diacritcs
stringlengths 1
36.7k
| no_diacritcs
stringlengths 1
35.5k
|
---|---|
Pakistan ti ń sún kẹ́rẹ́ ní ti ìgbé ayé Abódiakọ-akọ́diabo. Díẹ̀ lára àwọn abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn du ipò ìjọba nínú Ìbò ọdún 2018 fún ìgbà àkọ́kọ́. Ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ìbílẹ̀ kan gba Abódiakọ-akọ́diabo àkọ́kọ́ sí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atọ́kùn; Coke Studio, ètò orin, àwọn Abódiakọ-akọ́diabo méjì ni ó ti kópa ní orí ètò náà. slowly starting to make strides when it comes to transgender visibility. | Pakistan ti n sun kere ni ti igbe aye Abodiako-akodiabo. Die lara awon abodiako-akodiabo eniyan du ipo ijoba ninu Ibo odun 2018 fun igba akoko. Ile ise amohunmaworan ibile kan gba Abodiako-akodiabo akoko si ise gege bi atokun; Coke Studio, eto orin, awon Abodiako-akodiabo meji ni o ti kopa ni ori eto naa. slowly starting to make strides when it comes to transgender visibility. |
Bí nǹkan ṣe ń ṣe ẹnu ire fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo a sì ń gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ìrìnàjò náà kò yàrá. Síbẹ̀, ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó ní ìgbàgbọ́ wípé àyípadà ọ̀tún ń bọ̀ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti gbé ìgbé ayé ìfọkànbalẹ̀ nígbà tí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbogbo ní ìlú á wà ní ọ̀gbọọgba ní ojú àwọn ènìyàn àti ní abẹ́ òfin. | Bi nnkan se n se enu ire fun awon omo egbe Abodiako-akodiabo a si n gba won gege bi eniyan, irinajo naa ko yara. Sibe, ogoro eniyan ni o ni igbagbo wipe ayipada otun n bo fun awon eniyan wonyi lati gbe igbe aye ifokanbale nigba ti eto omoniyan gbogbo ni ilu a wa ni ogboogba ni oju awon eniyan ati ni abe ofin. |
Àdàwólulẹ̀ ilé ayé-àtijọ́ ọlọ́dún-un 150 fi àìkáràmáìsìkí ìjọba sí àwọn ibi àjogúnbáa Bangladesh hàn | Adawolule ile aye-atijo olodun-un 150 fi aikaramaisiki ijoba si awon ibi ajogunbaa Bangladesh han |
Ní Dhaka, ilé àjogúnbá ọlọ́gọ́rùn-ún ọdún kan di àdàwólulẹ̀ pátá ní alẹ́ ọjọ́ Ìtunu Àwẹ̀ 5, oṣù Òkúdù 2019. Ní nǹkan bíi ọdún-un 1870 ni a kọ́ ilé náà tí ó fẹ́ẹ́ dà bíi ọkọ̀ ojú-omi, tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń pè ní “Jahaj Bari”, òun sì ni ilé àyágbé àkọ́kọ́ ni olú-ìlúu Bangladesh. Àdàwólulẹ̀ tí a da ilé yìí ti mú kí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ó sọ ẹ̀dùn ọkàn-an wọn síta lórí àìbìkítà fún àwọn ilé tí ó jẹ́ ohun ìṣúra Dhaka. | Ni Dhaka, ile ajogunba ologorun-un odun kan di adawolule pata ni ale ojo Itunu Awe 5, osu Okudu 2019. Ni nnkan bii odun-un 1870 ni a ko ile naa ti o fee da bii oko oju-omi, ti awon omo ibile n pe ni “Jahaj Bari”, oun si ni ile ayagbe akoko ni olu-iluu Bangladesh. Adawolule ti a da ile yii ti mu ki awon opo eniyan o so edun okan-an won sita lori aibikita fun awon ile ti o je ohun isura Dhaka. |
Ìròyìn fi yé wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà lórí ipò ìyẹn Awami League gbé ẹ̀rọ tatapùpù wá sí ibẹ̀, wọ́n sì da ilé náà wó. Àwọn tí ó wá ṣiṣẹ́ náà sọ wípé olóríi àwọn, ọmọ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ (Dhaka-7) Haji Md. Salim, ti ra ilẹ̀ náà láti fi kọ́ ilé alájà tó pọ̀ sí ibùdó náà. Bákan náà àwọn alátìlẹ́yìn AL sọ wípé ilé àtijọ́ náà kò sí lóríi àwọn ibi àjogúnbá tí ó wà nínú àkọsílẹ̀. | Iroyin fi ye wipe awon omo egbe oselu ti o wa lori ipo iyen Awami League gbe ero tatapupu wa si ibe, won si da ile naa wo. Awon ti o wa sise naa so wipe olorii awon, omo igbimo ibile (Dhaka-7) Haji Md. Salim, ti ra ile naa lati fi ko ile alaja to po si ibudo naa. Bakan naa awon alatileyin AL so wipe ile atijo naa ko si lorii awon ibi ajogunba ti o wa ninu akosile. |
Ní ọjọ́ 13, oṣù Ògún ọdún-un 2018, Ilé-ẹjọ́ Gíga Dhaka pàṣẹ fún àjọ ìjọba tí ó ń rí sí ètò ìdàgbàsókè ìlú ní ìlànà tìgbàlódé ní Dhaka láti máà wó tàbí tún àwọn ilé àjogúnbá tí ó wà ní olú-ìlú náà tó bíi 2,200 kọ́. Jahaj Bari wà nínú àwọn ilé àkọ́pọ̀ Waqf (mortmain) tí kò ṣe é tà. Gẹ́gẹ́ bí alákòóso Bangladesh Waqf Administratioń ṣe sọ, gbígba àṣẹ pọn dandan láti gbé iṣẹ́ sílẹ̀, tà tàbí ṣe àtúnṣe sí ohunkóhun tí ó bá jẹ́ ti Waqf. Èyí kò rí bí ajàfẹ́tọ̀ọ́ AL náà ti ṣe wí, kò sí ohun tó jọ ọ́, kò sí àṣẹ tí ó ní kí wọ́n tà tàbí wó ilé tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí. | Ni ojo 13, osu Ogun odun-un 2018, Ile-ejo Giga Dhaka pase fun ajo ijoba ti o n ri si eto idagbasoke ilu ni ilana tigbalode ni Dhaka lati maa wo tabi tun awon ile ajogunba ti o wa ni olu-ilu naa to bii 2,200 ko. Jahaj Bari wa ninu awon ile akopo Waqf (mortmain) ti ko se e ta. Gege bi alakooso Bangladesh Waqf Administration se so, gbigba ase pon dandan lati gbe ise sile, ta tabi se atunse si ohunkohun ti o ba je ti Waqf. Eyi ko ri bi ajafetoo AL naa ti se wi, ko si ohun to jo o, ko si ase ti o ni ki won ta tabi wo ile ti a n soroo re yii. |
Nínú oṣùu Ẹrẹ́nà ọdún-un 2019, a gbé ìgbésẹ̀ kan láti da ilé náà wó lulẹ̀. Urban Study Group, ẹgbẹ́ aṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́-tí-kò-ní-èrè tí ó máa ń fi ààbò fún àwọn ohun àjogúnbá Dhaka Àtijọ́ fi ìwé ẹ̀dùn ìdáwọ́dúróo àdàwólulẹ̀ náà ránṣẹ́ sí àwọn tí ọ̀rán kàn, tí ó sì mẹ́nu ba àṣẹ Ilé-ẹjọ́ Gíga. | Ninu osuu Erena odun-un 2019, a gbe igbese kan lati da ile naa wo lule. Urban Study Group, egbe asise ofe-ti-ko-ni-ere ti o maa n fi aabo fun awon ohun ajogunba Dhaka Atijo fi iwe edun idawoduroo adawolule naa ranse si awon ti oran kan, ti o si menu ba ase Ile-ejo Giga. |
Síbẹ̀, bí ìwé ìròyìn ṣe jábọ̀, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń yọ̀ fún àdàwólulẹ̀ ilé náà. Wọ́n ò mọ̀ pé ilé náà ti di ẹgẹrẹmìtì, ó sì lè wò lulẹ̀ kí ó wó lù wọ́ntí í ṣe àpẹẹrẹ àìmọ̀kanmọ̀kàn àwọn ènìyàn sí ìpamọ́ ohun àjogúnbá àti àtìlẹ́yìn fún àtúnṣe sí ilé àtijọ́ tí ó wà ní Bangladesh. | Sibe, bi iwe iroyin se jabo, die lara awon omo ibile n yo fun adawolule ile naa. Won o mo pe ile naa ti di egeremiti, o si le wo lule ki o wo lu wonti i se apeere aimokanmokan awon eniyan si ipamo ohun ajogunba ati atileyin fun atunse si ile atijo ti o wa ni Bangladesh. |
Àjogúnbá Ìṣẹ̀lẹ̀ Àtẹ̀yìnwá ọ̀rọ̀ tí ò jẹ́ mọ́ nǹkan | Ajogunba Isele Ateyinwa oro ti o je mo nnkan |
Ọ̀pọ̀ ènìyàn l'ó fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àmúdipẹ̀tẹ́lẹ̀ ilé náà. Shuvra Kar kọ sí oríi Facebook: | Opo eniyan l'o fi edun okan-an won han nigba ti won gbo nipa amudipetele ile naa. Shuvra Kar ko si orii Facebook: |
Àjogúnbá , ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá, àṣá jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò já mọ́ nǹkan ní orílẹ̀-èdè yìí! | Ajogunba , itan-isele-ateyinwa, asa je oro ti ko ja mo nnkan ni orile-ede yii! |
Òǹkọ̀wé Tania Kamrun Nahar tan ìmọ́lẹ̀ sí ìdí tí kò fi yẹ kí ilé yìí di àdàwólulẹ̀: | Onkowe Tania Kamrun Nahar tan imole si idi ti ko fi ye ki ile yii di adawolule: |
Ilé alájà-mẹ́ta náà “Jahaj Bari” ní àwọn iṣẹ́ ọnà tí ó yàrà ọ̀tọ̀ lára ní ara irin àgbọ́wọ́lé gun àkàsọ̀. Iṣẹ́ ọnà aláràbarà ti orí òrùlé ibi ìbojúwòta gígùn. Ọ̀kanòjọ̀kan ọnà ni ó wà ní ara ilé náà àwọn àràbarà ọnà abẹ́ àjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òpó ní àwòṣe ọnà ilée ionic àti Corinthian. Ọnà ara ilé náà kọjá àfẹnusọ tí a kò le è rí lára àwọn ilé mìíràn ní àwọn agbègbè àtijọ́ọ Dhaka. Fún ìdí èyí, kò yẹ kí ilé náà di àdàwólulẹ̀. | Ile alaja-meta naa “Jahaj Bari” ni awon ise ona ti o yara oto lara ni ara irin agbowole gun akaso. Ise ona alarabara ti ori orule ibi ibojuwota gigun. Okanojokan ona ni o wa ni ara ile naa awon arabara ona abe aja ati bee bee lo. Awon opo ni awose ona ilee ionic ati Corinthian. Ona ara ile naa koja afenuso ti a ko le e ri lara awon ile miiran ni awon agbegbe atijoo Dhaka. Fun idi eyi, ko ye ki ile naa di adawolule. |
Ọdún-un 1610 ni Dhaka di olú-ìlúu Bengal, ìyẹn ogójì ọdún sẹ́yìn. Ní sáàa Mughal àti ìjọba amúnisìn British, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tí a kọ́ ni ó ní ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá àti àjogúnbá ìlú náà kan tí ó rọ̀ mọ́ ọn. | Odun-un 1610 ni Dhaka di olu-iluu Bengal, iyen ogoji odun seyin. Ni saaa Mughal ati ijoba amunisin British, opolopo ile ti a ko ni o ni itan-isele-ateyinwa ati ajogunba ilu naa kan ti o ro mo on. |
Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn ilé wọ̀nyí ni ó ti wó láti ọjọ́ pípẹ́. Àwọn tí ó ṣì ń dúró ti di ẹgẹrẹmìtì, èyí á mú kí àwọn kan ó máa lọ (ṣe ayédèrú ìwé láti) gbẹ́sẹ̀ lé ilé wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ kan ni Bara Katra, àrágbáramúramù ilé tí ó ní ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí Mir Abul Qasim, Diwan (alága ètò ìṣúná) ti ó jẹ́ ọmọba Shah Shuja Mughul kọ́ ní nǹkan bíi 1644 àti 1646. Ó jẹ́ nǹkan ìbànújẹ́ wípé ilé náà ti ṣe tán, ó lè wó nígbàkigbà látorí àìṣàtúnṣe, àìkáràmáìsìkí ohun àjogúnbá, àti ìbàjẹ́ tí àwọn tí ó gbé ilé láì gba àṣẹ ń fà. | Amo pupo ninu awon ile wonyi ni o ti wo lati ojo pipe. Awon ti o si n duro ti di egeremiti, eyi a mu ki awon kan o maa lo (se ayederu iwe lati) gbese le ile wonyi. Apeere kan ni Bara Katra, aragbaramuramu ile ti o ni itan-isele-ateyinwa ti Mir Abul Qasim, Diwan (alaga eto isuna) ti o je omoba Shah Shuja Mughul ko ni nnkan bii 1644 ati 1646. O je nnkan ibanuje wipe ile naa ti se tan, o le wo nigbakigba latori aisatunse, aikaramaisiki ohun ajogunba, ati ibaje ti awon ti o gbe ile lai gba ase n fa. |
Muntasir Mamun ti kọ àìmọye ìwé lóríi ìtàn-ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá àti àjogúnbá ìlúu Dhaka. Ó kọ sínú ìwé ìròyìn ìbílẹ̀ẹ Bhorer Kagoj: | Muntasir Mamun ti ko aimoye iwe lorii itan-isele-ateyinwa ati ajogunba iluu Dhaka. O ko sinu iwe iroyin ibilee Bhorer Kagoj: |
Mo ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn aláṣẹ fún ogójì ọdún tí ó kọjá láti gba àwọn ilé àjogúnbá bíi Bara Katra àti Choto Katra sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó fẹ́ pa ìtàn àtẹ̀yìnwá rẹ́. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn. Kí ni ká sọ? Nígbà tí ẹ̀ka tí ó ń ṣe àkópamọ́ sítám̀pù ti wo ògiri àtijọ́ àmọ̀káyée Lalbagh Fort láti fi ṣe àyè ìgbọ́kọ̀sí, báwo ni a ó ṣe dojú ìjà kọ ìwà òmùgọ̀? | Mo ti rawo ebe si awon alase fun ogoji odun ti o koja lati gba awon ile ajogunba bii Bara Katra ati Choto Katra sile lowo awon ti o fe pa itan ateyinwa re. Sugbon ko si eni ti o da mi lohun. Ki ni ka so? Nigba ti eka ti o n se akopamo sitampu ti wo ogiri atijo amokayee Lalbagh Fort lati fi se aye igbokosi, bawo ni a o se doju ija ko iwa omugo? |
Ilé oníròyìn orí-ayélujára kan ti ṣe àtẹ̀jáde àbájáde ìwádìí tí ó jinlẹ̀ nípa àìkáràmáìsìkí ìjọba lóríi àwọn ilé àjogúnbá àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó ń gbìyànjú láti da àwọn ilé tí ó kù wó: | Ile oniroyin ori-ayelujara kan ti se atejade abajade iwadii ti o jinle nipa aikaramaisiki ijoba lorii awon ile ajogunba ati awon alenuloro ti o n gbiyanju lati da awon ile ti o ku wo: |
Ilé tí ó wà ní ipò.14 ní orí ìwé àkọsílẹ̀ àjogúnbá ti di wíwó. Apá kan lára àwọn ilé àwòṣífìlà tí ó wà ní Sutrapur kò ṣe é rí mọ́n. Iṣẹ́ àtúnṣe sí àwọn àjogúnbá ìgbàa Mughal ní mọ́ṣálááṣí Bangshal Mukim Bazar Jam-e àti mọ́ṣálááṣí Siddique Bazar Jam-e ti di ohun ìgbàgbé nítorí ojú àpá ò le è jọ ojú ara, ó ti yàtọ̀. [..] Àmọ́ ṣá, ó ní àṣẹ ìjọba tí ó fi ààbò bo àwọn ilé àjogúnbá, àwọn agbèfúnjọba ti agbègbèe Rajdhani Unnayan Kartripakkha àti Àjọ Ìlúu Dhaka kò ṣe ohun tí ó yẹ kí wọn ó ṣe. Àìṣojúṣe wọn ni ó fà á tí àwọn olóṣèlú olójúkòkòrò ṣe ń gba àwọn ilé àtijọ́ tí wọ́n sì ń dà wọ́n wó lulẹ̀. | Ile ti o wa ni ipo.14 ni ori iwe akosile ajogunba ti di wiwo. Apa kan lara awon ile awosifila ti o wa ni Sutrapur ko se e ri mon. Ise atunse si awon ajogunba igbaa Mughal ni mosalaasi Bangshal Mukim Bazar Jam-e ati mosalaasi Siddique Bazar Jam-e ti di ohun igbagbe nitori oju apa o le e jo oju ara, o ti yato. [..] Amo sa, o ni ase ijoba ti o fi aabo bo awon ile ajogunba, awon agbefunjoba ti agbegbee Rajdhani Unnayan Kartripakkha ati Ajo Iluu Dhaka ko se ohun ti o ye ki won o se. Aisojuse won ni o fa a ti awon oloselu olojukokoro se n gba awon ile atijo ti won si n da won wo lule. |
Ẹgbẹ́ Urban Study ti ṣe àgbékalẹ̀ ìwọ́de àti àkójọ àwọn ènìyàn tí yóò fi ẹ̀hónú àdàwólulẹ̀ wọ̀nyí hàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gbèrò láti ṣe ìkéde nípa ìdààbò bo àwọn ilé àjogúnbá tí ọ̀rán kàn. | Egbe Urban Study ti se agbekale iwode ati akojo awon eniyan ti yoo fi ehonu adawolule wonyi han. Bee naa ni won gbero lati se ikede nipa idaabo bo awon ile ajogunba ti oran kan. |
Àwòrán ìsàlẹ̀ yìí ni àwọn ilé àjogúnbáa Bangladeshi tí àdàwólulẹ̀ ń bá: | Aworan isale yii ni awon ile ajogunbaa Bangladeshi ti adawolule n ba: |
Àwọn ọmọ Bangladeshi lo ẹ̀rọ-alátagbà fi gbógun ti àjàkálẹ̀ àìsàn ibà-ẹ̀fọn | Awon omo Bangladeshi lo ero-alatagba fi gbogun ti ajakale aisan iba-efon |
Ní àárín ọdún, mélòó kan tí ó kọjá, pàápàá ní àsìkò ìjì ọdọọdún monsoon, iye àwọn tí àìsàn-an ibàa ẹ̀fọn ti kọlù ní Bangladeshì ti lékún síi. Ní ọdún yìí, àwọn tí àìsàn-an ibàá kọlù tó bíi 7,179, àwọn - 2800 ní sáà kínní osùu Agẹmọ nìkan. | Ni aarin odun, meloo kan ti o koja, paapaa ni asiko iji odoodun monsoon, iye awon ti aisan-an ibaa efon ti kolu ni Bangladeshi ti lekun sii. Ni odun yii, awon ti aisan-an ibaa kolu to bii 7,179, awon - 2800 ni saa kinni osuu Agemo nikan. |
Bí ètò ìjọba ò ṣe dántọ́ tó láti borí àjàkálẹ̀ àìsàn ibà tí ó gbòde yìí, àwọn ènìyàn ń gbẹ́kẹ̀le ẹ̀rọ-alátagbà láti fi sọ ẹ̀dùn-un ọkàn-an wọn, pín àlàyé nípa ìtànkálẹ̀ kòkòrò náà, àti ṣe ìkéde nípa bí àwọn ènìyán ṣe le dá ààbò bo ara wọn. | Bi eto ijoba o se danto to lati bori ajakale aisan iba ti o gbode yii, awon eniyan n gbekele ero-alatagba lati fi so edun-un okan-an won, pin alaye nipa itankale kokoro naa, ati se ikede nipa bi awon eniyan se le da aabo bo ara won. |
Ibà-ẹ̀fọn ní Bangladesh: ó tó bíi ẹni 2800 tí àìsàn-an nì tẹ̀ wò nínúu àwọn ọjọ́ mẹ́rìndínlógún àkọ́kọ́ osùu Agẹmọ | Iba-efon ni Bangladesh: o to bii eni 2800 ti aisan-an ni te wo ninuu awon ojo merindinlogun akoko osuu Agemo |
Àkọsílẹ̀ Àìsàn Pọ̀ Sí i Ní Osù Agẹmọ | Akosile Aisan Po Si i Ni Osu Agemo |
Ilé ìwòsàn gba àwọn aláìsàn ibà ẹ̀fọn 403 tí ó pọ̀ jù lọ ní ọjọ́ 22 osù Agẹmọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ kan ṣe rò, ipa ìyípadà ojú-ọjọ́, òjò àìdágbá kan, ojú-ọjọ́ tó ń ṣe ségesège, àti àìṣèmọ́tótó ni ọ̀dádá tí ó ń dá àtànkálẹ̀ ibà sílẹ̀. Àwọn mìíràn sọ wípé ibà ẹ̀fọn ti ọdún nìí ń ṣekú paon | Ile iwosan gba awon alaisan iba efon 403 ti o po ju lo ni ojo 22 osu Agemo. Gege bi awon onimo kan se ro, ipa iyipada oju-ojo, ojo aidagba kan, oju-ojo to n se segesege, ati aisemototo ni odada ti o n da atankale iba sile. Awon miiran so wipe iba efon ti odun nii n seku paon |
ju ti ẹ̀yìn wá lọ. Ní ti òǹlò Twitter | ju ti eyin wa lo. Ni ti onlo Twitter |
“Ibà-ẹ̀fọn àti àmìi rẹ̀ ní ọdún yìí ti yàtọ̀ nítorí ìdí èyí ni o fi ní láti tọ oníṣègùn rẹ̀ lọ ní kété tí o bá ti ní ibà náà” – gẹ́gẹ́ bí ògbólògbó onímọ̀ ìlera ti Ilé-ìwòsàn Bangabandhu ti sọ. Àwọn ẹ̀yà ara àwọn aláìsàn tí amodi tẹ̀ ti ń daṣẹ́ sílẹ̀ – a kò gbọ́ èyí rí. | “Iba-efon ati amii re ni odun yii ti yato nitori idi eyi ni o fi ni lati to onisegun re lo ni kete ti o ba ti ni iba naa” – gege bi ogbologbo onimo ilera ti Ile-iwosan Bangabandhu ti so. Awon eya ara awon alaisan ti amodi te ti n dase sile – a ko gbo eyi ri. |
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ìwé ìròyìn Bangla Tribune, Dókítà Gulzar sọ wípé kò sí bí a ṣe lè wo ibà ẹ̀fọn yìí nígbà àkọ́kọ́ tó, kí ó máà tún ṣeni lẹ́ẹ̀ẹkejì. | Ninu iforowanilenuwo pelu iwe iroyin Bangla Tribune, Dokita Gulzar so wipe ko si bi a se le wo iba efon yii nigba akoko to, ki o maa tun seni leeekeji. |
Ibà-ẹ̀fọn ti ọdún yìí jẹ́ tuntun, ó sì yára pa ènìyàn. Ó sì ń fa àmì ìfòyà. Ohun tí ó lè fà á lè pọ̀ – ọ̀pọ̀ ni ó kó àìsàn ní ọdún tí ó kọjá, tí wọn kò fura. Bí ó bá tún tẹ̀ wọ́n ní ẹ̀rìn kejì, sààárè ń sún mọ́ nìyẹn. | Iba-efon ti odun yii je tuntun, o si yara pa eniyan. O si n fa ami ifoya. Ohun ti o le fa a le po – opo ni o ko aisan ni odun ti o koja, ti won ko fura. Bi o ba tun te won ni erin keji, saaare n sun mo niyen. |
Ìròyìn nípa àjàkálẹ̀ àìsàn yìí ń gba gbogbo orí ẹrọ-alátagbà kan tí ó sì ń mú àìbalẹ̀ara àti ọkàn bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹlo ẹ̀rọ-alátagbà. Shofiq Ahmed pín Túwíìtì kan nípa ìròyìn àìsàn tuntun: | Iroyin nipa ajakale aisan yii n gba gbogbo ori ero-alatagba kan ti o si n mu aibaleara ati okan ba opolopo awon onlo ero-alatagba. Shofiq Ahmed pin Tuwiiti kan nipa iroyin aisan tuntun: |
Alákòóso Olùgbé Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé náà papàá ti ní àìsàn ibà-ẹ̀fọn. . | Alakooso Olugbe Ajo Isokan Agbaye naa papaa ti ni aisan iba-efon. . |
Òǹlo Twitter Shorbo Bosonto wípé: | Onlo Twitter Shorbo Bosonto wipe: |
Àwọn dókítà méjì kan náà kú látàrí ibà-ẹ̀fọn, èyí sì ti ń mú kí àwọn ènìyàn ó máa bẹ̀rù. Ilé-ẹjọ́ Gíga Dhaka ti fi àṣẹ pe Ọ̀gá Àgbà Ètò Ìlera ti ìjọba. Àwọn tí ó ń kú nh pọ̀ ọ́ sí i. | Awon dokita meji kan naa ku latari iba-efon, eyi si ti n mu ki awon eniyan o maa beru. Ile-ejo Giga Dhaka ti fi ase pe Oga Agba Eto Ilera ti ijoba. Awon ti o n ku nh po o si i. |
Ǹjẹ́ ìjọbá ń ṣe tó? | Nje ijoba n se to? |
Ojú-ìwé Facebook ti BBC Bangla rọ àwọn òǹkàwée rẹ̀ láti jábọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ akin tí àwọn òníṣẹ́ ìlú Dhaka ń gbé láti gbógun ti ẹ̀fọn. Òǹlò Mohammad Mynuddin jábọ̀ ìfàsẹ́yìn láti ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti kápá àjàkálẹ̀ náà: | Oju-iwe Facebook ti BBC Bangla ro awon onkawee re lati jabo awon igbese akin ti awon onise ilu Dhaka n gbe lati gbogun ti efon. Onlo Mohammad Mynuddin jabo ifaseyin lati owo awon osise ijoba lati kapa ajakale naa: |
A ò tíì rí nǹkan. Òṣìṣẹ́ Àjọ Ìlú kan ti sọ wípé yóò tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí egbògi ìdáààbòbò tí yó sì dín ẹ̀fọn kù. Ó yà mí lẹ́nu | A o tii ri nnkan. Osise Ajo Ilu kan ti so wipe yoo to ose meloo kan ki egbogi idaaabobo ti yo si din efon ku. O ya mi lenu |
Àwọn kan lérò wípé ìjọba ò mú kiní ibà-ẹ̀fọn ọ̀hún ní kanpá, àwọn ọmọìlú ń lo ẹ̀rọ-alátagbà mú kí àwọn ènìyàn ó mọ̀ nípa kòkòrò náà. Health Barta gbé fídíò kan sí oríi YouTube tí ó ń ṣe àlàyé lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ ohun tí ó pọn dandan láti ṣe bí èèyán bá ní ibà-ẹ̀fọn: | Awon kan lero wipe ijoba o mu kini iba-efon ohun ni kanpa, awon omoilu n lo ero-alatagba mu ki awon eniyan o mo nipa kokoro naa. Health Barta gbe fidio kan si orii YouTube ti o n se alaye lekununrere ohun ti o pon dandan lati se bi eeyan ba ni iba-efon: |
Ọ̀gọ̀rọ̀ l’ó ń d'orí kọ ẹ̀rọ-alátagbà lọ láti gba ẹ̀jẹ̀ fún àwọn aláìsàn. Òǹlo Sajid Islam Khan túwíìtì pé òún nílò ẹ̀jẹ̀ fún àbúrò òun tí ibà-ẹ̀fọn ń bá fínra. Hannan Gazi náà se àgbéjáde tirẹ̀: | Ogoro l’o n d'ori ko ero-alatagba lo lati gba eje fun awon alaisan. Onlo Sajid Islam Khan tuwiiti pe oun nilo eje fun aburo oun ti iba-efon n ba finra. Hannan Gazi naa se agbejade tire: |
Chittagong ṣe àgbéjáde túwíìtì: | Chittagong se agbejade tuwiiti: |
Àmì ibà-ẹ̀fọn àti àtiṣe.. | Ami iba-efon ati atise.. |
Ní àárín-in àjàkálẹ̀ náà, Alákòóso-ìlú Àríwá Dhaka ti fagilé ìsinmi ránpẹ́ àwọn ikọ̀ tí ó ń rí sí pàntí kíkó àti ìgbégidínà àpọ̀si ẹ̀fọn. Síbẹ̀síbẹ̀, fún ìdáààbò àwọn ènìyàn, ṣíṣe ṣì kú. | Ni aarin-in ajakale naa, Alakooso-ilu Ariwa Dhaka ti fagile isinmi ranpe awon iko ti o n ri si panti kiko ati igbegidina aposi efon. Sibesibe, fun idaaabo awon eniyan, sise si ku. |
Ìṣọdẹ-àjẹ́ ṣì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko India | Isode-aje si n gba emi awon eniyan ni igberiko India |
Ìletò kan ní ẹ̀báa Jamshedpur ní Jharkhand. Àwòrán láti ọwọ́ọ Anumeha Verma | Ileto kan ni ebaa Jamshedpur ni Jharkhand. Aworan lati owoo Anumeha Verma |
Ní ọjọ́ 20 oṣù Agẹmọ, àgbájọ àwọn ènìyànkéènìà gba ẹ̀mí àwọn àgbàlagbà mẹ́rin kan láì dá wọn lẹ́jọ́ ní agbègbèe Gumla ní Jharkhand, India lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn wọ́n. Gẹ̀gẹ̀ bí ìjábọ̀ ìròyìn, àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ṣe ikú pa ọkùnrin kan, ni ìgbìmọ̀ abúlée Panchayat ṣe dá wọn lẹ́bi. Wọ́n wọ́ àwọn àgbàlagbà mẹ́rin wọ̀nyí jáde síta ilée wọn, àwọn ọkùnrin tí ó bòjú sì fi igi lù wọ́n títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára wọn. Mẹ́jọ nínú àwọn ènìyànkéènìà wọ̀nyí ti wà ní akóló ọlọ́pàá. | Ni ojo 20 osu Agemo, agbajo awon eniyankeenia gba emi awon agbalagba merin kan lai da won lejo ni agbegbee Gumla ni Jharkhand, India leyin ti a fi esun-un aje kan won. Gege bi ijabo iroyin, awon agbalagba wonyi se iku pa okunrin kan, ni igbimo abulee Panchayat se da won lebi. Won wo awon agbalagba merin wonyi jade sita ilee won, awon okunrin ti o boju si fi igi lu won titi ti emi fi bo lara won. Mejo ninu awon eniyankeenia wonyi ti wa ni akolo olopaa. |
Gẹ̀gẹ̀ bí àkọsílẹ̀ ọlọ́pàá tí Times of India tẹ̀jáde, ìṣọdẹ-àjẹ́ ní Jharkhand ti rán àwọn ènìyàn 123 sọ́run àpàpàǹdodo ní àárín-in oṣù Èbìbí ọdún-un 2016 sí oṣù Èbìbí ọdún-un 2019. Jákèjádò, ènìyàn 134 di ẹni ẹbọra-ń-bá-jẹun látàrí èsùn-un lílo “ògùngùn” ní ọdún-un 2016, ìyẹn gẹ̀gẹ̀ bí Àjọ Aṣàkọsílẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀ Orílẹ̀-èdè náà ṣe kọ́ ọ sílẹ̀. | Gege bi akosile olopaa ti Times of India tejade, isode-aje ni Jharkhand ti ran awon eniyan 123 sorun apapandodo ni aarin-in osu Ebibi odun-un 2016 si osu Ebibi odun-un 2019. Jakejado, eniyan 134 di eni ebora-n-ba-jeun latari esun-un lilo “ogungun” ni odun-un 2016, iyen gege bi Ajo Asakosile Ese Orile-ede naa se ko o sile. |
Àrùn T’ó Ń Peléke Sí i | Arun T’o N Peleke Si i |
“Ìṣọdẹ-àjẹ́ kò jẹ́ tuntun ní Jharkhand,” Prem Chand, Olúdásílẹ̀ àti Alága Free Legal Aid Committee ní Jharkhand, sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan. FLAC ti ń ṣe àtọ́nàa ìṣòfin tí ó tako ìṣọdẹ-àjẹ́ ní Jharkhand. Iléeṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agbègbè yìí ní ọdún-un 1991 nígbà tí àwọn aládùúgbò fi ẹ̀sùn kan obìnrin kan pé ó lọ́wọ́ nínú ikú ọmọdékùnrin kan. Àgbájọ àwọn ènìyànkéènìà kan dìgbò lù ú, wọ́n sì pa ọkọ àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Òún fi ara pa. | “Isode-aje ko je tuntun ni Jharkhand,” Prem Chand, Oludasile ati Alaga Free Legal Aid Committee ni Jharkhand, so ninuu iforowanilenuwo ori ero-ibanisoro kan. FLAC ti n se atonaa isofin ti o tako isode-aje ni Jharkhand. Ileese naa bere ise ni agbegbe yii ni odun-un 1991 nigba ti awon aladuugbo fi esun kan obinrin kan pe o lowo ninu iku omodekunrin kan. Agbajo awon eniyankeenia kan digbo lu u, won si pa oko ati omo re okunrin. Oun fi ara pa. |
Nígbàtí Prem Chand àti àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀ ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyí nínúu túbú, wọ́n bá ìpèníjà: | Nigbati Prem Chand ati awon elegbee re se ibewo si awon elese wonyi ninuu tubu, won ba ipenija: |
Wọ́n sọ fún wọn wípé àwọn dúró lé oríi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn. Wọ́n sì tún gbàgbọ́ wípé bí ẹ̀jẹ̀ẹ ẹni tí a pè ní àjẹ́ bá kan ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́, yóò pàdánù agbára ẹlẹyẹ rẹ̀. | Won so fun won wipe awon duro le orii esun ti won fi kan awon. Won si tun gbagbo wipe bi ejee eni ti a pe ni aje ba kan ile ogere, yoo padanu agbara eleye re. |
Prem Chand sọ wípé ó kan apá kan nínú àwọn ọmọ ìlú: | Prem Chand so wipe o kan apa kan ninu awon omo ilu: |
Nígbàgbogbo, àwọn obìnrin tí kò lárá tí ó tálákà ní í máa ń fi ara kááṣá. Àwọn tí ó f’ara kááṣá wọ̀nyìí ni àwọn Adivasis, Harijans àti Dalits. Ìfojú iyì àwọn obìnrin àti ìtasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin ẹ̀tọ́ sí ayé iyì fún gbogbo ọmọ ènìyàn. | Nigbagbogbo, awon obinrin ti ko lara ti o talaka ni i maa n fi ara kaasa. Awon ti o f’ara kaasa wonyii ni awon Adivasis, Harijans ati Dalits. Ifoju iyi awon obinrin ati itase agere si ofin eto si aye iyi fun gbogbo omo eniyan. |
Òtítọ́ Àwùjọ àti Ìṣèlú | Otito Awujo ati Iselu |
Àwọn ajìjàngbara sọ wípé ìgbàgbọ́-asán tí ó rinlẹ̀ ní ìgbèríko ni ó ń fa ìwà pálapalà náà. Àìgbẹ̀kọ́, ètò ìlera tí ò pójú òṣùwọ̀n àti kòlàkòṣagbe tí ó ń gb’àgbègbè tí ìwà pálapalà wọ̀nyí ti gbalẹ̀ bí i ìtàkùn ni ó fi wọ́pọ̀. | Awon ajijangbara so wipe igbagbo-asan ti o rinle ni igberiko ni o n fa iwa palapala naa. Aigbeko, eto ilera ti o poju osuwon ati kolakosagbe ti o n gb’agbegbe ti iwa palapala wonyi ti gbale bi i itakun ni o fi wopo. |
Ọ̀ràn wọ̀nyí ti fi hàn wípé àhesọ ni ó máa fi ń bẹ̀rẹ̀. Pẹ̀lú òfin àwọn ìpínlẹ̀ India tí ó ka ìṣọdẹ-àjẹ́ sí ohun tí ó lòdì sófin, àwọn akópa ọ̀ràn wọ̀nyí rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìdáààbò-ara-ẹni. | Oran wonyi ti fi han wipe aheso ni o maa fi n bere. Pelu ofin awon ipinle India ti o ka isode-aje si ohun ti o lodi sofin, awon akopa oran wonyi ri i gege bi ona idaaabo-ara-eni. |
Bákan náà ni wọ́n ń wí àwáwí fún gbígba ohun ìní àwọn obìnrin, fi agbára gbẹ̀san tàbí fi ipá bá obìnrin lò pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Prem Chand ṣe ti sọ: | Bakan naa ni won n wi awawi fun gbigba ohun ini awon obinrin, fi agbara gbesan tabi fi ipa ba obinrin lo po. Gege bi Prem Chand se ti so: |
Àtètèròtẹ́lẹ̀ ni wípé ní kété tí o bá ti pe obìnrin ní àjẹ́, o lè tẹríi rẹ̀ ba fún ìlòkulò. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe kókó láti mọ̀ wípé wọn máa ń lo ìwà pálapàla yìí fi gba tara àwọn obìnrin, kò sì kìí ṣe ìdí tí ó ń fà á pàtó. | Ateterotele ni wipe ni kete ti o ba ti pe obinrin ni aje, o le terii re ba fun ilokulo. Sibesibe, o se koko lati mo wipe won maa n lo iwa palapala yii fi gba tara awon obinrin, ko si kii se idi ti o n fa a pato. |
Ní ti ẹ̀fẹ̀, láì wí tó, panchayat náà sábà máa ń lọ́wọ́ sí ìpènìyàn ní àjẹ́ pàápàá bí kò bá pàṣẹ ìjìyà t'ó tọ́. | Ni ti efe, lai wi to, panchayat naa saba maa n lowo si ipeniyan ni aje paapaa bi ko ba pase ijiya t'o to. |
Ní àfikùn sí panchayat tí ìbó yàn, àwọn kan ńbẹ tí wọ́n pe ara wọn ní panchayat ipò-ìsàlẹ̀ láì ní àṣẹ kankan tí ó fún wọn lágbara níbikíbi ní orílẹ̀-èdè. Àwọn ẹgbẹ́ yìí máa ń dájọ́ àti fi ìyà jẹ ènìyàn tí kò sì sí ẹni tí ó ká wọn lápá kò. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní agbègbèe Ajmer ní Rajasthan lọ́dún-un 2017 jábọ̀ ìlọ́wọ́sí panchayat ipò-ìsàlẹ̀ tí ó ṣ’okùnfa ikú obìnrin ogójì ọdún kan. | Ni afikun si panchayat ti ibo yan, awon kan nbe ti won pe ara won ni panchayat ipo-isale lai ni ase kankan ti o fun won lagbara nibikibi ni orile-ede. Awon egbe yii maa n dajo ati fi iya je eniyan ti ko si si eni ti o ka won lapa ko. Isele kan ni agbegbee Ajmer ni Rajasthan lodun-un 2017 jabo ilowosi panchayat ipo-isale ti o s’okunfa iku obinrin ogoji odun kan. |
Gẹ́gẹ́ bí òfin, ilé ẹjọ́ lé gbé ìgbésẹ̀ tí ó tako irúu ìdájọ́ báwọ̀nyí yálà láti ọ̀dọ̀ àwọn panchayat tí ìbó yàn àti panchayat ipò-ìsàlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí ó fara kááṣá ò tilẹ̀ ní àǹfààní sí ilé-ẹjọ́ òfin kí àgbájọ-àwọn-ènìyànkéènìà ó tó kojúu wọn. | Gege bi ofin, ile ejo le gbe igbese ti o tako iruu idajo bawonyi yala lati odo awon panchayat ti ibo yan ati panchayat ipo-isale. Sibesibe, awon ti o fara kaasa o tile ni anfaani si ile-ejo ofin ki agbajo-awon-eniyankeenia o to kojuu won. |
Àwọn Ẹni-tó-fara-kááṣá àti Ẹni-tórí-kó-yọ | Awon Eni-to-fara-kaasa ati Eni-tori-ko-yo |
Àwọn ènìyàn ń f’ẹ̀sùn kan àwọn ẹlẹyẹ fún iṣẹ́-ibi ọwọ́ọ wọn: ikú ènìyàn tàbí ẹranko, ọ̀dá òjò, àìso jìngbìnnì irúgbìn, àti bẹ́èbẹ́è lọ. Ìkọlù tí ó kọ lu àwọn obìnrin wọ̀nyí (àti àwọn ọkùnrin kan) rorò bí ẹranko ẹhànnà. Nígbà mìíràn, àwọn èsùn náà àti ìjìyà ẹṣé máa wá láti ọ̀dọ̀ mọ̀lébíi wọn. | Awon eniyan n f’esun kan awon eleye fun ise-ibi owoo won: iku eniyan tabi eranko, oda ojo, aiso jingbinni irugbin, ati beebee lo. Ikolu ti o ko lu awon obinrin wonyi (ati awon okunrin kan) roro bi eranko ehanna. Nigba miiran, awon esun naa ati ijiya ese maa wa lati odo molebii won. |
Àwọn kan ń gbé tí wọ́n sì ń sọ ìtàn-an wọn tí wọ́n sì ń jà fún ẹ̀tọ́ọ wọn. Chutni Mahato ti Saraikela ní Jharkhand jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn ènìyàn láti agbègbè náà máa ń pè é ní ‘tigress’. Wọ́n fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn-án ní ọdún-un 1995. Láti ìgbà náà, ó ti yírapadà di ajìjàǹgbara olùtako ìfìyàjẹ àwọn obìnrin pẹ̀lú àtìléyìn Ilé-iṣẹ́-tí-kìí-ṣe-tìjọba. | Awon kan n gbe ti won si n so itan-an won ti won si n ja fun etoo won. Chutni Mahato ti Saraikela ni Jharkhand je okan lara won. Awon eniyan lati agbegbe naa maa n pe e ni ‘tigress’. Won fi esun-un aje kan-an ni odun-un 1995. Lati igba naa, o ti yirapada di ajijangbara olutako ifiyaje awon obinrin pelu atileyin Ile-ise-ti-kii-se-tijoba. |
Chutni sọ bí àìsí àtìlẹ́yìn tó késejárí ṣe mú u nira láti jà tako ìwà pálapàla yìí. “Ìbájẹ́pé àtìlẹ́yìn tó tó wá láti ọwọ́ àwọn oníṣẹọba àti ìjọba fún iṣẹ́ tí à ń ṣe níbí. Síbẹ̀síbẹ̀, mo ti jìyà nítorí ìwà pálapàla yìí. Bí ènìyàn bá tọ̀ mí wá fún ìrànlọ́wọ́, mo máa dúró tì wọ́n gbágbágbá,” ó sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan. | Chutni so bi aisi atileyin to kesejari se mu u nira lati ja tako iwa palapala yii. “Ibajepe atileyin to to wa lati owo awon oniseoba ati ijoba fun ise ti a n se nibi. Sibesibe, mo ti jiya nitori iwa palapala yii. Bi eniyan ba to mi wa fun iranlowo, mo maa duro ti won gbagbagba,” o so ninuu iforowanilenuwo ori ero-ibanisoro kan. |
Dídá Ohùn Gbogboògbò Sí i | Dida Ohun Gbogboogbo Si i |
Àwọn ẹni-tórí-kó-yọ àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ènìyàn rò wípé àwọn ènìyàn gbogbo kò ti ìfòpin sí ìṣọdẹ-àjẹ́ lẹ́yìn. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ènìyàn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ kí á mọ̀ wípé àbùkù ìrànwọ́ ìjọba àti àwọn onímọ̀ ni kò mú ìwà àìbójúmu náà ṣíra kásẹ̀ ńlẹ̀. | Awon eni-tori-ko-yo ati ajafetoo-eniyan ro wipe awon eniyan gbogbo ko ti ifopin si isode-aje leyin. Awon ajafetoo-eniyan ti a foro wa lenu wo lori isele yii je ki a mo wipe abuku iranwo ijoba ati awon onimo ni ko mu iwa aibojumu naa sira kase nle. |
Ohun tí ó dára jù lọ ni wípé àwọn tí ó ń tako ìwà burúkú yìí gbàgbọ́ wípé àyípadà lè dé. Ní ọ̀rọ̀ọ Prem Chand: | Ohun ti o dara ju lo ni wipe awon ti o n tako iwa buruku yii gbagbo wipe ayipada le de. Ni oroo Prem Chand: |
Akitiyan láti f’òpin sí ìṣọdẹ-àjẹ́ lè tẹ̀lé ìlànà tí ìjọba fi polongo ètò mímọ̀ọ-kọ-àti-mímọ̀ọ-kà. Bákan náà, àwọn onímọ̀ ní láti f’ọwọ́ sí i k’áwọn ènìyàn ó ba f’ohùn sí i. | Akitiyan lati f’opin si isode-aje le tele ilana ti ijoba fi polongo eto mimoo-ko-ati-mimoo-ka. Bakan naa, awon onimo ni lati f’owo si i k’awon eniyan o ba f’ohun si i. |
Ìṣọdẹ-àjẹ́ jákèjádò India | Isode-aje jakejado India |
Jharkhand ti ṣe àkọsílẹ̀ iye ẹṣẹ̀ àwọn ènìyán ṣẹ̀ tí ó pọ̀ jù lọ tí ó tan mọ́ ìṣọdẹ-àjẹ́ àmọ́ kì í ṣe ìpínlẹ̀ náà nìkan. | Jharkhand ti se akosile iye ese awon eniyan se ti o po ju lo ti o tan mo isode-aje amo ki i se ipinle naa nikan. |
Ọ̀ràn-an ìṣọdẹ-àjẹ́ ti wà l’ákọsílẹ̀ ní Chattisgarh, Odisha, Gujarat, West Bengal Assam, Bihar, Maharashtra àti Rajasthan pẹ̀lú. | Oran-an isode-aje ti wa l’akosile ni Chattisgarh, Odisha, Gujarat, West Bengal Assam, Bihar, Maharashtra ati Rajasthan pelu. |
Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní 2014, Debjani Bora, ẹlẹ́sẹ̀ ehoro ọmọ bíbíi orílẹ̀-èdèe India ti fi ara kááṣá rí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ọ Debjani, a f’ẹ̀sùn-un ìgbẹ̀mí ènìyàn púpọ̀ kàn án ní abúlée Cherekali tí ó wà ní kìlómità 180 láti Guwahati, olú-ìlúu India ti apáa ìlà-oòrùn. Olóríi gbọ̀gán àdúrà abúlé l’ó dárúkọ rẹ̀ tí àwọn ará abúlé sí fi ìyà jẹ́ ẹ. | Nigba isele kan ni 2014, Debjani Bora, elese ehoro omo bibii orile-edee India ti fi ara kaasa ri. Gege bi oroo Debjani, a f’esun-un igbemi eniyan pupo kan an ni abulee Cherekali ti o wa ni kilomita 180 lati Guwahati, olu-iluu India ti apaa ila-oorun. Olorii gbogan adura abule l’o daruko re ti awon ara abule si fi iya je e. |
Ìṣẹ̀lẹ̀ 2017 ní ipínlẹ̀ Rajasthan. Lára èyí ni, ọmọbìnrin ogójì ọdún kan Kanya Devi rí ìkọlù tí a sì lù ú pa lẹ́yìn tí mọ̀lẹ́bíi rẹ̀ fi ẹ̀sùn kàn án ní agbègbèe Ajmer. | Isele 2017 ni ipinle Rajasthan. Lara eyi ni, omobinrin ogoji odun kan Kanya Devi ri ikolu ti a si lu u pa leyin ti molebii re fi esun kan an ni agbegbee Ajmer. |
Bí àpamọ́ àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe mú ọ̀rọ̀ àyíká di mímọ̀ ní Mekong | Bi apamo alo ati itan atowodowo se mu oro ayika di mimo ni Mekong |
Ní ọdún 2014, ogunlọ́gọ̀ ìbílẹ̀ ní Mekong bẹ̀rẹ̀ sí ní í ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ aṣèwádìí kan tí ó ń ṣe àyẹ̀wò fínnífínní sí bí ìtàn wọ̀nyí ṣe lè ṣe ìrànwọ́ tí yóò tú àṣìírí ìmúdìbàjẹ́ àyíká tí àwọn iṣẹ́ ńláǹlà ń fà ní agbègbè náà. | Ni odun 2014, ogunlogo ibile ni Mekong bere si ni i se akosile awon alo ati itan atowodowoo won pelu iranlowo egbe asewadii kan ti o n se ayewo finnifinni si bi itan wonyi se le se iranwo ti yoo tu asiiri imudibaje ayika ti awon ise nlanla n fa ni agbegbe naa. |
Mekong jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn odò ńlá Ásíà tí ó ṣàn gba orílẹ̀-èdè mẹ́fà: China, Myanmar, Thailand, Laos, Cambodia, àti Vietnam. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ìṣẹ̀dá abẹ̀mí àti ewéko tí ó jẹ́ ohun ìsayéró fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbẹ̀ àti apẹja. | Mekong je okan ninu awon odo nla Asia ti o san gba orile-ede mefa: China, Myanmar, Thailand, Laos, Cambodia, ati Vietnam. O ni opolopo oro iseda abemi ati eweko ti o je ohun isayero fun egbeegberun agbe ati apeja. |
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ńláǹlà bíi kòtò ìdarí-omi ṣíṣàn fún Ìpèsè Iná Mànàmáná ti lé àwọn olùgbé jìnà ó sì ń ṣe àkóbá fún nnkan ìṣẹ̀dá odò náà. Ọ̀kanòjọ̀kan ìfẹ̀hànnúhàn kò ṣe nǹkan kan, àwọn iṣẹ́ ìdarí-omi ṣíṣàn ṣì ń lọ, pàápàá jù lọ ní Laos àti Thailand. | Ni odun die seyin, opolopo ise nlanla bii koto idari-omi sisan fun Ipese Ina Manamana ti le awon olugbe jina o si n se akoba fun nnkan iseda odo naa. Okanojokan ifehannuhan ko se nnkan kan, awon ise idari-omi sisan si n lo, paapaa ju lo ni Laos ati Thailand. |
Pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Mekong Watch, ẹgbẹ́ kan ní Jápáànì ń jà fún ìdàgbàsókè ní agbègbè náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà ní Mekong ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ wọn tí ó ní íṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀dá. Mekong Watch gbàgbọ́ wípé àwọn ìtàn wọ̀nyí “ti kó ipa ribiribi ní ti ìdáàbò ìṣẹ̀dá nípa dídẹ́kun ìwà àìbìkítà fún ọrọ̀ ìṣẹ̀dá.” | Pelu ajosepo Mekong Watch, egbe kan ni Japaani n ja fun idagbasoke ni agbegbe naa, opolopo awon agba ni Mekong ti bere si ni se akosile alo, isele ati itan atowodowoo won ti o ni ise pelu iseda. Mekong Watch gbagbo wipe awon itan wonyi “ti ko ipa ribiribi ni ti idaabo iseda nipa didekun iwa aibikita fun oro iseda.” |
Mekong Watch sọ wípé ohun ìṣẹ̀dá nìkan kọ́ ni a ní láti dáàbò bò àmọ́ àti àwọn “nǹkan àjogúnbá tí-a-kò-le-è-rí-dìmú” tí a lè pín àti rí lò. Toshiyuki Doi, olùdámọ̀ràn àgbà fún Mekong Watch, ní èyí láti sọ: | Mekong Watch so wipe ohun iseda nikan ko ni a ni lati daabo bo amo ati awon “nnkan ajogunba ti-a-ko-le-e-ri-dimu” ti a le pin ati ri lo. Toshiyuki Doi, oludamoran agba fun Mekong Watch, ni eyi lati so: |
Ó pọn dandan fún wa láti ka ìtàn àwọn ènìyàn Mekong kún, kí a dá wọn mọ̀, àti bọ̀wọ̀ fún wọn, papàá jù lọ ní òde òní tí wọ́n ti ń pàdánù àyè wọn ní ìrọ́pò ilé iṣẹ́ oníròyìn ìgbàlódé, tí wọn kò sì fi àjogúnbá lé ìran tí ó ń bọ̀ lọ́wọ́. | O pon dandan fun wa lati ka itan awon eniyan Mekong kun, ki a da won mo, ati bowo fun won, papaa ju lo ni ode oni ti won ti n padanu aye won ni iropo ile ise oniroyin igbalode, ti won ko si fi ajogunba le iran ti o n bo lowo. |
Ẹgbẹ́ náà ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà kí ó tó kó oríṣiríṣi ìtàn 102 jọ ní Cambodia, Laos, àti Thailand. A ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtàn wọ̀nyí, dà á kọ sílẹ̀ sínú ìwé, àti ìtúmọ̀ ìtàn sí àwọn èdè orílẹ̀ Thailand, Laos, àti Cambodia kí ó tó kan ẹ̀da ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mekong Watch tẹ àwọn ìtàn wọ̀nyí jáde sórí ìwé ìròyìn pélébé àti sórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá, wọ́n sì tún lò ó ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àyíká ní àwọn ìlú náà. | Egbe naa se gudugudu meje yaya mefa ki o to ko orisirisi itan 102 jo ni Cambodia, Laos, ati Thailand. A se akosile awon itan wonyi, da a ko sile sinu iwe, ati itumo itan si awon ede orile Thailand, Laos, ati Cambodia ki o to kan eda ti ede Geesi. Mekong Watch te awon itan wonyi jade sori iwe iroyin pelebe ati sori ero ayarabiasa, won si tun lo o ni idanilekoo nipa ayika ni awon ilu naa. |
Àwọn agbègbè ní Mekong níbi tí àwọn oníṣẹ́-ìwádìí ti ṣe iṣẹ́. | Awon agbegbe ni Mekong nibi ti awon onise-iwadii ti se ise. |
Kmhmu’ ní àríwá àti àárín gbùngbùn Laos;; | Kmhmu’ ni ariwa ati aarin gbungbun Laos;; |
Siphandon ní gúúsù Laos; | Siphandon ni guusu Laos; |
Akha ní àríwá Thailand; | Akha ni ariwa Thailand; |
Thai So atí Isan ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand; | Thai So ati Isan ni ariwa-iwo-oorun Thailand; |
Bunong ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Cambodia. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ. | Bunong ni ariwa-iwo-oorun Cambodia. A lo o pelu ase. |
Láti ìparí ọdún 2016, a ti fi ìtàn àwọn ènìyàn ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àyíká fún àwọn èwe ní ìgbèríko Laos àti Thailand. A ti ṣe àgbékalẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé àti ní ìlú ìbílẹ̀ láti tọ́ àwọn èwe sọ́nà, àti àwọn àgbà nígbà mìíràn, láti ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn ẹnu àwọn àgbàlagbà, fi ìtàn náà kọ́gbọ́n, àti láti sọ wọ́n di kíkà. | Lati ipari odun 2016, a ti fi itan awon eniyan se idanilekoo ayika fun awon ewe ni igberiko Laos ati Thailand. A ti se agbekale idanilekoo ni ile-iwe ati ni ilu ibile lati to awon ewe sona, ati awon agba nigba miiran, lati se akosile itan enu awon agbalagba, fi itan naa kogbon, ati lati so won di kika. |
Àpẹẹrẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ni ìtúnsọ àlọ́ ‘Òwìwí àti Àgbọ̀nrín‘ àwọn aráa Kmhmu ní àárín gbùngbùn àti àríwá Laos. Àlọ́ náà dá lóríi òwìwí tí kò ríran ní ọ̀sán nítorí ó yan àgbọ̀nrín jẹ. | Apeere idanilekoo kan ni itunso alo ‘Owiwi ati Agbonrin‘ awon araa Kmhmu ni aarin gbungbun ati ariwa Laos. Alo naa da lorii owiwi ti ko riran ni osan nitori o yan agbonrin je. |
Níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan, a bi àwọn èwe tí ó kópa: “Irúfẹ́ ẹranko wo ni a bá nínú àlọ́ náà?”, “Ǹjẹ́ a lè rí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní abúlée yín bí?”, àti”bóyá àwọn ẹranko wọ̀nyí ti dínkù sí ti ìgbà kan, kí ni ìwọ rò wípé ó ti ṣẹlẹ̀?” | Nibi idanilekoo kan, a bi awon ewe ti o kopa: “Irufe eranko wo ni a ba ninu alo naa?”, “Nje a le ri awon eranko wonyi ni abulee yin bi?”, ati”boya awon eranko wonyi ti dinku si ti igba kan, ki ni iwo ro wipe o ti sele?” |
Lẹ́yìn èyí, a gba àwọn akópa ní ìyànjú láti so àlọ́ náà mọ́ ìdìbàjẹ́ àyíká ní ìlúu wọn. | Leyin eyi, a gba awon akopa ni iyanju lati so alo naa mo idibaje ayika ni iluu won. |
Ní agbègbè Champasak, gúúsù Laos, ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ ẹranko omi tí ó ti ń dínkù Irrawaddy dolphin àti ẹyẹ Sida ni a ń lò fi ṣe àpèjúwe bí iṣẹ́ ìdarí-omi-ṣíṣàn ṣe ń ṣe àkóbá fún ẹja inú odò Mekong. | Ni agbegbe Champasak, guusu Laos, itan atowodowoo eranko omi ti o ti n dinku Irrawaddy dolphin ati eye Sida ni a n lo fi se apejuwe bi ise idari-omi-sisan se n se akoba fun eja inu odo Mekong. |
Àlọ́ mìíràn láti gúúsù Laos ní àwọn ìlànà tí ó kọ́ni nípa ìmọrírìi ìbójútó ọrọ̀ ìṣẹ̀dá: | Alo miiran lati guusu Laos ni awon ilana ti o koni nipa imoririi ibojuto oro iseda: |
Ní ìgbà kan, ológun kan wọ inú igbó iwin kan. Ó ṣe alábàápàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewé kátabá níbẹ̀ ó sì ṣẹ́ wọ́n. Àmọ́ ṣá, bí ó ti fẹ́ẹ́ jáde nínú igbó náà, ọ̀nà dí mọ́n ọn ní ojú, kò sì mọ ọ̀nà mọ́. Nítorí wípé ó ṣẹ́ ewé kátabá tí ó pọ̀ ju èyí tí ó lè lò lọ ni kò fi mọ ọ̀nà mọ́n. Ó wá ọ̀nà títí kò rí. Ẹ̀rí-ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ ẹ fún ohun tí ó ṣe, ó pinnu láti dá àwọn ewé kátabá náà padà sí ibi tí ó ti gbé ṣẹ́ ẹ. Wéré tí ó sọ ọ́ sílẹ̀, logan ni ó rí ọ̀nà ní iwájúu rẹ̀. | Ni igba kan, ologun kan wo inu igbo iwin kan. O se alabaapade opolopo ewe kataba nibe o si se won. Amo sa, bi o ti fee jade ninu igbo naa, ona di mon on ni oju, ko si mo ona mo. Nitori wipe o se ewe kataba ti o po ju eyi ti o le lo lo ni ko fi mo ona mon. O wa ona titi ko ri. Eri-okan bere si ni je e fun ohun ti o se, o pinnu lati da awon ewe kataba naa pada si ibi ti o ti gbe se e. Were ti o so o sile, logan ni o ri ona ni iwajuu re. |
A ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ Orí Erinmi ní ọjọ́ 16, oṣù Belu, ọdún 2014, ní etídò Songkran ní àríwá-ìwọ̀-oòrùn Thailand. Mun Kimprasert, ẹni ọdún 68. ni asọ̀tàn. Mekong Watch ló ni àwòrán, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ. | A se akosile alo Ori Erinmi ni ojo 16, osu Belu, odun 2014, ni etido Songkran ni ariwa-iwo-oorun Thailand. Mun Kimprasert, eni odun 68. ni asotan. Mekong Watch lo ni aworan, a lo o pelu ase. |
Ní àríwá Thailand, àlọ́ àwọn aráa Akha kan nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ swing tí ó sọ iṣẹ́ takuntakun ìfaraẹnisílẹ̀ t'ẹ̀gbọ́ntàbúrò tí ó mú ayé rọrùn. | Ni ariwa Thailand, alo awon araa Akha kan nipa ipilese swing ti o so ise takuntakun ifaraenisile t'egbontaburo ti o mu aye rorun. |
Ní àríwá ìwọ-oòrùn Thailand, àlọ́ kan tí ó dá lórí Ta Sorn tí Tongsin Tanakanya sọ ṣe ìgbélárugẹ ìṣọ̀kan láàárín aládùúgbò ní ìlú iṣẹ́ àgbẹ̀. Ìtàn mìíràn ṣe ìrántí bí pípa àgbànrere kan ṣe fa iyọ̀ títà ní apá orílẹ̀-èdè yìí. | Ni ariwa iwo-oorun Thailand, alo kan ti o da lori Ta Sorn ti Tongsin Tanakanya so se igbelaruge isokan laaarin aladuugbo ni ilu ise agbe. Itan miiran se iranti bi pipa agbanrere kan se fa iyo tita ni apa orile-ede yii. |
Ní Bunong, tí ó wà ní àríwá ìwọ-oòrùn Cambodia, àwọn àlọ́ tí ó sọ nípa ètùtù fún àtúnṣe sí ìgbéyàwó tí kò ní adùn àti ètùtù ìfọ́nrúgbìn àti ìkórè tí Khoeuk Keosineam jẹ́ asọ̀tàn. Bákan náà ni ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ọ erin tí Chhot Pich sọ ṣe àfihàn bí àwọn òrìṣà ṣe sọ àwọn ará abúlé tí ó fi májèlé sí inú odò di erin. Ó sọ ìdí tí ó fi rọrùn fún erin láti máa gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, wọ́n gbàgbé ìpìlẹ̀ wọn, wọ́n lọ ń gbé nínú igbó. | Ni Bunong, ti o wa ni ariwa iwo-oorun Cambodia, awon alo ti o so nipa etutu fun atunse si igbeyawo ti ko ni adun ati etutu ifonrugbin ati ikore ti Khoeuk Keosineam je asotan. Bakan naa ni itan atowodowoo erin ti Chhot Pich so se afihan bi awon orisa se so awon ara abule ti o fi majele si inu odo di erin. O so idi ti o fi rorun fun erin lati maa gbe pelu awon eniyan amo, leyin opolopo iran, won gbagbe ipile won, won lo n gbe ninu igbo. |
Fún Mekong Watch àti àwọn agbègbè ní ìlú náà tí àkóbá ti bá, ìpamọ́ àwọn ìtàn wọ̀nyí ṣe kókó nínú ìpolongo ìkọjú-ìjà sí àwọn iṣẹ́ tí yóò lé ẹgbẹẹgbẹ̀rún olùgbé Mekong kúrò ní ilée wọn: | Fun Mekong Watch ati awon agbegbe ni ilu naa ti akoba ti ba, ipamo awon itan wonyi se koko ninu ipolongo ikoju-ija si awon ise ti yoo le egbeegberun olugbe Mekong kuro ni ilee won: |