diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Ìjọba Burundi fi akẹ́kọ̀ọ́bìnrin sí àtìmọ́lé látàrí ẹ̀sùn ìkọkúkọ sí orí àwòrán ààrẹ. A túwíìtì àwòrán ìkọkúkọ wa ní ìbánikẹ́dùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ijoba Burundi fi akekoobinrin si atimole latari esun ikokuko si ori aworan aare. A tuwiiti aworan ikokuko wa ni ibanikedun isele naa.
Wọ́n ní kí a dán an wò, kí a kọ nǹkan sí orí àwòrán ààrẹ mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Mo ní ìgbóyà wípé ẹnikẹ́ni kò ní mú mi níbí.
Won ni ki a dan an wo, ki a ko nnkan si ori aworan aare mo si se bee. Mo ni igboya wipe enikeni ko ni mu mi nibi.
Ìfòfinlíle mú àtakò
Ifofinlile mu atako
Ìjọba Burundi ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìkanra mú ìwà àtakò láti ọdún 2015, lẹ́yìn ìjákulẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ kan, ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ adìtẹ̀ kan, àtakò lórí ìlòkulò ẹ̀tọ́, òfin kànńpá, ìnira pẹ̀lú ètò ọrọ̀-ajé àti rògbòdìyàn àwọn asásàálà. European Union pẹ̀lú United Nations tako ìgbésẹ̀ Nkurunziza fún sáà kẹ́ta, wọ́n sì béèrè fún ìdápadà ìlọdéédé kí àsìkò ìdìbò ó tó dé. Pẹ̀lú àwọn ìdojúkọ wọ̀nyí, “ipò náà” le sí i. Àwọn aláṣẹ sì ń fi ìkanra mú gbogbo ìhàlẹ̀ tí wọ́n ń rí.
Ijoba Burundi ti bere si i fi ikanra mu iwa atako lati odun 2015, leyin ijakule isote kan, idojuko pelu awon egbe adite kan, atako lori ilokulo eto, ofin kannpa, inira pelu eto oro-aje ati rogbodiyan awon asasaala. European Union pelu United Nations tako igbese Nkurunziza fun saa keta, won si beere fun idapada ilodeede ki asiko idibo o to de. Pelu awon idojuko wonyi, “ipo naa” le si i. Awon alase si n fi ikanra mu gbogbo ihale ti won n ri.
Ìjábọ̀ pàtàkì ti àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn ṣe ní oṣù Èbìbí 2018 rí i pé àwọn èṣọ́ aláàbò ní Burundi, àwọn afòyeṣiṣẹ́ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà nípò, àwọn ẹgbẹ́ Imbone… ń kọlu àwọn alátakò àti àwọn ẹni tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bí alátakò pẹ̀lú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn àti akọ̀ròyìn. “Wọ́n pa èèyàn tó tó 1700, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi ipá lé àwọn ẹlòmíìn, wọ́n ń fi ipá bá wọn ní ìbálòpọ̀, wọ́n ń fi ìyà jẹ wọ́n, wọ́n ń tì wọ́n mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń dẹ́rùba àìmọye àwọn mìíràn”.
Ijabo pataki ti ajo ajafetoo eniyan se ni osu Ebibi 2018 ri i pe awon eso alaabo ni Burundi, awon afoyesise ati awon omo egbe oselu ti o wa nipo, awon egbe Imbone… n kolu awon alatako ati awon eni ti won fura si gege bi alatako pelu ajafetoo eniyan ati akoroyin. “Won pa eeyan to to 1700, bee ni won si n fi ipa le awon elomiin, won n fi ipa ba won ni ibalopo, won n fi iya je won, won n ti won mole, bee ni won si n deruba aimoye awon miiran”.
Èyí ti dá wàhálà ìsásàálà sílẹ̀, a ti rí àwọn ará Burundi tí wọ́n sá lọ sí Tanzania, Rwanda, Congo àti Uganda. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti padà sílé. Alákòóso United Nations fún ìsásàálà ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn asásàálà tí ó wá láti Burundi tí wọ́n lé ní 347,000 ní oṣù Èrèlé 2019, UNHCR fìdí ẹ̀ múlẹ̀:
Eyi ti da wahala isasaala sile, a ti ri awon ara Burundi ti won sa lo si Tanzania, Rwanda, Congo ati Uganda. Bi o tile je pe egbeegberun ti pada sile. Alakooso United Nations fun isasaala ti se akosile awon asasaala ti o wa lati Burundi ti won le ni 347,000 ni osu Erele 2019, UNHCR fidi e mule:
Làásìgbò nínú òṣèlú Burundi le sí i ní ọdún 2015 lẹ́yìn tí ààrẹ́ kéde èròńgbàa rẹ̀ láti lọ fún sáà kẹ́ta. Ìfẹ̀hónúhàn àwọn èèyàn láti tako èròńgbà fa ìkọlura, ọgọọgọ̀rún àwọn èèyàn sì sá lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè ìtòsí láti fi oríi wọn pamọ.”
Laasigbo ninu oselu Burundi le si i ni odun 2015 leyin ti aare kede erongbaa re lati lo fun saa keta. Ifehonuhan awon eeyan lati tako erongba fa ikolura, ogoogorun awon eeyan si sa lo si awon orile-ede itosi lati fi orii won pamo.”
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, ìjọba Burundi ti ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations tí wọ́n sì sọ pé àwọn kò nílòo wọn mọ́. Ìjọba náà ń bínú sí alákòóso tẹ́lẹ̀-rí ẹ̀ka náà, Zeid Ra'ad Al Hussein tí ó ṣàpèjúwe Nkurunziza ti Burundi gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára “àwọn apanilẹ́kúnjayé ènìyàn tí ó ń gbèrú sí i láìpẹ́ yìí” ní oṣù Èrèlé 2018.
Ni ibere osu yii, ijoba Burundi ti ofiisi eka awon ajafetoo eniyan labe United Nations ti won si so pe awon ko niloo won mo. Ijoba naa n binu si alakooso tele-ri eka naa, Zeid Ra'ad Al Hussein ti o sapejuwe Nkurunziza ti Burundi gege bi okan lara “awon apanilekunjaye eniyan ti o n gberu si i laipe yii” ni osu Erele 2018.
Àtipa àwọn Ilé-iṣẹ́ Akọ̀ròyìn, ìyọlẹ́nu àwọn alátakò, ìfòfinlíle mú àwọn ìdásílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìjọba (NGOs) àti ìdiwọ́ fún àwọn mìíràn láti sọ̀rọ̀ tàbí ṣe àfihàn ara wọn ní ààyè òṣèlú.
Atipa awon Ile-ise Akoroyin, iyolenu awon alatako, ifofinlile mu awon idasile ti ki i se ti ijoba (NGOs) ati idiwo fun awon miiran lati soro tabi se afihan ara won ni aaye oselu.
Fún àpẹẹrẹ, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélọ́gbọ̀n fún ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn Germain Rukiki fún “ìdarapọ̀ mọ́ ìgbìyànjú ìrúlùú, “jíjin ètò ààbò ìlú lẹ́sẹ̀, àti ìṣọ̀tẹ̀” ní 2018 nítorí pé ó ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí ìjọba Nkurunziza ń gbà fìyà jẹni. Àwọn àìṣedede kan dá ìgbẹ́jọ́ Rukiki dúró, ó sì wáyé ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú àríyànjiyàn ìdìbò abófinmu náà.
Fun apeere, won dajo ewon odun mejilelogbon fun ajafetoo eniyan Germain Rukiki fun “idarapo mo igbiyanju iruluu, “jijin eto aabo ilu lese, ati isote” ni 2018 nitori pe o se akosile awon ona ti ijoba Nkurunziza n gba fiya jeni. Awon aisedede kan da igbejo Rukiki duro, o si waye ni ose meloo kan saaju ariyanjiyan idibo abofinmu naa.
“Ọ̀rọ̀ ìkọkúkọ” náà ń ṣe àfihàn ìdúróṣánṣán ìjọba náà tí kò yẹ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ẹ̀tọ́ọ wọn, títí mọ́ ṣíṣe ìgbéyàwó kànńpá fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n ń gbépọ̀ láìṣe ìgbéyàwó ní 2017: ìfòfinlíle mú òwòo panṣágà àti agbe ṣíṣe.
“Oro ikokuko” naa n se afihan idurosansan ijoba naa ti ko ye ati ona ti won n gba se etoo won, titi mo sise igbeyawo kannpa fun awon tokotaya ti won n gbepo laise igbeyawo ni 2017: ifofinlile mu owoo pansaga ati agbe sise.
Àfilé iye owó fún gbígba ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà mú àwọn ọmọ Angola fi ẹ̀hónú hàn
Afile iye owo fun gbigba iwe eri omo-ilu-fun-irinna mu awon omo Angola fi ehonu han
Inú ń bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Angola látàrí iye owó ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà tuntun 30,500 kwanzas (ó tó 97 owó dollar) tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ polongo ní ọjọ́ 21 oṣù Ṣẹẹrẹ. 2500 kwanzas (owó dollar orílẹ̀-èdè US mẹ́jọ) ni ó jẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Inu n bi awon omo orile-ede Angola latari iye owo iwe eri omo-ilu-fun-irinna tuntun 30,500 kwanzas (o to 97 owo dollar) ti ijoba sese polongo ni ojo 21 osu Seere. 2500 kwanzas (owo dollar orile-ede US mejo) ni o je teletele.
Ní àfikún, ìjọba ti pín iye owó irúfẹ́ ìrìnàjò tí ó wà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Lábẹ́ ìlànà tuntun yìí ni ìjọba yóò ti máa gba 45,250 kwanzas fún ìwé ìwọ̀lú ìdúró-sí-ìlú; 21,350 fún ìwé ìwọ̀lú ìrìnàjò-afẹ́; 36,500 fún ìwé ìwọ̀lú àgbàníbodè; 38,125 fún ìsúnsíwájú ìwé ìwọ̀lú iṣẹ́; 15,250 fún ìwé ìwọ̀lú ọ̀rọ̀ ìlera ara; àti 30,500 fún ìwé pélébé ìgbélùú.
Ni afikun, ijoba ti pin iye owo irufe irinajo ti o wa si otooto, o to o ni eseese. Labe ilana tuntun yii ni ijoba yoo ti maa gba 45,250 kwanzas fun iwe iwolu iduro-si-ilu; 21,350 fun iwe iwolu irinajo-afe; 36,500 fun iwe iwolu agbanibode; 38,125 fun isunsiwaju iwe iwolu ise; 15,250 fun iwe iwolu oro ilera ara; ati 30,500 fun iwe pelebe igbeluu.
Agbẹnusọ fún Ẹ̀ka Ìjọba tí ó ń ṣe àbójútó ètò ìforúkọsílẹ̀, Valdemar José, sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ìbílẹ̀ Angola pé ìdíyelé fún ìwé ìrìnnà ìwọ̀lú lásán-làsàn lọ sí òkè nítorí owó gegere ni ó ń jẹ láti ṣe ìwé náà:
Agbenuso fun Eka Ijoba ti o n se abojuto eto iforukosile, Valdemar Jose, so fun awon akoroyin ibile Angola pe idiyele fun iwe irinna iwolu lasan-lasan lo si oke nitori owo gegere ni o n je lati se iwe naa:
Ìjọba rí i wípé ó tó àsìkò láti sún owó ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà, ó sì ti yọ ọwọ́ọ Kílàńkóo rẹ̀ kúrò nínú kíkó owó lé e lórí, kí ó ba lè ṣe, fún àpẹẹrẹ, pèsè omi, ináa mànàmáná àti àwọn ohun amáyérọrùn mìíràn. Ohun èlò fún ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà máa ń gbọ́n owó mì, nítorí iṣẹ́ ìdáàbòbò oríi rẹ̀, tí àjọ ọba ń kówó lé lórí tẹ́lẹ̀ kí ó tó di ìgbà yìí.
Ijoba ri i wipe o to asiko lati sun owo iwe eri omo-ilu-fun-irinna, o si ti yo owoo Kilankoo re kuro ninu kiko owo le e lori, ki o ba le se, fun apeere, pese omi, inaa manamana ati awon ohun amayerorun miiran. Ohun elo fun iwe eri omo-ilu-fun-irinna maa n gbon owo mi, nitori ise idaabobo orii re, ti ajo oba n kowo le lori tele ki o to di igba yii.
Èyí jẹ́ ìrántí ohun tí ojú àwọn ọmọ Mozambique rí ní ìparí ọdún-un 2018, nígbàtí ìjọba pinnu láti fi owó kún ìwé àṣẹ gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ó bá ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà, tí ìdíyelée rẹ̀ fi ìdá 500 gbéwó lórí.
Eyi je iranti ohun ti oju awon omo Mozambique ri ni ipari odun-un 2018, nigbati ijoba pinnu lati fi owo kun iwe ase gbogbo, bee naa ni o ba iwe ase oko wiwa, ti idiyelee re fi ida 500 gbewo lori.
Àfilé iye owó náà ti dá awuyewuye sílẹ̀. Ìfẹ̀hónúhàn ọ̀dọ̀ tí ó tó bíi 100 wáyé ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù Èrèlé, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú kan tí ó rí ìgbésẹ̀ ìjọba gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn fún ìrìnàjò ṣíṣe.
Afile iye owo naa ti da awuyewuye sile. Ifehonuhan odo ti o to bii 100 waye ni ojo kerin osu Erele, pelu atileyin egbe awon omo ilu kan ti o ri igbese ijoba gege bi ona lati gbese le eto awon eniyan fun irinajo sise.
Ìfẹ̀hónúhàn náà
Ifehonuhan naa
Ní ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé, Global Voices bá Fernando Gomes, ajìjàǹgbara ọmọ orílẹ̀ èdè Angola tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alátìlẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn náà tàkùrọ̀sọ, láti mọ ohun gbogbo tí ó rọ̀ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó sọ fún wa:
Ni ojo kerin osu Erele, Global Voices ba Fernando Gomes, ajijangbara omo orile ede Angola ti o je okan lara awon alatileyin ifehonuhan naa takuroso, lati mo ohun gbogbo ti o ro mo isele naa. O so fun wa:
Èyí [ni ọ̀nà kan] fún ìpèsí àkíyèsí ìjọba João Lourenço, wípé àfilé ìdíyelé kò yẹ nírú àsìkò yìí, nítorí owó náà ti ṣe gegere ju fún àwọn ọmọ ìlú. (…) Àti pé “iṣẹ́ ìdàgbàsókè ọrọ̀ Ajé orílẹ̀-èdè Angola” kò lé wáyé nípasẹ̀ àfilé owó orí, nítorí wípé àwọn ọmọ ìlú ni ó ń fi orí kó o, àwọn tí ó wà ní ipò ìjọba ní àǹfààní tí ó pọ̀ ní ìkáwọ́ọ wọn, tí ó ṣe pé àpò ará ìlú tí ó ń rùnpà ni wọ́n ti ń mú owó tí wọ́n ń ná.
Eyi [ni ona kan] fun ipesi akiyesi ijoba Joao Lourenco, wipe afile idiyele ko ye niru asiko yii, nitori owo naa ti se gegere ju fun awon omo ilu. (…) Ati pe “ise idagbasoke oro Aje orile-ede Angola” ko le waye nipase afile owo ori, nitori wipe awon omo ilu ni o n fi ori ko o, awon ti o wa ni ipo ijoba ni anfaani ti o po ni ikawoo won, ti o se pe apo ara ilu ti o n runpa ni won ti n mu owo ti won n na.
Àwọn alátakò ti sọ pé ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà dúró fún ìdánimọ̀ ọmọ ìlú ní òkè òkun, torí ìdí èyí, kò ṣe é yẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.
Awon alatako ti so pe o se pataki lati ranti wipe iwe eri omo-ilu-fun-irinna duro fun idanimo omo ilu ni oke okun, tori idi eyi, ko se e ye sile fun won.
A máa wà ní ojú òpópónà ní olú ìlú fún oṣù Èrèlé, ní àwọn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí a yàn, ọjọ́ kẹrin oṣù Èrèlé ni ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ní ọjọ́ kéje ni a máa padà sí ojú òpópónà, tí a óò tún wà ní ọjọ́ kankànlá, tí a ó sì jábọ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá, bí ìjọba kò bá yí ohùn padà.
A maa wa ni oju opopona ni olu ilu fun osu Erele, ni awon ojo kookan ti a yan, ojo kerin osu Erele ni iwode naa bere, amo ni ojo keje ni a maa pada si oju opopona, ti a oo tun wa ni ojo kankanla, ti a o si jabo ni ojo ketala, bi ijoba ko ba yi ohun pada.
Àwọn akọrin ewì-alohùn ráàpù, Lilo Kwanza àti Adérito Gonçalves, kọ orin kan, tí wọ́n sì ya àwòrán-an orin tí ó dá lóríi ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn yìí, “Ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà 30,000″ ni àkọlé orin náà, tí ó ń ṣe ẹ̀fẹ̀ lórí iye owó tabua tí ọmọ-ìlú yóò san fún ìwé ìrìnnà.
Awon akorin ewi-alohun raapu, Lilo Kwanza ati Aderito Goncalves, ko orin kan, ti won si ya aworan-an orin ti o da lorii iwode ifehonuhan yii, “Iwe eri omo-ilu-fun-irinna 30,000″ ni akole orin naa, ti o n se efe lori iye owo tabua ti omo-ilu yoo san fun iwe irinna.
Ó ku ọjọ́ díẹ̀ kí ìwọ́de náà ó kò, ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Angola Pedrowski Teca sọ wípé ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnná pọn dandan ju ìwé ìdánimọ̀ pélébé lọ, ó rọ àwọn ènìyàn láti kọ́wọ̀ọ́ rìn, nítorí àìkọ́wọ̀ọ́ rìn, ní í ṣe ikú pa ọmọ ejò:
O ku ojo die ki iwode naa o ko, ajafuneto omo orile-ede Angola Pedrowski Teca so wipe iwe eri omo-ilu-fun-irinna pon dandan ju iwe idanimo pelebe lo, o ro awon eniyan lati kowoo rin, nitori aikowoo rin, ni i se iku pa omo ejo:
Àwọn àjọ àgbáyé ti dẹ̀yìn kọ Òfin Ìṣíkúrò tí ó pàṣẹ àfilé ìdíyelé tí ó gbéra nílẹ̀ fìrì tí ó sì lọ òkè lálá.
Awon ajo agbaye ti deyin ko Ofin Isikuro ti o pase afile idiyele ti o gbera nile firi ti o si lo oke lala.
Ìwé ìdánimọ̀ pélébé (B.I) wúlò gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀ ní àárín ìlú Angola. Ní ẹ̀yìn odi ìlú Angola, pánda tí kò wúlò ni ìwé ìdánimọ̀ pélébé, kò sí àmì ìdánimọ̀ kan tí ó wà bí kò ṣe ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà.
Iwe idanimo pelebe (B.I) wulo gege bi ami idanimo ni aarin ilu Angola. Ni eyin odi ilu Angola, panda ti ko wulo ni iwe idanimo pelebe, ko si ami idanimo kan ti o wa bi ko se iwe eri omo-ilu-fun-irinna.
Àwa, tí a wà nínú ìlú, ni a ó fi ààbò bò tí a ó sì ké pe àwọn aráa wa ní òkè òkun, kí àwọn náà ó ké gbàjarè, nítorí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà ṣe kókó fún wọn.
Awa, ti a wa ninu ilu, ni a o fi aabo bo ti a o si ke pe awon araa wa ni oke okun, ki awon naa o ke gbajare, nitori iwe eri omo-ilu-fun-irinna se koko fun won.
Kí ìròyìn náà ó ba hó ye létí àwọn ènìyàn, ajàfúnẹ̀tọ́ọ nì àti akẹ́kọ̀ọ́ Ifáfitì, David Mendes, kọ, ní ọjọ́ ìwọ́de náà, iṣẹ́-ìjẹ́ fún ààre orílẹ̀-èdè Angola João Lourenço:
Ki iroyin naa o ba ho ye leti awon eniyan, ajafunetoo ni ati akekoo Ifafiti, David Mendes, ko, ni ojo iwode naa, ise-ije fun aare orile-ede Angola Joao Lourenco:
Ọmọ-ẹgbẹ́ ààrẹ João Lourenço, kì í ṣe nítorí èyí ni àwọn aráa Angola ṣe yàn ọ́ sípò, kò sí ibi tí o ti sọ nínú ìpolongo ìléríi rẹ, o kò sọ pé ìwé ẹ̀rí yóò gbówó lórí, síbẹ̀ kí ni ò ń rò?
Omo-egbe aare Joao Lourenco, ki i se nitori eyi ni awon araa Angola se yan o sipo, ko si ibi ti o ti so ninu ipolongo ilerii re, o ko so pe iwe eri yoo gbowo lori, sibe ki ni o n ro?
Kí ni ẹ fi ṣe ohùn àwọn mẹ̀kúnnù? A ti rí ìrora látàrí àwọn àfilé ìdíyelé, ǹjẹ́ o mọ ìṣòro tí ó ń fà fún àwọn ará ìlú? A kò tilẹ̀ mọ ẹni náà tí ó tọ́ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Angola, báwo ni ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ tí kò lábọ̀ yóò ṣe rí owó gba ìwé ẹ̀rí?
Ki ni e fi se ohun awon mekunnu? A ti ri irora latari awon afile idiyele, nje o mo isoro ti o n fa fun awon ara ilu? A ko tile mo eni naa ti o to lati tuko orile-ede Angola, bawo ni odo ti ko nise ti ko labo yoo se ri owo gba iwe eri?
Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀, ìjọba kò ì tíì sọ tó, tàbí kí ó kéde láti sọ bóyá òun yóò mú ìdíyelé náà wálẹ̀.
Pelu gbogbo re, ijoba ko i tii so to, tabi ki o kede lati so boya oun yoo mu idiyele naa wale.
Àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wọ̀yáàjà láti nípa lórí ètò ìdìbò ọdún-un 2019
Awon ogagun ajagun feyinti orile-ede Naijiria woyaaja lati nipa lori eto idibo odun-un 2019
Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń múra fún ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ nínú Oṣù Èrèlé, àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí wọn di olóṣèlú, jẹ́ igi gbòógì fún òye ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tàbí àwọn tí wọn ṣe àtìlẹ́yìn fún láti dé orí ipò ni ó ti ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 tí ìjọba tiwantiwa ti padà.
Bi orile-ede Naijiria se n mura fun eto idibo si ipo Aare ninu Osu Erele, awon ogagun ti o ti jagun feyinti ti won di oloselu, je igi gboogi fun oye eto oselu orile-ede Naijiria. Awon ogagun ti o ti feyinti tabi awon ti won se atileyin fun lati de ori ipo ni o ti n tuko orile-ede Naijiria lati odun 1999 ti ijoba tiwantiwa ti pada.
Asọ̀ tí ó wáyé láìpẹ́ yìí láàárín Ààrẹ àná, Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ àti Ààrẹ tí ó wà lórí àlééfà, Ààrẹ Muhammadu Buhari – tí àwọn méjèèjì jẹ́ ajagun fẹ̀yìntì afipásèjọba ológun –ní ipa tí ó pọ̀ lórí ètò ìdìbò oṣù tí ó ń bọ̀.
Aso ti o waye laipe yii laaarin Aare ana, Olusegun Obasanjo ati Aare ti o wa lori aleefa, Aare Muhammadu Buhari – ti awon mejeeji je ajagun feyinti afipasejoba ologun –ni ipa ti o po lori eto idibo osu ti o n bo.
Nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí a kò rí irúu rẹ̀ rí tí ó kọ ránṣẹ́ sí Buhari, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kàn-án wípé ó ní ètè láti ṣe èrú ìbò. Ó kọ ọ́ sínú ìwé náà wípé:
Ninu iwe apileko kan ti a ko ri iruu re ri ti o ko ranse si Buhari, Obasanjo fi esun kan-an wipe o ni ete lati se eru ibo. O ko o sinu iwe naa wipe:
Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ìjọba tiwantiwa, bí ètò ìbò tí o yẹ kí ó lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀ láì fi ti apá kan ṣe, ṣùgbọ́n tí ìṣesíi wọn kò fi ìṣedéédé hàn, àìmúdọ́gba tí ó hàn kedere, ẹ̀tàn àti ìjòye àwòdì máà le è gbẹ́dìẹ.
Itiju nla gbaa lo je fun ijoba tiwantiwa, bi eto ibo ti o ye ki o lo ni irowo-irose lai fi ti apa kan se, sugbon ti isesii won ko fi isedeede han, aimudogba ti o han kedere, etan ati ijoye awodi maa le e gbedie.
Ọbásanjọ́ tẹnu mọ́ ọn wípé Buhari kò leè “ṣe ètò ìbò tí ó kẹ́sẹjárí”, àti wípé ìsèjọba tiwantiwa ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari ni a lè fi wé tí ìjọba ológun fàmílétè-kí-n-tutọ́ọ ti Abacha.
Obasanjo tenu mo on wipe Buhari ko lee “se eto ibo ti o kesejari”, ati wipe isejoba tiwantiwa ni abe isakoso Buhari ni a le fi we ti ijoba ologun familete-ki-n-tutoo ti Abacha.
Ní ọdún 1998, Sani Abacha, tí ó jẹ́ ológun apàṣẹwàá ní ìgbà náà, pè fún ìbò gbogboògbò ṣùgbọ́n tí ó hàn ketekete pé Abacha kò ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀ fún alágbádá. Ní àsìkò tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó fọwọ́ síi wípé kí Abacha ó jẹ́ olùdíje fún ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlúu wọn. Ní báyìí ó ti ṣípò-padà, òkìkí Abacha tàn káàkiri ó sì di ìlú-mọ̀-ọ́-ká nípa ìtẹrí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn mọ́lẹ̀ àti ìjẹgùdùjẹrà. Ọbásanjọ́ tẹnumọ́ọ wípé “ipasẹ̀” Abacha ní ọjọ́ kínní àná náà ni Buhari ń tọ́ báyìí “láì wo ẹ̀yìn wò.”
Ni odun 1998, Sani Abacha, ti o je ologun apasewaa ni igba naa, pe fun ibo gbogboogbo sugbon ti o han ketekete pe Abacha ko setan lati gbe ijoba sile fun alagbada. Ni asiko ti a n soroo re yii, awon egbe oselu marun-un otooto ni o fowo sii wipe ki Abacha o je oludije fun ipo Aare ninu egbe oseluu won. Ni bayii o ti sipo-pada, okiki Abacha tan kaakiri o si di ilu-mo-o-ka nipa iteri eto omo-eniyan mole ati ijegudujera. Obasanjo tenumoo wipe “ipase” Abacha ni ojo kinni ana naa ni Buhari n to bayii “lai wo eyin wo.”
Shehu Garba, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí gbígbé ìròyìn jáde, bu ẹnu àtẹ́ lu ìwé àpilẹ̀kọ Ọbásanjọ́:
Shehu Garba, ti o je oluranlowo pataki fun Aare Buhari lori gbigbe iroyin jade, bu enu ate lu iwe apileko Obasanjo:
Ètò ìdìbò tí yóò wáyé nínú osù tí ó ń bọ̀ yìí yóò lọ ní pẹ̀lẹ́-kùtù, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Buhari ti ṣe ìlérí fún ọmọ orílẹ̀-èdè yìí àti àgbáyé.
Eto idibo ti yoo waye ninu osu ti o n bo yii yoo lo ni pele-kutu, gege bi Aare Buhari ti se ileri fun omo orile-ede yii ati agbaye.
Ọbásanjọ́, òǹkọ̀wé àpilẹ̀kọ?
Obasanjo, onkowe apileko?
Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, tí ó jẹ́ Ààrẹ ìjọba ológun àná (láti ọdún 1976 sí 1979), tí ó sì tún ṣe Ààrẹ ìjọba alágbádá tí ìbò gbé wọlé (ní ọdún 1999 sí 2007), kúndùn láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ètò ìjọba Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ tẹ̀lé e.
Olusegun Obasanjo, ti o je Aare ijoba ologun ana (lati odun 1976 si 1979), ti o si tun se Aare ijoba alagbada ti ibo gbe wole (ni odun 1999 si 2007), kundun lati maa bu enu ate lu awon eto ijoba Aare orile-ede Naijiria ti o je tele e.
Ní èṣí, Ọbásanjọ́ gba Buhari ni ìmọ̀ràn láti má díje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, ṣùgbọ́n kí ó “da ìfẹ̀yìntì rò nítorí ọjọ́ oríi rẹ̀.” Àmọ̀ràn yìí dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí wípé Ọbásanjọ́ jẹ́ alátìlẹ́yìn àgbà fún Buhari gẹ́gẹ́ bí òǹdíje nínú ìbò ipò Ààrẹ ni sáà àkọ́kọ́ ní ọdún 2015.
Ni esi, Obasanjo gba Buhari ni imoran lati ma dije fun ipo Aare fun igba keji, sugbon ki o “da ifeyinti ro nitori ojo orii re.” Amoran yii da yanponyanrin sile ni orile-ede Naijiria nitori wipe Obasanjo je alatileyin agba fun Buhari gege bi ondije ninu ibo ipo Aare ni saa akoko ni odun 2015.
Ṣáájú àsìkò yìí, Ọbásanjọ́ ti bá ìjọba Goodluck Jónátánì wí nínú ìwé àpilẹ̀kọ tí ó kọ ránṣẹ́ sí i ní ọdún 2013, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kan Jónátánì wípé ó ń darí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí oko ìparun pẹ̀lú bí ó ṣe fi àyè gba ẹ̀tàn, ìjẹ́gùdùjẹrà, ìbápín àìgbẹ́kẹ̀lé láti fa aṣọ iyì àti ìtẹ̀síwájú orílè-èdè náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”
Saaju asiko yii, Obasanjo ti ba ijoba Goodluck Jonatani wi ninu iwe apileko ti o ko ranse si i ni odun 2013, Obasanjo fi esun kan Jonatani wipe o n dari orile-ede Naijiria lo si oko iparun pelu bi o se fi aye gba etan, ijegudujera, ibapin aigbekele lati fa aso iyi ati itesiwaju orile-ede naa ya perepere.”
Ní àpárá, Ọbásanjọ́ ti Goodluck Jónátánì lẹ́yìn nínú ètò ìdìbò tí ó wáyé ní ọdún 2011. Àti wípé ni ọdún 2007, òun yìí kan náà ni ó ti Umaru Musa Yar'Adua tí ó jẹ kí Jónátánì ó tó jẹ lẹ́yìn digbídigbí. Ṣùgbọ́n tí ó pa ìdí ọ̀rẹ́ dá sí Yar'Adua lẹ́yìn ìgbátí ó bẹ̀rẹ̀ àìsàn tí kò sì gbé ètò ìṣe ìjọba fún igbákèjì rẹ̀ tii ṣe Goodluck Jónátánì.
Ni apara, Obasanjo ti Goodluck Jonatani leyin ninu eto idibo ti o waye ni odun 2011. Ati wipe ni odun 2007, oun yii kan naa ni o ti Umaru Musa Yar'Adua ti o je ki Jonatani o to je leyin digbidigbi. Sugbon ti o pa idi ore da si Yar'Adua leyin igbati o bere aisan ti ko si gbe eto ise ijoba fun igbakeji re tii se Goodluck Jonatani.
Ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì kì í sinmi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ogagun ti o ti jagun feyinti ki i sinmi ni orile-ede Naijiria
Abẹ ìgbèkùn àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì àti àwọn asọ́mogbée wọn ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà. Bí àpẹẹrẹ, Ọbásanjọ́ jẹ́ alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó mọ àludé tòun àpadé bí àwọn Ààrẹ ṣe ń gba ipò láti ọdún 2007 sí 2015. Bíótiwùkíórí, láì jọ ti àwọn alágbádá – Yar'Adua àti Jónátánì – tí ó gbé ní arugẹ, tí ó sì tún yẹpẹrẹ wọn, ti Buhari dá yàtọ̀ gedegbe.
Abe igbekun awon ogagun ti o ti jagun feyinti ati awon asomogbee won ni orile-ede Naijiria wa. Bi apeere, Obasanjo je alenuloro ti o mo alude toun apade bi awon Aare se n gba ipo lati odun 2007 si 2015. Biotiwukiori, lai jo ti awon alagbada – Yar'Adua ati Jonatani – ti o gbe ni aruge, ti o si tun yepere won, ti Buhari da yato gedegbe.
Bí ó ti lẹ̀ jé pé Ọbásanjọ́ ti Buhari lẹ́yìn láti leè yege ní ọdún 2015, a kò leè sọ pé àtìlẹyìn rẹ̀ nìkan ni ó gbé e dé ipò Ààrẹ. Nítorí ohun tí ó jẹ́ kí ó ṣeé ṣe ò ju bí Buhari ṣe fi ọwọ́ wẹ ọwọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú ìgbàanì Action Congress of Nigeria (ACN) ti Bọ́lá Tinubu. Ẹgbẹ́ òṣèlú Congress for Progressive Change (CPC) ti Buhari jẹ ọmọ ẹgbẹ́ ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín parapọ̀ mọ́ ACN, wọ́n sì di ọkàn nínú oṣù Kejì ọdún 2013, èyí tí ó ṣe okùnfà ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú Gbogboògbò (APC).
Bi o ti le je pe Obasanjo ti Buhari leyin lati lee yege ni odun 2015, a ko lee so pe atileyin re nikan ni o gbe e de ipo Aare. Nitori ohun ti o je ki o see se o ju bi Buhari se fi owo we owo pelu egbe oselu igbaani Action Congress of Nigeria (ACN) ti Bola Tinubu. Egbe oselu Congress for Progressive Change (CPC) ti Buhari je omo egbe ni igbeyingbeyin parapo mo ACN, won si di okan ninu osu Keji odun 2013, eyi ti o se okunfa idasile egbe oselu tuntun ti oruko re n je Ajo Itesiwaju Gbogboogbo (APC).
Ní àfikún, Buhari tí ó ṣe olórí ìjọba ológun ní ọdún (1983 sí 1985) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ‘ẹgbẹ́’ ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tí ó ti takú ti ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fún ìdí èyí, bí Ọbásanjọ́ ṣe tàbùkù Buhari ní gbangba tó, ó níí ṣe pẹ̀lú agbára àti ipò ẹgbẹ́ tí àwọn méjèèjì wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì.
Ni afikun, Buhari ti o se olori ijoba ologun ni odun (1983 si 1985) je okan lara awon omo ‘egbe’ ogagun ti o ti feyinti ti o ti taku ti eto oselu orile-ede Naijiria. Fun idi eyi, bi Obasanjo se tabuku Buhari ni gbangba to, o nii se pelu agbara ati ipo egbe ti awon mejeeji wa gege bi ogagun ti o ti jagun feyinti.
Ọbásanjọ́ nìkan sì kọ́ ni ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí ó ń tàbùkù Buhari.
Obasanjo nikan si ko ni ogagun ti o ti jagun feyinti ti o n tabuku Buhari.
Theophilus Danjuma, tí òun náà jẹ́ ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì ní oṣù kẹ́ta ọdún tí ó kọjá fi ẹ̀sùn kan “ẹgbẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wípé ó ń gbárùkù ti ìpànìyàn nípakúpa tí ó ń lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”
Theophilus Danjuma, ti oun naa je ogagun ti o ti jagun feyinti ni osu keta odun ti o koja fi esun kan “egbe ologun orile-ede Naijiria wipe o n gbaruku ti ipaniyan nipakupa ti o n lo ni orile-ede Naijiria.”
Danjuma, tí ó jẹ olórí àwọn ológun, tí o si tún jẹ́ mínísítà fún ètò abo ní ìgbà kan rí, bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ ológun bí wọ́n ṣe ń gbé lẹ́yìn apá kan dá apá kan sí nínú aáwọ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn darandaran àti àgbẹ̀, pàápàá jù lọ èyí tí ó wáyé ní ilée rẹ̀ tí í ṣe ìpínlẹ̀ Taraba. Ìrí-bá-kan-náà, Danjuma fi ariwo ta nípa ète bí àwọn “ọlọ́pàá àti ológun” ṣe ń gbìmọ̀pọ̀ láti ṣe ẹ̀rú nínú ìbò ọdún 2019.
Danjuma, ti o je olori awon ologun, ti o si tun je minisita fun eto abo ni igba kan ri, bu enu ate lu egbe ologun bi won se n gbe leyin apa kan da apa kan si ninu aawo ti o waye laaarin awon darandaran ati agbe, paapaa ju lo eyi ti o waye ni ilee re ti i se ipinle Taraba. Iri-ba-kan-naa, Danjuma fi ariwo ta nipa ete bi awon “olopaa ati ologun” se n gbimopo lati se eru ninu ibo odun 2019.
Bákannáà ẹ̀wẹ̀wẹ̀, nínú Oṣù Kejì ọdún tí ó kọjá, ajagun fẹ̀yìntì tí ó tún jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láyé ológun, Ibrahim Babangida gba Ààrẹ Buhari ní ìyànjú láti máà du ìje fún ipò Ààrẹ fún ìgbà kejì, nítorí wípé ọgọ́rùn-ún ọdún 21 tí Nàìjíríà wà yìí jẹ́ àsìkò àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ìrírí ìgbàlódé. Ó gbàgbọ́ wípé ìgbàkanìgbàkàn “ohun tí yóò jẹ́ àǹfààní gbogbo ará ìlú gbọdọ̀ bo orí àǹfààní ti ara ẹni.”
Bakannaa ewewe, ninu Osu Keji odun ti o koja, ajagun feyinti ti o tun je olori orile-ede Naijiria laye ologun, Ibrahim Babangida gba Aare Buhari ni iyanju lati maa du ije fun ipo Aare fun igba keji, nitori wipe ogorun-un odun 21 ti Naijiria wa yii je asiko awon odo ti o ni iriri igbalode. O gbagbo wipe igbakanigbakan “ohun ti yoo je anfaani gbogbo ara ilu gbodo bo ori anfaani ti ara eni.”
Pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ, yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pẹ́ díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó tó le è ní Ààrẹ tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú, tàbí tí kò ní àtìlẹ́yìn ‘ẹgbẹ́’ àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì.
Pelu bi gbogbo nnkan se n lo, yoo feree pe die ki orile-ede Naijiria o to le e ni Aare ti ko ni nnkan se pelu, tabi ti ko ni atileyin ‘egbe’ awon ogagun ajagun feyinti.
Mọ àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ọdún 2019
Mo awon ondije si ipo aare Naijiria odun 2019
Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè tí ó ní ènìyàn tí ó pọ̀ jù ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, yóò di ìbò ipò ààrẹ ní ọjọ́ 16, oṣù 2019. Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-wípé àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ t'ó 73, eré Àpáta Agbára – ibùjókòó ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà – yóò wáyé ní àárín-in ẹgbẹ́ olóṣèlú méjì tí ó ti ń figagbága ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́ àti àwọn òǹdíje tí a pè ní “agbára ìkẹta”, ìyẹn àwọn ẹgbẹ́ a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Naijiria, orile-ede ti o ni eniyan ti o po ju ni Ile-Adulawo, yoo di ibo ipo aare ni ojo 16, osu 2019. Bi-o-ti-le-je-wipe awon ondije si ipo aare t'o 73, ere Apata Agbara – ibujokoo aare orile-ede Naijiria – yoo waye ni aarin-in egbe oloselu meji ti o ti n figagbaga ni ojo ti o ti pe ati awon ondije ti a pe ni “agbara iketa”, iyen awon egbe a sese de sinu iselu orile-ede Naijiria.
Ẹgbẹ́ méjèèjì tí ó gbajúmọ̀ jù lọ, Ìpéjọ Ìlọsíwájú Gbogboògbò APC àti Ẹgbẹ́-olóṣèlú Ìjọba-àwa-arawa PDP, láì ṣe àní-àní, yóò tari òǹdíje wọn sí gbangba wálíà:
Egbe mejeeji ti o gbajumo ju lo, Ipejo Ilosiwaju Gbogboogbo APC ati Egbe-oloselu Ijoba-awa-arawa PDP, lai se ani-ani, yoo tari ondije won si gbangba walia:
Ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó jẹ́ òǹdíje lábẹ́ àsíá APC, Buhari ló jáwé olúborí nínú ìbò ààrẹ ti ọdún 2011 tí ààrẹ ìgbà kan Goodluck Jónátánì sí pàdánù. Nítorí irú ènìyàn tí Buhari ń ṣe àti èrò wípé yóò gbógun ti ìjẹgúdújẹrá àti ìgbáwọlẹ̀ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò Boko Haram ni àwọn ará ìlú fi gbé e sórí àlééfà.
Aare lowolowo ti o je ondije labe asia APC, Buhari lo jawe olubori ninu ibo aare ti odun 2011 ti aare igba kan Goodluck Jonatani si padanu. Nitori iru eniyan ti Buhari n se ati ero wipe yoo gbogun ti ijegudujera ati igbawole egbe afemisofo Boko Haram ni awon ara ilu fi gbe e sori aleefa.
Síbẹ̀, lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, ààbò ẹ̀mí kò sí pẹ̀lú ìkọlù láàárín darandaran àti àgbẹ̀ bí àwọn darandaran láti àríwá ṣe ń wọ gúúsù láti wá koríko fún ẹran ọ̀sìn-in wọn. Bákan náà, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti wó lulẹ̀ nínú ìṣàkóso ìjọba rẹ̀, pẹ̀lú àìjẹ̀yà àti ìṣowó-ìlú-mọ̀kumọ̀ku ní ibi gíga nínú ìjọba.
Sibe, labe isakoso re, aabo emi ko si pelu ikolu laaarin darandaran ati agbe bi awon darandaran lati ariwa se n wo guusu lati wa koriko fun eran osin-in won. Bakan naa, eto omoniyan ti wo lule ninu isakoso ijoba re, pelu aijeya ati isowo-ilu-mokumoku ni ibi giga ninu ijoba.
Abubakar ni igbá-kejì ààrẹ ìgbà kan àti òǹdíje lábẹ́ àsíá PDP. Ó ti gbìyànjú sẹ́yìn láti di ààrẹ àmọ́ orí kò ṣe ní oore. Bíótiwùkíórí, ìpolongo rẹ̀ jẹ́ ìgbàwọlé nítorí ìparí ìjà tí ó wà ní àárín òun àti ọ̀gáa rẹ̀, Ààrẹ ìgbà kan rí Olusegun Obasanjo tí ó sọ wípé ìṣàkóso ìjọba Buhari kùnà. Gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́, Abubakar ni ó ṣe bònkárí ìsọhun-ìjọba-di-àdáni àti títa ọ̀kẹ́ àìmọye ilé iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti ìjọba tí kò pa owó sí àpò ìjọba.
Abubakar ni igba-keji aare igba kan ati ondije labe asia PDP. O ti gbiyanju seyin lati di aare amo ori ko se ni oore. Biotiwukiori, ipolongo re je igbawole nitori ipari ija ti o wa ni aarin oun ati ogaa re, Aare igba kan ri Olusegun Obasanjo ti o so wipe isakoso ijoba Buhari kuna. Gege bi amugbalegbee, Abubakar ni o se bonkari isohun-ijoba-di-adani ati tita oke aimoye ile ise ti o je ti ijoba ti ko pa owo si apo ijoba.
Àwọn mìíràn tí ó ní ìrètí sí ipò ààrẹ Nàìjíríà ni:
Awon miiran ti o ni ireti si ipo aare Naijiria ni:
Ezekwesili, obìrin kan ṣoṣo tí ó ń du ipò nínú eré ìbò sísá ti ọdún tí a wà yìí, ti ṣe mínísítà ọrọ̀ líle inú-ilẹ̀ àti ètò ẹ̀kọ́ ní àsìkò ìjọba Olusegun Obasanjo ní àárín ọdún 1999 sí 2007. Ó sì ti ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ààrẹ Ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé ẹ̀ka ti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ìgbà kan láti oṣù Igbe ọdún 2007 sí oṣù Igbe ọdún 2012. Ezekwesili ti ṣe bẹbẹ nínú akitiyan ìdásílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin 200 tí ọmọ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfo Ẹlẹ́sìn ìmale jí gbé ní ọdún 2014. Ó jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ Ìpolongo BringBackOurGirls . Bákan náà ni ó jẹ́ òǹdíje sí ipò ààrẹ ní abẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Allied Congress Party ti Nàìjíríà.
Ezekwesili, obirin kan soso ti o n du ipo ninu ere ibo sisa ti odun ti a wa yii, ti se minisita oro lile inu-ile ati eto eko ni asiko ijoba Olusegun Obasanjo ni aarin odun 1999 si 2007. O si ti se amugbalegbee aare Ile ifowopamo Agbaye eka ti Ile Adulawo igba kan lati osu Igbe odun 2007 si osu Igbe odun 2012. Ezekwesili ti se bebe ninu akitiyan idasile awon akekoo-binrin 200 ti omo egbe afemisofo Elesin imale ji gbe ni odun 2014. O je okan lara oludasile Ipolongo BringBackOurGirls . Bakan naa ni o je ondije si ipo aare ni abe egbe oloselu Allied Congress Party ti Naijiria.
Moghalu jẹ́ onímọ̀ nínú ìdókòwò àgbáyé àti òfin gbogbo ènìyàn ní ilé ìwé Òfin àti Ọgbọ́n Fletcher ní Ifásitì Tufts ní Massachusetts, USA. Moghalu ti ṣiṣẹ́ rí ní United Nations láti ọdún 1992 sí 2008. Ó ti ṣe igbá-kejì gómìnà Ilé Ìfowópamọ́ Àgbà ti Nàìjíríà láti ọdún 2009 sí 2014, níbi tí “ó ti tukọ̀ ọ àwọn àgbà iṣẹ́ àtúnṣe nínú ètò ìkówóoamọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí ọrọ̀ Ajé àgbáyé ti ṣe òjòjò tán.” Òun ni òǹdíje ní abẹ́ àsíá Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Ìtẹ̀síwájú Ọ̀dọ́ – YPP.
Moghalu je onimo ninu idokowo agbaye ati ofin gbogbo eniyan ni ile iwe Ofin ati Ogbon Fletcher ni Ifasiti Tufts ni Massachusetts, USA. Moghalu ti sise ri ni United Nations lati odun 1992 si 2008. O ti se igba-keji gomina Ile Ifowopamo Agba ti Naijiria lati odun 2009 si 2014, nibi ti “o ti tuko o awon agba ise atunse ninu eto ikowooamo orile ede Naijiria leyin igba ti oro Aje agbaye ti se ojojo tan.” Oun ni ondije ni abe asia Egbe Oloselu Itesiwaju Odo – YPP.
Sowore ni olùdásílẹ̀ àti atẹ̀wéjáde SaharaReporters , ilé-iṣẹ́ oníròyìn aṣèwádìí orí-ayélujára. SR ni à ń pè ní Wikileaks Ilé Adúláwọ̀. Ajà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn yìí ń jáde lábẹ́ àsíá African Action Congress.
Sowore ni oludasile ati atewejade SaharaReporters , ile-ise oniroyin asewadii ori-ayelujara. SR ni a n pe ni Wikileaks Ile Adulawo. Aja-fun-eto-omoniyan yii n jade labe asia African Action Congress.
Aré ti ń lọ fún ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Are ti n lo fun ojo iwaju orile ede Naijiria
Buhari àti Abubakar ni afigagbága ìdíje ìbò aré yìí. Àwọn méjèèjì ti ń figagbága nínú ìbò Nàìjíríà ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Ní ọ̀nà kejì, Ezekwesili, Moghalu, Sowore, àwọn “agbára ìkẹ́ta”, jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó ń wọ inú ètò ìṣèlú fún ìgbà àkọ́kọ́.
Buhari ati Abubakar ni afigagbaga idije ibo are yii. Awon mejeeji ti n figagbaga ninu ibo Naijiria ni ojo ti o ti pe. Ni ona keji, Ezekwesili, Moghalu, Sowore, awon “agbara iketa”, je egbe ti o n wo inu eto iselu fun igba akoko.
Iṣẹ́ ìṣàkóso Buhari ọdún mẹ́ta ni yóò “gbè é” lẹ́yìn àti pé yóò bá ìfi Nàìjíríà sí ipò olú orílẹ̀-èdè tí ìṣẹ́ ti pọ̀ jù. Ìwé ìròyìn Punch ṣe ìfojúsùn “ìpèsípò” gẹ́gẹ́ bí “àìròtẹ́lẹ̀ ” àti pé ó ti pín ìlú yẹ́bẹyẹ̀bẹ. Ètò ìgbógunti ìwà àjẹbánu rẹ̀ fì sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ìgbésẹ̀ tí ó gbé láì pẹ́ yìí láti ṣe ìgbẹ́jọ́ Adájọ́ Àgbà orílẹ̀ èdè tí ó ti sún mọ́ ìbò ààrẹ ni Àjọ Adájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Nigerian Bar Association pè ní “àwòṣe ìkọlù ní lemọ́lemọ́ ní orí àwọn àgbà ẹ̀ka ìjọba méjèèjì tí-kò-gbáralé ìjọba” ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari.
Ise isakoso Buhari odun meta ni yoo “gbe e” leyin ati pe yoo ba ifi Naijiria si ipo olu orile-ede ti ise ti po ju. Iwe iroyin Punch se ifojusun “ipesipo” gege bi “airotele ” ati pe o ti pin ilu yebeyebe. Eto igbogunti iwa ajebanu re fi si egbe kan. Igbese ti o gbe lai pe yii lati se igbejo Adajo Agba orile ede ti o ti sun mo ibo aare ni Ajo Adajo orile ede Naijiria Nigerian Bar Association pe ni “awose ikolu ni lemolemo ni ori awon agba eka ijoba mejeeji ti-ko-gbarale ijoba” ni abe isakoso Buhari.
Abubakar, ní ọ̀nà kejì, ń dúró lórí “ìgbẹ́kẹ̀lé” àwọn “ẹgbẹlẹmùkù okòwò tí ó ní èrè lóríi rẹ̀”. Bíótiwùkíórí, ó ní láti bá agbára ìwàlóríoyè afigagbága rẹ̀ takọ̀ngbọ̀n.
Abubakar, ni ona keji, n duro lori “igbekele” awon “egbelemuku okowo ti o ni ere lorii re”. Biotiwukiori, o ni lati ba agbara iwalorioye afigagbaga re takongbon.
Ẹni yòówù tí ó bá gbégbá-orókè nínú ìdíje sí ipò ààrẹ ọdún 2019 ní iṣẹ́ ìmúgbòòrò ọrọ̀ Ajé, ààbò ní àárín ìlú, àtúntò agbára àti ìmúkárí agbára, àti ìṣèlú elẹ́yàmẹyà làti ṣe.
Eni yoowu ti o ba gbegba-oroke ninu idije si ipo aare odun 2019 ni ise imugbooro oro Aje, aabo ni aarin ilu, atunto agbara ati imukari agbara, ati iselu eleyameya lati se.
‘Ẹ Yé é Pa Àwọn Òbìnrin’ – ìpolongo tuntun tí ó ń tako ìjìyà inú ìgbéyàwó ní Angola
‘E Ye e Pa Awon Obinrin’ – ipolongo tuntun ti o n tako ijiya inu igbeyawo ni Angola
Nígbà tí wọ́n bá òkú agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ẹni ọdún 26, Carolina Joaquim de Sousa da Silva nínú ilée rẹ̀ ní ọjọ́ 3, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018, ọkọ rẹ̀ jẹ́wọ́ ọ̀ràn náà, ó sì di èrò àhámọ̀ ẹ̀ka tí ó ń ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn ti Angola tí a mọ̀ sí SIC.
Nigba ti won ba oku agbejoro ti o je eni odun 26, Carolina Joaquim de Sousa da Silva ninu ilee re ni ojo 3, osu Ope odun 2018, oko re jewo oran naa, o si di ero ahamo eka ti o n se iwadii iwa odaran ti Angola ti a mo si SIC.
Láàárín ọ̀sẹ̀ kan náà, ìròyìn ikú obìnrin kan ni ó jáde láti ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Gbogboògbò orílẹ̀-èdè Angola tí ó ní wípé ọ̀rẹ́kùnrin ìgbà-kan-rí obìnrin náà ni ó gún un pa.
Laaarin ose kan naa, iroyin iku obinrin kan ni o jade lati ile-ise Amohun-maworan Gbogboogbo orile-ede Angola ti o ni wipe orekunrin igba-kan-ri obinrin naa ni o gun un pa.
Àwọn ọ̀ràn ìwà ọ̀darànmọràn yìí ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ní orílẹ̀-èdè Angola dúró gírígírí, èyí sì fa ìpolongo tuntun kan tí ó ń tako ìjìyà abẹ́lé tí wọ́n pe àkóríi rẹ̀ ní “Ẹ Yé é Pa àwọn Obìnrin” tí Ẹgbẹ́ Ondjango tí ó jẹ́ àjọ ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin tí kì í ṣe ti ìjọba ṣe àgbékalẹ̀ẹ rẹ̀. Wọ́n ṣe àmúlò Facebook gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìkórajọ wọn, èròńgbà wọn ni láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa àwọn ìjìyà obìnrin ní orílẹ̀-èdè Angola:
Awon oran iwa odaranmoran yii ti mu opolopo awon obinrin ni orile-ede Angola duro girigiri, eyi si fa ipolongo tuntun kan ti o n tako ijiya abele ti won pe akorii re ni “E Ye e Pa awon Obinrin” ti Egbe Ondjango ti o je ajo ajafuneto obinrin ti ki i se ti ijoba se agbekalee re. Won se amulo Facebook gege bi ohun elo ikorajo won, erongba won ni lati je ki awon eniyan mo nipa awon ijiya obinrin ni orile-ede Angola:
Àsìkò yìí jẹ́ èyí tí ó le. Lóòótọ́, fún àwa obìnrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ni ó le tí ó sì ń dùn èèyàn nítorí pé a ṣì wà ní ipò tí ó jẹ́ pé a máa ń yẹra fún ìjìyà lọ́nà kan tàbí òmíràn. Láìpẹ́ yìí gan-an pàápàá, ó dunni láti máa kojú àwọn ìhùwàsí tí ó ń jáde lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ti Carolina…
Asiko yii je eyi ti o le. Loooto, fun awa obinrin opolopo ojo ni o le ti o si n dun eeyan nitori pe a si wa ni ipo ti o je pe a maa n yera fun ijiya lona kan tabi omiran. Laipe yii gan-an paapaa, o dunni lati maa koju awon ihuwasi ti o n jade leyin oro ti Carolina…
Lóòótọ́ ni ìjìyà àwọn obìnrin, ó wà lóòótọ́. Kì í ṣe ohun tí ó kàn wá lórí àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin, kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ àgbélẹ̀rọ tàbí ọ̀rọ̀ òfìfo, LÓÒÓTỌ́ NI! Ó ṣeni láàánú pé ti Carolina kún ìṣirò tí ó ti wà nílẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀ràn báyìí ti wáyé kí tirẹ̀ ó tó ṣẹlẹ̀ tí àwọn ènìyàn gbọ́ sí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀ràn mìíràn tí àwọn èèyàn ò mọ̀ sí, ó jẹ́ ìṣòro kan tí ó ti wà níbẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà níwájú wa. Ó sì jẹ́ ìṣòro tí ó ń ro ti ìbáṣe láàárín tọkọtaya – ìṣòro àtilẹ̀wá ni.
Loooto ni ijiya awon obinrin, o wa loooto. Ki i se ohun ti o kan wa lori awon ajafuneto obinrin, ki i si i se oro agbelero tabi oro ofifo, LOOOTO NI! O seni laaanu pe ti Carolina kun isiro ti o ti wa nile, opo oran bayii ti waye ki tire o to sele ti awon eniyan gbo si, bee si ni egbeegberun awon oran miiran ti awon eeyan o mo si, o je isoro kan ti o ti wa nibe lenu ona niwaju wa. O si je isoro ti o n ro ti ibase laaarin tokotaya – isoro atilewa ni.
Ètò ìpìlẹ̀ kan wà tí ó ń pàṣẹ tí ó sì ń rẹ àwọn obìnrin sílẹ̀ sí ipò ẹ̀yìn tí èyí sì sọ wọ́n di olùfaragbá ìjìyà lóríṣiríṣi àti ní gbogbo ọ̀nà. Ètò fífi akọ ṣe olórí yìí tí ó ti kọ́ wa lọ́rùn tipẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń kọ̀ pé kò rí bẹ́ẹ̀ – ìyẹn kò sì ṣe é rí – ohun tí ó ń ṣe rè é: ó ń sọni di aláàbọ̀-ara, ó ń ba ayé àwọn obìnrin jẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ń pani.
Eto ipile kan wa ti o n pase ti o si n re awon obinrin sile si ipo eyin ti eyi si so won di olufaragba ijiya lorisirisi ati ni gbogbo ona. Eto fifi ako se olori yii ti o ti ko wa lorun tipe ti opolopo si n ko pe ko ri bee – iyen ko si se e ri – ohun ti o n se re e: o n soni di alaabo-ara, o n ba aye awon obinrin je, bee lo n pani.
Àwa obìnrin lọ́kọ̀ọ̀kan àti àpapọ̀ọ wa, a máa tẹ̀síwajú láti máa pariwo kí ‘ẹ yéé pa wá’ kí ẹ sì ‘yéé ṣe wá léṣe’.
Awa obinrin lokookan ati apapoo wa, a maa tesiwaju lati maa pariwo ki ‘e yee pa wa’ ki e si ‘yee se wa lese’.
À ń fẹ́ àwọn òfin tí yóò dáàbò bò wá tí wọn yóò sì kún ojú ìwọ̀n, a fẹ́ àwọn ètò àmúlò gbogboògbò tí yóò mú àpọ́nlé wa lọ sí àwọn ìtàkùrọ̀sọ àti àwọn ìdásílẹ̀. A fẹ́ àwùjọ tí ẹ̀rù àtijáde ò ti ní bà wá! A máa tẹ̀síwajú láti béèrè fún àwùjọ tí a óò ti ní òmìnira ti ara, òmìnira ìmọ̀lára, òmìnira ìrìn àti òmìnira ríronú bí a ṣe fẹ́.
A n fe awon ofin ti yoo daabo bo wa ti won yoo si kun oju iwon, a fe awon eto amulo gbogboogbo ti yoo mu aponle wa lo si awon itakuroso ati awon idasile. A fe awujo ti eru atijade o ti ni ba wa! A maa tesiwaju lati beere fun awujo ti a oo ti ni ominira ti ara, ominira imolara, ominira irin ati ominira rironu bi a se fe.
A máa tẹ̀síwajú láti béèrè fún àwùjọ tí a ti lè gbáyé pẹ̀lú ààbò tó péye.
A maa tesiwaju lati beere fun awujo ti a ti le gbaye pelu aabo to peye.
Bẹ́ẹ̀, ìpolongo yìí mú èsì tí ó ń takoni wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n rí ìdí fún ìdáláre fún ìrúkèrúdò fífi ìyà jẹ obìnrin. Wọ́n pe ìpolongo wọn ní “Ẹ Yé é Dà Wá”, wọ́n gbà pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ jẹ́ ìdí tí ó tọ́ láti máa fìyà jẹ obìnrin. Bíótilẹ̀jẹ́pé èrò wọn ò tí ì máa rinlẹ̀, Olórin Angola, Gill Slows Allen Russell náà sọ̀rọ̀;
Bee, ipolongo yii mu esi ti o n takoni wa lati odo awon okunrin kan ti won ri idi fun idalare fun irukerudo fifi iya je obinrin. Won pe ipolongo won ni “E Ye e Da Wa”, won gba pe iwa odale je idi ti o to lati maa fiya je obinrin. Biotilejepe ero won o ti i maa rinle, Olorin Angola, Gill Slows Allen Russell naa soro;
“Ẹ yé é da ẹlòmíràn, ẹ jọ̀wọ́ a ò fẹ́ aláìṣòdodo aya mọ́. À ń ké tantan, ẹ̀yin obìnrin bí ẹ kò bá nífẹ̀ẹ́ wa mọ́, ẹ béèrè fún ìtúká kí ẹ tó máa dà wa, ẹ máa lọ.
“E ye e da elomiran, e jowo a o fe alaisododo aya mo. A n ke tantan, eyin obinrin bi e ko ba nifee wa mo, e beere fun ituka ki e to maa da wa, e maa lo.
Onímọ̀ àwùjọ Mbangula Kemba sọ̀rọ̀ tako ojú tí wọ́n fi wo ọ̀rọ̀ yìí, ó tẹnumọ́ọ pé wọn ò gbọdọ̀ fi ìfìyàjẹni yanjú ìṣòro nínú ìgbéyàwó.
Onimo awujo Mbangula Kemba soro tako oju ti won fi wo oro yii, o tenumoo pe won o gbodo fi ifiyajeni yanju isoro ninu igbeyawo.
Angola fi ìdí òfin tí ó ń de ìfìyàjẹni tí wọ́n mọ̀ sí múlẹ̀ ní ọdún 2011 tí ó ń sọ onírúurú ìfìyàjẹni abẹ́lé di ìwà ọ̀daràn ní gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀, ìdájọ́ òfin yìí kò le tó, ìtìmọ́lé ọdún méjì sí mẹ́jọ.
Angola fi idi ofin ti o n de ifiyajeni ti won mo si mule ni odun 2011 ti o n so oniruuru ifiyajeni abele di iwa odaran ni gbangba. Sibesibe, idajo ofin yii ko le to, itimole odun meji si mejo.
Sizaltina Cutaia, tí í ṣe ajìjàǹgbara àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin ní Angola; tí ó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká fún iṣẹ́ẹ rẹ̀ lórí ẹ̀tọ́ obìnrin béèrè fún ìṣàmúlò òfin náà lórí àwọn gbàgede ìtàkùrọ̀sọ lórí ẹ̀rọ-alátagbà:
Sizaltina Cutaia, ti i se ajijangbara ati ajafetoo obinrin ni Angola; ti o je ilumooka fun isee re lori eto obinrin beere fun isamulo ofin naa lori awon gbagede itakuroso lori ero-alatagba:
Àfikún ọdún ẹ̀wọ̀n kò tó, arábìnrin igbá-kejì Ààrẹ MPLA [Àjọ Àwọn ènìyàn tó fẹ́ ìdásílẹ̀ Angola], Ó nílò kí orílẹ̀-èdè ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ìlànà àtilẹ̀wá tí yóò kojú ìpanilára – Àwọn ohun tí wọ́n fara mọ́ ní 2007 nípa àjọsọ ìlànà Maputo ní láti di ṣíṣe. Bákan náà ni ti èyí, ó nílò kí wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ òfin arọ́pò tí yóò mú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin rinlẹ̀. Lára èyí ni gbogbo òfin tí ó de obìnrin ní ti ìbálòpọ̀ àti ẹ̀tọ́ ọmọ bíbí wà.
Afikun odun ewon ko to, arabinrin igba-keji Aare MPLA [Ajo Awon eniyan to fe idasile Angola], O nilo ki orile-ede se idasile awon ilana atilewa ti yoo koju ipanilara – Awon ohun ti won fara mo ni 2007 nipa ajoso ilana Maputo ni lati di sise. Bakan naa ni ti eyi, o nilo ki won se idasile ofin aropo ti yoo mu eto awon obinrin rinle. Lara eyi ni gbogbo ofin ti o de obinrin ni ti ibalopo ati eto omo bibi wa.
Kò sí ìwúlò ìsọ̀rọ̀ tako ìjìyà abẹ́lé kí ó wá di ẹ̀yìn wá kí a máa ṣe ìgbèlẹ́yìn àwọn òfin tí ó fi àṣẹ fún agbófinró láti yẹ̀yẹ́ obìrin ní títì ní ojúmọ́, kò bá ara mu!
Ko si iwulo isoro tako ijiya abele ki o wa di eyin wa ki a maa se igbeleyin awon ofin ti o fi ase fun agbofinro lati yeye obirin ni titi ni ojumo, ko ba ara mu!
Kò wúlò kí a máa sọ̀rọ̀ tako ìjìyà abẹ́lé kí a sì tún máa gbèlẹ́yìn àṣàrò ìnáwó tí kò ní ṣe ààbò ètò àwùjọ, ìṣúná àìtó tí gbogbo wa mọ̀ pé ipa òdì ni ó ń kó nínú ayé àwọn obìnrin. Ó ṣe pàtàkì kí a fi ọgbọ́n kún àwọn ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ṣíṣe gidi. Ẹ fi owó yín sí ibi tí ẹnu yín wà.
Ko wulo ki a maa soro tako ijiya abele ki a si tun maa gbeleyin asaro inawo ti ko ni se aabo eto awujo, isuna aito ti gbogbo wa mo pe ipa odi ni o n ko ninu aye awon obinrin. O se pataki ki a fi ogbon kun awon oro naa pelu sise gidi. E fi owo yin si ibi ti enu yin wa.
Ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin Cecelia Kitombé sọ̀rọ̀ sí àwọn tí ó ń ṣe àtìlẹyìn ìbáṣepọ̀ tí ó níyà nínú:
Ajafetoo obinrin Cecelia Kitombe soro si awon ti o n se atileyin ibasepo ti o niya ninu:
Lára wa tí à ń tẹnumọ́ ọn pé ó pọ̀jù [láti sọ̀rọ̀ síta tako ìjìyà Abẹ́lé] náà ni ẹni tí ó ń gba àwọn ọmọbìnrin, arábìnrin àti ìbátan lóbìnrin níyànjú láti máa fi ara da ìbáṣepọ̀ tí ó ń pani lára pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ẹ̀tàn pé ọ̀rọ̀ tọkọtaya ò ṣe é dá sí, àwọn mìíràn á ní kí o tẹ̀síwajú bẹ́ẹ̀, bí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya ṣe rí nìyẹn… Àwọn kan tilẹ̀ rò pé obìnrin lè ṣe gbogbo nǹkan, ṣùgbọ́n wọn ò gbọdọ̀ gbàgbé ‘ojúṣe’ wọn.
Lara wa ti a n tenumo on pe o poju [lati soro sita tako ijiya Abele] naa ni eni ti o n gba awon omobinrin, arabinrin ati ibatan lobinrin niyanju lati maa fi ara da ibasepo ti o n pani lara pelu oro-etan pe oro tokotaya o se e da si, awon miiran a ni ki o tesiwaju bee, bi oro lokolaya se ri niyen… Awon kan tile ro pe obinrin le se gbogbo nnkan, sugbon won o gbodo gbagbe ‘ojuse’ won.
Ẹ yéé pa wá!!!
E yee pa wa!!!
Ìjàm̀bá Àwọn Ológun Mauritania 28 tí wọ́n pa ní ọjọ́ Òmìnira tí a kò sọ
Ijamba Awon Ologun Mauritania 28 ti won pa ni ojo Ominira ti a ko so
Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Belu ọdún 1990, àwọn ẹgbẹ́ ológun yẹgi fún ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n tí a fi ìfarabalẹ̀ ṣà lọ́kọ̀ọ̀kan láti pa nínú ẹ̀wọ̀n láàárín òru, ní Inal ní orílẹ̀-èdè Mauritania lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn ìpète-lati-gba-ìjọba kàn wọ́n.
Ni ojo kejidinlogbon osu Belu odun 1990, awon egbe ologun yegi fun okunrin mejidinlogbon ti a fi ifarabale sa lokookan lati pa ninu ewon laaarin oru, ni Inal ni orile-ede Mauritania leyin ti a fi esun ipete-lati-gba-ijoba kan won.
Ọjọ́ yìí, tún jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè Mauritania gba òmìnira lọ́wọ́ France ní ọdún 1960, lé góńgó sọ́kàn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania kan tí wọ́n ń wá ìdájọ́ òdodo fún ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn ọkùnrin 28 yìí, tí gbogbo wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú.
Ojo yii, tun je ayajo ojo ti orile-ede Mauritania gba ominira lowo France ni odun 1960, le gongo sokan awon omo orile-ede Mauritania kan ti won n wa idajo ododo fun ipakupa ti won pa awon okunrin 28 yii, ti gbogbo won si je alawo dudu.
Orílẹ̀-èdè Mauritania ti Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ jẹ́ ìdàpọ̀ àwọn Lárúbáwá àti àwọn aláwọ̀ dúdú, àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sọ pé àwọn aláwọ̀ dúdú ti ń dojúkọ ìyàsọ́tọ̀ àti ìlòkulò fún ìgbà pípẹ́.
Orile-ede Mauritania ti Iwo-oorun Ile-Adulawo je idapo awon Larubawa ati awon alawo dudu, awon egbe ajafetoo omoniyan so pe awon alawo dudu ti n dojuko iyasoto ati ilokulo fun igba pipe.
Ààrẹ Ìgbìmọ̀ àwọn Inal-France, Youba Dianka, ṣàlàyé:
Aare Igbimo awon Inal-France, Youba Dianka, salaye:
Mo fẹ́ fi hàn wípé àpẹẹrẹ ni Inal jẹ́; ọ̀pọ̀ ọmọ ‘Inal’ ni ó ti wà ní Mauritania. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abanilẹ́rù ti wáyé ní Azlatt, Sony Malé, Wothie, Walata, Jreida àti nínú àfonífojì. Nínú ọgbà àwọn ológun ní Inal àti àgbègbè rẹ̀, wọ́n pín àwọn ológun yẹ́lẹyẹ̀lẹ, wọ́n rì wọ́n mọ́lẹ̀ ní òòyẹ̀, wọ́n yìnbọn lù wọ́n, wọ́n sì yẹgi fún wọn ní ìrántí òmìnira orílẹ̀-èdè náà lọ́dún 1990.
Mo fe fi han wipe apeere ni Inal je; opo omo ‘Inal’ ni o ti wa ni Mauritania. Awon isele abanileru ti waye ni Azlatt, Sony Male, Wothie, Walata, Jreida ati ninu afonifoji. Ninu ogba awon ologun ni Inal ati agbegbe re, won pin awon ologun yeleyele, won ri won mole ni ooye, won yinbon lu won, won si yegi fun won ni iranti ominira orile-ede naa lodun 1990.
Ní àyájọ́ ọjọ́ òmìnira ti ọdún yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mauritania fi ọkàn sí yíyàn tí a yan ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè wọn sí àṣekágbá ìdíje Ife-ẹ̀yẹ ti àwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (CAF) ju bí wọ́n ṣe ṣe sí àwọn ẹni ìgbàgbé, “àwọn ológun tí wọ́n wà nínú kòtò àìmọ̀… tí wọ́n ṣì ń dúró de ìsìnkú tí ó yẹni“, Kaaw Elimane Bilbassi Toure tí í ṣe olóòtú ibùdó ìròyìn orí ayélujára Le Flambeau ti Mauritania kọ.
Ni ayajo ojo ominira ti odun yii, awon omo orile-ede Mauritania fi okan si yiyan ti a yan egbe agbaboolu orile-ede won si asekagba idije Ife-eye ti awon orile-ede Ile-Adulawo (CAF) ju bi won se se si awon eni igbagbe, “awon ologun ti won wa ninu koto aimo… ti won si n duro de isinku ti o yeni“, Kaaw Elimane Bilbassi Toure ti i se olootu ibudo iroyin ori ayelujara Le Flambeau ti Mauritania ko.
Kiné-Fatim Diop, adarí ìpolongo Amnesty International ní Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀, sọ̀rọ̀ ní ọdún yìí nípa ìtakora tí ó wà ní àárín ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ọjọ́ ìṣèrántí-dunnú àti ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí àwọn olùfarapa ń rò:
Kine-Fatim Diop, adari ipolongo Amnesty International ni Iwo-oorun Ile-Adulawo, soro ni odun yii nipa itakora ti o wa ni aarin ohun ti o ye ki o je ojo iseranti-dunnu ati ohun ti opolopo ebi awon olufarapa n ro:
Lọ́dọọdún, bí àwọn tí wọ́n dipò mú ṣe ń ṣe ìrántí ìgùnkè wọn sí ipò gíga pẹ̀lú ìdùnnú, ẹbí àwọn olùfarapa máa ń sunkún, tí wọ́n sì máa ń fi ẹhónú hàn pẹ̀lú ìbànújẹ́ fún àtúnṣe àti ìdájọ́ òdodo. Àwọn tí ó wà nípò àṣẹ kàn ń gbìyànjú láti ri apá òmìnira tí kò farahàn yìí mọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe dìbò yan òfin ìdáríjì ìjọba ní ìkọ̀kọ̀ lọ́dún 1993 tí wọ́n sì fìdí ìgbàgbé ìjọba múlẹ̀ nípa ìpakúpa àwọn ológun náà lọ́gbọ̀n ọdún sẹ́yìn.
Lodoodun, bi awon ti won dipo mu se n se iranti igunke won si ipo giga pelu idunnu, ebi awon olufarapa maa n sunkun, ti won si maa n fi ehonu han pelu ibanuje fun atunse ati idajo ododo. Awon ti o wa nipo ase kan n gbiyanju lati ri apa ominira ti ko farahan yii mole, gege bi won se dibo yan ofin idariji ijoba ni ikoko lodun 1993 ti won si fidi igbagbe ijoba mule nipa ipakupa awon ologun naa logbon odun seyin.