diacritcs
stringlengths
1
36.7k
no_diacritcs
stringlengths
1
35.5k
Àjọ tí ó ń tako àìjìyà ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àìṣòdodo ní orílẹ̀-èdè Mauritania Forum Against Impunity and Injustice fi ìbànújẹ́ hàn lórí ìjàm̀bá àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tí a yẹgi fún lálẹ́ ọjọ́ burúkú Èṣù gb'omi mu yìí.
Ajo ti o n tako aijiya elese ati aisododo ni orile-ede Mauritania Forum Against Impunity and Injustice fi ibanuje han lori ijamba awon tegbon-taburo kan ti a yegi fun lale ojo buruku Esu gb'omi mu yii.
Láìsí àní-àní, èpè ja àwọn ológun 28 yẹn lóru ọjọ́ náà. Bí i ti àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Diallo Oumar Demba àti àbúròo rẹ̀ Diallo Ibrahima tí a yẹgi fún pẹ̀lú àkọsílẹ̀ nọ́ḿbà tí ó tẹ̀lé ara wọn tí a fi gègé kọ sí wọn lára. Ohun tí ó mú èyí bani nínú jẹ́ jù ni fún ẹni láti rí ikú tí ó pa ẹ̀gbọ́n ẹni. Àwọn apani ṣe iṣẹ́ wọn pé, wọn kò sì dáwọ́ dúró lẹ́yìn tí wọ́n yẹgi fún wọn, wọ́n tún wọ́ òkúu wọn nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń jókòó lé wọn lórí.
Laisi ani-ani, epe ja awon ologun 28 yen loru ojo naa. Bi i ti awon tegbon-taburo, Diallo Oumar Demba ati aburoo re Diallo Ibrahima ti a yegi fun pelu akosile nomba ti o tele ara won ti a fi gege ko si won lara. Ohun ti o mu eyi bani ninu je ju ni fun eni lati ri iku ti o pa egbon eni. Awon apani se ise won pe, won ko si dawo duro leyin ti won yegi fun won, won tun wo okuu won nile bee naa ni won si n jokoo le won lori.
Àwọn Ẹni-orí-kó-yọ sọ̀rọ̀ síta
Awon Eni-ori-ko-yo soro sita
Ẹ̀rí túbọ̀ ń tẹnu àwọn ẹni-orí-kó-yọ jáde lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún.
Eri tubo n tenu awon eni-ori-ko-yo jade leyin ogbon odun.
Mamadou Sy jẹ́ apàṣẹ ẹgbẹ́-ológun nínú ẹgbẹ́ ológun Mauritania, ó ti jẹ́ igbákejì apàṣẹ, kí ó tó wá di apàṣẹ ẹgbẹ́ ológun ẹ̀ka kan kí wọ́n tó mú un ní alẹ́ ọjọ́ yẹn.
Mamadou Sy je apase egbe-ologun ninu egbe ologun Mauritania, o ti je igbakeji apase, ki o to wa di apase egbe ologun eka kan ki won to mu un ni ale ojo yen.
Nínú ìwée rẹ̀, “Ọ̀run-àpáàdì ní Inal“, tí a tẹ̀ jáde ní ọdún 2000, ó ṣàpèjúwe ìjìyà-oró tí ó jẹ, nígbà tí àwọn apàṣẹ ológun dì í lójú, so ó mọ́lẹ̀, tí wọ́n sì jù ú sínú omi ìdọ̀tí rírùn.
Ninu iwee re, “Orun-apaadi ni Inal“, ti a te jade ni odun 2000, o sapejuwe ijiya-oro ti o je, nigba ti awon apase ologun di i loju, so o mole, ti won si ju u sinu omi idoti rirun.
Ológun mìíràn tí orí kó yọ lálẹ́ ọjọ́ burúkú yìí tiraka gba France lọ fún ìtọ́jú lẹ́yìn tí ó kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn Àjọ Onígbàgbọ́ tí ó ń tako Ìfìyàjẹni (ACAT lédè Faransé). Ní ipò àìlórúkọ, ó jẹ́rìí sí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà tí ó rí láàárín ọdún mẹ́rìnlélógún tí ó fi ṣiṣẹ́ ológun:
Ologun miiran ti ori ko yo lale ojo buruku yii tiraka gba France lo fun itoju leyin ti o kuro ni ogba ewon pelu iranwo awon Ajo Onigbagbo ti o n tako Ifiyajeni (ACAT lede Faranse). Ni ipo ailoruko, o jerii si iyasoto eya ti o ri laaarin odun merinlelogun ti o fi sise ologun:
Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe rántí, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi, mo ti máa ń ṣàkíyèsí pé àwọn aláwọ̀ dúdú kì í ní ẹ̀tọ́ kankan, ṣùgbọ́n àwọn aláwọ̀ funfun ará Mauritania máa ń ní àǹfààní tí ó pọ̀. Níbí, nínú ogún àwọn adarí ipò ìjọba, ìdá mẹ́rin péré ni wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú. Nínú ẹgbẹ́ ológun, aláwọ̀ dúdú kan ṣoṣo ni ó máa ń wà láàárín ológun mẹ́wàá. Nígbà ìkọ́ṣẹ́, bí ọmọ Mauritania aláwọ̀ funfun kan kò bá ṣe dáadáa, wọn á ṣì borí aláwọ̀ dúdú mìíràn. A ò sì gbọdọ̀ fi ẹhónú hàn…
Gege bi mo se ranti, nigba ti o bere si i ye mi, mo ti maa n sakiyesi pe awon alawo dudu ki i ni eto kankan, sugbon awon alawo funfun ara Mauritania maa n ni anfaani ti o po. Nibi, ninu ogun awon adari ipo ijoba, ida merin pere ni won je alawo dudu. Ninu egbe ologun, alawo dudu kan soso ni o maa n wa laaarin ologun mewaa. Nigba ikose, bi omo Mauritania alawo funfun kan ko ba se daadaa, won a si bori alawo dudu miiran. A o si gbodo fi ehonu han…
Ó ṣe àpèjúwe àwọn ìfìyàorójẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ológun mìíràn rí:
O se apejuwe awon ifiyaorojeni ti oun pelu awon ologun miiran ri:
Fún àpẹẹrẹ, wọ́n gbẹ́ kòtò sínú iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì rì wá mọ́lẹ̀ dé ibi ọrùn, orí wa ò ṣe é yí, ojú wa sì wà ní ìhà oòrùn. Tí a bá sì gbìyànjú láti pa ojú dé, àwọn ẹ̀ṣọ́ á da iyẹ̀pẹ̀ sí wa. Wọ́n á sì wọ ìbòjú padà.
Fun apeere, won gbe koto sinu iyepe, won si ri wa mole de ibi orun, ori wa o se e yi, oju wa si wa ni iha oorun. Ti a ba si gbiyanju lati pa oju de, awon eso a da iyepe si wa. Won a si wo iboju pada.
Maimouna Alpha Sy, akọ̀wé gbogboògbò fún Ẹgbẹ́ Ọ̀ràn Opó àti Aṣàánù ọmọ-ènìyàn, ti fi ìgbà kan rí jẹ́ aya Ba Baïdy Alassane, tí ó jẹ́ adarí àwọn ẹ̀ṣọ́ ibodè tẹ́lẹ̀. Alpha Sy sọ pé ọkọ rẹ̀ tí ó ti di olóògbé wà lára àwọn tí wọ́n pa lọ́dún 1990.
Maimouna Alpha Sy, akowe gbogboogbo fun Egbe Oran Opo ati Asaanu omo-eniyan, ti fi igba kan ri je aya Ba Baidy Alassane, ti o je adari awon eso ibode tele. Alpha Sy so pe oko re ti o ti di oloogbe wa lara awon ti won pa lodun 1990.
Oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ni a fi wá ọkọ mi, ṣùgbọ́n pàbó ni ó já sí… Àwọn ẹ̀ṣọ́-ibodè sọ fún wa pé àìsàn ọkàn ló pa á, tí èyí kò sì jẹ́ òtítọ́. Wọ́n mú àwọn tó jẹ́rìí pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n so wọ́n, wọ́n sì fi ìyà oró jẹ wọ́n pẹ̀lú rẹ̀. Ní iwájú wọn ni wọ́n ti pa á.
Osu meta ati ojo mewaa ni a fi wa oko mi, sugbon pabo ni o ja si… Awon eso-ibode so fun wa pe aisan okan lo pa a, ti eyi ko si je otito. Won mu awon to jerii pelu re, won so won, won si fi iya oro je won pelu re. Ni iwaju won ni won ti pa a.
‘Kò tún gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́’
‘Ko tun gbodo sele mo’
Lọ́dún yìí ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, àwọn ọmọ Mauritania tí wọ́n jẹ́ aṣíkiri fi ẹ̀hónú hàn níwájú Ẹ́mbásì Mauritania ní ìlú Paris, ní orílẹ̀-èdè France, lórí àìfiyèsí ìjọba nípa ìṣẹ̀lẹ̀ oró yìí.
Lodun yii ni ojo kejidinlogbon, awon omo Mauritania ti won je asikiri fi ehonu han niwaju Embasi Mauritania ni ilu Paris, ni orile-ede France, lori aifiyesi ijoba nipa isele oro yii.
Kardiata Malick Diallo, tí ó jẹ́ igbákejì, sọ ọrọ àròjinlẹ̀ ní ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Mauritania láti máà jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbàgbé, tí ó sì fi ẹ̀sùn kàn ààrẹ tí ó wà lórí oyè pé ó ń dáàbò bo àwọn oníṣẹ́-ibi náà, tí wọ́n ṣì ń dipò gíga mú nínú ìjọba nígbà tí wọn kò tí ì wá nǹkan ṣe sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa:
Kardiata Malick Diallo, ti o je igbakeji, so oro arojinle ni ile Igbimo asofin Mauritania lati maa je ki awon eniyan gbagbe, ti o si fi esun kan aare ti o wa lori oye pe o n daabo bo awon onise-ibi naa, ti won si n dipo giga mu ninu ijoba nigba ti won ko ti i wa nnkan se si eto awon olufarapa:
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kọ́ ni o ṣe iṣẹ́-ibi tí ó kó àbààwọ́n ba gbogbo ọjọ́ 28 oṣù Belu jẹ́, ìwọ ni ó yẹ kí o wá ojútùú sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa sí òtítọ́ àti òdodo… Àwọn orílẹ̀-èdè olókìkí àti àwọn èèyàn ńlá kì í gbìyànjú láti pa ìṣẹ̀lẹ̀ aburú inú ìtàn-an wọn rẹ́, dípò èyí wọ́n máa ń fi han ayé kí gbogbo ènìyàn lè rántí kí wọ́n sì sọ pé “KÒ TÚN GBỌDỌ̀ ṢẸLẸ̀ MỌ́’. Ọ̀gbẹ́ni ààrẹ, àkósoò rẹ ti ṣe àmúlò òfin ìyàsọ́tọ̀ àti ìyọkúrò ẹ̀yà.
Bi o tile je pe iwo ko ni o se ise-ibi ti o ko abaawon ba gbogbo ojo 28 osu Belu je, iwo ni o ye ki o wa ojutuu si eto awon olufarapa si otito ati ododo… Awon orile-ede olokiki ati awon eeyan nla ki i gbiyanju lati pa isele aburu inu itan-an won re, dipo eyi won maa n fi han aye ki gbogbo eniyan le ranti ki won si so pe “KO TUN GBODO SELE MO’. Ogbeni aare, akosoo re ti se amulo ofin iyasoto ati iyokuro eya.
Ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2018, nínú àwọn adarí ipò ìjọba 24, márùn-ún péré ni àwọn tí ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú àti elẹ́yà-méjì, tí wọ́n ń ṣojú ìdá 70 àwọn mẹ̀kúnù. Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnù ni wọ́n kò ní aṣojú láàárín àwọn aṣojú tí wọ́n dìbò yàn, láàárín àwọn ẹgbẹ́ àbò àti àwọn adarí ipò ìjọba ìbílẹ̀.
Ni osu Owara odun 2018, ninu awon adari ipo ijoba 24, marun-un pere ni awon ti o je alawo dudu ati eleya-meji, ti won n soju ida 70 awon mekunu. Opo awon mekunu ni won ko ni asoju laaarin awon asoju ti won dibo yan, laaarin awon egbe abo ati awon adari ipo ijoba ibile.
Mauritania ni orílẹ̀-èdè tí ó gbẹ́yìn láti pa òwò-ẹrú rẹ ní àgbáyé ní ọdún 1981, ṣùgbọ́n wọn kò fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ títí di ọdún 2007, ìdá 20 àwọn ènìyàn ni wọ́n ṣì ń gbáyé ìṣẹrúsìn tí púpọ̀ nínú wọn sì jẹ́ aláwọ̀ dúdú tàbí elẹ́yà-méjì.
Mauritania ni orile-ede ti o gbeyin lati pa owo-eru re ni agbaye ni odun 1981, sugbon won ko fi idii re mule titi di odun 2007, ida 20 awon eniyan ni won si n gbaye iserusin ti pupo ninu won si je alawo dudu tabi eleya-meji.
Nítorí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà yìí ṣì ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Mauritania, ìdájọ́ òdodo kò sí ní àrọ́wọ́tó fún àwọn ẹni orí-kó-yọ àti àwọn ìdílé wọn.
Nitori iyasoto eya yii si n sele ni orile-ede Mauritania, idajo ododo ko si ni arowoto fun awon eni ori-ko-yo ati awon idile won.
Kí ló dé tí ìjọba Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ń f'òfin de ọ̀rọ̀ sísọ orí-ayélujára? Nítorí wọ́n bẹ̀rù agbára rẹ̀.
Ki lo de ti ijoba Ile-Adulawo n f'ofin de oro siso ori-ayelujara? Nitori won beru agbara re.
Ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ti ń rí ìfúnpa láti ọwọ́ ìjọba díẹ̀ díẹ̀. Nínú ìlànà òfin àti ọ̀rọ̀ Ajé, iye òmìnira ọ̀rọ̀ ń dìde kárí Ilẹ̀-Adúláwọ̀.
Oro siso lori ayelujara ti n ri ifunpa lati owo ijoba die die. Ninu ilana ofin ati oro Aje, iye ominira oro n dide kari Ile-Adulawo.
Nígbà tí àwọn ìjọba kan mọ rírì ètò ìjọba àwa-arawa nípasẹ̀ ṣíṣe ìbò pẹ̀lú ọlọ́pọ̀-ẹgbẹ́ òṣèlú àti sọ nígbangba nípa àjọṣe, nínú ìṣe, ọ̀pọ̀ máa ń lo àṣẹ tí ò ṣe é yí padà wọ́n sì ń lo agbára àṣẹ yìí lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá bí ọjọ́ ṣe ń gun orí ọjọ́.
Nigba ti awon ijoba kan mo riri eto ijoba awa-arawa nipase sise ibo pelu olopo-egbe oselu ati so nigbangba nipa ajose, ninu ise, opo maa n lo ase ti o se e yi pada won si n lo agbara ase yii lori ero-ayarabiasa bi ojo se n gun ori ojo.
Cameroon, Tanzania, Uganda, Ethiopia, Nigeria, àti Benin ti ní Ìtìpa Ẹ̀rọ-ayélujára, ìjọba ti fi owó-orí lé lílo búlọ́ọ̀gù àti ẹ̀rọ-alátagbà, wọ́n sì ti fi ọwọ́ ṣìgún òfin mú oníròyìn. Òṣìṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ọmọ-ìlú ti di èrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn àtẹ̀jáde “ìròyìn irọ́” títí kan ìkóròyìn ìkòkọ̀ ìlú sí etí ìgbọ́ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò.
Cameroon, Tanzania, Uganda, Ethiopia, Nigeria, ati Benin ti ni Itipa Ero-ayelujara, ijoba ti fi owo-ori le lilo buloogu ati ero-alatagba, won si ti fi owo sigun ofin mu oniroyin. Osise iroyin ati awon omo-ilu ti di ero atimole lori esun atejade “iroyin iro” titi kan ikoroyin ikoko ilu si eti igbo egbe afemisofo.
Ní ibi Àpérò Òmìnira Ẹ̀rọ-ayélujára ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (FIFA) tí ó wáyé ní Accra, Ghana, ikọ̀ akópa láti àwọn ìlú ilẹ̀ Adúláwọ̀ pátá sọ wípé kò ní ṣe ẹnu rere bí ìjọba bá fi òfin de ọmọ-ìlú tí ó ń lo ẹ̀rọ-ayárabíaṣá.
Ni ibi Apero Ominira Ero-ayelujara ni Ile-Adulawo (FIFA) ti o waye ni Accra, Ghana, iko akopa lati awon ilu ile Adulawo pata so wipe ko ni se enu rere bi ijoba ba fi ofin de omo-ilu ti o n lo ero-ayarabiasa.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní àwọn òfin àti àbádòfin tí ó fún ọmọ ènìyàn ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ní Nàìjíríà, fún àpẹẹrẹ, Àbádòfin Òmìnira Ọ̀rọ̀ fún ọmọ ìlú ní òmìnira láti béèrè fún ìwífun lọ́wọ́ àjọ ìjọba. Abala 22 ìwé òfin ọdún 1999 pèsè fún ẹ̀tọ́ òmìnira ìròyìn àti Abala 39 fi lélẹ̀ wípé “gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, títí kan òmìnira láti gbá ìròyìn mú àti gba ọgbọ́n àti ìwífun láì sí ìdíwọ́…”
Opo orile-ede lo ni awon ofin ati abadofin ti o fun omo eniyan ni eto si ominira oro siso. Ni Naijiria, fun apeere, Abadofin Ominira Oro fun omo ilu ni ominira lati beere fun iwifun lowo ajo ijoba. Abala 22 iwe ofin odun 1999 pese fun eto ominira iroyin ati Abala 39 fi lele wipe “gbogbo eniyan ni o ni eto si ominira oro siso, titi kan ominira lati gba iroyin mu ati gba ogbon ati iwifun lai si idiwo…”
Síbẹ̀, Nàìjíríà tí tẹ àwọn òfin kan tí ó tẹ orí àwọn ẹ̀tọ́ òkè yìí bọlẹ̀.
Sibe, Naijiria ti te awon ofin kan ti o te ori awon eto oke yii bole.
Abala 24 Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára fi ẹ̀sùn kan “ẹnikẹ́ni tí ó bá tan iṣẹ́-ìjẹ́ tí kò ní òótọ́ kan nínú, tí ó lè fa ìbínú, ìnira, ewu, ìdíwọ́, àfojúdi, ìdáyàfò ọ̀daràn, ọ̀tá, ìkórìíra, tàbí ìbínú láì ní ìdí sí ẹlòmíràn ká tàbí fa kí a fi irúfẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́.”
Abala 24 Ofin Ese ori-ayelujara fi esun kan “enikeni ti o ba tan ise-ije ti ko ni ooto kan ninu, ti o le fa ibinu, inira, ewu, idiwo, afojudi, idayafo odaran, ota, ikoriira, tabi ibinu lai ni idi si elomiran ka tabi fa ki a fi irufe ise-ije bee ranse.”
Ìṣòfin àìdájú àti àwọn gbólóhùn bíi “ìnira” tàbí “ìwọ̀sí” jẹ́ nǹkan tí a ní láti mójútó. Ìjọba àti àwọn àjọ rẹ̀ máa ń sábà fi èyí ṣe bójúbójú fún ìtẹríbọlẹ̀ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.
Isofin aidaju ati awon gbolohun bii “inira” tabi “iwosi” je nnkan ti a ni lati mojuto. Ijoba ati awon ajo re maa n saba fi eyi se bojuboju fun iteribole ominira oro siso.
Ta ni ẹni tí ó ń sọ bóyá ọ̀rọ̀ kan jẹ́ àfojúdi? Ǹjẹ́ ó yẹ kí òṣìṣẹ́ ìjọba ó ṣe ìmúdàgbà àwọ̀-ara tí ó ní ipọn? Ní àgbáyé, ọmọ-ìlú ní ẹ̀tọ́ láti wá àìṣedéédé aláṣẹ ìjọba. Kí ló dé tí Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tí ó ṣe pàtàkì nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ?
Ta ni eni ti o n so boya oro kan je afojudi? Nje o ye ki osise ijoba o se imudagba awo-ara ti o ni ipon? Ni agbaye, omo-ilu ni eto lati wa aisedeede alase ijoba. Ki lo de ti Ile-Adulawo ko ni eto lati se gege bi eka ti o se pataki ninu ominira oro siso?
Ní ọdún 2017 àti 2016, oníròyìn orí-ayélujára ọmọ bíbí ìlú Nàìjíríà àti akọbúlọ́ọ̀gù Abubakar Sidiq Usman àti Kẹ́mi Olúnlọ́yọ̀ọ́ tí ta ẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin nípasẹ̀ ṣíṣe iṣẹ́ ìkóròyìnjọ lóríi Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára.
Ni odun 2017 ati 2016, oniroyin ori-ayelujara omo bibi ilu Naijiria ati akobuloogu Abubakar Sidiq Usman ati Kemi Olunloyoo ti ta ese agere si ofin nipase sise ise ikoroyinjo lorii Ofin Ese ori-ayelujara.
Máà jìyà nínú ìdákẹ́rọrọ máa wí lọ
Maa jiya ninu idakeroro maa wi lo
Ìwà tí ó jẹ́ gbòògì àwọn ìpèníjà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ti òfin ń sọ fún ọmọ-ìlú pé ohùn-un wọn ṣe kókó. Kí a mú un láti Ìdádúró Tanzania tí ó dá lóríi ìtànká “ìròyìn irọ́, ìtànjẹ, tàbí ìròyìn tí ò pé ojú òṣùwọ̀n” lórí ayélujára títí kan owó-orí Uganda fún ìlò ẹ̀rọ-alátagbà fún ìgbógunti “àhesọ”, ariwo orí ẹ̀rọ-ayárabíaṣá ń já àwọn ìjọba aninilára láyà. Ní ìgbà mìíràn, ó máa mú wọn pa àwọn ìwàa wọn tì.
Iwa ti o je gboogi awon ipenija wonyi gege bii ti ofin n so fun omo-ilu pe ohun-un won se koko. Ki a mu un lati Idaduro Tanzania ti o da lorii itanka “iroyin iro, itanje, tabi iroyin ti o pe oju osuwon” lori ayelujara titi kan owo-ori Uganda fun ilo ero-alatagba fun igbogunti “aheso”, ariwo ori ero-ayarabiasa n ja awon ijoba aninilara laya. Ni igba miiran, o maa mu won pa awon iwaa won ti.
Ìrírí akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ìlú Ethiopia jẹ́ àpẹẹrẹ.
Iriri akobuloogu Zone9 ilu Ethiopia je apeere.
Ní ọdún 2014, àwọn òǹkọ̀wé ọmọ bíbí Ethiopia mẹ́sàn-án lọ sí ẹ̀wọ̀n àti jìyà oró látàrí iṣẹ́ àjọṣepọ̀ tí wọ́n jọ kọ nípa ìtẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn ìjọba àná ìlú Ethiopia, kí òótọ́ ó di mímọ̀. Ìjọba pe ẹgbẹ́ yìí ni “afẹ̀míṣòfò” nítorí àtẹ̀jáde orí ẹ̀rọ-ayélujára wọn a sì ti wọ́n mọ́lé fún oṣù 18.
Ni odun 2014, awon onkowe omo bibi Ethiopia mesan-an lo si ewon ati jiya oro latari ise ajosepo ti won jo ko nipa itese agere si eto omo-eniyan ijoba ana ilu Ethiopia, ki ooto o di mimo. Ijoba pe egbe yii ni “afemisofo” nitori atejade ori ero-ayelujara won a si ti won mole fun osu 18.
Àwọn mẹ́fà lára àwọn ẹgbẹ́ náà tí ó ti gba òmìnira báyìí ṣe ìtàkùrọ̀sọ àgbáyé àkọ́kọ́ ní ìlú Ghana ní àsìkò àpérò FIFA: Atnaf Berhane, Befeqadu Hailu Techane, Zelalem Kibret, Natnael Feleke Aberra, àti Abel Wabella náà wá sí àpérò. Jomanex Kasaye, ẹni tí ó ti bá ẹgbẹ́ náà ṣiṣẹ́ kí àtìmọ́lé ó tó ṣẹlẹ̀ (àmọ́ tí a kò fi àṣẹ mú) náà kò gbẹ́yìn níbi àpérò.
Awon mefa lara awon egbe naa ti o ti gba ominira bayii se itakuroso agbaye akoko ni ilu Ghana ni asiko apero FIFA: Atnaf Berhane, Befeqadu Hailu Techane, Zelalem Kibret, Natnael Feleke Aberra, ati Abel Wabella naa wa si apero. Jomanex Kasaye, eni ti o ti ba egbe naa sise ki atimole o to sele (amo ti a ko fi ase mu) naa ko gbeyin nibi apero.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ẹgbẹ́ yìí ti bá Ohùn Àgbáyé ṣe pọ̀ láti kọ àti ṣe ìtúmọ̀ ìròyìn sí èdè Amharic. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé ṣe ìpolongo àti ìpanupọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àgbáyé gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ láti ọjọ́ tí wọ́n dé akoto ọba.
Opolopo ninu egbe yii ti ba Ohun Agbaye se po lati ko ati se itumo iroyin si ede Amharic. Gege bi omo egbe Ohun Agbaye se ipolongo ati ipanupo ajafuneto omoniyan agbaye gege bi agbenuso lati ojo ti won de akoto oba.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tí a tẹ ọ̀kanòjọ̀kan ìròyìn jáde àti ìgbélárugẹ ìtàkùrọ̀sọ ọ̀ràn wọn lórí Twitter, ìdálébi ìfàṣẹmú àti àtìmọ́lé gba ojúlé ìjọba àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní àgbáyé kọjá, láì gbàgbé àwọn ọgọọ́gọ̀rún àti ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún alátìlẹ́yìn orí ẹ̀rọ-ayélujára. Láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, igbe ńlá ni ó gba àwọn akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Ethiopia.
Leyin opolopo osu ti a te okanojokan iroyin jade ati igbelaruge itakuroso oran won lori Twitter, idalebi ifasemu ati atimole gba ojule ijoba ati awon alenuloro ajafuneto omoniyan ni agbaye koja, lai gbagbe awon ogoogorun ati egbeegberun alatileyin ori ero-ayelujara. Lati origun mereerin agbaye, igbe nla ni o gba awon akobuloogu Zone9 sile lowo ijoba ile Ethiopia.
Nínú ọ̀rọ̀ wọn ní FIFA, àwọn akọbúlọ́ọ̀gù náà sọ wípé ìkẹ́gbẹ́ẹ wọn nínú Ohùn Àgbáyé ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà ní àsìkò tí àwọn ń fi aṣọ pénpé ro oko ọba. Ní ètò ìtàkùrọ̀sọ wọn, wọ́n gbé orí yìn fún ìpolongo Ohùn Àgbáyé tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi tí ó mú àwọn wà láyé.
Ninu oro won ni FIFA, awon akobuloogu naa so wipe ikegbee won ninu Ohun Agbaye se gudugudu meje yaya mefa ni asiko ti awon n fi aso penpe ro oko oba. Ni eto itakuroso won, won gbe ori yin fun ipolongo Ohun Agbaye ti o se ise ribiribi ti o mu awon wa laye.
Berhan Taye, atọ́kùn ìtàkùrọ̀sọ, bi ẹgbẹ́ yìí ní ìbéèrè ìrírí wọn ní inú túbú. Bí wọ́n ti ṣe sọ, iná amọ́roro ìtàgé wálẹ̀ díẹ̀. Ohùn-un wọn mú kí iyàrá ètò pa lọ́lọ́.
Berhan Taye, atokun itakuroso, bi egbe yii ni ibeere iriri won ni inu tubu. Bi won ti se so, ina amororo itage wale die. Ohun-un won mu ki iyara eto pa lolo.
Abel Wabella, alákòóso Ohùn Àgbáyé ní ‘ Èdè Amharic , kò fi etí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ kan gbọ́ràn já geere mọ́n láti ara ìjìyà oró tí ó jẹ́ nítorí pé ó kọ̀ láti ti ọwọ́ bọ ìwé ìjẹ́wọ́.
Abel Wabella, alakooso Ohun Agbaye ni ‘ Ede Amharic , ko fi eti egbee re kan gboran ja geere mon lati ara ijiya oro ti o je nitori pe o ko lati ti owo bo iwe ijewo.
Atnaf Berhane rántí wípé òún jẹ ìyà oró di aago méjì òru tí òún padà sí lẹ́yìn oorun díẹ̀.
Atnaf Berhane ranti wipe oun je iya oro di aago meji oru ti oun pada si leyin oorun die.
Ọ̀kan lára àwọn agbófinró tí ó mú Zelalem Kibret ti fi ìgbà kan rí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Kibret ní Ifásitì tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ olùkọ́.
Okan lara awon agbofinro ti o mu Zelalem Kibret ti fi igba kan ri je akekoo Kibret ni Ifasiti ti o ti n se ise oluko.
Jomanex Kasaye náà ṣe ìrántí ìwàyáìjà ọpọlọ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìrònú ìfìlú Ethiopia sílẹ̀ kí wọ́n ó tó fi ọwọ́ òfin mú àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ ìrora àìlágbára ìlàkàkà ọkàn àti àìfẹ̀dọ̀lórí òróòró àti ìbẹ̀rù wípé àwọn ọ̀rẹ́ òhun ò ní jáde láàyè.
Jomanex Kasaye naa se iranti iwayaija opolo ti o ni i se pelu ironu ifilu Ethiopia sile ki won o to fi owo ofin mu awon oree re irora ailagbara ilakaka okan ati aifedolori orooro ati iberu wipe awon ore ohun o ni jade laaye.
Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, àwọn akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 sọ wípé: “A kò kí ń ṣe ẹni tí ó ní okun tàbí ìgboyà.. inúu wa dùn nítorí wípé a fún àwọn ènìyàn mìíràn ní ìmísí ni.”
Pelu irele, awon akobuloogu Zone9 so wipe: “A ko ki n se eni ti o ni okun tabi igboya.. inuu wa dun nitori wipe a fun awon eniyan miiran ni imisi ni.”
Síbẹ̀, akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ṣe àtúnlò ìfẹ́-ìlú-ẹni nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Ó gba ìgboyà láti fẹ́ràn ìlú ẹni pàápàá lẹ́yìn ìjìyà nítorí wípé a sọ̀rọ̀ síta.
Sibe, akobuloogu Zone9 se atunlo ife-ilu-eni ninu oro ati ise. O gba igboya lati feran ilu eni paapaa leyin ijiya nitori wipe a soro sita.
Oníròyìn ọmọ Uganda Charles Onyango-Obbo, tí òun náà wà ní FIFA, mẹ́nu ba òwe Igbo tí gbajúgbajà òǹkọ̀wée nì Chinua Achebe mú di mímọ́ tí ó sọ wípé:
Oniroyin omo Uganda Charles Onyango-Obbo, ti oun naa wa ni FIFA, menu ba owe Igbo ti gbajugbaja onkowee ni Chinua Achebe mu di mimo ti o so wipe:
Níwọ̀n ìgbà tí òde ti já ọgbọ́n àtamátàsè, ẹyẹ Eneke náà ti kọ́ fífò láì bà.
Niwon igba ti ode ti ja ogbon atamatase, eye Eneke naa ti ko fifo lai ba.
Ní àkótán, ohun tí ó fẹ́ sọ ní wípé láti mú ayélujára wà ní ipò ọ̀fẹ́ àti ààbò, àwọn tí ó ń jà fún èyí nílò láti wá ọgbọ́n mìíràn dá.
Ni akotan, ohun ti o fe so ni wipe lati mu ayelujara wa ni ipo ofe ati aabo, awon ti o n ja fun eyi nilo lati wa ogbon miiran da.
Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ tí ó ń lé iwájú nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìlú-Gúúsù-Aṣálẹ̀-Sàhárà àti káríayé kò gbọdọ̀ ṣe aláì máà wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣ'àdá lórí ọ̀ràn yìí. Pẹ̀lú agbára àti àjọṣe wa, ẹ̀rọ-ayélujára yóò di ibi òmìnira fún ìtẹ̀síwájú ìjọba àwa-arawa.
Awon ajafuneto ti o n le iwaju ninu ominira oro siso ni ilu-Guusu-Asale-Sahara ati kariaye ko gbodo se alai maa wa woroko fi s'ada lori oran yii. Pelu agbara ati ajose wa, ero-ayelujara yoo di ibi ominira fun itesiwaju ijoba awa-arawa.
Òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú olóbìrin nìkan wọ ìwé ìtàn ní Mozambique
Osise inu oko ofuurufu olobirin nikan wo iwe itan ni Mozambique
Ọjọ́ ìtàn ni ọjọ́ yìí: ojú yìí ni ogunlọ́gọ̀ ọmọ-ìlú Mozambique fi wo ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018 nígbà tí, fún ìgbà àkókọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé ètò ọkọ̀ òfuurufú ìlú náà, tí obìnrin jẹ́ atukọ̀.
Ojo itan ni ojo yii: oju yii ni ogunlogo omo-ilu Mozambique fi wo isele ojo 14, osu Ope odun 2018 nigba ti, fun igba akoko ninu itan igbesi aye eto oko ofuurufu ilu naa, ti obinrin je atuko.
Ikọ̀ bàlúù TM112/3, tí ó rin ìrìn àjò láti olú ìlú, Maputo, àti Manica tí jíjìn sí ara wọn tó máìlì 442 ni a tí rí atukọ̀ Admira António, atukọ̀ kejì Elsa Balate, olóyè ọkọ̀ Maria da Luz Aurélio, àti òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ Débora Madeleine.
Iko baluu TM112/3, ti o rin irin ajo lati olu ilu, Maputo, ati Manica ti jijin si ara won to maili 442 ni a ti ri atuko Admira Antonio, atuko keji Elsa Balate, oloye oko Maria da Luz Aurelio, ati osise inu oko Debora Madeleine.
Àwọn obìrin wọ̀nyí wà nínú ẹgbẹ́ MEX, ilé-iṣẹ́ tí a dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àkànṣe LAM Linhas Aéreas de Moçambique. Ní 1995, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bíi ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú aládàáni , Mozambique Express.
Awon obirin wonyi wa ninu egbe MEX, ile-ise ti a da sile gege bii Eka Ise Akanse LAM Linhas Aereas de Mocambique. Ni 1995, o bere ise bii ile-ise oko ofuurufu aladaani , Mozambique Express.
Àtẹ̀jáde ìkíni orí Facebook láti ọwọ́ ajàfúnẹ̀tọ́ obìrin Eliana Nzualo, ti ní ìsọsí tí ó tó 450, tí a ti pín tó ìgbà 460, àti pé ọ̀pọ̀ èsì tí ó tó 2,000 ni ó gbà:
Atejade ikini ori Facebook lati owo ajafuneto obirin Eliana Nzualo, ti ni isosi ti o to 450, ti a ti pin to igba 460, ati pe opo esi ti o to 2,000 ni o gba:
ỌJỌ́ ÌTÀN – Ikọ̀ ọkọ̀ òfuurufú TM
OJO ITAN – Iko oko ofuurufu TM
MEX kú oríire!
MEX ku oriire!
Ikọ̀ ẹ kú oríire!
Iko e ku oriire!
Mozambique, kú oríire!
Mozambique, ku oriire!
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìrin nínú iṣẹ́ gbogbo.
Fun opolopo obirin ninu ise gbogbo.
Àjàfúnẹ̀tọ́ ìkẹ́gbẹ́ Mauro Brito sọ ní tirẹ̀ wípé obìrin gbọ́dọ̀ ní ìgbéraga “nígbàtí [wọ́n] bá jẹ́ aṣojú nínú iṣẹ́ gbogbo”:
Ajafuneto ikegbe Mauro Brito so ni tire wipe obirin gbodo ni igberaga “nigbati [won] ba je asoju ninu ise gbogbo”:
Obìrin kò pọ̀ nínú iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe rí káríayé. Mo rò ó wípé àwọn obìrin tí ó ronú láti ṣe iṣẹ́ tí ọkùnrin máa ń ṣe, gbọdọ̀ gbéraga.
Obirin ko po ninu ise oko ofuurufu, bee ni o si se ri kariaye. Mo ro o wipe awon obirin ti o ronu lati se ise ti okunrin maa n se, gbodo gberaga.
Mozambique nìkan kọ́. Ní oṣù Ògún ọdún 2018, nínú ọkọ̀ òfuurufú ìlú apá Gúúsù Ilẹ̀-Adúláwọ̀ SAA, ìrìnàjò ìlú dé ìlú pẹ̀lú ikọ̀ olóbìrin fò ní ojú sánmà wọ́n sì kó èrò láti Johannesburg sí Sao Paulo, Brazil.
Mozambique nikan ko. Ni osu Ogun odun 2018, ninu oko ofuurufu ilu apa Guusu Ile-Adulawo SAA, irinajo ilu de ilu pelu iko olobirin fo ni oju sanma won si ko ero lati Johannesburg si Sao Paulo, Brazil.
Oṣù méjìlá sẹ́yìn, ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2017, Ilé-iṣẹ́ Ọkọ̀ òfuurufú Ethiopia fún ìgbà àkókọ́ gbé ikọ̀ òṣìṣẹ́bìrin fò. Awọn atukọ̀ títí kan òṣìṣẹ́ gbogbo, ọkọ̀ òfuurufú láti Addis Ababa ní Ethiopia sí Èkó ní Nàìjíríà jẹ́ obìrin pátápátá porongodo.
Osu mejila seyin, ni osu Ope odun 2017, Ile-ise Oko ofuurufu Ethiopia fun igba akoko gbe iko osisebirin fo. Awon atuko titi kan osise gbogbo, oko ofuurufu lati Addis Ababa ni Ethiopia si Eko ni Naijiria je obirin patapata porongodo.
Oníròyìn Orí ẹ̀rọ-alátagbà Luis Carlos Diaz di àwátì ní Venezuela
Oniroyin Ori ero-alatagba Luis Carlos Diaz di awati ni Venezuela
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ 11, oṣù Ẹrẹ́nà olùfèsì sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú Naky Soto tí ó tún jẹ́ aya akọ̀ròyìn àti ajììjàǹgbara iṣẹ́ ìròyìn tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ Venezuela, Luis Carlos Díaz túwíìtì pé òun ti ń wá ọkọ òun fún wákàtí márùn-ún.
Ni irole ojo 11, osu Erena olufesi si oro iselu Naky Soto ti o tun je aya akoroyin ati ajiijangbara ise iroyin ti o je omo orile Venezuela, Luis Carlos Diaz tuwiiti pe oun ti n wa oko oun fun wakati marun-un.
[Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́] Àjọ àwọn Òṣìṣẹ́ Ìròyìn (SNTP lédè Spanish) jábọ̀ pé àwọn Agbófinró Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Bolivaria (SEBIN) ti fi Luis Carlos sí àtìmọ́lé.
[Iroyin ti o te wa lowo] Ajo awon Osise Iroyin (SNTP lede Spanish) jabo pe awon Agbofinro Otelemuye Bolivaria (SEBIN) ti fi Luis Carlos si atimole.
PÀJÁWÌRÌ Àjọ Sebin kan fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé akọ̀ròyìn Luis Carlos Diaz ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá yẹn. Wọ́n yọ àwọn ohun ìjà ti akọ̀ròyìn Marco Ruiz, Luz Mely Rehes àti Federico Black [pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìròyìn.
PAJAWIRI Ajo Sebin kan fidii re mule pe akoroyin Luis Carlos Diaz ti wa ni ahamo awon olopaa yen. Won yo awon ohun ija ti akoroyin Marco Ruiz, Luz Mely Rehes ati Federico Black [pelu awon omo egbe osise iroyin.
Wákàtí díẹ̀ sẹ́yìn, Soto túwíìtì pé àwọn ti ń wá Luis Carlos Díaz fún wákàtí márùn-ún:
Wakati die seyin, Soto tuwiiti pe awon ti n wa Luis Carlos Diaz fun wakati marun-un:
Ẹ̀yin èèyàn àtàtà: Mi ò rí LuisCarlos bá sọ̀rọ̀ láti aago 5:30 lọ́sàn-án yìí, ó sì sọ fún mi pé òun ń bọ̀ nílé láti sinmi nítorí pé òun ní ìkéde pàtàkì kan láti se lórí Unionradionet láti aago 10:00 alẹ́ sí 5:00 ìdájí DóndeEstáLuisCarlos
Eyin eeyan atata: Mi o ri LuisCarlos ba soro lati aago 5:30 losan-an yii, o si so fun mi pe oun n bo nile lati sinmi nitori pe oun ni ikede pataki kan lati se lori Unionradionet lati aago 10:00 ale si 5:00 idaji DondeEstaLuisCarlos
LuisCarlos wà ní orí kẹ̀kẹ́ẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n láti aago 5:30 ni mi kò ti gbúròó rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀:
LuisCarlos wa ni ori kekee re, sugbon lati aago 5:30 ni mi ko ti gburoo re mo, bee:
Kò sí ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà
Ko si ni ile ise igbohunsafefe naa
Kò sí nílé
Ko si nile
Kò tíì túwíìtì
Ko tii tuwiiti
Kò gbé ìpèe rẹ̀
Ko gbe ipee re
Kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí iṣẹ́-ìjẹ́ oríi WhatsApp
Ko fesi si atejise tabi ise-ije orii WhatsApp
[Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́] Luz Mely Reyes tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojúu rẹ̀, fi tó wa létí nípa bí àwọn Agbófinró SEBIN ṣe yẹ ilée Díaz pẹ̀lú ilée Soto náà wò. Ìsọ̀kan àwọn Oníròyìn náà fẹ ọ̀rọ̀ náà lójú:
[Iroyin to tewa lowo] Luz Mely Reyes ti isele naa se ojuu re, fi to wa leti nipa bi awon Agbofinro SEBIN se ye ilee Diaz pelu ilee Soto naa wo. Isokan awon Oniroyin naa fe oro naa loju:
NÍ KÍÁKÍÁ Ní dédé àsìkò yìí, ní dédé agogo 3:00 òwúrọ̀ kùtùkùtù, ìgbìmọ̀ láti àjọ Amúninípá dé ilé oníròyìn àti ajà-fún- ẹ̀tọ́ọ ọmọ ènìyàn Luis Carlos Díaz, tí ó ti di ẹni àwátì láti agogo 5:30 ìrọ̀lẹ́ .
NI KIAKIA Ni dede asiko yii, ni dede agogo 3:00 owuro kutukutu, igbimo lati ajo Amuninipa de ile oniroyin ati aja-fun- etoo omo eniyan Luis Carlos Diaz, ti o ti di eni awati lati agogo 5:30 irole .
Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àjọ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ náà darapọ̀ mọ ìpolongo yìí pẹ̀lú DondeEstaLuisCarlos (Níbo ni Luis Carlos wà?), tí ó jẹ́ pé, ní báyìí, ni àkọlé tí ó gbajúmọ̀ ní orí ìkànnì ayélujára Twitter ti Orílẹ̀ Èdè Venezuela.
Awon ajafuneto omoniyan ati ajo ominira oro siso naa darapo mo ipolongo yii pelu DondeEstaLuisCarlos (Nibo ni Luis Carlos wa?), ti o je pe, ni bayii, ni akole ti o gbajumo ni ori ikanni ayelujara Twitter ti Orile Ede Venezuela.
Díaz jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn àti a-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọ ènìyàn tí ó jẹ́ ògbólógbòó ajàfúnẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n sì mọ ìṣe rẹ̀ fún un l'órílẹ̀ èdè Venezuela àti òkè òkun fún ìdásọ́rọ̀ àti ìtakò ìjọba Nicholas Maduro. Ó ti tó ìgbà díẹ̀ kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti olùdásọ́rọ̀ òṣèlú tí ó gbajúmọ̀ n nì, Naky Soto, tí wọn sì ń ṣe ìgbéjáde àwọn fídíò àti ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ayélujára èyí tí ó dá lórí ìṣèlú àti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní Venezuela. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ́ni àti olùgbé-lárúgẹ ìdásílẹ̀ àyè ọ̀tọ̀ fún àwọn ará ìlú àti àwọn àkànṣe eto ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ tí kò lọ́wọ́ ìjọ̀ba nínú. Díaz tún jẹ́ olùkópa nínú ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé fún ọdún mẹ́wàá.
Diaz je ajabo iroyin ati a-ja-fun-eto-omo eniyan ti o je ogbologboo ajafuneto ominira oro siso ti won si mo ise re fun un l'orile ede Venezuela ati oke okun fun idasoro ati itako ijoba Nicholas Maduro. O ti to igba die kan ti o ti n sise pelu iyawo re ati oludasoro oselu ti o gbajumo n ni, Naky Soto, ti won si n se igbejade awon fidio ati eto Igbohunsafefe lori ayelujara eyi ti o da lori iselu ati eto omo eniyan ni Venezuela. O ti sise gege bi akoni ati olugbe-laruge idasile aye oto fun awon ara ilu ati awon akanse eto igbohun safefe ti ko lowo ijoba ninu. Diaz tun je olukopa ninu egbe Ohun Agbaye fun odun mewaa.
Lọ́dọ̀ tèmi, Luis Carlos jẹ́ onílàákàyè ẹ̀dá kan, ó gbọ́njú nínú ìròyìn gbígbà àti ìkànsì-ara-ẹni nínú Venezuela ti wa yìí tí kò fara rọ. Ó ti ṣe àwárí ìjápọ̀ nínú ìlú (láti ìtakò sí ibi ìṣẹ̀ṣe) .
Lodo temi, Luis Carlos je onilaakaye eda kan, o gbonju ninu iroyin gbigba ati ikansi-ara-eni ninu Venezuela ti wa yii ti ko fara ro. O ti se awari ijapo ninu ilu (lati itako si ibi isese) .
Láàrin ọjọ́ péréte tó ṣíwájú ìpòóráa rẹ̀, ètò ìkàn-sára- ẹni ti ìjọba Con el Mazo Dando ṣàfihàn fídíò tí Díaz sọ̀rọ̀ nínúu rẹ̀. Atọ́kùn ètò ọ̀hún, olóṣèlú Diosdado Cabello, rò kàn pé Díaz lọ́wọ́ sí ìfẹ̀hónú hàn àìsí ináa mọ̀nàmọ̀nà tí ò lọ jákèjádò orílẹ̀ èdè èyí tí ó mú kí àwọn ọmọ Venezuela máa gbé nínú òkùnkùn fún ó lé ní wákàtí mẹ́rin lé lógún lọ́jọ́ 7 àti 8 Oṣù Ẹrẹ́nà
Laarin ojo perete to siwaju ipooraa re, eto ikan-sara- eni ti ijoba Con el Mazo Dando safihan fidio ti Diaz soro ninuu re. Atokun eto ohun, oloselu Diosdado Cabello, ro kan pe Diaz lowo si ifehonu han aisi inaa monamona ti o lo jakejado orile ede eyi ti o mu ki awon omo Venezuela maa gbe ninu okunkun fun o le ni wakati merin le logun lojo 7 ati 8 Osu Erena
Kò sí ẹ̀rí tí ó fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀.
Ko si eri ti o fi ese rinle.
Bí ọjọ́ ṣe ń lọ láì rí ẹ̀rí tí ó yanrantí dì mú, SNTP darapọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò sí olú ilé iṣẹ́ẹ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ :
Bi ojo se n lo lai ri eri ti o yanranti di mu, SNTP darapo ti o bere abewo si olu ile isee Otelemuye :
Wákàtí méje ti ré kọjá lọ tí Luis Carlos Díaz ti di àwátì. [Díaz] jẹ́ oníròyìn fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Unión Radio Noticias , ó sì tún jẹ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.
Wakati meje ti re koja lo ti Luis Carlos Diaz ti di awati. [Diaz] je oniroyin fun ile ise igbohunsafefe Union Radio Noticias , o si tun je ajafuneto omoniyan.
Àwa ní olú ilé iṣẹ́ẹ SEBIN headquarters àti pé wọ́n ní àwọn kò ní í [ní àhámọ́ àwọn] .
Awa ni olu ile isee SEBIN headquarters ati pe won ni awon ko ni i [ni ahamo awon] .
[Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́: wọ́n pàpà jẹ́wọ́ wípé [Diaz wà ní akolóo wọn]
[Iroyin ti o te wa lowo: won papa jewo wipe [Diaz wa ni akoloo won]
Akọ̀ròyìn Vladimir Villegas sọ wípé kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ wípé ìjọba ni ó fi ọwọ́ agbára mú u:
Akoroyin Vladimir Villegas so wipe ko ri bee mo wipe ijoba ni o fi owo agbara mu u:
Olóbó ti ta wá wípé oníròyìn fún Unionradionet Luis Carlos Díaz, ti wà nínú àtìmọ́lé agbófinró Ìlú. A bá a kẹ́dùn ipò tí ó wà. A béèrè fún ìtọ́sọ́nà nípa mímọ ibi tí ó wà, àti ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn-an rẹ̀.
Olobo ti ta wa wipe oniroyin fun Unionradionet Luis Carlos Diaz, ti wa ninu atimole agbofinro Ilu. A ba a kedun ipo ti o wa. A beere fun itosona nipa mimo ibi ti o wa, ati ibowo fun eto omoniyan-an re.
Ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé dúró ṣinṣin pẹ̀lú Luis Carlos, ẹbíi rẹ̀, àti oníròyìn aládàáṣiṣẹ́ gbogbo àwọn tí ó ń mú ìjọba ṣe bí ó ti yẹ ní Venezuela. À ń retíi rẹ̀ kí ó dé kíákíá ní àlàáfíà ara àti ẹ̀mí, a ó máa gbé àwọn ìròyìn síta nípa ìròyìn yìí bí ó ba ṣe ń tẹ̀ wá lọ́wọ́.
Egbe Ohun Agbaye duro sinsin pelu Luis Carlos, ebii re, ati oniroyin aladaasise gbogbo awon ti o n mu ijoba se bi o ti ye ni Venezuela. A n retii re ki o de kiakia ni alaafia ara ati emi, a o maa gbe awon iroyin sita nipa iroyin yii bi o ba se n te wa lowo.
‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn
‘Ohun-un Jamaica fun Ayipada Oju-ojo’ fi orin jisee won
Bí orin reggae àti dancehall ṣe ń lọ ni àwọn ìpolongo tí ó ń sọ nípa ohun gbogbo láti ọṣẹ ìfọṣọ àbùfọ̀ sí oúnjẹ àsèsílẹ̀, orin ni ènìyán lè gbà dé ọkàn ọmọ Jamaica èyí ló mú Panos Caribbean, ẹni tí ó ní ilé iṣẹ́ ìròyìn tí kì í ṣe ti ìjọba, láti fi orin kéde nípa ọ̀rọ̀ àyíká. Iléeṣẹ́ náà ti yege nínúu ìtànká àwọn ìkéde tí ó ṣe kókó nípasẹ̀ẹ iṣẹ́ Ohùn fún Àyípadà Ojú-ọjọ́.
Bi orin reggae ati dancehall se n lo ni awon ipolongo ti o n so nipa ohun gbogbo lati ose ifoso abufo si ounje asesile, orin ni eniyan le gba de okan omo Jamaica eyi lo mu Panos Caribbean, eni ti o ni ile ise iroyin ti ki i se ti ijoba, lati fi orin kede nipa oro ayika. Ileese naa ti yege ninuu itanka awon ikede ti o se koko nipasee ise Ohun fun Ayipada Oju-ojo.
Kedere ni ohùn ń jáde láti inú ilé àpérò ìlú-mọ̀ńká United Nations Conference ní Paris (COP21) lọ́dún-un 2015. Níbẹ̀, ọ̀kọrin ọmọ Jamaica Aaron Silk darapọ̀ mọ́ àwọn olórin mìíràn pẹ̀lú eléré Belizean Adrian Martinez láti ṣe alágbàáwí ìdínkù fún ìgbóná àgbáyé sí ìwọ̀n-ọn ojúàmì 1.5.
Kedere ni ohun n jade lati inu ile apero ilu-monka United Nations Conference ni Paris (COP21) lodun-un 2015. Nibe, okorin omo Jamaica Aaron Silk darapo mo awon olorin miiran pelu elere Belizean Adrian Martinez lati se alagbaawi idinku fun igbona agbaye si iwon-on ojuami 1.5.
Ìfiránṣẹ́ olórin náà, tí ó ṣe àtìlẹ́yìn, ipòo ti ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Erékùṣù Kéékèèké Tí-ó-ń-gòkè, jẹ́ ohun àfiyèsí, tí ó ń ní ipa nínúu ìwé-ìpamọ́ ìkẹyìn-in ti COP21.
Ifiranse olorin naa, ti o se atileyin, ipoo ti idasile Ipinle Erekusu Keekeeke Ti-o-n-goke, je ohun afiyesi, ti o n ni ipa ninuu iwe-ipamo ikeyin-in ti COP21.
Ọdún gorí ọdún, iṣẹ́ “1.5 túbọ̀ ń rinlẹ̀ sí i ní ìlà-oòrùn Caribbean, níbi tí àwọn ọ̀kọrin ti ṣe àlọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ akéwì St. Lucian Kendel Hippolyte’s pẹ̀lú orin-in ti wọn láti ṣe àrídájú wípé iṣẹ́ náà dé ibi tí ó yẹ kí ó dé.
Odun gori odun, ise “1.5 tubo n rinle si i ni ila-oorun Caribbean, nibi ti awon okorin ti se alopo oro akewi St. Lucian Kendel Hippolyte’s pelu orin-in ti won lati se aridaju wipe ise naa de ibi ti o ye ki o de.
Wàhálà àyípadà ojú-ọjọ́ ní ọdún-un 2019 jẹ́ ohun tí ó nílò àbójútó kíákíá ju ti ìdúnrin lọ, àti ní Jamaica, àwọn ará ìgbèríko tí ó jẹ́ àgbẹ̀, àwọn apẹja ń gbọ́ ìpè itanijí yìí. Akọrin, ọmọ ilé ìwé àti àwọn aládùúgbò péjọ ní Kingston, Lionel Town, Ridge Red Bank àti White River fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin nínúu oṣù Ẹrẹ́nà àti Igbe. Níbẹ̀, wọ́n fi ẹ̀kọ́ kún ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìtàkùrọ̀sọ àti kọ́ nípa ipa àyípadà ojú-ọjọ́. Ọ̀rọ̀ orin tí ó lágbára gbérí, ọgbọ́n ń tayọ àti ìrìnàjò ìṣíjú ojú ẹsẹ̀:
Wahala ayipada oju-ojo ni odun-un 2019 je ohun ti o nilo abojuto kiakia ju ti idunrin lo, ati ni Jamaica, awon ara igberiko ti o je agbe, awon apeja n gbo ipe itaniji yii. Akorin, omo ile iwe ati awon aladuugbo pejo ni Kingston, Lionel Town, Ridge Red Bank ati White River fun idanilekoo olojo merin ninuu osu Erena ati Igbe. Nibe, won fi eko kun eko imo itakuroso ati ko nipa ipa ayipada oju-ojo. Oro orin ti o lagbara gberi, ogbon n tayo ati irinajo isiju oju ese:
Ìyá Ilẹ̀-ayé ń ké tantan
Iya Ile-aye n ke tantan
Nínú igbó kìjikìji níbi tí àwọn igi ń wó sí
Ninu igbo kijikiji nibi ti awon igi n wo si
Wo òkúta ìsàlẹ̀ òkun, wo ẹja bí ó ṣe kéré
Wo okuta isale okun, wo eja bi o se kere
Fún wọn ní àsìkò, jẹ́ kí wọ́n dàgbà àti ga
Fun won ni asiko, je ki won dagba ati ga
Àwọn akọrin láti Kingston, Clarendon àti Spanish Town ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lóríi ọ̀rọ̀ orin níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìfiṣẹ́ránṣẹ́ Àyípadà Ojú-ọjọ́. Àwòrán-an Emma Lewis, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.
Awon akorin lati Kingston, Clarendon ati Spanish Town n sise po lorii oro orin nibi idanilekoo Ifiseranse Ayipada Oju-ojo. Aworan-an Emma Lewis, a lo o pelu ase.