di ọ̀gá onímọ̀-ẹ̀rọ. Adétutù gba oyè ìmò-ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀gùn. Olúwaṣeun di ọ̀mọ̀wé nínú iṣẹ́ olùkọ́ni. Abímbọ́lá, àbíkẹ́yìn wọ́n yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láàyò. Òun nìkan ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn yòókù sì fi òkè-òkun ṣe ibùgbé. Bí Adéagbó àti Ajíbíkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀ ẹe padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ilé tí Abímbọ́lá kọ́ fún wọn ni wọ́n dé sí. Mọ́tò ọ̀bọ̀kún ọlọ́yẹ́ tí Olúwaṣeún rà fún wọn ni ó wá gbé wọn ní pápákọ̀ òfurufú.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "\"Wọn kò fọwọ́ fẹ́ràn\" túmọ̀ sí pé", | |
"a": "wọ́n múra síṣẹ́ oko", | |
"b": "wọ́n fi ìṣòro wọn gún lagídí", | |
"c": "wọ́n ń ṣi láti ìlú kan sí ìkejì", | |
"d": "wọ́n wá ojútùú sí ìṣòro wọn.", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Ẹlẹ́dàá fi jìnkí àwọn ará abúlé Aṣaka ló sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn di ẹni tí ajé ń bá jẹun. Ṣakaṣaka ni orúkọ baba ńlá wọn tí ó ti ìlú Aperin wa, lẹ́yìn tí ó ti kọ́kọ́ tẹ̀dó sí abúlé Ọmọ́là.\nIlẹ̀ abà yìí tí ó dára jẹ́ kí nǹkan oko wọ́n máa ṣe dáradára, ṣùgbọ́n àwọn olè kò jẹ́ kí wọn ó ri owó tí wọ́n pa ná. Àwọn ará abà yìí náà kò fọwọ́ lẹ́rán, àwọn géndé abà yìí pín ara wọn sí ẹgbẹẹgbẹ́ ojú-lalákan-fi-í -ṣọ́rí. Wọn a máa jáde ní òru, wọn a sì máa ṣọ́ ìlú.\n\nÀṣé Àmọ̀dá ni kòkòrò tí ó ń jẹ̀fọ́. Ìlú Ìlokọ́ ló ti sá wálé. Oko kòkó Kásúmù, baba rẹ̀ tí ó sì sọ pé òún wá jókòó ti férè run tán. Kò wá sí ẹni tí ó torí éyí fura sí i. Kúrá kìí lọ sí oko olè, àmó òun ló máa ń júwe ilé ẹni tí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ta irè-oko fún àwọn apamọlẹ́kún-jayé. Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ṣoṣo ni tolóhun. Ní òru ọjọ́ kan ọwọ́ tẹ díẹ̀ lára àwọn ìgárá náà, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé Àmọ̀dá jẹ́ ọ̀kan lára igi-lẹ́yìn-ọgbà àwọn. Lọ́gán ni wọ́n lọ mú u, tí wọ́n sì fa òun àti àwọn ọmọ-iṣẹ́ rẹ̀ lé ìjọba lọ́wọ́.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni ó kéré jù lọ́jọ́ orí?", | |
"a": "Kọ́lájọ", | |
"b": "Yéwándé", | |
"c": "Àdùkẹ́", | |
"d": "Kọ́ládé", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Mọ́tọ̀ mẹ́fà ni Awódélé ní. Pijó kan, Mẹ́sídìsì méjì, Ìsúsù kan, Tòyótà kan àti Jíìpù kan. Mẹ́sídìsì ni ó máa ń gbé lọ síbi iṣẹ́. Tó bá fẹ́ rin ìrìnàjò pàtàkì, Jíìpù ló máa ń gbe lọ. Kàsálí awakọ̀ rẹ̀ ń wa kísà.\n\nỌmọ mẹ́rin ni Awódélé bí: Kọ́ládé làkọ́bí, Àdùkẹ́ làtẹ̀lé, Kọ́lájọ lọ́mọ, kẹta ń jẹ́, Yéwándé làbíkẹ́yìn wọn lénjélénje. Wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì. Gbogbo rẹ̀ sẹ wẹ́kú bí ìdodo ẹfọ̀n. Gbogbo ọmọ tí Ọmọ́yẹni bí fún Awódélé ló yàn tó yanjú. Àwọn àgbà ní \"Ojú tó ríbi tí kò fọ́, ire ló ń dúró dè\" kò sí ẹni tí ó lè rí Awódélé lónìí kó gbàgbọ́ wí pé alágbe ni bàbá rẹ̀. Ọdún kẹta gééré tí bàbá rẹ̀ kú ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹnu re fún un. Ó sì ti wa nínú yọ̀tọ̀mì yìí́ fún ọdún mẹ́wàá gbáko.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "‘ìlàkàkà’", | |
"a": "akitiyan", | |
"b": "ìlérí", | |
"c": "ebe", | |
"d": "ìmúrasílẹ̀", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni", | |
"a": "Ìfẹ́ Owó", | |
"b": "Aàbò ní ilẹ̀ wa", | |
"c": "Àwọn agbófinró", | |
"d": "Eèmọ́ Wọ̀lú", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.\n\nIlé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí\nAfúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.\n\nOwó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ohun tí ó pa àwọn arìnrìn-àjò yìí pọ̀ ni pé wọ́n", | |
"a": "fẹ́ ṣe òògùn owó", | |
"b": "wọ irú ṣòkòtò kan náà", | |
"c": "wá simi ní abúlé wọn", | |
"d": "òòkùn nínú omi", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọ̀rọ̀ tí a lè fi dípò 'pínnísín' nínú àyọkà yìí ni", | |
"a": "ọ̀dọ́", | |
"b": "kékeré", | |
"c": "àgùnbánirò", | |
"d": "àgbà", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Orí yeye ní mògún, tàìṣẹ̀ ló pọ̀. ìdògbé ọmọ Mẹ̀múnà ará Ìlórò, ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí. ó jókòó síta láti reti Jókòótadé ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀, tí ó rán ní àkàrà èyí tí yóò fi jẹ ẹ̀kọ.\n\nJẹ́jẹ́nìwà ni àbúrò bàbá Ìdògbé. Àti pínníṣín ni ó ti gba ìdògbé mọ́ra, tí ó sì fí sí ẹnu ìkọ́ṣẹ́ mẹkáníìkì nígbà tí ó pé ọmọ ọdún rnẹ́tàlá. l̀dògbé já fáfá lẹ́nu ìkọ́ṣẹ́, kì í pa ibí iṣẹ́ jẹ, tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀n. Ọmọ tó ṣeé mú yangàn ni. Ní ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí, jíjókòó tí l̀dògbé jókòó sí ìta pẹ̀lú aṣo iṣẹ́ rẹ̀, tí ó dọ̀tí kọjá ààlà, ni ó ṣokùnfà kíkó tí àwọn ọlọ́pàá kó o mọ́ àwọn ẹlẹ́gírí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní àdúgbò kejì. Kí á tó ṣẹ́jú pé, Ìdògbé ti bá ará rẹ̀ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Báwo ni Títí ṣe jẹ́ sí Akin?", | |
"a": "ọ̀rẹ́", | |
"b": "l̀yá", | |
"c": "ẹ̀gbọ́n", | |
"d": "ọ̀gá", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni Alájé", | |
"a": "Adélàjà", | |
"b": "Bọ́lájí", | |
"c": "Adébàyọ̀", | |
"d": "Ògúnyè", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ oníràwọ̀ kò ṣe ìpàdé ní gbọ̀ngán ìlú lọ́sàn-án mọ́. Òròoru niwọ́n ń ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní ìdíkọ̀ èrò ní Ajé báyìí. Bọ̀sún ní olórí wọn. Adélàjà ni àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ fà kalẹ̀ láti bá Bọ́lájí du ipò gómìnà nínú ìdìbò tó ń bọ̀. Àdùké faramọ́-ọn kí ẹgbẹ́ fa ọkọ òun sílẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó báálé rẹ̀ kejì ni kí ọkọ wọn yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àlàké so pé ní ìdúnta ni àwọn kan rán jàǹdùkú láti jó ilé àwọn tí ó wà ní Adágbó, ìlú ìyá ọkọ òun. Inú Adélàjà kò dùn sí ìmọ̀ràn aya rẹ̀ rárá. Ó ní kò lè fi juujuu bo òun lójú nítorí Bọ́lájí tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ṣé Àníkẹ́ tí ó dèjè lé Àlàkẹ́ lórí ni ẹ̀gbọ́n Bọ́lájí.\n\nÀwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí fún ipò gómìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló mọ̀ pé ó kówó jẹ níbí iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó fẹ̀yìn rẹ̀ tì. Àwọn àgbà wá fẹ́ kí Ògúnyè ti ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin fà kalẹ̀ bá Bọ́lájí díje. Èyí ló fàá tí àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́ fi ń forí gbárí. Ọwọ́ Alájé kò sì ká ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ sì ti já òwú dí etí, a á lo Adébáyò kó ran wọn mọ. Ọ̀rọ̀ yìí ti pín ẹgbẹ́ Oníràwọ̀ sí méjì, inú fùù, ẹ̀dọ̀ fùù ni gbogbo ẹgbẹ́ wà báyìí. Ìpòlongo ìbò ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí ọ̀rọ̀ Bọ́lájí àti Wàlé fẹ́ di iṣu a-tà-yàn-àn-yàn-àn. Ọbàkan Adélàjà ni Wálé tí ó jẹ́ ìgbákèjì olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin. Wálé náà ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣójà láì ní àbàwọ́n kankan. Òwò kòkó ni Bọ́lájí ń ṣe l'Ékòó báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ti ṣiṣẹ́ ọba rí. \n\nÓ bínú kọ̀wẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọ̀yà tasore tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà nígbà náà. Akùtupu hù lọ́jọ́ tí Bọ́lájí àti Wále pólongo ìbò dé Ajé. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjèèjì fi ìjá pẹ̀ẹ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àbá Onírù ni Adélàjà lọ fara pamọ́ sí. Ọ̀gbọ́n àyínìke ni Adégòkè fi pòórá níbi rògbòdìyàn náà. Ènìyàn méjọ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Ańbàlì, akọ̀wé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin-pẹ̀lú Adéyọ̀mí àbíkẹ́yìn Adélàjà wà lára àwọn tí wọ́n fi orí wọn fọ́ àgbọn rògbòdìyàn náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Oṣù tí Títilayọ̀ wọ ilé ọkọ ni ó", | |
"a": "bímọ", | |
"b": "lóyún", | |
"c": "lọ sìnrú ìlú", | |
"d": "lọ mọ Òkeehò", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "\"Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.\nÀbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.\n\nTádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà\nfi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ewó ni ó jẹ mọ́ àròko asọ̀tàn jù?", | |
"a": "Iṣẹ́ àgbẹ̀", | |
"b": "Ewu\nìkóbìnrin jọ ", | |
"c": "Àlàbọrùn fẹ́rẹ̀ dẹ̀wù", | |
"d": "Eré ìdárayá tí\nmo ṣe", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni eléré ìbítè?", | |
"a": "l̀dàgẹ̀rẹ̀", | |
"b": "Músílíù", | |
"c": "Hárúnà", | |
"d": "Àyìnlá", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ohun gbogbo ló ni àsìkò tirẹ̀. Nígbà tí àsìkò tó fún àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ wọ̀nyí láti jó kí ọba ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wá ríran wò. Ṣé ní ti ẹgbẹ́, wọ́n pọ̀ lọ súà bí ọlá Ọlọ́run: Ìdáǹdè, Ọmọladé, Òmìnira, Ọmọ́yèiú, Bọ́bakẹyẹ, Ajagungbadé, Ọbatèkóbọ̀, Ọbaníbàṣírí, Bọ́bagúntẹ̀, àti bẹ́è bẹ́ẹ̀ lọ.\n\nTí a bá ní kí á máa to àwọn orúkọ ẹgbẹ́ wọ̀nyí bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, yóò gba odindin ojú-ìwé méjì níbi tí wọ́n pọ̀ dé. Bí oníkàlùkù wọn ti ń jáde lọ síwájú kábíyèsí pẹ̀lú ẹ̀bùn wọn lọ́wọ́ ni àwọn òṣèré wọn ń lù tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Músílíù ọmọ Hárúnà Ìṣọ̀lá kọ kísà lórin. Eléré ìbílẹ̀ kan tí wọn ń pè ní Ìdàgẹ̀rẹ̀ náà ko ségè lórin. Orí ẹṣin funfun ni Jẹnẹra Àyìnlá wà tó ń kọrin fún ẹgbẹ́ Ìdáǹdè.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni oníṣòwò", | |
"a": "Agboadé", | |
"b": "Ọláìyá", | |
"c": "Bọ́ládé", | |
"d": "Sáúdátù", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Bí àlá ló ń ṣe Bọ́ládé nígbà tí èsì ìbò tí àwọn ará Àlàdé àti agbègbè rẹ̀ dì jáde pé òun ni wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí alága ìjọba ìbíla Ayédé. Èsì ìbò yìí ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu nítorí kò ṣẹni tó tilẹ̀ rò pé ó lè rú-fin-in nítorí pé àgbẹ̀ paraku ni, kò lówó lọ́wọ́ àti pé àwọn lóókọlóókọ nílùú bí Olóyè\nAgboadé, Dọ́kítà Ọláìyá, Lọ́yà ìbídàpọ̀ àti Arábinin Sáúdátù tíí ṣe oníṣòwò pàtàkì ló bá a fi iga gbága.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àyọlọ̀ yìí sọ pé ayé àtijọ́", | |
"a": "kún fún ìbéèrè", | |
"b": "rọ ènìyàn lọ́rùn", | |
"c": "pa ẹmọ́ run", | |
"d": "ni oníṣọ̀nà lára", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Òréré ayé, awo ojú\nẸ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó\nẸ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà\nẸ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun\nÀgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí\nỌmọ adáríhunrun sí sàkun ayé\nNítorí ojú làgbà á yá\nÀgbà kan kì í yánu\nẸmọ́ kú, ojú òpó dí\nOníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ\nBó bá wá rí bẹ́ẹ̀\nẸ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀\nÌdí abájọ táyé ò fi gún mọ́\nẸ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́\nÀkàṣù kò yó géńdé\nÀkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún\nÀṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́\nAyé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ohun tí ó jẹ àyọkà yìí lógún ni pé", | |
"a": "ópò ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó wà ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá", | |
"b": "olè nìkan ni àtìmọ́lé ọlọ́pàá wà fún", | |
"c": "ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò ní lọ láìjìyà", | |
"d": "ẹnikẹ́ni ni ó lè di ẹni àtìmọ́lé ọlọ́pàá", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Orí yeye ní mògún, tàìṣẹ̀ ló pọ̀. ìdògbé ọmọ Mẹ̀múnà ará Ìlórò, ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí. ó jókòó síta láti reti Jókòótadé ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀, tí ó rán ní àkàrà èyí tí yóò fi jẹ ẹ̀kọ.\n\nJẹ́jẹ́nìwà ni àbúrò bàbá Ìdògbé. Àti pínníṣín ni ó ti gba ìdògbé mọ́ra, tí ó sì fí sí ẹnu ìkọ́ṣẹ́ mẹkáníìkì nígbà tí ó pé ọmọ ọdún rnẹ́tàlá. l̀dògbé já fáfá lẹ́nu ìkọ́ṣẹ́, kì í pa ibí iṣẹ́ jẹ, tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀n. Ọmọ tó ṣeé mú yangàn ni. Ní ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí, jíjókòó tí l̀dògbé jókòó sí ìta pẹ̀lú aṣo iṣẹ́ rẹ̀, tí ó dọ̀tí kọjá ààlà, ni ó ṣokùnfà kíkó tí àwọn ọlọ́pàá kó o mọ́ àwọn ẹlẹ́gírí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní àdúgbò kejì. Kí á tó ṣẹ́jú pé, Ìdògbé ti bá ará rẹ̀ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Kí ni akéwì fi ìlà méjì àkọ́kọ́ ewì yìí ṣe?", | |
"a": "Èébú", | |
"b": "Ìmọ̀ràn", | |
"c": "l̀báwí", | |
"d": "Ẹ̀gọ́", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù\nỌgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò\nKò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù\nBá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́ \nBí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn \nBí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre \nBí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ \nBí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà\nWò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ \nMo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn \nÌfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀ \nAláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru\nÀwọn tí kìí fojú róhun olóhun\nAlágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó\nẸni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé\nẸyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò\nÈyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin\nỌ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "l̀yálájé àná ni", | |
"a": "Súọlá", | |
"b": "Bísí", | |
"c": "Yétúndé", | |
"d": "Adúlójù", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Mílíọ̀nù náírà mélòó ni ẹni tí ó ẹe ipò kìíní gbà?", | |
"a": "Ọ̀kan", | |
"b": "Méjì", | |
"c": "Mẹ́tà", | |
"d": "Mẹ́rin", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún\nsí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.\n\nInú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere\nláìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Adáhunṣe", | |
"b": "Òṣìṣẹ́ ìjọba", | |
"c": "Àìsàn wárápá", | |
"d": "Èéfín nìwà", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Ọ̀wọ́n gógó omi ló mú Ṣùbòmí jí ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ó wá àwọn málà lọ láti bá a pọn omi nítorí àwọn aráabí kò mú iná ìjọba tí èrọ amómiwá yóò fi ṣiṣẹ́ wá. Bí Ṣùbòmí ṣe pe málà tí ó ń gbé omi kọjá sí àdúgbò kéjì, ó tajú kán, ó rí apẹ kan àti èròjà inú rẹ̀ ní oríta mẹ́ta. Ẹbọ yìí ni adáhunṣe, ní kí ẹnìkan tí àrún wárápá ń bá jà rú kí wàhálà rẹ̀ lè dópin. Owó ẹyọ, ẹ̀kọ yangan, àkàrà, epo pupa àti ọ̀pọ̀lọpọ̀, owó bébà ẹlẹ́gbẹ̀rún náírà ló wà nínú ìpèsè náà.\n\nṢé ìwà kò ní fi oníwà sílẹ̀. Ṣùbòmí sáré síwájú, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti ṣa bébà owó mẹ́fà, ó fi ẹyọ kan sílè, ó fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Ọ̀rọ̀ yìí jọ málà lójú, ó sì gba ọ̀nà rẹ̀ lọ. Ní kété tí Sùbòmí délé ló bá ṣubú lulẹ̀ tó ń rú itọ́ lẹ́nu. Igbe \"kí ló dé?\" Ni ìyàwó ń ké nígbà tí àwọn irú rẹ̀ ń bomijé lójú. \"Ta -ló dán irú èyí wò?\" ni ìbéèrè àwọn aládùúgbò. Ẹbọ tí Adóníyì ṣe ni ó mú wárápá Sùnmónù san.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àwọn tí a lè pè ní \"amúnibúni-ẹran-ìbíyé\" ni àwọn tí ó \"", | |
"a": "gbé òògùn olóró", | |
"b": "ta ọjà", | |
"c": "bọ ògún", | |
"d": "jẹ oyè", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọlé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni", | |
"a": "ìranù ṣíṣe", | |
"b": "Àìgba ìmọ̀ràn", | |
"c": "Ìsìnrú ìlú", | |
"d": "Ọjà títà", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "\"Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!\" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.\n\nLáì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni àjẹ́ tí ó pọmọ jẹ nínú àyọkà yìí", | |
"a": "Àmọ̀kẹ́", | |
"b": "Àjàní", | |
"c": "Ọláifá", | |
"d": "l̀yàwó", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Háà Òyéfèsọ̀! Ibi tí ó wà parí àjò ayé rẹ̀ sì rèé. Gbogbo ẹbí ló bá ọ sọ̀rọ̀ pé ìwọ̀nba là ń jẹ lájá tó sínwín kú Àríkọ́gbọ́n ni irú rẹ̀ jẹ́ fún àwọn òróbìnrin-dórí.\n\nNítorí pé o bá ọlá nílé, ó sọ ará rẹ̀ di àkẹ́ra ọmọ, ó wá ń pààrọ̀ abo bí ẹni pààrọ̀ aṣọ. Èyí tó tílẹ̀ wá burú jù ni pé bí ó bá fẹ́ fẹ́ obìnrin, èwó ni ti l̀yàwó Ọláifá. O kò lóògùn ìrìndò, ò ń jẹ aáyán. Bàbá sọ lọ́jọ́ náà pé òun yóò fi àjùlọ hàn ọ́, àwa ni ò fura. Àjẹ́ ké lánàá, ọmọ kú lónìí, ta ni kò mọ̀ pé àjé àná ló pọmọ jẹ, Ohun tí ó ṣe òkùnfà ikú Òyéfẹ̀sọ̀ nìyí. Ẹyẹ, kú torí èso.\nÀjálù burúkú ni ikú Òyéfẹ̀sọ̀ jẹ́ fún Àjàní àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Àmọ̀kẹ́. Àtigbọ́ bùkátà l̀yàwọ́ méjì àti ọmọ márún-ún tí olóògbé fi sílẹ̀ wá di ti ìyá òkú àti Àjàní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni wàhálà rẹ̀ dópin?", | |
"a": "Òṣìṣẹ́ ìjọba", | |
"b": "Málà", | |
"c": "Ṣùbòmí", | |
"d": "Sùnmónù", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Ọ̀wọ́n gógó omi ló mú Ṣùbòmí jí ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ó wá àwọn málà lọ láti bá a pọn omi nítorí àwọn aráabí kò mú iná ìjọba tí èrọ amómiwá yóò fi ṣiṣẹ́ wá. Bí Ṣùbòmí ṣe pe málà tí ó ń gbé omi kọjá sí àdúgbò kéjì, ó tajú kán, ó rí apẹ kan àti èròjà inú rẹ̀ ní oríta mẹ́ta. Ẹbọ yìí ni adáhunṣe, ní kí ẹnìkan tí àrún wárápá ń bá jà rú kí wàhálà rẹ̀ lè dópin. Owó ẹyọ, ẹ̀kọ yangan, àkàrà, epo pupa àti ọ̀pọ̀lọpọ̀, owó bébà ẹlẹ́gbẹ̀rún náírà ló wà nínú ìpèsè náà.\n\nṢé ìwà kò ní fi oníwà sílẹ̀. Ṣùbòmí sáré síwájú, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti ṣa bébà owó mẹ́fà, ó fi ẹyọ kan sílè, ó fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Ọ̀rọ̀ yìí jọ málà lójú, ó sì gba ọ̀nà rẹ̀ lọ. Ní kété tí Sùbòmí délé ló bá ṣubú lulẹ̀ tó ń rú itọ́ lẹ́nu. Igbe \"kí ló dé?\" Ni ìyàwó ń ké nígbà tí àwọn irú rẹ̀ ń bomijé lójú. \"Ta -ló dán irú èyí wò?\" ni ìbéèrè àwọn aládùúgbò. Ẹbọ tí Adóníyì ṣe ni ó mú wárápá Sùnmónù san.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Délé ni", | |
"a": "ó bá enìkan ṣeré ìfẹ́", | |
"b": "ó dáko ẹgàn", | |
"c": "bùkátà rẹ̀ wó lura wọn", | |
"d": "ó ra mọ́tò", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Nígbà ìwáṣẹ̀ bí ọmọkùnrin bá tó níyàwó, àwọn obí rẹ̀ yóò wáya fún un ṣùgbọ́n lóde òní. ojú awo ni awo fí ń gbọbẹ́. Èyí ni Láyí kò ṣe fi òjò Déwálé àti lyùnadé gbin ọkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fé kí Láyi ni irú láyé, bí i ti Démọ́lá àti Àkàndé, tí wọ́n bí sí Ìdọ̀gọ̀ níbi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí.\nLáyí tí ń dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ ará rẹ̀ nígbà tí Déwálé lọ dáko ẹgan ní Kétu ní ibi tí lyùnadé tí ń ṣiṣẹ́ olùkọ́.\n\nLádépò ni a ti bí Láyi ṣùgbọ́n Ìpólé ni ó ń gbé báyìí. Láti ìgbà tí ó ti di ọmọ òrukàn ni Déwálé àti Iyùnadé ti gbà á tọ́. Ní ìlú yìí kan náà ni ó ti ṣe alábàápàdé Fúnmilọ́lá, Ṣadé, Tọ́lá àti Yẹ́misí tí ó sì yan Fúnmilọ́lá, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyò. Èrò ọkàn àwọn alágbàtọ́ Láyí ni pé bí wọ́n ṣe fẹ́yàwó fún Àkàndé àti Démọ́lá tí gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò náà ni kí wọ́n ṣe fún un, ṣùgbọ́n ibi wọ́n fi ojú sí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ.\n\nÀsìkò tí Láyí gbéyàwó rọ̀ ọ́ lọ́rùn ju ti àwọn irò rẹ̀ tí ó fi ìkánjú lábẹ̀ gbígbóná. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí Délé tí ń wáṣẹ́ ló ti bá ọmọbìnrin kan pàdé. Wón ṣeré oge, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ di tọkọtaya ṣùgbọ́n ará ò rokùn, ará ò radìyẹ. Bákan náà ni Kínyọ fi afẹ́ ayé kojú sí bùkátà mọ́to kí ó tó to ilé rẹ̀, bùkátà wá wó lu ara wọn ṣùgbọ́n ti Láyí yàtọ̀ gédégédé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó Láyí, ó ríṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́ kan. Èyí ló mú un pinnu láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí Ayédáadé níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́. Lára àwọn ọmọ tí Olórun fi jíǹkí rẹ̀ ni Dékémi, tíi ṣe ọmọlójú rẹ̀. Nítorí l̀jáfárá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́., Láyí di ọ̀gá pátápátá láìpẹ́. Ó kọ́lẹ́, ó ra mọ́tò. l̀yàwó rẹ̀ náà sì di oníṣòwò ńlá tí àwọn aláròóbò ń ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọlátẹ́jú ni ó", | |
"a": "gbin igbó", | |
"b": "ṣe fàyàwọ́", | |
"c": "pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́", | |
"d": "dá ilé-iṣẹ́ ńlá sílẹ̀", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Èwo ni ó bá ayé mulẹ̀?", | |
"a": "Onísọ̀nà", | |
"b": "Ọmi òkun", | |
"c": "Ẹmọ́", | |
"d": "Òréré ayé", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Òréré ayé, awo ojú\nẸ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó\nẸ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà\nẸ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun\nÀgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí\nỌmọ adáríhunrun sí sàkun ayé\nNítorí ojú làgbà á yá\nÀgbà kan kì í yánu\nẸmọ́ kú, ojú òpó dí\nOníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ\nBó bá wá rí bẹ́ẹ̀\nẸ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀\nÌdí abájọ táyé ò fi gún mọ́\nẸ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́\nÀkàṣù kò yó géńdé\nÀkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún\nÀṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́\nAyé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni oyè rẹ̀ jẹ́ mọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́?", | |
"a": "Ọlátẹ́jú", | |
"b": "Tàlàbí", | |
"c": "Yétúndé", | |
"d": "Adédùntán", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àwọn tí ó ń tu ọkọ̀ ni à ń pè ní", | |
"a": "ọlọ́pàá", | |
"b": "jomijòkè", | |
"c": "olóbèlé", | |
"d": "alálùpàyídà", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "ìgbéyàwó Láyí rọ̀ ọ́ lọ́rùn nítorí pé", | |
"a": "kò kánjú láti gbéyàwó", | |
"b": "ó kó lọ sí Ayédáadé", | |
"c": "àwọn alágbàtọ́ rẹ̀ kò sí ní tòsí", | |
"d": "l̀yàwó rẹ̀ rí tajé ṣe", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Nígbà ìwáṣẹ̀ bí ọmọkùnrin bá tó níyàwó, àwọn obí rẹ̀ yóò wáya fún un ṣùgbọ́n lóde òní. ojú awo ni awo fí ń gbọbẹ́. Èyí ni Láyí kò ṣe fi òjò Déwálé àti lyùnadé gbin ọkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fé kí Láyi ni irú láyé, bí i ti Démọ́lá àti Àkàndé, tí wọ́n bí sí Ìdọ̀gọ̀ níbi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí.\nLáyí tí ń dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ ará rẹ̀ nígbà tí Déwálé lọ dáko ẹgan ní Kétu ní ibi tí lyùnadé tí ń ṣiṣẹ́ olùkọ́.\n\nLádépò ni a ti bí Láyi ṣùgbọ́n Ìpólé ni ó ń gbé báyìí. Láti ìgbà tí ó ti di ọmọ òrukàn ni Déwálé àti Iyùnadé ti gbà á tọ́. Ní ìlú yìí kan náà ni ó ti ṣe alábàápàdé Fúnmilọ́lá, Ṣadé, Tọ́lá àti Yẹ́misí tí ó sì yan Fúnmilọ́lá, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyò. Èrò ọkàn àwọn alágbàtọ́ Láyí ni pé bí wọ́n ṣe fẹ́yàwó fún Àkàndé àti Démọ́lá tí gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò náà ni kí wọ́n ṣe fún un, ṣùgbọ́n ibi wọ́n fi ojú sí, ọ̀nà kò gba ibẹ̀ lọ.\n\nÀsìkò tí Láyí gbéyàwó rọ̀ ọ́ lọ́rùn ju ti àwọn irò rẹ̀ tí ó fi ìkánjú lábẹ̀ gbígbóná. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí Délé tí ń wáṣẹ́ ló ti bá ọmọbìnrin kan pàdé. Wón ṣeré oge, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ di tọkọtaya ṣùgbọ́n ará ò rokùn, ará ò radìyẹ. Bákan náà ni Kínyọ fi afẹ́ ayé kojú sí bùkátà mọ́to kí ó tó to ilé rẹ̀, bùkátà wá wó lu ara wọn ṣùgbọ́n ti Láyí yàtọ̀ gédégédé. Lẹ́yìn ìgbéyàwó Láyí, ó ríṣẹ́ sí ilé ìfowópamọ́ kan. Èyí ló mú un pinnu láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí Ayédáadé níbi tí ó tí ń ṣiṣẹ́. Lára àwọn ọmọ tí Olórun fi jíǹkí rẹ̀ ni Dékémi, tíi ṣe ọmọlójú rẹ̀. Nítorí l̀jáfárá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́., Láyí di ọ̀gá pátápátá láìpẹ́. Ó kọ́lẹ́, ó ra mọ́tò. l̀yàwó rẹ̀ náà sì di oníṣòwò ńlá tí àwọn aláròóbò ń ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni Oyèjí́dé máa ń gbìn", | |
"a": "Àgbàdo", | |
"b": "Gbágùúdá", | |
"c": "Iṣu", | |
"d": "Ilá", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Àgbẹ̀ pàtàkì ni Oyèjídé ní agbègbè ìbọ́ṣẹ́. Kì í gbin kòkó, bẹ́ẹ̀ ni kì í gbin ọ̀gẹ̀dẹ̀. Ohun tí ó fi ta àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yọ ni oko àlọ̀ tí ó ń dá. A máa tó ẹgbàá mẹ́rin. Ó máa ń gbin ewùrà díè ṣùgbọ́n èsúrú kì í pọ̀ púpọ̀. Yàtọ̀ si pé ó jé àgbẹ̀, ó tún gbówọ́. Lára àwọn tí ó bà a pààlà ni Àdìsá, Dérìn. Àrẹ̀mú àti Sùúrù. Ọ̀gbìn àgbàdo ni ti Àdìsá, Dérìn a máa dáko rodo; Àrẹ̀mú àti Sùúrù sì gbádùn gbágùúdá àti ilá ní tiwọn.\n\nOlè a máa jà púpọ̀ ní agbègbè yìí. Púpọ̀ nínú àwọn àgbẹ̀ l̀bọ́ṣẹ ti dọdẹ àwọn olè náà títí ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Ọjọó tí ọwọ́ pálábá olè kan máa ségi, oko Oyèjídé ni ó lọ. Lẹ́yìn tí ó tí palẹ̀ oko mọ́ láàjìn, ó gbé ẹrù; ó fẹ́ máa lọ. Bí ó ti gbé ẹrù karí́ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pòòyì lójú kan náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹrù kò ṣée sọ̀. Ibẹ̀ ni ilè mọ bá olórò tí àwọn olóko dé bá a; wọ́n sì mú un lọ sí ilé baálẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Kò-là-kò-sagbe", | |
"b": "ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́", | |
"c": "Bùkátà", | |
"d": "ẹbí Ògúndìran", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Kò-là-kò-sagbe ni Yàyá ọmọ Ògúndìran. Atàpáta-dìde ni ọbàkan rẹ̀, Bísí, ó sì jẹ́ obìnrin. Iṣẹ́ káràkátà ni Yàyá ń ṣe kí ó tó dé ipò tí ó wà yìí. Yàyá ni àbúrò méjì, okùnrin ni àwọn méjèèjì. Àkókò wa ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni, èkejì náà wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama. \n\nYàyá ni ó ń gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ wọ̀nyí láti ìgbà tí ìyàwó wọn ti di olóògbé. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé Ògúndìran wà láyé bí aláìsí ni. Ẹ̀rù yìí pọ̀ fún un láti dá gbé ṣùgbọ́n nítorí pé Ṣọlá jáfáfá lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ, l̀jọba fi ẹ̀kọ́ dá a lọ́lá láti tẹ̀síwájú sí yunifásítì.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Adébáre nìkan ni ó", | |
"a": "rántí ilé", | |
"b": "rí tajé ṣe", | |
"c": "pa màlúù", | |
"d": "lọ sílùú ọba", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ọdún kejìlá rè é tí Adébáre, Adéyanjú àti Adéoyè ti wà ní Tòróńtò, ìlú ọba. Gbogbo wọn ló ti lówó. Adébáre nìkan ni ó pinnu láti wá dá ilé-iṣẹ́ sílẹ̀ ní Ajélàńwá, ìlú rẹ̀, nítorí pé ilé làbọ̀ ìsinmi oko. Ó sì tún rò pé yóò fún àwọn ará ìlú rẹ̀ ní àǹfààní láti ríṣẹ́ àti òwò ṣe.\n\nNí ọjọ́ ìṣílé-iṣẹ́ yìí, ìlú kún fọ́nfọ́n, ayé gbọ́ ọ̀rún sì mọ̀. Màlúù méjì ni ọba Àkànní, Alájé ti Ajélàńwá rà kalẹ̀ nítorí ìdùnnú tí ó ṣubú layọ̀ fún un pé àsìkò òun ni ilé-iṣẹ́ wọ̀lú. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Adébáre fún àìgbàgbé ilé. Ó sì ṣí ilé-iṣẹ́ náà nípa gígé aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ tí a ta sí ẹnu ọ̀nà.\n\nNínú ilé-iṣẹ́ yìí ni a ti rí oríṣiríṣi ẹ̀ka bíi aṣọ híhun, ike ṣíṣe, búrẹ́dì ṣíṣe, abọ́ ìjẹun ṣíṣe àti ṣíṣe omi amọ́lóló. Àdépìtàn tí ó jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá ní agbègbè yìí ṣèlérí ìpèse ààbò tó péye fún ilé-iṣẹ́ náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ibo ni wọ́n ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́?", | |
"a": "Òró", | |
"b": "Àbújá", | |
"c": "Òkeehò", | |
"d": "Ọ̀fà", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "\"Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.\nÀbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.\n\nTádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà\nfi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Ààlà oko", | |
"b": "Ọ̀gbìn àgbàdo", | |
"c": "Àwọn àgbẹ̀ Ìbọ́ṣẹ", | |
"d": "Àwọn olè Ìbọ́ṣẹ", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Àgbẹ̀ pàtàkì ni Oyèjídé ní agbègbè ìbọ́ṣẹ́. Kì í gbin kòkó, bẹ́ẹ̀ ni kì í gbin ọ̀gẹ̀dẹ̀. Ohun tí ó fi ta àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yọ ni oko àlọ̀ tí ó ń dá. A máa tó ẹgbàá mẹ́rin. Ó máa ń gbin ewùrà díè ṣùgbọ́n èsúrú kì í pọ̀ púpọ̀. Yàtọ̀ si pé ó jé àgbẹ̀, ó tún gbówọ́. Lára àwọn tí ó bà a pààlà ni Àdìsá, Dérìn. Àrẹ̀mú àti Sùúrù. Ọ̀gbìn àgbàdo ni ti Àdìsá, Dérìn a máa dáko rodo; Àrẹ̀mú àti Sùúrù sì gbádùn gbágùúdá àti ilá ní tiwọn.\n\nOlè a máa jà púpọ̀ ní agbègbè yìí. Púpọ̀ nínú àwọn àgbẹ̀ l̀bọ́ṣẹ ti dọdẹ àwọn olè náà títí ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Ọjọó tí ọwọ́ pálábá olè kan máa ségi, oko Oyèjídé ni ó lọ. Lẹ́yìn tí ó tí palẹ̀ oko mọ́ láàjìn, ó gbé ẹrù; ó fẹ́ máa lọ. Bí ó ti gbé ẹrù karí́ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pòòyì lójú kan náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹrù kò ṣée sọ̀. Ibẹ̀ ni ilè mọ bá olórò tí àwọn olóko dé bá a; wọ́n sì mú un lọ sí ilé baálẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] ni Awódélé máa ń gbé lo síbi iṣẹ́.", | |
"a": "Jíìpù", | |
"b": "Pijó", | |
"c": "Tòyótà", | |
"d": "Mẹ́sídìsì", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "Mọ́tọ̀ mẹ́fà ni Awódélé ní. Pijó kan, Mẹ́sídìsì méjì, Ìsúsù kan, Tòyótà kan àti Jíìpù kan. Mẹ́sídìsì ni ó máa ń gbé lọ síbi iṣẹ́. Tó bá fẹ́ rin ìrìnàjò pàtàkì, Jíìpù ló máa ń gbe lọ. Kàsálí awakọ̀ rẹ̀ ń wa kísà.\n\nỌmọ mẹ́rin ni Awódélé bí: Kọ́ládé làkọ́bí, Àdùkẹ́ làtẹ̀lé, Kọ́lájọ lọ́mọ, kẹta ń jẹ́, Yéwándé làbíkẹ́yìn wọn lénjélénje. Wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì. Gbogbo rẹ̀ sẹ wẹ́kú bí ìdodo ẹfọ̀n. Gbogbo ọmọ tí Ọmọ́yẹni bí fún Awódélé ló yàn tó yanjú. Àwọn àgbà ní \"Ojú tó ríbi tí kò fọ́, ire ló ń dúró dè\" kò sí ẹni tí ó lè rí Awódélé lónìí kó gbàgbọ́ wí pé alágbe ni bàbá rẹ̀. Ọdún kẹta gééré tí bàbá rẹ̀ kú ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹnu re fún un. Ó sì ti wa nínú yọ̀tọ̀mì yìí́ fún ọdún mẹ́wàá gbáko.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Iku gbígbóná", | |
"b": "Ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́", | |
"c": "Àtunbọ̀tán ìwà", | |
"d": "ìkẹ́kọ̀ọ́gboyè", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Onírúurú akẹ́kọ̀ọ́ ló wà ní lé ẹ̀kọ́ gíga. Àwọn kán wà bíi Túńdé tó ṣe pé fàájì ni wọ́n wá lọ. Àwọn mìíràn bá ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lọ bíi Tóyìn tí wọ́n sì ń ṣe tẹ́rùn. Àwọn kan gbájú mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní tiwọn bíi Tólá, tí àwọn kán sì joyè bá-n-kúnjọ, èyí tí gbogbo ènìyán mọ Tèlé mọ́. Kì í fẹ́ gbé nǹkan kan ṣe. Àwọn kan ní tiwọ́n bá ìmọ̀ àti ìwé kíkà lọ, wón sì kà á dójú àmì gẹ́gẹ́ bíi Tádé, tó máa ń fi gbogbo ọjọ́ ráńtí ọmọ ẹni tí òun í ṣe.\n\nṢé gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ló lérè. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí gbogbo wọ́n ti jáde ilé-ẹ̀kọ́ gíga, Tádé di olùkó pàtàkì nílé-ẹ̀kọ́ gíga, ìjọbá sì ń sanwó gọbọi fún un. Tèlé ní tirẹ̀ kò rí ibì kankan bá wọ̀ ọ́ nítorí ìwé-èrí tí kò múná dóko tó ń gbé kiri. Òkú Tọ́lá ní tirẹ̀ í fẹ́rẹ̀ jẹrà tán nínú sàréè nípasẹ̀ ikú gbígbóná tó ṣàgbákò lọ́dọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀. Tóyìn ti di ẹni àpatì, ó sì rù hàn-n-gogo nítorí àrun kògbóògùn tó kó. Bẹ́ẹ̀ ni àìsan kíndìnrín ń bá Túndé wọ̀yá ìjà nílé-ìwòsàn nítorí otí àti sìgá àmujù rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ìtumọ̀ \"ayé alákátá\" ni ayé", | |
"a": "Aláìsàn", | |
"b": "tó le", | |
"c": "tó lẹ́wà", | |
"d": "ìjẹkújẹ", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "\"Orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo, báa wi fọ́mọ ẹni a gbọ́\", èyí ni gbólóhùn tí ó jáde lẹ́nu Àkàndé tí i ṣe bàbá Àlàó, bí ọmọ rẹ̀ tí ń japoró ikú lóríbùsùn ní ilé-Ìwòsàn Márapé ní Dòho.\n\nÀlàó jẹ́ ọmọ ìlú Òkè-Ẹgàn. Láti kékeré ni l̀yápé, l̀yá Àlàó ti bà á jẹ́, nítorí pé ó jẹ́ ògúnná kanṣoṣo tí ó ní. Gbogbo akitiyan Àkàndé ní títọ́ Àlàó sọ́nà ló já sí pàbó. Àlàó jayé alákátá, ó gbé ìwà ìṣekúṣe wọ̀ bí ẹ̀wù. Bí dúdú ti ń wá, ni pupa ń wá sọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀, kódà ó fẹ́rè lè máa gbé wèrè ní àgbésùn. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe ni ó fi hàn pé ó ti kó àrùn-kògbóògùn.\n\nÀlàó gbà pé ikú yá ju ẹ̀sín, èyí ni ó mú un gbé májèlé jẹ, èyí tí ó sọ ọ́ di èró ilé-ìwòsàn.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni l̀dògbé rán níṣẹ́?", | |
"a": "Jókòótadé", | |
"b": "Mèmúnà", | |
"c": "Jẹ́jẹ́nìwà", | |
"d": "Ọlọ́pàá", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Orí yeye ní mògún, tàìṣẹ̀ ló pọ̀. ìdògbé ọmọ Mẹ̀múnà ará Ìlórò, ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí. ó jókòó síta láti reti Jókòótadé ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀, tí ó rán ní àkàrà èyí tí yóò fi jẹ ẹ̀kọ.\n\nJẹ́jẹ́nìwà ni àbúrò bàbá Ìdògbé. Àti pínníṣín ni ó ti gba ìdògbé mọ́ra, tí ó sì fí sí ẹnu ìkọ́ṣẹ́ mẹkáníìkì nígbà tí ó pé ọmọ ọdún rnẹ́tàlá. l̀dògbé já fáfá lẹ́nu ìkọ́ṣẹ́, kì í pa ibí iṣẹ́ jẹ, tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀n. Ọmọ tó ṣeé mú yangàn ni. Ní ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí, jíjókòó tí l̀dògbé jókòó sí ìta pẹ̀lú aṣo iṣẹ́ rẹ̀, tí ó dọ̀tí kọjá ààlà, ni ó ṣokùnfà kíkó tí àwọn ọlọ́pàá kó o mọ́ àwọn ẹlẹ́gírí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní àdúgbò kejì. Kí á tó ṣẹ́jú pé, Ìdògbé ti bá ará rẹ̀ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ohun takuntakun ti àwọn ti a fi joyè ṣè ni pé wọ́n", | |
"a": "gbógun ti èṣù", | |
"b": "gbé ìdàgbàsókè ìlú láruge", | |
"c": "gbógun ti gbígbé ógùn olóró", | |
"d": "bá ìlú bọ ògùn", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Mo kí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi tí ẹ péjọ̀ síbí lónìí. Inú mi sì dùn jọjọ dé ibi pé bí ènìyàn bá gẹṣin nínú mi olúwarẹ̀ kò ní kọsè. A dájọ́, ọjọ́ pé, a dá ìgbà, ìgbà sì kò. Mo sì dúpẹ́ Iọ́wọ́ Adẹ́dàá nítorí èyí ṣojú wa ná.\n\nNí ìdunta ni irú ayẹyẹ, ìfinijoyè báyìí wáyé gbẹ̀yìn ní ìlú wa yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ènìyàn mẹ́ta péré ni mo fi oyè dá lọ́lá, ṣùgbọ́n lónìí, ènìyàn mẹ́jọ ni n ó já ewé oyè lé lóri - ọkùnrin márùn-ún àtí obìnrin mẹ́ta - fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè ìlú yìí. Mo sì fẹ́ kí eléyìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin tó nífọ̀n tó tún ní èékánná ní ìlú yìí. Ògún ilé ni mo fé kí ẹ kọ́kọ́ máa bẹ̀ kí ẹ tó bẹ tìta, kí ẹ sì jáwọ́ nínú ìwà aláǹgbàá orí èṣù àti ìwà amúnibúni ẹran-ìbíyẹ. Ẹ jáwọ́ nínú ìwà fàyàwọ́ àti òògùn olóró gbígbé kí ẹ má baà ta epo sí àlà orúkọ ìlú wa yìí mọ́. Mo sọ èyí kí ọ̀rọ̀ yín má baà dà bí i ti Adélọjá àti Ọláòṣéépín. Ẹ̀wọ̀n ogún ọdún ni ẹni àkọ́kọ́ tí i ṣe ọmo ìlú Ayépé ń ṣe lọ́wọ́ báyìí fún fàyàwọ́ nígbà tí ẹnìkejì fi ẹ̀yìn tàgbá ní Sòǹdókò fún igbó gbíngbìn.\n\nỌlátẹ́jú tí i ṣe ọ̀gá àgbà ní ilé ìfowópamọ́ òlóògunebí ni yóò jẹ oyè Bàbálájé ìlú wa yìí. Ṣé ẹ kò gbàgbé ilé iṣẹ́ ńlá tó dá sílẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú yìí tí ń ṣiṣẹ́? Oyè Ọ̀tún Bàbálájé ni ti ọ̀rẹ́dẹbí rẹ̀ Adédùntán. Ẹ má gbàgbé pé Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn niwọ́n àti pé Adédùntán tí i ṣe oníṣòwò pàtàkì ti ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó kù díẹ̀ káà-tó fún ní ìlú yìí bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Ìbídàpọ̀ ni ó ti wá. Ọládélé tí ṣe ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí ó ran àwọn ọmọ bíbí ìlú yìí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ ọba ni yóò jẹ oyè Alátùn-únṣe ìlú nígbà tí oníṣègùn Babátúndé yóò di Agbáṣàga. Káńsílọ̀ ètò ẹ̀kó ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí di Olóyè Akéwejẹ̀. Arábìnrin Bísí, aya Adélọdún ni yóò dipò olóogbé Súọlá aya Tẹ̀là gẹ́gẹ́ bí l̀yálájé. Ṣèbí gbogbo wa ni a mọ̀ ón sí gbajúmọ̀ òǹtajà ní ìlú Kánnádopó. llé ìtajà tí ó kọ́ sílẹ̀ wa yìí àti agbègbè rẹ̀ jẹ́ méwàá. Màmá wa Adúlójú ni n ó já ewé oyè Yèyé Ọba lé lórí lónìí, nígbà tí arábìnrin Yétúndé aya Babalọlá, yóò jẹ oyè Onígègé Àrà ìlú Ajégúnlẹ̀ wa yìí láti òní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àròkọ wó ni ènìyàn méjì ti máa ń sọ̀rọ̀ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lẹ́?", | |
"a": "Aṣàríyànjiyàn", | |
"b": "Onísọ̀rọ̀gbèsì", | |
"c": "Ajẹmọ́-ìṣípayá", | |
"d": "Onílẹ́tà", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ọjọ́ kan ṣoṣo òjò a máa borí ọ̀dá. Láìpé Ajéwọlé gbàgbé pé ìgbà kan wà rí tí Tóórẹra ìyàwó òun jẹ́ àgàn tí ó ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ, tí o ń rọ́mọ lẹ́yìn adìe, tí ó bú puru sẹ́kún, tí àwọn ń fojoojúmọ́ ṣèránún ọmọ. Nígbà tí ó yá ọmọ wá pọ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbogbo sì dayọ̀. Ó ti kúrò nínú ò-lóńjẹ-nílé-fi-túlààsì-gbààwẹ̀. Kó máa rù hangogo bí alágẹmọ mọ́. Kó sì máa mì tíẹ́tíẹ́ bí ọlọ́kùnrùn mọ́. Ó kúrò nínú à-ń-mu-hàntúrú, à-ń-ya-ojúlé ààfáà àti adáhunṣe kiri. Adùn sì wá gbẹ̀yìn ewúro fún un.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọ̀kan lára ohun elò fún títà ìgbòkùn ni", | |
"a": "àtùpà amọ̀", | |
"b": "òbèlè", | |
"c": "aṣọ", | |
"d": "ẹyìn imọ́kọ̀", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "ìlú wo ni àwọn adigunjalè ti ṣiṣẹ́ láabi?", | |
"a": "Kórípé", | |
"b": "Tèmípémi", | |
"c": "Ìfẹ́lódùn", | |
"d": "Ṣọ́balójú", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.\n\nIlé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí\nAfúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.\n\nOwó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni ilé rẹ̀ jó?", | |
"a": "Adéwálé", | |
"b": "Adéyọ̀mí", | |
"c": "Adélàjà", | |
"d": "Ògúnyè", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ oníràwọ̀ kò ṣe ìpàdé ní gbọ̀ngán ìlú lọ́sàn-án mọ́. Òròoru niwọ́n ń ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní ìdíkọ̀ èrò ní Ajé báyìí. Bọ̀sún ní olórí wọn. Adélàjà ni àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ fà kalẹ̀ láti bá Bọ́lájí du ipò gómìnà nínú ìdìbò tó ń bọ̀. Àdùké faramọ́-ọn kí ẹgbẹ́ fa ọkọ òun sílẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó báálé rẹ̀ kejì ni kí ọkọ wọn yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àlàké so pé ní ìdúnta ni àwọn kan rán jàǹdùkú láti jó ilé àwọn tí ó wà ní Adágbó, ìlú ìyá ọkọ òun. Inú Adélàjà kò dùn sí ìmọ̀ràn aya rẹ̀ rárá. Ó ní kò lè fi juujuu bo òun lójú nítorí Bọ́lájí tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ṣé Àníkẹ́ tí ó dèjè lé Àlàkẹ́ lórí ni ẹ̀gbọ́n Bọ́lájí.\n\nÀwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí fún ipò gómìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló mọ̀ pé ó kówó jẹ níbí iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó fẹ̀yìn rẹ̀ tì. Àwọn àgbà wá fẹ́ kí Ògúnyè ti ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin fà kalẹ̀ bá Bọ́lájí díje. Èyí ló fàá tí àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́ fi ń forí gbárí. Ọwọ́ Alájé kò sì ká ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ sì ti já òwú dí etí, a á lo Adébáyò kó ran wọn mọ. Ọ̀rọ̀ yìí ti pín ẹgbẹ́ Oníràwọ̀ sí méjì, inú fùù, ẹ̀dọ̀ fùù ni gbogbo ẹgbẹ́ wà báyìí. Ìpòlongo ìbò ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí ọ̀rọ̀ Bọ́lájí àti Wàlé fẹ́ di iṣu a-tà-yàn-àn-yàn-àn. Ọbàkan Adélàjà ni Wálé tí ó jẹ́ ìgbákèjì olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin. Wálé náà ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣójà láì ní àbàwọ́n kankan. Òwò kòkó ni Bọ́lájí ń ṣe l'Ékòó báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ti ṣiṣẹ́ ọba rí. \n\nÓ bínú kọ̀wẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọ̀yà tasore tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà nígbà náà. Akùtupu hù lọ́jọ́ tí Bọ́lájí àti Wále pólongo ìbò dé Ajé. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjèèjì fi ìjá pẹ̀ẹ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àbá Onírù ni Adélàjà lọ fara pamọ́ sí. Ọ̀gbọ́n àyínìke ni Adégòkè fi pòórá níbi rògbòdìyàn náà. Ènìyàn méjọ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Ańbàlì, akọ̀wé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin-pẹ̀lú Adéyọ̀mí àbíkẹ́yìn Adélàjà wà lára àwọn tí wọ́n fi orí wọn fọ́ àgbọn rògbòdìyàn náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni wọ́n yàn bí alága?", | |
"a": "Bọ́ládé", | |
"b": "Agboadé", | |
"c": "Ọláìyá", | |
"d": "Ìbídàpọ̀", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Bí àlá ló ń ṣe Bọ́ládé nígbà tí èsì ìbò tí àwọn ará Àlàdé àti agbègbè rẹ̀ dì jáde pé òun ni wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí alága ìjọba ìbíla Ayédé. Èsì ìbò yìí ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu nítorí kò ṣẹni tó tilẹ̀ rò pé ó lè rú-fin-in nítorí pé àgbẹ̀ paraku ni, kò lówó lọ́wọ́ àti pé àwọn lóókọlóókọ nílùú bí Olóyè\nAgboadé, Dọ́kítà Ọláìyá, Lọ́yà ìbídàpọ̀ àti Arábinin Sáúdátù tíí ṣe oníṣòwò pàtàkì ló bá a fi iga gbága.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "\"'Ògúnná kanṣoṣo\" nínú àyọkà yìí tọ́ka sí", | |
"a": "l̀yápé", | |
"b": "Àlàó", | |
"c": "Àkàndé", | |
"d": "Alákátá", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "\"Orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo, báa wi fọ́mọ ẹni a gbọ́\", èyí ni gbólóhùn tí ó jáde lẹ́nu Àkàndé tí i ṣe bàbá Àlàó, bí ọmọ rẹ̀ tí ń japoró ikú lóríbùsùn ní ilé-Ìwòsàn Márapé ní Dòho.\n\nÀlàó jẹ́ ọmọ ìlú Òkè-Ẹgàn. Láti kékeré ni l̀yápé, l̀yá Àlàó ti bà á jẹ́, nítorí pé ó jẹ́ ògúnná kanṣoṣo tí ó ní. Gbogbo akitiyan Àkàndé ní títọ́ Àlàó sọ́nà ló já sí pàbó. Àlàó jayé alákátá, ó gbé ìwà ìṣekúṣe wọ̀ bí ẹ̀wù. Bí dúdú ti ń wá, ni pupa ń wá sọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀, kódà ó fẹ́rè lè máa gbé wèrè ní àgbésùn. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe ni ó fi hàn pé ó ti kó àrùn-kògbóògùn.\n\nÀlàó gbà pé ikú yá ju ẹ̀sín, èyí ni ó mú un gbé májèlé jẹ, èyí tí ó sọ ọ́ di èró ilé-ìwòsàn.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "ìmọ̀ràn tí a fún Ṣàngó ni pé kí ó", | |
"a": "pa àwọn jagunjagun", | |
"b": "fa ojú àwọn jagunjagun mọ́ra", | |
"c": "dín inú bíbí rẹ̀ ku", | |
"d": "sọ́ra fún àwọn ìyàwó rẹ̀", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.\n\nBí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ilú abínibí Bádéjọ ni", | |
"a": "Ìbòdì", | |
"b": "Arómisá", | |
"c": "Béyìíòṣe", | |
"d": "Ìlú-ọba", | |
"answerKey": "C", | |
"context": "Ọmọ bíbí ìlú Béyìíòṣe ni Ìṣọ̀lá. Òun àti àbúrò rẹ̀ Fọláhànmí, nìkan ni Bádéjọ, bàbá wọ́n bí. Àgbẹ̀ oníkòkó aládàáńlá ni Bádéjọ. Bọ́látitó, aya rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò obì. Bádéjọ kò kàwé ṣùgbọ́n ó pinnu láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjéèjì débi tí wọ́n bá lè kàwé dé láyé, nítorí pé ìya àìkàwé jẹ ẹ́ púpọ̀ nídi òwò tí ó ń ṣe.\n\nLẹ́yìn tí Ìṣọ̀lá parí ìwé mẹ́wàá ní ìlú l̀bòdì ni ó gba ìlú Arómisá lọ láti tẹ̀ síwáiú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní fásitì. Ìlú ọbá ni ó sì ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kejì nínú òfin. Ìṣọ̀lá padà sílúu Béyìíròṣe, ó sì di gbajúgbajà agbẹjọ́rò káàkiri agbègbè náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkólé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni", | |
"a": "Ajá tó sínwín kú", | |
"b": "Ẹni a wí fún", | |
"c": "òògùn ìrìndọ̀", | |
"d": "àwa ni ò fura", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Háà Òyéfèsọ̀! Ibi tí ó wà parí àjò ayé rẹ̀ sì rèé. Gbogbo ẹbí ló bá ọ sọ̀rọ̀ pé ìwọ̀nba là ń jẹ lájá tó sínwín kú Àríkọ́gbọ́n ni irú rẹ̀ jẹ́ fún àwọn òróbìnrin-dórí.\n\nNítorí pé o bá ọlá nílé, ó sọ ará rẹ̀ di àkẹ́ra ọmọ, ó wá ń pààrọ̀ abo bí ẹni pààrọ̀ aṣọ. Èyí tó tílẹ̀ wá burú jù ni pé bí ó bá fẹ́ fẹ́ obìnrin, èwó ni ti l̀yàwó Ọláifá. O kò lóògùn ìrìndò, ò ń jẹ aáyán. Bàbá sọ lọ́jọ́ náà pé òun yóò fi àjùlọ hàn ọ́, àwa ni ò fura. Àjẹ́ ké lánàá, ọmọ kú lónìí, ta ni kò mọ̀ pé àjé àná ló pọmọ jẹ, Ohun tí ó ṣe òkùnfà ikú Òyéfẹ̀sọ̀ nìyí. Ẹyẹ, kú torí èso.\nÀjálù burúkú ni ikú Òyéfẹ̀sọ̀ jẹ́ fún Àjàní àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Àmọ̀kẹ́. Àtigbọ́ bùkátà l̀yàwọ́ méjì àti ọmọ márún-ún tí olóògbé fi sílẹ̀ wá di ti ìyá òkú àti Àjàní.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Orí-ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ àròkọ aṣàpèjúwe ni", | |
"a": "Ààfin ọba ìlú mi", | |
"b": "Owó kò níran", | |
"c": "Ìmọ́tótó", | |
"d": "Ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi tí ó kọjá", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ọjọ́ kan ṣoṣo òjò a máa borí ọ̀dá. Láìpé Ajéwọlé gbàgbé pé ìgbà kan wà rí tí Tóórẹra ìyàwó òun jẹ́ àgàn tí ó ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ, tí o ń rọ́mọ lẹ́yìn adìe, tí ó bú puru sẹ́kún, tí àwọn ń fojoojúmọ́ ṣèránún ọmọ. Nígbà tí ó yá ọmọ wá pọ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbogbo sì dayọ̀. Ó ti kúrò nínú ò-lóńjẹ-nílé-fi-túlààsì-gbààwẹ̀. Kó máa rù hangogo bí alágẹmọ mọ́. Kó sì máa mì tíẹ́tíẹ́ bí ọlọ́kùnrùn mọ́. Ó kúrò nínú à-ń-mu-hàntúrú, à-ń-ya-ojúlé ààfáà àti adáhunṣe kiri. Adùn sì wá gbẹ̀yìn ewúro fún un.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Irúfẹ́ àròkọ, wó ni \"ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ mi\" lè jẹ́?", | |
"a": "Aṣàpèjúwe", | |
"b": "Asọ̀tàn", | |
"c": "Aṣàríyànjiyàn", | |
"d": "Ajẹmọ́-ìṣípayá", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Báyọ̀ àti àwọn àbúrò rè méjèèjì jẹ́ ọmọ òrukàn, kò sí olùrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ní àforítì. Báyọ̀ ni ó gbọ́ bùkátà àtilọ sílé ẹ̀kọ́ ara rẹ̀ àti ìtọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ kárakára. Ó tiraka, ó jáde ìwé mẹ́wàá, ó sì ṣe àṣeyọrí. Èyí mú kí ìjọba fún un ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí ìlú òyìnbó. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí Báyọ̀ kúrò ni Ìtelè lọ sí òke òkun, ó gboyè ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣègùn. Ó ṣiṣẹ́ díẹ̀ fún ọdún kan láti lè rí owó tí yóò fi padà wálé nítorí àáyún àwọn àbúrò rẹ̀ ń yun ún.\n\nNí kété tí Báyọ̀ padà sí Nàìjíríà, ìlú l̀bàdàn ni ó ríṣẹ́ sí ní ilé-ìwòsàn ńlá kan. Láìpẹ̀ láìjìnà, ó ti di ìlúmọ̀ọ́ká nínú iṣẹ́ ìṣègùn. Lẹ́nu iṣẹ́ yìí ni ó ti ṣe alábàápádé Jọkẹ́, Ọlọ́run sì fi èso-inú mẹ́rin jíǹkín wọn.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àwọn òbí pinnu láti máa?", | |
"a": "ṣẹ̀tọ́ fún ọmọ", | |
"b": "ṣe ọjọ́ ìbí\nọmọ ", | |
"c": "kọrin kí ènìyàn", | |
"d": "", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Ajírọ́lá àti àwọn àbúrò rẹ̀ pa ẹnu pò láti sé ọjọ́ ìbí fún bàbá wọn. Gbogbo ìlàkàkà bàbá wọn láti ri pé wọ́n di ẹni ayé ń fẹ́ ni ó wú wọn lórí tí wọ́n fi ṣe ẹ̀yẹ yìí fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ ni Olóyè Bọ̀sún Owóṣeéní ní ilé iṣẹ́ ìjọba, síbẹ̀ kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ọmọ. Bí ó tí ń ṣiṣẹ́ ọba ní Pápákọ̀ náà ni ó ń dáko tí ó sì tún ń gba àjọ.\n\nÀṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀ ló rí jájẹ. Ajírọ́lá di dọ́kítà, Adébọ́lá tí ó tẹ̀lé e jẹ́ akọ̀wé àgbà ní báǹki, nígbà tí Mọbọ́lárìn ń ṣe iṣẹ́ lọ́yà, Akin àbíkẹ́yìn rẹ̀ sì jẹ́, oníṣòwò pàtàkì.\nLọ́gán ni ìmúrasílè fún ayẹyẹ bẹ̀rẹ̀. Olóyè Ṣubúọlá, mọ́gàjí agbo-ilé bàbá wọn, ni àwọn ọmọ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ ayẹyẹ yìí tó létí. Wọ́n sì tún ránṣẹ́ sí Adégbọ́lá, báálẹ̀ Àkùkọ. Ṣé Balógun ìlú Àkùkọ ni Owóṣeéní. Gbogbo ètò bí ayẹyẹ yóò ṣe kẹ́sẹ̀ járí ni wọ́n farabalẹ̀ ṣe. Wọ́n fìwé ìpè ránṣẹ́ sí ẹbí, ará, àtọ̀rẹ́. Wọ́n sì pín bùkátà ayẹyẹ láàárín ará wọn. Nìgbá tí ó yá, ọjọ́ ayẹyẹ kò. Bí wọ́n tí ń sè ni wọ́n ń sọ̀. Ìdajì nínú àwọn obìnrin ilé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin kí ọlọ́jọ́ ìbí lọ́kan-ò-jọ̀kan. \n\nWọ́n wọ aṣọ àǹkárá tí ó jiná, àwọn ọmọ ilé wọ léèsì aláwọ̀ ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán ni ayẹyẹ yóò bẹ̀rẹ̀, agogo mẹ́wáà àárọ̀ ni àwọn tí a fi ìwé pè ti ń dé láti Èkó, ìbàdàn àti Abẹ́òkúta sí Àkùkọ. Tọmọdé tàgbà lo gbédìí fún àwọn ọkọ̀ bọ̀bìnnì bọ̀bìnnì tí ó wọ̀lú lọ́jọ́ náà. Àwọn ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ òbí ló sì tipasẹ̀ ayẹyẹ yìí pinnu láti máa ṣojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sí ọmọ.\n", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Oríṣi irun dídì wo ni a mẹ́nu bà gbẹ̀yìn nínú àyọkà yìí", | |
"a": "Korobá", | |
"b": "Pàtẹ́wọ́", | |
"c": "Kọjúsọ́kọ", | |
"d": "Ṣùkú", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.\n\nLóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!\n\nIrun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọlé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni", | |
"a": "Àṣà Yorùbá ń kú lọ", | |
"b": "Aṣọ wíwọ̀ lóde òní", | |
"c": "Irun dídì nílẹ̀ Yorùbá", | |
"d": "júṣe ọmọ Yorùbá àtàtà", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.\n\nLóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!\n\nIrun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Nínú àwọn tí bàbá àgbá sọ̀rọ̀ ìṣítí fún, mélòó ló mókè?", | |
"a": "Ọ̀kan", | |
"b": "Méjì", | |
"c": "Mẹ́ta", | |
"d": "Mẹ́rin", | |
"answerKey": "D", | |
"context": "\"Ẹ firun dúdú ṣiṣẹ́.\" Gbólóhún yìí ni bàbá àgbà, Adélabí, máa ń fi ṣí àwọn ọmọọmọ rẹ̀ létí ní gbogbo ìgbà. Ìgbà tí wọ́n bá wá kí i lábúlé Ológo ló máa ń ráyè ṣe èyí. Àyọ̀ká àti Gbénró kọ́kọ́ máa ń kọtí ọ̀gbọn-in sí àwọn ọ̀rọ ìṣítí wọ̀nyí ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ríi pé àwọn ẹ̀gbọ́n wọn, Ọlá àti Bíọ́dún, tó ń tẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ń mókè nínú ẹ̀kọ́ wọn, ni àwọn náà bá yára fara mọ́ ọ. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọláníkẹ̀ẹ́ ní tirẹ̀ kò já gbogbo rẹ̀ kúnra.\n\nNítorí ìdí èyí, kò wá yani lẹ́nu pé nígbà tí wọ́n dàgbà tán, gbogbo àwọn tó tẹ̀lé ọ̀rọ ìṣítí bàbá àgbà ló mókè: wọ́n di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ tí wọ́n yàn Iáàyò; wọ́n wá là, tí wọ́n sì lu. Ọláníkẹ̀ẹ́ ni tirẹ̀ wá gúnlẹ̀ sí Ọjàaba níbi tó ti ń gbàárù.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Èwo ni òótọ?", | |
"a": "Ẹgbẹ́ olóṣèlú méjì ló wà", | |
"b": "Ańbàlí ni ilé rẹ̀ jó", | |
"c": "Adélàjà ni ẹ̀gbọ́n Adéyọ̀mi", | |
"d": "Ọba pín ẹgbẹ́ sí méjì", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ oníràwọ̀ kò ṣe ìpàdé ní gbọ̀ngán ìlú lọ́sàn-án mọ́. Òròoru niwọ́n ń ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ ní ìdíkọ̀ èrò ní Ajé báyìí. Bọ̀sún ní olórí wọn. Adélàjà ni àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ fà kalẹ̀ láti bá Bọ́lájí du ipò gómìnà nínú ìdìbò tó ń bọ̀. Àdùké faramọ́-ọn kí ẹgbẹ́ fa ọkọ òun sílẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó báálé rẹ̀ kejì ni kí ọkọ wọn yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àlàké so pé ní ìdúnta ni àwọn kan rán jàǹdùkú láti jó ilé àwọn tí ó wà ní Adágbó, ìlú ìyá ọkọ òun. Inú Adélàjà kò dùn sí ìmọ̀ràn aya rẹ̀ rárá. Ó ní kò lè fi juujuu bo òun lójú nítorí Bọ́lájí tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ṣé Àníkẹ́ tí ó dèjè lé Àlàkẹ́ lórí ni ẹ̀gbọ́n Bọ́lájí.\n\nÀwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ kò fẹ́ kí Adélàjà gbé àpótí fún ipò gómìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló mọ̀ pé ó kówó jẹ níbí iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó fẹ̀yìn rẹ̀ tì. Àwọn àgbà wá fẹ́ kí Ògúnyè ti ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin fà kalẹ̀ bá Bọ́lájí díje. Èyí ló fàá tí àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́ fi ń forí gbárí. Ọwọ́ Alájé kò sì ká ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ọ̀dọ́ sì ti já òwú dí etí, a á lo Adébáyò kó ran wọn mọ. Ọ̀rọ̀ yìí ti pín ẹgbẹ́ Oníràwọ̀ sí méjì, inú fùù, ẹ̀dọ̀ fùù ni gbogbo ẹgbẹ́ wà báyìí. Ìpòlongo ìbò ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí ọ̀rọ̀ Bọ́lájí àti Wàlé fẹ́ di iṣu a-tà-yàn-àn-yàn-àn. Ọbàkan Adélàjà ni Wálé tí ó jẹ́ ìgbákèjì olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin. Wálé náà ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣójà láì ní àbàwọ́n kankan. Òwò kòkó ni Bọ́lájí ń ṣe l'Ékòó báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ti ṣiṣẹ́ ọba rí. \n\nÓ bínú kọ̀wẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí owó ọ̀yà tasore tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà nígbà náà. Akùtupu hù lọ́jọ́ tí Bọ́lájí àti Wále pólongo ìbò dé Ajé. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjèèjì fi ìjá pẹ̀ẹ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àbá Onírù ni Adélàjà lọ fara pamọ́ sí. Ọ̀gbọ́n àyínìke ni Adégòkè fi pòórá níbi rògbòdìyàn náà. Ènìyàn méjọ̀ ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Ańbàlì, akọ̀wé ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ṣin-pẹ̀lú Adéyọ̀mí àbíkẹ́yìn Adélàjà wà lára àwọn tí wọ́n fi orí wọn fọ́ àgbọn rògbòdìyàn náà.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni ọ̀rẹ́ Ọdẹ́wálé?", | |
"a": "Tájù", | |
"b": "Ṣínà", | |
"c": "Babaláwo", | |
"d": "Adékàńńbí", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Kò sí iṣẹ́ tí Ọdẹ́wálé, bàbá Ṣínà, kò lè ṣe. Bí ó tí ń dáko, ló ń dẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ló sì ń ṣe iṣẹ́ káràkátà. Síbẹ̀, ó kàn ń ṣiṣẹ́ bí erin ni, ìjẹ èlíírí ló ń jẹ! Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Tájù, Níyì àti Délé kò tilẹ̀ béèrè rẹ̀ mọ́.\n\nÌdí nìyí tí bàbá rẹ̀, Adékàńńbí, ṣe fééjì kẹ́ẹ̀ta tó gboko àwo lọ láti wádìí ohun tí òun lè ṣe kí ọmọ rẹ̀ lè lu àlùyọ. Babaláwo ló wá ṣí aṣọ lójú eégún nípa ohun tí ó fa sábàbí wàhálà tó ń bá Ọdẹ́wálé fínra. Gbogbo ohun tí babaláwo kà fún un bí ètùtù ni ó ṣe. Ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí dọ́gba fún Ọdẹ́wálé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lù àlùyọ, ọwọ́ rẹ̀ wá tẹ́nu.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ọ̀rọ̀ mìíràn fún 'dọdẹ' nínú àyọkà yìí ni", | |
"a": "sọ́", | |
"b": "pa", | |
"c": "yọ", | |
"d": "nà", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "Àgbẹ̀ pàtàkì ni Oyèjídé ní agbègbè ìbọ́ṣẹ́. Kì í gbin kòkó, bẹ́ẹ̀ ni kì í gbin ọ̀gẹ̀dẹ̀. Ohun tí ó fi ta àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yọ ni oko àlọ̀ tí ó ń dá. A máa tó ẹgbàá mẹ́rin. Ó máa ń gbin ewùrà díè ṣùgbọ́n èsúrú kì í pọ̀ púpọ̀. Yàtọ̀ si pé ó jé àgbẹ̀, ó tún gbówọ́. Lára àwọn tí ó bà a pààlà ni Àdìsá, Dérìn. Àrẹ̀mú àti Sùúrù. Ọ̀gbìn àgbàdo ni ti Àdìsá, Dérìn a máa dáko rodo; Àrẹ̀mú àti Sùúrù sì gbádùn gbágùúdá àti ilá ní tiwọn.\n\nOlè a máa jà púpọ̀ ní agbègbè yìí. Púpọ̀ nínú àwọn àgbẹ̀ l̀bọ́ṣẹ ti dọdẹ àwọn olè náà títí ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Ọjọó tí ọwọ́ pálábá olè kan máa ségi, oko Oyèjídé ni ó lọ. Lẹ́yìn tí ó tí palẹ̀ oko mọ́ láàjìn, ó gbé ẹrù; ó fẹ́ máa lọ. Bí ó ti gbé ẹrù karí́ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pòòyì lójú kan náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹrù kò ṣée sọ̀. Ibẹ̀ ni ilè mọ bá olórò tí àwọn olóko dé bá a; wọ́n sì mú un lọ sí ilé baálẹ̀.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àsìkò wó ni ìrìn àjò bèrè?", | |
"a": "Àárọ̀", | |
"b": "l̀rọ̀lẹ́", | |
"c": "Òru", | |
"d": "Ọ̀sán", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Lẹ́yìn tí Kọ́lá àti Jèrùgbé ti fi ara mọ́ àwọn ènìyàn wọn fún ìgbà díẹ̀, wọ́n mú ṣòkòtò bọ́ láti lọ pe ẹni tí yóò fi irun ajá ṣe òògùn owó fún wọn. Iṣẹ́ onítibí ni láti ṣe ẹ̀dà. Ibi tí ó ń gbé jìnnà sí Ẹrè. Kò sí ọ̀nà méjì tí ó dé ìlú náà jù ojú omi lọ lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ọkọ̀ ojú omi niwọn ní láti dé ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ ọ̀pá àti òbèlè niwọn fi ń wa ọkọ̀, ó gbà wọ́n ní àkókò díẹ̀. Kọ́lá rọ ìyá rẹ̀ láti fún un ní owó díẹ̀ tí ó nílò fún ìrìn àjò yìí.\n\nÒòrùn ti wọ̀ kí àwọn ènìyàn yìí tó 'mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Wọ́n jẹun jẹun yó, wọ́n sì gbé àtùpà amọ̀, okùn, àṣọ àti ọ̀pá sínú ọkọ̀ láti fi ta ìgbòkùn. Ọkọ̀ kékeré tí l̀yá Akin fi máa ń ra ẹja ni wọ́n wọ̀. Akin jókòó sí ẹ̀yìn, Kọ́lá wà ní iwájú. Àyìndé sì lé téé sí orí tẹ́ba ní àárin. Kí wọ́n tó wo ọkọ̀ rẹ̀. Títí fi àdúrà sin Akin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Àyìndé kò wọ ọkọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n wẹ̀, kò lè mòòkùn nínú omi kí á má sọ nípa odò ńlá tí ó na ìyẹ́ láti ìsálú dé Ẹrẹ̀, ṣùgbọ́n kò jáyà. Ọ̀kan rẹ̀ balẹ̀ pé bí ó bá di bákan, àwọn ọ̀rẹ́ òun yóò gba òun là. llẹ̀ ti ṣú kí ọkọ̀ tó kúrò ní èbúté, Akin ni ó sì ń darí ọkọ̀. Iwájú ọkọ̀ niwọ́n gbé àtùpà sí láti máa ríran. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbùsọ̀ mẹ́tàlá, wọ́n yà sí èbúté Ṣabọ́jọ láti sùn.\n\nNígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo ilẹ̀ ni ó kún fún yànmùyánmú, wọ́n ti yó, agbèdu wọn pọ́n dòmùdòmù bí ẹ̀yìn ìmọ̀kọ̀. Gbogbo ará àwọn arìnrìn-àjò wá rí pàtipàti. Wọ́n tu ọkọ̀ títí tí ilẹ̀ fi ṣú ní ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Wọ́n ìbá tẹ̀síwájú ṣùgbọ́n epotó wà nínú fìtílà ti gbẹ. Èyí ló mú kí wọ́n ó tún sún bèbè odò Sanjọ́.Àkùkọ kò ì kọ ṣùgbọ́n òyẹ̀ ti là nígbà tí wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n. Kí òòrùn tó yọ, wọ́n ti gúnlẹ̀ sí èbúté Táǹńwá níbi tí Sòǹdókò ń gbé.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jù ni [MASK]", | |
"a": "Awẹ̀jẹ̀-wẹ̀mu", | |
"b": "Èrè títọ́ ọmọ", | |
"c": "Ọjọ́-ìbí", | |
"d": "ìlú Ọlá", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ìlú Ọlá ni Ọláolú ń gbé; ibẹ̀ ló sì bí gbogbo ọmọ rẹ̀ sí. Gbogbo àwọn ọmọ wọ̀nyi ló kàwé dáadáa. Àwọn tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ni Tìjání tí ó jẹ́ akọ-níwájú-adájọ́. Bọ́lá ni adarí ilé iṣẹ́ mádàámidófò kan ní Sọ́bẹ. Lọ́ládé sì ni ọ̀gá àgbà pátápátá ní ilé-ìwòsàn ìjọba ni Àpà. Dáramájà, àkọ́ṣẹ́- igi Ọáolú, ni gííwá ilé okòwò kátàkárà ní ara rẹ̀ ni Sohó. Rẹ̀mí tíí ṣe abígbẹ̀yìn, nìkan ló kù ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ní Abraka. Dáramájà wòye pé ó yẹ kí àwọn yẹ́ bàbá àwọn sí fún iṣẹ́ takuntakun tí ó ṣe lórí ọmọ. Wọ́n fẹnu kò láti fi ayẹyẹ ọjọ́-ìbí yẹ bàbá sí.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "[MASK] máa ń jẹ́ ìgbésẹ̀ kẹ́ta nínú lẹ́tà àìgbagbẹ̀fẹ̀", | |
"a": "Àdìrẹ́sì akọlẹ́tà", | |
"b": "Ìkíni ìbẹ̀rẹ̀", | |
"c": "Àkọ́lé lẹ́tà", | |
"d": "Orúkọ", | |
"answerKey": "B", | |
"context": "Ọjọ́ kan ṣoṣo òjò a máa borí ọ̀dá. Láìpé Ajéwọlé gbàgbé pé ìgbà kan wà rí tí Tóórẹra ìyàwó òun jẹ́ àgàn tí ó ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ, tí o ń rọ́mọ lẹ́yìn adìe, tí ó bú puru sẹ́kún, tí àwọn ń fojoojúmọ́ ṣèránún ọmọ. Nígbà tí ó yá ọmọ wá pọ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbogbo sì dayọ̀. Ó ti kúrò nínú ò-lóńjẹ-nílé-fi-túlààsì-gbààwẹ̀. Kó máa rù hangogo bí alágẹmọ mọ́. Kó sì máa mì tíẹ́tíẹ́ bí ọlọ́kùnrùn mọ́. Ó kúrò nínú à-ń-mu-hàntúrú, à-ń-ya-ojúlé ààfáà àti adáhunṣe kiri. Adùn sì wá gbẹ̀yìn ewúro fún un.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Àkọ́lé tí ó bá àoykà yìí mu jùlọ ni", | |
"a": "Ìgbéyàwó kan", | |
"b": "Ìsìnrú ìlú", | |
"c": "Ìdílé Akinadé", | |
"d": "Gbígba ọmọ tọ́", | |
"answerKey": "A", | |
"context": "\"Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.\nÀbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.\n\nTádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà\nfi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.", | |
"grade": "SS3", | |
"preamble": "", | |
"category": "Reading comprehension" | |
}, | |
{ | |
"question": "Ta ni àgàn nígbà kan rí?", | |
"a": "Tóórẹra", | |
"b": "Adáhunṣe", | |
"c": "Ààfáà", | |

} | |
] |