diacritcs
stringlengths 1
36.7k
| no_diacritcs
stringlengths 1
35.5k
|
---|---|
Pẹ̀lú ìfilọ́lẹ̀ẹ Panos fún àkòrí orin tuntun fún Caribbean fún Àyájọ́ Ilẹ̀-ayé, ẹgbẹ́ẹ Jamaica náà ti ṣe tán láti ṣe eré ní iléèwé àti ní àdúgbò, láì yọ Kàwé Jákèjádò Jamaica sílẹ̀ àti iṣẹ́ igi gbíngbìn. Àwọn orin báwọ̀nyí, tí a kọ sí orí ìlú reggae àtijọ́ tí a fi àlùjó kún, ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mi ìgboro: | Pelu ifilolee Panos fun akori orin tuntun fun Caribbean fun Ayajo Ile-aye, egbee Jamaica naa ti se tan lati se ere ni ileewe ati ni adugbo, lai yo Kawe Jakejado Jamaica sile ati ise igi gbingbin. Awon orin bawonyi, ti a ko si ori ilu reggae atijo ti a fi alujo kun, se kerekere mi igboro: |
Ìyá Ìṣẹ̀dá ń kérora fún ìwàláàyè | Iya Iseda n kerora fun iwalaaye |
Bí àwọn iléeṣẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́, ìyá ń ké. | Bi awon ileese se n sise, iya n ke. |
Ìgbà wo ni a óò kọ́ ẹ̀kọ́, tí a ó fi gbọ́n? | Igba wo ni a oo ko eko, ti a o fi gbon? |
Bí omi-dídì ilé ayé ṣe ń yọ́, òkun ń kún. | Bi omi-didi ile aye se n yo, okun n kun. |
Ta ni yóò jáwé olúborí nínú Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019? | Ta ni yoo jawe olubori ninu Ayeye ijo ita-gbangba orile-ede Trinidad ati Tobago odun-un 2019? |
Àwọn alárìíyá máa ń gba títì kan ní ọdọọdún fún Ijó ìta-gbangba Ijó ìta-gbangba Trinidad àti Tobago, tí wọn ń ṣe pẹ̀lú orin. Àwọn àṣàyàn orin tí wọ́n máa ń jó sí máa ń jẹ́ àkójọpọ̀ orin soca tí ó mi ìgboro títì nínú ọdún yẹn, àmọ́ Ìwọ́de Ojúnà orin náà tí máa ń jẹ́ jíjó jù lọ ní àwọn ibi kọ̀ọ̀kan ní ojú ọ̀nà ìyíde jẹ́ oyè tí ó mú ẹ̀bùn àti iyì ìgbélárugẹ àjogúnbá ohun àtijọ́. | Awon alariiya maa n gba titi kan ni odoodun fun Ijo ita-gbangba Ijo ita-gbangba Trinidad ati Tobago, ti won n se pelu orin. Awon asayan orin ti won maa n jo si maa n je akojopo orin soca ti o mi igboro titi ninu odun yen, amo Iwode Ojuna orin naa ti maa n je jijo ju lo ni awon ibi kookan ni oju ona iyide je oye ti o mu ebun ati iyi igbelaruge ajogunba ohun atijo. |
Fún àwọn òṣèré soca, kí ni kan ní í máa mú ni jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà, kò ju, dídáńgájíá ní oríi òpópónà. Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tàbí nnkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ pé ìdíje náà ní màgòmágó nínú pẹ̀lu ìlọ́wọ́sí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó ni ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, afiorin-tí-a-ti-ká-sílẹ̀ dá àwọn ènìyàn lára dá àti àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ orin kíkọ tí a mọ̀ sí “jàndùkú soca” kò ì yọ́ ìgbàgbọ́ wípé Ìwọ́de Ojúnà jẹ́ ohun àwọn ènìyàn. | Fun awon osere soca, ki ni kan ni i maa mu ni jawe olubori ninu Iwode Ojuna, ko ju, didangajia ni orii opopona. Ni odun mewaa seyin tabi nnkan bee ni won so pe idije naa ni magomago ninu pelu ilowosi awon alenuloro ti o ni ile ise igbohunsafefe, afiorin-ti-a-ti-ka-sile da awon eniyan lara da ati awon alase ile ise orin kiko ti a mo si “janduku soca” ko i yo igbagbo wipe Iwode Ojuna je ohun awon eniyan. |
Ìràwọ̀ òṣèrée soca Machel Montano, ẹni tí ó ṣe ojúkòkòrò jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà ní ẹ̀rìnmẹ́sàn-án, ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “orin tí ó máa ń mú àwọn ènìyàn ní ìdùnnú àti tí máa ń mú àwọn ènìyàn jáde nínú ara wọn” akọrin wo ni kò ní fẹ́ gba irú oyè bẹ́ẹ̀? | Irawo oseree soca Machel Montano, eni ti o se ojukokoro jawe olubori ninu Iwode Ojuna ni erinmesan-an, se apejuwe re gege bi “orin ti o maa n mu awon eniyan ni idunnu ati ti maa n mu awon eniyan jade ninu ara won” akorin wo ni ko ni fe gba iru oye bee? |
Àmọ́ kí ẹnikẹ́ni máà rò wípé iṣẹ́ ọpọlọ nìkan ni ìrìnàjò sí Ìwọ́de Ojúnà. Orin Ìwọ́de Ojúnà gbọdọ̀ ní àwọn èròjà tí ó ṣe kókó nínú kí ó tó lè kópa: | Amo ki enikeni maa ro wipe ise opolo nikan ni irinajo si Iwode Ojuna. Orin Iwode Ojuna gbodo ni awon eroja ti o se koko ninu ki o to le kopa: |
Ó gbọdọ̀ ṣe é jó sí, síbẹ̀ ó ní láti dùn ún ní etí àwọn ènìyàn tí yóò “mú wọn gbàgbé ara” ní orí ìtàgé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin tí yóò mú ayọ̀ jáde, èyí tí a mọ Ijó ìta-gbangba mọ́. | O gbodo se e jo si, sibe o ni lati dun un ni eti awon eniyan ti yoo “mu won gbagbe ara” ni ori itage, pelu oro orin ti yoo mu ayo jade, eyi ti a mo Ijo ita-gbangba mo. |
Ègbè tí àwọn òǹwòran lè kọ tẹ̀lé orin, ní ìdásí àti ìdáhùn tí í ṣe àṣà calinda, tí calypso àti àdàlù ìgbàlódé, soca ti wáyé. | Egbe ti awon onworan le ko tele orin, ni idasi ati idahun ti i se asa calinda, ti calypso ati adalu igbalode, soca ti waye. |
Orin tí a gbé jáde ní ìgbà tí ó yẹ. Bí orín bá tètè jáde, tí kò sí dúró pẹ́ títí ní ìgboro, orin mìíràn tí ó ń bá a figagbága lè rọ́ ọ sí ẹ̀gbẹ́. Ní ọ̀nà mìíràn, bí orin tí ó dára gan-an bá pẹ́ jù kí ó tó jáde, àwọn ayírapadà lè máà ní àyè tí ó tó fún wọn láti mọ ọ̀rọ̀ orin náà ní ìgbáradì kí ọjọ́ Ijó ìta-gbangba ó tó dé. | Orin ti a gbe jade ni igba ti o ye. Bi orin ba tete jade, ti ko si duro pe titi ni igboro, orin miiran ti o n ba a figagbaga le ro o si egbe. Ni ona miiran, bi orin ti o dara gan-an ba pe ju ki o to jade, awon ayirapada le maa ni aye ti o to fun won lati mo oro orin naa ni igbaradi ki ojo Ijo ita-gbangba o to de. |
Ní ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀wẹ̀, ìdíje Ìwọ́de Ojúnà máa ń ní orin àyànfẹ́ tí kò ní afigagbága rárá; kò sí rí bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn, ìfigagbága náà máa ń le dé ibi wípé ó máa ń ṣòro láti yan olúborí. Láì wípé ọ̀kan ju ọ̀kan lọ, àwọn wọ̀nyí ni orin tí a rò wípé yóò figagbága nínú Ijó ìta-gbangba Ìwọ́de Ojúnà Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019… | Ni igba miiran ewewe, idije Iwode Ojuna maa n ni orin ayanfe ti ko ni afigagbaga rara; ko si ri bee nigba miiran, ifigagbaga naa maa n le de ibi wipe o maa n soro lati yan olubori. Lai wipe okan ju okan lo, awon wonyi ni orin ti a ro wipe yoo figagbaga ninu Ijo ita-gbangba Iwode Ojuna Trinidad ati Tobago odun-un 2019… |
Pápáa Queen's Park Savannah, ibi tí ó ní ewéko bíi kàá-sí-nǹkan ní àárín gbùngbùn olú ìlú Trinidad, ni ibi tí ayẹyẹ Ijó ìta-gbangba àti ilé ìtàgé àjọ̀dún náà. Orin yìí dá lóríi agbègbè ayẹyẹ náà, àti ìrántí tí ó ti mú bá àwọn ayírapadà tí ó ti ń kópa láti ọdúnmọ́dún. | Papaa Queen's Park Savannah, ibi ti o ni eweko bii kaa-si-nnkan ni aarin gbungbun olu ilu Trinidad, ni ibi ti ayeye Ijo ita-gbangba ati ile itage ajodun naa. Orin yii da lorii agbegbe ayeye naa, ati iranti ti o ti mu ba awon ayirapada ti o ti n kopa lati odunmodun. |
Orin náà ń fi ọ̀wọ̀ wọ agbègbè náà: bí ẹni wípé Agbègbè Papa náà ni oòrùn ní àárín àgbá-ńlá Ijó ìta-gbangba àti ohun tí ó kù ń yí i ká. “Savannah Grass” jẹ́ ìpè sí ìrírí idán ayée àjọ̀dún yìí. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni, ìlù orin náà ba orin náà mú gẹ́gẹ́ bí àwọn olólùfẹ́ẹ Ijó ìta-gbangba tí ó máa ń gbádùn un Ijó ìta-gbangba ṣe máa ń fẹ́ ẹ. | Orin naa n fi owo wo agbegbe naa: bi eni wipe Agbegbe Papa naa ni oorun ni aarin agba-nla Ijo ita-gbangba ati ohun ti o ku n yi i ka. “Savannah Grass” je ipe si iriri idan ayee ajodun yii. Bee ko, amo bee naa ni, ilu orin naa ba orin naa mu gege bi awon ololufee Ijo ita-gbangba ti o maa n gbadun un Ijo ita-gbangba se maa n fe e. |
Orin náà dún dáadáa ní etí àti pé ó mú èèyàn gbàgbé ara rẹ̀, ní ọ̀nà tí ó ń mú kí àwọn ayírapadà ó máa gbé ẹsẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan bí wọ́n ṣe ń rìn/jó ní ojú ọ̀nà. Orin náà ṣe àmúlò àti àfikún àwòrán ìlànà Ijó ìta-gbangba bí a ti ṣe mọ̀ ọ́ ni ìgbà-dé-ìgbà, fídíò orin náà túbọ̀ ṣe àfihàn ìdàgbàsókè orin soca láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí í ṣe orin calypso. Bí kò bá ti ẹ̀ jáwé olúborí nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúnà (bí ó ti lẹ̀ jé pé ó ní àyè tí ó pọ̀!), “Savannah Grass” yóò wà nínú àkópamọ́ orin soca gẹ́gẹ́ bí orin ìgbà-dé-ìgbà tí ó mú inú àwọn olólùfẹ́ẹ Ijó ìta-gbangba ní ibi gbogbo dùn. | Orin naa dun daadaa ni eti ati pe o mu eeyan gbagbe ara re, ni ona ti o n mu ki awon ayirapada o maa gbe ese ni okookan bi won se n rin/jo ni oju ona. Orin naa se amulo ati afikun aworan ilana Ijo ita-gbangba bi a ti se mo o ni igba-de-igba, fidio orin naa tubo se afihan idagbasoke orin soca lati ipilese ti i se orin calypso. Bi ko ba ti e jawe olubori ninu idije Iwode Ojuna (bi o ti le je pe o ni aye ti o po!), “Savannah Grass” yoo wa ninu akopamo orin soca gege bi orin igba-de-igba ti o mu inu awon ololufee Ijo ita-gbangba ni ibi gbogbo dun. |
Ìwà tí ó dùn mọ́ni ti “playing mas'” àti jíjó sí orin ni wípé ní bákan, àwọn èèyàn máa ń ju ọwọ́ sí òkè, pẹ̀lú ohunkóhun tí wọ́n bá mú ní ọwọ́, títì kan ohun-mímu àti aṣọ inujú. Aṣọ inujú yìí ni wọ́n máa ń pè ní “àkísà”, èyí tí wọn máa fi ń nu àágùn bí wọ́n bá ń “fò sókè”. Ìlànà Ijó ìta-gbangba náà kò sọnù ní ara Super Blue, ẹni tí ó kọ “Get Something and Wave”, orin tí ó jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà ọdún-un 1991. | Iwa ti o dun moni ti “playing mas'” ati jijo si orin ni wipe ni bakan, awon eeyan maa n ju owo si oke, pelu ohunkohun ti won ba mu ni owo, titi kan ohun-mimu ati aso inuju. Aso inuju yii ni won maa n pe ni “akisa”, eyi ti won maa fi n nu aagun bi won ba n “fo soke”. Ilana Ijo ita-gbangba naa ko sonu ni ara Super Blue, eni ti o ko “Get Something and Wave”, orin ti o jawe olubori ninu Iwode Ojuna odun-un 1991. |
Ó fọnrere àtinúdá náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé oyè tí ó gbà pẹ̀lú “Bacchanal Time”, tí ó pa àṣẹ fún àwọn ayírapadà láti máa “fi ọwọ́” bí àwọn afọnfèrè brass ṣe ń kọrin “F-jam” tí gbogbo ènìyàn mọ̀ tàbí “tantana” tí ó ń dún ní abẹ́lẹ̀. Super Blue tí ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà fún irúfẹ́ orin kan tí ó dára fún ojú ọ̀nà: ó tún jáwé olúborí ní èèkàn sí i ní ọdún-un 1995 pẹ̀lú orin-in rẹ̀ ewì sí agbábọ́ọ̀lù kríkẹ́ẹ̀tì Brian Lara, tí ó pa á ní àṣẹ fún àwọn olùwòran láti “na pátákóo wọn sí òkè kí wọn ó ṣe àríyá”. | O fonrere atinuda naa ni odun ti o tele oye ti o gba pelu “Bacchanal Time”, ti o pa ase fun awon ayirapada lati maa “fi owo” bi awon afonfere brass se n korin “F-jam” ti gbogbo eniyan mo tabi “tantana” ti o n dun ni abele. Super Blue ti se agbekale ilana fun irufe orin kan ti o dara fun oju ona: o tun jawe olubori ni eekan si i ni odun-un 1995 pelu orin-in re ewi si agbaboolu krikeeti Brian Lara, ti o pa a ni ase fun awon oluworan lati “na patakoo won si oke ki won o se ariya”. |
“Ìjì Àkísà” ní àwọn ohun tí ó mú soca yàtọ̀ bíi irúfẹ́ lavway ìpè-àti-ìfèsì, pẹ̀lú àyè tí ó fẹ́ fún àwọn ènìyàn láti fi àkísà. Orin tí ó dára lórí ìtàgé fún àwọn ayírapadà láti tú ara sílẹ̀ àti “ṣeré tìkára wọn”, lè fi hàn kedere wípé kò kì í ń ṣe wàsá láti fi ọwọ́ rọ́ sí ẹ̀gbẹ́ nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúnà ti ọdún nìí. | “Iji Akisa” ni awon ohun ti o mu soca yato bii irufe lavway ipe-ati-ifesi, pelu aye ti o fe fun awon eniyan lati fi akisa. Orin ti o dara lori itage fun awon ayirapada lati tu ara sile ati “sere tikara won”, le fi han kedere wipe ko ki i n se wasa lati fi owo ro si egbe ninu idije Iwode Ojuna ti odun nii. |
Bí ó bá ní orin kan tí ń fi gbogbo ọ̀nà wá oyè Ìwọ́de Ojúnà ti ọdún yìí, ni orin yìí tí ó ní àyè láti jáwé olúborí: ìlù “soca tí ó tani jí”, ọ̀rọ̀ orin tí ó sọ nípa ìṣọ̀kan tí àjọ̀dún náà máa ń mú wá, àti ègbé ọlọ́pọlọ tí ó kó gbogbo ẹ̀yà tí ó ń kópa nínú Ijó ìta-gbangba náà pọ̀ tí ó ń bá òṣìṣẹ́ akọrin kiri, tàbí bí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Trinbago ṣe máa ń sọ, “famalay” rẹ (kí a máà ṣèṣì fi wé “ẹbí”) : | Bi o ba ni orin kan ti n fi gbogbo ona wa oye Iwode Ojuna ti odun yii, ni orin yii ti o ni aye lati jawe olubori: ilu “soca ti o tani ji”, oro orin ti o so nipa isokan ti ajodun naa maa n mu wa, ati egbe olopolo ti o ko gbogbo eya ti o n kopa ninu Ijo ita-gbangba naa po ti o n ba osise akorin kiri, tabi bi awon omo ibile Trinbago se maa n so, “famalay” re (ki a maa sesi fi we “ebi”) : |
Ṣé ẹ rí i , ẹ jẹ́ kí n sọ fún un yín ní ẹ̀rìnkan sí i, famalay ni famalay ń jẹ́ àti pé ó yàtọ̀ sí ẹbí tí ènìyàn ti wá | Se e ri i , e je ki n so fun un yin ni erinkan si i, famalay ni famalay n je ati pe o yato si ebi ti eniyan ti wa |
Àwọn kan ní ẹ̀jẹ̀ ni àmọ́ wọn kò fẹ́ rí oòrùn | Awon kan ni eje ni amo won ko fe ri oorun |
Famalay kì í bẹ̀rù láyé láti tì ọ́ lẹ́yìn ní ìgbà gbogbo… | Famalay ki i beru laye lati ti o leyin ni igba gbogbo… |
Láì pa àṣẹ (yàtọ̀ sí abala kan tí Skinny kọ “fi ọwọ́ọ̀ rẹ hàn mí” àti “wá tẹ̀lé mi”, orin náà dàbí orin ológun. Ègbé soca tí ó dùn ní etí, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin dancehall díẹ̀díẹ̀, ti ń da orí àwọn ènìyàn rú ní ìtaja Ijó ìta-gbangba. | Lai pa ase (yato si abala kan ti Skinny ko “fi owoo re han mi” ati “wa tele mi”, orin naa dabi orin ologun. Egbe soca ti o dun ni eti, pelu oro orin dancehall diedie, ti n da ori awon eniyan ru ni itaja Ijo ita-gbangba. |
Bí ó ti lẹ̀ jé pé ó ní àríyànjiyàn bóyá “Famalay” yóò kópa nínú Ìwọ́de Ojúnà tàbí kò ní í kópa, nítorí Skinny wá láti St. Vincent àti Grenadines, òfin sọ wípé bí “ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tí ó ń lé orin” yẹ kí “ó jẹ́ ṣíṣe láti ọwọ́ọ ọmọ bíbíi Trinidad àti Tobago”, orin náà lè jẹ́ afigagbága – eléyìí sì jẹ́ ọ̀kan. | Bi o ti le je pe o ni ariyanjiyan boya “Famalay” yoo kopa ninu Iwode Ojuna tabi ko ni i kopa, nitori Skinny wa lati St. Vincent ati Grenadines, ofin so wipe bi “opo awon akorin ti o n le orin” ye ki “o je sise lati owoo omo bibii Trinidad ati Tobago”, orin naa le je afigagbaga – eleyii si je okan. |
Èyí kì í ṣe wípé orin mẹ́ta péré ni ó ń du oyè. Ó ku bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí Ijó ìta-gbangba ó wáyé, àwọn orin wọn mìíràn tí ó ní akọrin obìrin Destra Garcia àti Patrice Roberts tí yóò mú ìdíje le fún àwọn ọkùnrin, àti bí àwọn akọrin soca ṣì ń gbé àwo orin tuntun jáde, ìfigagbága Ìwọ́de Ojúnà ọdún-un 2019 ṣì ń lọ lọ́wọ́. | Eyi ki i se wipe orin meta pere ni o n du oye. O ku bi ose meta ki Ijo ita-gbangba o waye, awon orin won miiran ti o ni akorin obirin Destra Garcia ati Patrice Roberts ti yoo mu idije le fun awon okunrin, ati bi awon akorin soca si n gbe awo orin tuntun jade, ifigagbaga Iwode Ojuna odun-un 2019 si n lo lowo. |
Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí. | Akekoobirin kan ti o je omo Tibet-Canada ri ikolu lori ayelujara leyin ti o ja ewe olu bori ninu idibo ajo-igbimo akekoo. O ro pe, Beijing lo ye a ba wi. |
Leung Hoi Ching ni ó kọ́kọ́ kọ ìròyìn yìí tí a sì tẹ̀jáde ní èdèe Chinese lórí ilé ìgbéròyìn jáde ará ìlú Hong Kong, Stand News ní ọjọ́ karùn-ún-dínlógún, Oṣù Èrèlé, ọdún-un 2019. Zhao Yunlin ni ó tú ìmọ̀ọ rẹ̀ sí èdèe Gẹ̀ẹ́sì. | Leung Hoi Ching ni o koko ko iroyin yii ti a si tejade ni edee Chinese lori ile igberoyin jade ara ilu Hong Kong, Stand News ni ojo karun-un-dinlogun, Osu Erele, odun-un 2019. Zhao Yunlin ni o tu imoo re si edee Geesi. |
Ní ọjọ́ kẹsàn-án Oṣù Èrélé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti Ifáfitì Toronto, ọgbà Scarborough dìbò yan ọmọ ọdún méjìlél'ógún kan tí ìlú abínibíi rẹ̀ jẹ́ Tibet, gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ìgbìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́. | Ni ojo kesan-an Osu Erele, awon akekoo ti Ifafiti Toronto, ogba Scarborough dibo yan omo odun mejilel'ogun kan ti ilu abinibii re je Tibet, gege bi aare igbimo awon akekoo. |
Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí a kéde èsì ìdìbò ọ̀hún, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ China tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ l'ókè òkun fi òǹtẹ̀ lu àpilẹ̀kọ ìfi-èhónú kan ní orí ẹ̀rọ-ayélujára, tí wọ́n sì ń t'ọ́ka àbùkù sí Lhamo pé ó ń l'ẹ̀díàpòpọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ tó ń jà fún òmìnira Tibet. Wọn rọ àwọn aláṣẹ ilé-ìwé ọ̀hún láti yọ ọ́ kúrò l'órí òye náà. | Leyin ojo meloo kan ti a kede esi idibo ohun, ogunlogo awon omo China ti won n kekoo l'oke okun fi onte lu apileko ifi-ehonu kan ni ori ero-ayelujara, ti won si n t'oka abuku si Lhamo pe o n l'ediapopo pelu awon ajo to n ja fun ominira Tibet. Won ro awon alase ile-iwe ohun lati yo o kuro l'ori oye naa. |
Kòbákùngbé ìfèsì ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ń gbé ní òkè òkun gbùngbùn òkè-odò China. | Kobakungbe ifesi oro lati enu awon akekoo ti o n gbe ni oke okun gbungbun oke-odo China. |
Ìṣàmúlò ẹ̀rọ-alátagbàa ti Lhamo kún fún àwọn kòbákùngbé ìjábọ̀-ọ̀rọ̀ àti èyí tí ó ń pè fún ìwàa jàgídíjàgan, èyí tí kò ṣẹ̀yìn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé gbùngbùn China. Bí àwọn ilé ìgbéròyìn sáfẹ́fẹ́ àgbàńlá-ayé gbogbo ṣe tán ìròyìn-in rẹ̀ ká, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà láti Hong Kong àti Taiwan gbìnnàyá láti gbéjàa Lhamo. | Isamulo ero-alatagbaa ti Lhamo kun fun awon kobakungbe ijabo-oro ati eyi ti o n pe fun iwaa jagidijagan, eyi ti ko seyin awon akekoo oke-okun ti o n gbe gbungbun China. Bi awon ile igberoyin safefe agbanla-aye gbogbo se tan iroyin-in re ka, awon akekoo ti o wa lati Hong Kong ati Taiwan gbinnaya lati gbejaa Lhamo. |
Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwo orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Stand News, Chemi Lhamo sọ pé òun nígbàgbọ́ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kò sẹ́yìn àwọn àjọ tí wọ́n ń bá Ìjọba China ṣe, ẹ̀sùn èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ àgbà àjọ ọba China ti sẹ́ lé lórí. | Ninu iforowani-lenuwo ori ero ibanisoro pelu Stand News, Chemi Lhamo so pe oun nigbagbo pe ohun ti o sele ko seyin awon ajo ti won n ba Ijoba China se, esun eyi ti awon osise agba ajo oba China ti se le lori. |
Kí a tó dìbò yìí, a ti yàn mí gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì ààrẹ ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́jọ gbáko, kò sì sí ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀. Ní ìdakèjì, lẹ́yìn gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ẹ pàjáwìrì wọ̀nyìí, kò sí àní-àní pé àjọ kan ń gbìyànjú láti tìka bọ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nwọ̀nyí ní bírípó. Ó pani lẹ́rìn-ín pé láti ìgbà yìí wá tí mo ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì ààrẹ, bí mo ti ṣe ń ṣe ètò oríṣiríṣi tí n ò sì yé fi àwọn àṣàyàn ìhùwàsí mi l'éde, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó ti wádìí nípa àwọn ọ̀nà òṣèlú tí mo yàn ní ààyò. | Ki a to dibo yii, a ti yan mi gege bi igba-keji aare igbimo akekoo fun osu mejo gbako, ko si si ohun kan ti o sele. Ni idakeji, leyin gbogbo iselee pajawiri wonyii, ko si ani-ani pe ajo kan n gbiyanju lati tika bo isele wonwonyi ni biripo. O pani lerin-in pe lati igba yii wa ti mo ti n sise gege bi igba-keji aare, bi mo ti se n se eto orisirisi ti n o si ye fi awon asayan ihuwasi mi l'ede, sugbon ko si eni ti o ti wadii nipa awon ona oselu ti mo yan ni aayo. |
Ó tẹ̀ síwájú sí i pé ìwà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ akẹgbẹ́ òun láti gbùngbùn China tí ń yí padà. Ọ̀kàn nínú àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wá láti gbùngbùn China fi ìwàǹwara pè é níjà láti fi èrò rẹ s'óde lórí gbígba òmìnira Tibet. Ó tún gba àwọn ìpè kan, èyí tí ó ń kọ “orin pupa” (orin ọ̀tẹ̀ tí ó ń yín Ẹgbẹ́ Òṣèlú Chinese Communist Party). Àwọn orin wọ̀nyìí kò yé Lhamo, bó ṣe jẹ́ pé kò mọ èdèe Mandarin Ilẹ̀ China sọ. | O te siwaju si i pe iwa awon akekoo akegbe oun lati gbungbun China ti n yi pada. Okan ninu awon akegbee re ti o wa lati gbungbun China fi iwanwara pe e nija lati fi ero re s'ode lori gbigba ominira Tibet. O tun gba awon ipe kan, eyi ti o n ko “orin pupa” (orin ote ti o n yin Egbe Oselu Chinese Communist Party). Awon orin wonyii ko ye Lhamo, bo se je pe ko mo edee Mandarin Ile China so. |
Bí àkànlù àtakò àti ìjàbọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí ayélujára, àpapọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí gbógun lọ sí ọ́fíìsì ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láti lọ pè fún gbígbé èsì ìdìbò ọ̀hún yẹ̀wò. Ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ sì ti ti ìyàrá ìpàdée wọn pa fún ìgbà díẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ àbò. | Bi akanlu atako ati ijabo se n lo lowo lori ayelujara, apapo awon akekoo kan ti gbogun lo si ofiisi igbimo akekoo lati lo pe fun gbigbe esi idibo ohun yewo. Igbimo akekoo si ti ti iyara ipadee won pa fun igba die, nitori oro abo. |
Chemi Lhamo ti jẹ́ ajàjàǹgbara akẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mélòó kan. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tó ní áápọn ní ìlú àjọgbé àwọn Tibet tí ó wà ní Toronto àti pé ó ti kópa nínú ìjàfẹ́tọ̀ọ́ kan tí ó wáyé níta Akànkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Confucius tí fáfitì ọ̀hún, ẹ̀ka ìbílẹ̀ àjọ ìsọdọ̀kan àṣà Ilẹ̀ China tí ìjọba China ń ṣe agbátẹrù fún lọ́nà tí ó fi ń mú kí China lágbára sí i ní ilẹ̀ òkèèrè. Ní ìgbà yìí wá, ó ti fi èrò ọkàn-an rẹ̀ hàn pẹ̀lú àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìlú láti Hong Kong àti Taiwan lórí kókó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ̀, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìdá-gbé nǹkan ṣe, ìjọba àwarawa àti àwọn kókó tó jọ mọ́ ọ ní ìpàdé ìta gbangba. | Chemi Lhamo ti je ajajangbara akekoo fun odun meloo kan. O je omo egbe to ni aapon ni ilu ajogbe awon Tibet ti o wa ni Toronto ati pe o ti kopa ninu ijafetoo kan ti o waye nita Akanko Ile Eko Confucius ti fafiti ohun, eka ibile ajo isodokan asa Ile China ti ijoba China n se agbateru fun lona ti o fi n mu ki China lagbara si i ni ile okeere. Ni igba yii wa, o ti fi ero okan-an re han pelu awon ajafetoo ilu lati Hong Kong ati Taiwan lori koko oro to je mo, ominira oro siso, ida-gbe nnkan se, ijoba awarawa ati awon koko to jo mo o ni ipade ita gbangba. |
Lhamo ò fi ìgbà kan bẹ̀rù láti sọ èrò ọkàn-an rẹ̀ jáde rí tàbí fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Tibet- ó má ń wọ Chuba, aṣọ ìbílẹ̀ àwọn ọmọ Tibet, ní gbogbo ọjọ́ Ọjọ́rú. Títí di ìgbà ìdìbò, kò gbó-òórùn inúnibíni kán rí láti ọ̀dọ àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ China. Èyí ni ó mú u fura pé ìkoni síta bíi ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ yìí kò sẹ́yìn àwọn aláṣẹ China. | Lhamo o fi igba kan beru lati so ero okan-an re jade ri tabi fi ara re han gege bi omo Tibet- o ma n wo Chuba, aso ibile awon omo Tibet, ni gbogbo ojo Ojoru. Titi di igba idibo, ko gbo-oorun inunibini kan ri lati odo awon akegbee re ti won je omo China. Eyi ni o mu u fura pe ikoni sita bii omo ojo mejo yii ko seyin awon alase China. |
Láti èèyàn ogúnléndé aláìníbùgbé sí olórí ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ | Lati eeyan ogunlende alainibugbe si olori igbimo akekoo |
Kí ó tó rin ìrìnàjò lọ sí Canada ní ọmọ ọdún mọ́kànlá , Chemi Lhamo jẹ́ ẹni ogúnléndé tí kò rí ibùgbé kan gbé ní India. Àwọn òbíi rẹ̀ àgbà sá kúrò ní ilẹ̀ẹ wọn pẹ̀lú Dalai Lama ní ọdún-un 1959. Nínú hàhámọ́ ìnira tí wọ́n wà yìí, kò sí ibi tí òun àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ, tí wọ́n kà wọ́n kún. | Ki o to rin irinajo lo si Canada ni omo odun mokanla , Chemi Lhamo je eni ogunlende ti ko ri ibugbe kan gbe ni India. Awon obii re agba sa kuro ni ilee won pelu Dalai Lama ni odun-un 1959. Ninu hahamo inira ti won wa yii, ko si ibi ti oun ati molebi re lo, ti won ka won kun. |
Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá bí mí léèrè pé : ‘Ibo lo ti wá?’ Ara mi máa ń kótì láti dáhùn – Ìgbà mìíràn mà á pé India ni mo ti wá, ṣùgbọ́n wọn kò fún mi ní ìwé ìgbèlùú; nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ mà á dáhùn pé Tibet ni mo ti wá, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá béèrè pé báwo ni Tibet ṣe rí, n ò mọ bí n ó ṣe dáhùn-un rẹ̀, ìdí ni pé China ò fún mi ní ìwé ìgbèlùú lọ sí Tibet. Ṣùgbọ́n ìrírí mi bí wọ́n ṣe ń rí mi bíi atọ̀húnrìnwá ti jẹ́ kí n ní ìmọ̀ nípa àṣà àwọn èèyàn mi: àṣà Tibet. | Nigbakuugba ti won ba bi mi leere pe : ‘Ibo lo ti wa?’ Ara mi maa n koti lati dahun – Igba miiran ma a pe India ni mo ti wa, sugbon won ko fun mi ni iwe igbeluu; nigba miiran ewe ma a dahun pe Tibet ni mo ti wa, sugbon ti won ba beere pe bawo ni Tibet se ri, n o mo bi n o se dahun-un re, idi ni pe China o fun mi ni iwe igbeluu lo si Tibet. Sugbon iriri mi bi won se n ri mi bii atohunrinwa ti je ki n ni imo nipa asa awon eeyan mi: asa Tibet. |
Llamo sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjòo rẹ̀ lọ sí Canada, ọmọ kékeré akẹ́kọ̀ọ́ tuntun kan tí ó wá láti Tibet tí ó bá wá sí ìyàrá ìkẹ́ẹ̀kọ̀ọ́. Ara rẹ̀ yá gágá, inú rẹ̀ dùn láti ṣe alábàpàdé àwọn ọ̀rẹ́ tí ó wá láti ilẹ̀ẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló mọ̀ pé ó lé sọ èdè Tibet. Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ìfún-ojúpọ̀, ó sọ fún un pé: “Tí a kò bá sọ èdè Tibet ńkọ́? Mo lè sọ Gẹ̀ẹ́sì.” | Llamo soro nipa irinajoo re lo si Canada, omo kekere akekoo tuntun kan ti o wa lati Tibet ti o ba wa si iyara ikeekoo. Ara re ya gaga, inu re dun lati se alabapade awon ore ti o wa lati ilee re, bee lo mo pe o le so ede Tibet. Sibesibe, ninu ifun-ojupo, o so fun un pe: “Ti a ko ba so ede Tibet nko? Mo le so Geesi.” |
N ò mọ̀ bóyá ojú ń tì í ni tàbí ẹ̀rí ọkàn ń jẹ́ ẹ. N ò mọ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà náà ni mo tó mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ Tibet kan ò fẹ́ sọ èdè wọn bí ẹni pé wọn kàn-án nípa fún wọn láti sọ èdè elédè. | N o mo boya oju n ti i ni tabi eri okan n je e. N o mo. Sugbon igba naa ni mo to mo pe awon odo Tibet kan o fe so ede won bi eni pe won kan-an nipa fun won lati so ede elede. |
Ní ìgbà yẹn, Lhamo jẹ́ ọmọ ọdún 12. Ẹ̀míi rẹ̀ ò lé ‘lẹ̀ nípa ìdánimọ̀ọ rẹ̀, ó yìí ọkàn àwọn òbí rẹ̀ padà láti kó lọ sí àdúgbò tí àwọn ọmọ Tibet ń gbé. Láti ìgbà náà wá, ó kọ́ nípa èdè, àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Buddha ti Tibet, ó sì di àjà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn. | Ni igba yen, Lhamo je omo odun 12. Emii re o le ‘le nipa idanimoo re, o yii okan awon obi re pada lati ko lo si adugbo ti awon omo Tibet n gbe. Lati igba naa wa, o ko nipa ede, asa ati isese Buddha ti Tibet, o si di aja-fun-eto omo eniyan. |
Àwọn àdáyanrí ìwà Tibet bíi ìní elẹgbẹ́ ẹni lọ́kàn, ìbọ̀wọ̀ fún àgbà, àìmọ̀kan ní ìpilẹ̀ ìbàjẹ́, ti fún mi ní ìgboyà. Bí ìmọ̀ mi ṣe ń lé kún sí i nínú àṣà ìbílẹ̀ẹ mi, ní ìgboyà mi ṣe ń pọ̀ sí i. | Awon adayanri iwa Tibet bii ini elegbe eni lokan, ibowo fun agba, aimokan ni ipile ibaje, ti fun mi ni igboya. Bi imo mi se n le kun si i ninu asa ibilee mi, ni igboya mi se n po si i. |
Agbára àti ìgboyà yìí, bí ó ṣe sọ, tí mú u láti lè sọ̀rọ̀ akin gẹ́gẹ́ bí atọ̀hùn-rìnwá àti ọmọ Tibet: | Agbara ati igboya yii, bi o se so, ti mu u lati le soro akin gege bi atohun-rinwa ati omo Tibet: |
Ó le láti jẹ́ atọ̀hùn-rìnwá, ṣùgbọ́n ìjàjàǹgbara yìí ní ó sọ mí di bí mo ṣe wà. Lónìí, mò ń sọ̀rọ̀ ní ohùn ìrara nípa àwọn ará Tibet ní kíkankíkan àti ìwúrí ọlọ́pẹ́ tí ìdánimọ̀ọ mi gẹ́gẹ́ bí ọmọ Tibet fún mi. | O le lati je atohun-rinwa, sugbon ijajangbara yii ni o so mi di bi mo se wa. Lonii, mo n soro ni ohun irara nipa awon ara Tibet ni kikankikan ati iwuri olope ti idanimoo mi gege bi omo Tibet fun mi. |
Nígbà tí à ń dìbò ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń tẹnu mọ ọn pé ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ayàsọ́tọ̀ ní aṣojú nígbà ìdìbò. À ń fẹ́ aṣojú tí yóò rí i wípé à ń rí ẹtọ wa gbà lóòrèkóòrè. | Nigba ti a n dibo igbimo akekoo, mo maa n tenu mo on pe o ye ki awon ti won ayasoto ni asoju nigba idibo. A n fe asoju ti yoo ri i wipe a n ri eto wa gba loorekoore. |
Ìjìyà yóò wá sópin | Ijiya yoo wa sopin |
Fún Lhamo, ayé tí ó pé pérépéré ni èyí tí kò sí ìdálọ́wọ́kọ́ tàbí ìyàsọ́tọ̀ Òmìnira Tibet àti ìdádúróo rẹ̀ kọ́ ni ohun tí ó hún jẹ wá lẹ́sẹ̀. | Fun Lhamo, aye ti o pe perepere ni eyi ti ko si idalowoko tabi iyasoto Ominira Tibet ati idaduroo re ko ni ohun ti o hun je wa lese. |
Ìmísí ọjọ́ ọ̀la mi sí Tibet kan náà ni mo ní sì gbogbo àgbá-ńlá-ayé: Mo fẹ́ jẹ́ kí ẹ̀tọ́ tí àwọn ará Tibet ń jẹ gbádùn máà yàtọ̀ sí ti àwọn Canada, àwọn ni òmìnira láti lè sọ èrò ọkàn ẹni, òmìnira láti ní ìgbàgbọ́, òmìnira láti máà fi òṣèlú pá ẹniẹlẹ́ni lẹ́kún. | Imisi ojo ola mi si Tibet kan naa ni mo ni si gbogbo agba-nla-aye: Mo fe je ki eto ti awon ara Tibet n je gbadun maa yato si ti awon Canada, awon ni ominira lati le so ero okan eni, ominira lati ni igbagbo, ominira lati maa fi oselu pa enieleni lekun. |
N ò ṣe ojúṣàájú fún àwọn ará Tibet láti ní àwọn ẹ̀tọ́ wọn yìí nìkan, ó wù mí kí àwọn tí wọ́n wá láti Hong Kong àti Taiwan, ìwọ̀-oòrùn Turkey, àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ní ìlọ́po méjì 60 ẹni ogúnléndé tí ó wà ní kárí ayé àti fún gbogbo àwọn ènìyàn láti jàǹfààní ẹ̀tọ̀ wọ̀nyí. | N o se ojusaaju fun awon ara Tibet lati ni awon eto won yii nikan, o wu mi ki awon ti won wa lati Hong Kong ati Taiwan, iwo-oorun Turkey, awon egbeegberun lona egberun ni ilopo meji 60 eni ogunlende ti o wa ni kari aye ati fun gbogbo awon eniyan lati janfaani eto wonyi. |
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn láti Hong Kong ní ìgbàgbọ́ pé China tí ń lo agbára tìkúùkú, wọ́n sì ń lo ètò ìlú láti ṣẹ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn ẹ̀yà tí kò pọ̀ lẹ́yìn. Kódà ni Hong Kong, àyè láti sọ ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni jáde àti láti bá èèyàn ṣe pọ̀ ti jákulẹ̀. | Opo awon eeyan lati Hong Kong ni igbagbo pe China ti n lo agbara tikuuku, won si n lo eto ilu lati se awon ota ati awon eya ti ko po leyin. Koda ni Hong Kong, aye lati so oro enu eni jade ati lati ba eeyan se po ti jakule. |
Àwọn ìpèníjà òṣèlú tí ó ń kojú wọn ní Hong Kong lẹ́yìn Àkójọpọ̀ Ẹgbẹ́ Alábùradà; 2014 Umbrella Movement kò ṣe àjòjì sí Chemi Lhamo, ṣùgbọ́n ó bá àwọn ará Hong Kong kẹ́dùn, ó pẹ̀tù sí wọn lọ́kàn pé kò kí wọ́n máà ṣe juwọ́ sílẹ̀: | Awon ipenija oselu ti o n koju won ni Hong Kong leyin Akojopo Egbe Alaburada; 2014 Umbrella Movement ko se ajoji si Chemi Lhamo, sugbon o ba awon ara Hong Kong kedun, o petu si won lokan pe ko ki won maa se juwo sile: |
Mo kọ́ ẹ̀kọ́ kan nínú àṣà àwọn Tibet nípa àìwàfúnìgbàpípẹ́: gbogbo nǹkan ni òpin yóò dé bá. Mo ní ìgbàgbọ́ pé ìjìyà gbogbo ń bọ̀ wá dópin…Mo ní ìrètí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí mo máa wọ aṣọ Chuba mi lọ sí Tibet. | Mo ko eko kan ninu asa awon Tibet nipa aiwafunigbapipe: gbogbo nnkan ni opin yoo de ba. Mo ni igbagbo pe ijiya gbogbo n bo wa dopin…Mo ni ireti pe ojo kan n bo ti mo maa wo aso Chuba mi lo si Tibet. |
Ìpolongo ìtakò Kérésìmesì ìlú China mú yíyan àjọyọ̀ le fún ọmọ-ìlú | Ipolongo itako Keresimesi ilu China mu yiyan ajoyo le fun omo-ilu |
Kérésìmesì ń sún mọ́ dẹ̀dẹ̀ ṣùgbọ́n kàkà kí inú àwọn tí ó ń gbé ní orí-ilẹ̀ ìlú China ò dùn, ọ̀pọ́ ti fi ẹ̀hónú-u wọn hàn lórí ìpolongo tí ó tako ayẹyẹ Kérésìmesì tí ó kà á sí àjọ̀dún Òyìnbó. | Keresimesi n sun mo dede sugbon kaka ki inu awon ti o n gbe ni ori-ile ilu China o dun, opo ti fi ehonu-u won han lori ipolongo ti o tako ayeye Keresimesi ti o ka a si ajodun Oyinbo. |
Ní ọdún 2017, ìgbìmọ̀ àgbà àti àjọ ìpínlẹ̀ lábẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú Communist ìlú China kọ ìwé àṣẹ kan tí a pe àkọlée rẹ̀ ní “Ìmọ̀ràn lórí imúdiṣíṣẹ iṣẹ́ ìgbélárugẹ àti ìdàgbà àṣà ìbílẹ̀ China dé ibi gíga “. Wọ́n la àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìsọjí àṣà bíi Ọdún Òṣùpá Tuntun àti Àjọ̀dún Àtùpà sílẹ̀, láì pa ìyìókù tì, gẹ́gẹ́ bí ìpàgọ́ tí ó jẹ mọ́ ti àṣà tí ó lákaakì. | Ni odun 2017, igbimo agba ati ajo ipinle labe egbe oloselu Communist ilu China ko iwe ase kan ti a pe akolee re ni “Imoran lori imudisise ise igbelaruge ati idagba asa ibile China de ibi giga “. Won la awon akanse ise isoji asa bii Odun Osupa Tuntun ati Ajodun Atupa sile, lai pa iyioku ti, gege bi ipago ti o je mo ti asa ti o lakaaki. |
Kí òfin yìí lè di àmúṣẹ, ìjọba China ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ètò ìpolongo kéékèèké mélòó kan fún ìkọ̀yìn sí àwọn ayẹyẹ tí kì í ṣe ti ìbílẹ̀ China. Ọdún nìín, ọjọ́ díẹ̀ sí Kérésìmesì, ìjọba ní àwọn ìlú ńlá bíi Langfang, ní agbègbèe Hebei, ti pa á ní àṣẹ fún ìsọ̀ gbogbo láti yọ ẹ̀ṣọ́ ọdún Kérésìmesì kúrò lójú títí àti fèrèsé. | Ki ofin yii le di amuse, ijoba China ti se ifilole awon eto ipolongo keekeeke meloo kan fun ikoyin si awon ayeye ti ki i se ti ibile China. Odun niin, ojo die si Keresimesi, ijoba ni awon ilu nla bii Langfang, ni agbegbee Hebei, ti pa a ni ase fun iso gbogbo lati yo eso odun Keresimesi kuro loju titi ati ferese. |
Ọ̀rọ̀ àlùfànṣá tí ó dá lórí ìtako àjọ̀dún Òyìnbó ti gba ẹ̀rọ-alátagbà ìlú China kan, èyí mú kí yíyan ayẹyẹ Kérésìmesì láàyò le koko fún àwọn tí ó rò wípé ní ìkọ̀kọ̀ ni ayọ̀ àwọn gbọdọ̀ wà. | Oro alufansa ti o da lori itako ajodun Oyinbo ti gba ero-alatagba ilu China kan, eyi mu ki yiyan ayeye Keresimesi laayo le koko fun awon ti o ro wipe ni ikoko ni ayo awon gbodo wa. |
Ònlo Weibo Long Zhigao ya àwòrán ìròyìn orí WeChat ti rẹ̀ ní orí Weibo ní ìfihàn àríyànjiyàn. Kókó ìròyìn àkọ́kọ́ 1. Àjọ̀dún Òyìnbó ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀. Kí a ṣe àjọyọ̀ àbí kí á máà ṣe é, ìbéèrè ni ìyẹn. 2. Ọmọ China ni mí n kò sì kí ń ṣe àjọyọ̀ Òyìnbó. 3. Sọ pé rárá fún ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nínú ọgbà ilé-ìwé. 4. Ẹgbẹ́ òṣèlú-ìpínlẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí àjọ̀dún Òyìnbó. Àjọyọ̀ àjọ̀dún ti wa di ọ̀rọ̀ ìṣèlú. | Onlo Weibo Long Zhigao ya aworan iroyin ori WeChat ti re ni ori Weibo ni ifihan ariyanjiyan. Koko iroyin akoko 1. Ajodun Oyinbo n bo lona dede. Ki a se ajoyo abi ki a maa se e, ibeere ni iyen. 2. Omo China ni mi n ko si ki n se ajoyo Oyinbo. 3. So pe rara fun isajoyo ajodun Oyinbo ninu ogba ile-iwe. 4. Egbe oselu-ipinle ti ko eyin si ajodun Oyinbo. Ajoyo ajodun ti wa di oro iselu. |
Láfikún-un Kérésìmesì, àkàsílẹ̀ àwọn àjọ̀dún Òyìnbó kò yọ Àyájọ́ Ọjọ́ Olólùfẹ́, Àjíǹde àti Halowíìnì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí ẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ka àjọ̀dún sí “ìgbógunti àṣà” tàbí “ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú”. | Lafikun-un Keresimesi, akasile awon ajodun Oyinbo ko yo Ayajo Ojo Ololufe, Ajinde ati Halowiini, ati bee bee lo si eyin. Opolopo eniyan ni o ka ajodun si “igbogunti asa” tabi “iresile ilu”. |
Fún àpẹẹrẹ, ọ̀kan tí ó ràn ká bí ìgbà tí iná bá ń jó pápá inú ọyẹ́ sọ wípé: | Fun apeere, okan ti o ran ka bi igba ti ina ba n jo papa inu oye so wipe: |
Bí àwọn ènìyàn ìlú kan bá mú àjọyọ̀ àjọ̀dún ìlú mìíràn ní òkúnkúndùn ju bí ó ṣe yẹ, èyí fi hàn wípé orílẹ̀-èdè náà ń jẹ ìyà ìgbógunti àṣà. Bí ẹlẹ́gbẹ́ olóṣèlú kò bá mọ èyí, a jẹ́ wípé wọn kò ní ìkọbiarasí ìṣèlú wọ́n sì ti pàdánù ìlọsíwájúu wọn. | Bi awon eniyan ilu kan ba mu ajoyo ajodun ilu miiran ni okunkundun ju bi o se ye, eyi fi han wipe orile-ede naa n je iya igbogunti asa. Bi elegbe oloselu ko ba mo eyi, a je wipe won ko ni ikobiarasi iselu won si ti padanu ilosiwajuu won. |
Awuyewuye náà tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá Eight-Nation Alliance, ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan tí a dá ní ìdáhùnsí Tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun Akànṣẹ́ ní China láàárín-in ọdún 1899 àti 1901 nígbàtí àwọn àgbẹ̀ rokoroko fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba amúnisìn, ètò ìṣèlú ní ìlànà Krìstẹ́nì àti àṣà. Síwájú sí i, ó ní wípé ọjọ́ ìbíi Mao Zedong, bàbá ìsàlẹ̀ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti Èèyàn-an China, ni ó yẹ kí a kà sí Kérésìmesì ìlú China: | Awuyewuye naa toka si isele-ateyinwa Eight-Nation Alliance, egbe isokan ti a da ni idahunsi Tembelekun Akanse ni China laaarin-in odun 1899 ati 1901 nigbati awon agbe rokoroko fi ehonu han si ijoba amunisin, eto iselu ni ilana Kristeni ati asa. Siwaju si i, o ni wipe ojo ibii Mao Zedong, baba isale Ilu-ti-ko-fi-oba-je ti Eeyan-an China, ni o ye ki a ka si Keresimesi ilu China: |
Alága àkọ́kọ́ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti China Mao Zedong ti yọ àwọn ènìyàn nínú ìṣòro. A gbọdọ̀ sọ ọjọ́ ìbíi rẹ̀ di Kérésìmesì China. Gbé ìgbésẹ̀ kí o kọ àjọ̀dún Òyìnbó. | Alaga akoko Ilu-ti-ko-fi-oba-je ti China Mao Zedong ti yo awon eniyan ninu isoro. A gbodo so ojo ibii re di Keresimesi China. Gbe igbese ki o ko ajodun Oyinbo. |
Àmọ́ àwọn ènìyàn kan lórí Weibo kò rí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n kankan nínú àríyànjiyàn wọ̀nyí. Ẹnìkan sọ pé: | Amo awon eniyan kan lori Weibo ko ri oro ologbon kankan ninu ariyanjiyan wonyi. Enikan so pe: |
Bí àwọn Òyìnbó bá ń ṣe àjọyọ̀ Ọdún Òṣùpá Tuntun, àwọn aráa China á gbéraga wọ́n á sì rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìdàgbà ìsọjí àṣà ìbílẹ̀ China … Bí àwọn aráa China bá ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó, kí ni ìdí tí a fi kà wọ́n sí ìgbógunti àṣà? Àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nítorí àríyá àti fún ayọ̀. Àwọn àjọ̀dún wọ̀nyí lè mú ìkóúnjẹjẹ gbòòrò, kí ni ó burú nínú ìyẹn? | Bi awon Oyinbo ba n se ajoyo Odun Osupa Tuntun, awon araa China a gberaga won a si ri eyi gege bi idagba isoji asa ibile China … Bi awon araa China ba se ajoyo ajodun Oyinbo, ki ni idi ti a fi ka won si igbogunti asa? Awon odo maa n se ajoyo ajodun Oyinbo nitori ariya ati fun ayo. Awon ajodun wonyi le mu ikounjeje gbooro, ki ni o buru ninu iyen? |
Àwọn kan gbèrò wọ́n fẹ́ gbé àjọyọ̀ Kérésìmesì fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú tí ó wáyé ní 160 ọdún sẹ́yìn. Fún kí ni? | Awon kan gbero won fe gbe ajoyo Keresimesi fi egbe kan egbe pelu iresile ilu ti o waye ni 160 odun seyin. Fun ki ni? |
Ẹgbẹ́kíkó, ìkóraẹni-níjàánu | Egbekiko, ikoraeni-nijaanu |
Àgbàrá òdì ọ̀rọ̀ sí Kérésìmesì ti ṣàn gba orí ẹ̀rọ-alátagbà ó sì ti mú kí àwọn òǹlò kan ó kó ara wọn ní ìjánu. Ònlo Weibo kan fi ẹ̀hónú hàn: | Agbara odi oro si Keresimesi ti san gba ori ero-alatagba o si ti mu ki awon onlo kan o ko ara won ni ijanu. Onlo Weibo kan fi ehonu han: |
Kérésìmesì ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀. Ní agbo ọ̀rẹ́ẹ wa, àgọ́ alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó àti alòdìsí alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó ń ṣe àríyànjiyàn. Kò kan ẹnikéni bóyá èèyàn féràn àjọyọ̀ tàbí kò fẹ́, kí ni ó dé tí àwọn ènìyàn ṣe fẹ́ràn láti máa fi túláàsì mú ẹlòmíràn gba èròńgbà ti wọn? Ojú kan tí gbogbo ènìyàn dúró sí ti kún. Fún àwa tí a wà láàárín, kí a ba mú un dọ́gba, a ní láti dúró sí ẹ̀gbẹ́ kejì. | Keresimesi n bo lona dede. Ni agbo oree wa, ago alodisi ajodun Oyinbo ati alodisi alodisi ajodun Oyinbo n se ariyanjiyan. Ko kan enikeni boya eeyan feran ajoyo tabi ko fe, ki ni o de ti awon eniyan se feran lati maa fi tulaasi mu elomiran gba erongba ti won? Oju kan ti gbogbo eniyan duro si ti kun. Fun awa ti a wa laaarin, ki a ba mu un dogba, a ni lati duro si egbe keji. |
Awuyewuye ti kọjáa ti gbàgede orí ẹ̀rọ-alátagbà, ó kàn dé ilé-ìwé àti àjọ ìlú. | Awuyewuye ti kojaa ti gbagede ori ero-alatagba, o kan de ile-iwe ati ajo ilu. |
Àwọn òǹlo Weibo kan ti pín ìkìlọ̀ ilé-ìwé ti a fún akẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀kan nínú ìkìlọ̀ náà (ọ̀tún) ń tọ́ka sí òfin “Ìmọ̀ràn” ó sì rọ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ àyájọ́ tí ó fi ara jọ ti Òyìnbó sílẹ̀. | Awon onlo Weibo kan ti pin ikilo ile-iwe ti a fun akekoo. Okan ninu ikilo naa (otun) n toka si ofin “Imoran” o si ro oluko ati akekoo lati ko ayajo ti o fi ara jo ti Oyinbo sile. |
Bákan náà ni ìkìlọ̀ rọ akẹ́kọ̀ọ́ láti fọ́n iṣẹ́-ìjẹ́ òdì-ọ̀rọ̀ ìgbógunti àṣà Òyìnbó ká sí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ lórí WeChat àti lórí àwọn irinṣẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ ẹ̀rọ-alátagbà mìíràn. | Bakan naa ni ikilo ro akekoo lati fon ise-ije odi-oro igbogunti asa Oyinbo ka si ore ati ojulumo lori WeChat ati lori awon irinse ise-ije ero-alatagba miiran. |
Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ìyá kan nígbàtí ọmọọ rẹ̀ kọ ẹ̀bùn Kérésìmesì. Ìyá kọ sórí Weibo: | Iyalenu ni o je fun iya kan nigbati omoo re ko ebun Keresimesi. Iya ko sori Weibo: |
Ìyá: Ọmọ mi, ẹ̀bùn wo lo fẹ́ fún Kérésìmesì? | Iya: Omo mi, ebun wo lo fe fun Keresimesi? |
Ọmọ: Èmi ò ní ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó kì í ṣe àjọ̀dún ìlúu China. | Omo: Emi o ni se ajoyo ajodun Oyinbo ki i se ajodun iluu China. |
Ó dáa, dájúdájú onígbọràn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn ará ìlú ni ọ́. | O daa, dajudaju onigboran omo egbe oselu ati awon ara ilu ni o. |
Síbẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ṣe àròjinlẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ìbéèrè lórí òfin ilé-ìwé lórí Weibo: | Sibe, awon akekoo ile-eko giga se arojinle. Akekoo kan ni ibeere lori ofin ile-iwe lori Weibo: |
Ilé-ìwé ti gbé ẹsẹ̀ lé ìṣẹ̀ṣọ́ọ Kérésìmesì nínú ọgbà ó sì ti sọ pàṣìpàrọ̀ ẹ̀bùn di èèwọ̀ ní ìpolongo ìtako àjọ̀dún Òyìnbó. Ǹjẹ́ fún ìdàgbàsókè àṣà ilẹ̀ China ni gbogbo ọ̀nà yìí tàbí àmì ìpàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ ẹni? | Ile-iwe ti gbe ese le isesoo Keresimesi ninu ogba o si ti so pasiparo ebun di eewo ni ipolongo itako ajodun Oyinbo. Nje fun idagbasoke asa ile China ni gbogbo ona yii tabi ami ipadanu igbekele asa ibile eni? |
Àwọn kan ti yan ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún náà ní ìkọ̀kọ̀. Òǹlo Weibo kan sọ: | Awon kan ti yan isajoyo ajodun naa ni ikoko. Onlo Weibo kan so: |
Ilé-iṣẹ́ ti sọ ayẹyẹ àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó di èèwọ̀. Ṣùgbọ́n akọ̀wé láti ẹ̀ka ètò-òṣìṣẹ́ ti fi òró Kérésìmesì (ẹ̀bùn Kérésìmesì tí ó wọ́pọ̀) fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹ jẹ́ kí a fẹ́ àlàáfíà. | Ile-ise ti so ayeye ajoyo ajodun Oyinbo di eewo. Sugbon akowe lati eka eto-osise ti fi oro Keresimesi (ebun Keresimesi ti o wopo) fun awon osise ni ikoko. E je ki a fe alaafia. |
Òǹlo Weibo mìíràn fi èròńgbàa rẹ̀ hàn pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́ fún Kérésìmesì: | Onlo Weibo miiran fi erongbaa re han pelu ohun ti o fe fun Keresimesi: |
Ẹ kú ọdún Kérésìmesì! Mo nífẹ̀ẹ́-ẹ̀ rẹ olúwa! Bàba Kérésìmesì, jọ̀wọ́ fún mi ní ìbọsẹ̀ nílá gbàngbà pẹ̀lú òmìnira nínúu rẹ̀. | E ku odun Keresimesi! Mo nifee-e re oluwa! Baba Keresimesi, jowo fun mi ni ibose nila gbangba pelu ominira ninuu re. |
Ìwọ́de afẹ́ àwọn abódiakọ-akọ́diabo àkọ́kọ́ lè tú èrò nípa wọn ní Pakístánì ká | Iwode afe awon abodiako-akodiabo akoko le tu ero nipa won ni Pakistani ka |
Jannat Ali Pẹ̀lú àwọn alágbèékalẹ̀ láti ilé-iṣẹ́ Sathi àti Track-T. Àwòrán láti ọwọ́ọ Syed Noman. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ. | Jannat Ali Pelu awon alagbeekale lati ile-ise Sathi ati Track-T. Aworan lati owoo Syed Noman. A lo o pelu ase. |
Fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ẹ̀tọ́ àti imúdiṣíṣẹ ìbéèrè wọn lábẹ́ òfin, ìwọ́de Afẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo wáyé ní Lahore, Pakistan, lọ́jọ́ 29 oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ìlúu nì, àwọn Abódiakọ-akọ́diabo kò bẹ̀rù láti jáde síta nínú ibi ìkòkọ̀ wọn àti fún ìjọba láti mú òfin Ààbò Ẹ̀tọ́ Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn ọjọ́ 24, oṣù Èbìbì 2018. | Fun ifesemule eto ati imudisise ibeere won labe ofin, iwode Afe Abodiako-akodiabo waye ni Lahore, Pakistan, lojo 29 osu Ope odun 2018. Fun igba akoko ninu itan iluu ni, awon Abodiako-akodiabo ko beru lati jade sita ninu ibi ikoko won ati fun ijoba lati mu ofin Aabo Eto Abodiako-akodiabo Eniyan ojo 24, osu Ebibi 2018. |
Ìwé òfin ìlú Pakistan sọ wípé “A kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìgbé ayé tàbí òmìnira du ẹnikẹ́ni ní ìbámu òfin,” tí ó wà lábẹ́ Àwọn Ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú. Síbẹ̀, Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn ní ìtàn mìíràn láti sọ bí ó bá kan ti ẹ̀tọ́ àti ìgbé ayé; wọ́n ti jìyà oró, ìfipábánilòpọ̀, dáná sun wọ́n ní ààyè, bẹ́ wọn lórí àti yin ìbọn pa wọ́n, ìjọba kò fi torí gbogbo èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú pé Ìjọba ti tari òfin Ààbò Ẹ̀tọ́ Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn wọlé nínú oṣù Ẹrẹ́nà ọdún 2018. | Iwe ofin ilu Pakistan so wipe “A ko gbodo fi eto igbe aye tabi ominira du enikeni ni ibamu ofin,” ti o wa labe Awon Eto omo ilu. Sibe, Abodiako-akodiabo eniyan ni itan miiran lati so bi o ba kan ti eto ati igbe aye; won ti jiya oro, ifipabanilopo, dana sun won ni aaye, be won lori ati yin ibon pa won, ijoba ko fi tori gbogbo eyi ran won lowo pelu pe Ijoba ti tari ofin Aabo Eto Abodiako-akodiabo Eniyan wole ninu osu Erena odun 2018. |
Jannat Ali, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Lahore's Trans Diva, ni olùdásílẹ̀ Abódiakọ-akọ́diabo Track Transgender àti Olùdarí Ètò fún Ilé-iṣẹ́ Sathi tí ó ṣe àgbékalẹ̀ Ìwọ́de Afẹ́ náà. Àwọn Abódiakọ-akọ́diabo mìíràn àti àwọn tí kì í ṣe Abódiakọ-akọ́diabo àmọ́ tí ó jẹ́ alátìlẹ́yìn náà kó ipa nínú ìyíde náà àti àṣeyọríi rẹ̀. Ilé-iṣẹ́ ìpìlẹ̀ Sathi jẹ́ ilé-iṣẹ́ fún àlàáfíà àti ìmójútó ààbò ẹgbẹ́ abódiakọ-akọ́diabo ní Pakistan. | Jannat Ali, ti oruko inagije re n je Lahore's Trans Diva, ni oludasile Abodiako-akodiabo Track Transgender ati Oludari Eto fun Ile-ise Sathi ti o se agbekale Iwode Afe naa. Awon Abodiako-akodiabo miiran ati awon ti ki i se Abodiako-akodiabo amo ti o je alatileyin naa ko ipa ninu iyide naa ati aseyorii re. Ile-ise ipile Sathi je ile-ise fun alaafia ati imojuto aabo egbe abodiako-akodiabo ni Pakistan. |
Ènìyàn Abódiakọ-akọ́diabo tí ó tó bí 250 láti agbègbè jákèjádò ìlú Pakistan. Gbajúmọ̀ nínú wọn ni Kami Sid, Bebo láti Sindh, Nadra láti KPK, Anmol láti Agbègbè Sahiwal, Nayab láti Okara, Sunaina Khan (Oníjó ìbílẹ̀), Naghma àti Lucky (Akọrin Coke Studio), Laila Naz àti Neeli Rana. Ìpàdé oníròyìn ni a fi bẹ̀rẹ̀ ètò ní Ilé Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn ní Lahore níbi tí wọ́n ti fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn; lẹ́yìn náà ni wọ́n yide kiri dé Ilé Àṣà Al Hamra níbi tí wọ́n ti jó, kọrin lọ́nà, kí wọn ó tó fọ́nká lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán. | Eniyan Abodiako-akodiabo ti o to bi 250 lati agbegbe jakejado ilu Pakistan. Gbajumo ninu won ni Kami Sid, Bebo lati Sindh, Nadra lati KPK, Anmol lati Agbegbe Sahiwal, Nayab lati Okara, Sunaina Khan (Onijo ibile), Naghma ati Lucky (Akorin Coke Studio), Laila Naz ati Neeli Rana. Ipade oniroyin ni a fi bere eto ni Ile Egbe Akoroyin ni Lahore nibi ti won ti fi edun okan-an won han; leyin naa ni won yide kiri de Ile Asa Al Hamra nibi ti won ti jo, korin lona, ki won o to fonka leyin ti won jeun tan. |
Pẹ̀lú pé ìpàdé fún oníròyìn wáyé ní Ilé Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn Lahore, Ìyíde Ìgbéraga náà ó jáde nínú ìròyìn. Bíótilẹ̀jépé àwọn alágbèékalẹ̀ fi ìwé pe aláṣẹ ìlú, bí i Punjab MNA Saadia Sohail láti Pakistan Tehreek e Insaf, àwọn aláṣẹ kò yọjú. Ìyíde ọ̀hún fa awuyewuye lórí ẹ̀rọ-alátagbà níbi tí àwọn ènìyàn gbé oríyìn fún ìyíde kiri náà nígbà tí àwọn ènìyàn kan fẹ́ mọ ìdí tí ilé iṣẹ́ oníròyìn kò ṣe rò nípa rẹ̀. | Pelu pe ipade fun oniroyin waye ni Ile Egbe Akoroyin Lahore, Iyide Igberaga naa o jade ninu iroyin. Biotilejepe awon alagbeekale fi iwe pe alase ilu, bi i Punjab MNA Saadia Sohail lati Pakistan Tehreek e Insaf, awon alase ko yoju. Iyide ohun fa awuyewuye lori ero-alatagba nibi ti awon eniyan gbe oriyin fun iyide kiri naa nigba ti awon eniyan kan fe mo idi ti ile ise oniroyin ko se ro nipa re. |
Ni ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ alágbèékáa Jannat Ali ní: | Ni oroo re alagbeekaa Jannat Ali ni: |
Ìyíde náà tún tẹnu mọ́ ìlọsíwájú àti ìbáṣepọ̀ rere láàárín ẹgbẹ́ abódiakọ-akọ́diabo; bákan náà ni ó tẹnu mọ́ ìyàsọ́tọ̀ àti rògbòdìyàn. Nítorí wípé kò sí iṣẹ́ fún wọn, àwọn abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn kò ní ṣíṣe ju kí wọn ó ṣe òwò nọ̀bì láti rí oúnjẹ òòjọ́. Látàrí ìbálòpọ̀ tí kò ní ààbò, ọ̀pọ̀ l'ó ti kó àrùn kògbéwékògbègbó HIV àti AIDS. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣe kókó fún àjọ ọlọ́pàá àti oníṣègùn nítorí àwọn ni kì í mú ayé rọrùn fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn tí ó bá ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ tàbí nílò ìrànlọ́wọ́ ètò ìlera. | Iyide naa tun tenu mo ilosiwaju ati ibasepo rere laaarin egbe abodiako-akodiabo; bakan naa ni o tenu mo iyasoto ati rogbodiyan. Nitori wipe ko si ise fun won, awon abodiako-akodiabo eniyan ko ni sise ju ki won o se owo nobi lati ri ounje oojo. Latari ibalopo ti ko ni aabo, opo l'o ti ko arun kogbewekogbegbo HIV ati AIDS. Idanilekoo se koko fun ajo olopaa ati onisegun nitori awon ni ki i mu aye rorun fun Abodiako-akodiabo eniyan ti o ba ra owo ebe tabi nilo iranlowo eto ilera. |
A ti fi ẹ̀tọ́ àwọn abódiakọ-akọ́diabo yí iyẹ̀pẹ̀. Láti ọdún 2015, abódiakọ-akọ́diabo tí ó tó 500 ni a ti rán lọ sí ọ̀run alakákeji ní Pakistan , Jannat Ali sì tún sọ wípé Abódiakọ-akọ́diabo 60 ni a dá ẹ̀mí wọn ní ẹ̀gbodò ní ọdún tí ó kọjá. | A ti fi eto awon abodiako-akodiabo yi iyepe. Lati odun 2015, abodiako-akodiabo ti o to 500 ni a ti ran lo si orun alakakeji ni Pakistan , Jannat Ali si tun so wipe Abodiako-akodiabo 60 ni a da emi won ni egbodo ni odun ti o koja. |
Asad Zaidi túwíìtì nípa ojú tí àwọn ènìyàn Pakistan fi wo ẹgbẹ́ Abódiakọ-akọ́diabo: | Asad Zaidi tuwiiti nipa oju ti awon eniyan Pakistan fi wo egbe Abodiako-akodiabo: |
Nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ ní TEDxLahore ní ọdún 2017, Jannat Ali ṣe àlàyé ìrìnàjòo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abódiakọ-akọ́diabo ní Pakistan lẹ́yìn ìgbà tí ó fi irú ènìyàn tí òun ń jẹ́ han ẹbí àti àwọn ènìyàn. | Ninu oroo re ni TEDxLahore ni odun 2017, Jannat Ali se alaye irinajoo re gege bi abodiako-akodiabo ni Pakistan leyin igba ti o fi iru eniyan ti oun n je han ebi ati awon eniyan. |
Òfin Ẹ̀tọ́ Ààbò Abódiakọ-akọ́diabo Ènìyàn ọdún 2018 tí a bu ọwọ́ lù nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fi àṣẹ fún ọmọ ẹgbẹ́ náà láti gba ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà, ìwé ìrìnnà, ní ẹ̀tọ́ láti pààrọ ìṣẹ̀dá ẹni nínú àkọsílẹ̀ ìlú àti Àjọ Ìforúkọsílẹ̀ (NADRA), ìfòpinsí ìjìyà, àyè láti kàwé, iṣẹ́ nínú káràkátà àti ètò ìlera láì sí ìyàsọ́tọ̀. | Ofin Eto Aabo Abodiako-akodiabo Eniyan odun 2018 ti a bu owo lu ninu ile igbimo asofin fi ase fun omo egbe naa lati gba iwe ase oko wiwa, iwe irinna, ni eto lati paaro iseda eni ninu akosile ilu ati Ajo Iforukosile (NADRA), ifopinsi ijiya, aye lati kawe, ise ninu karakata ati eto ilera lai si iyasoto. |
Òfin náà ní ìjọba yóò pèsè àyè ilé ààbò fún Abódiakọ-akọ́diabo ènìyàn, ètò ìlera àti ohun èlò ẹ̀kọ́ àti ilanilọ́yẹ. Wọ́n máa lè jẹ ogún àti ẹ̀tọ́ láti di ìbò. | Ofin naa ni ijoba yoo pese aye ile aabo fun Abodiako-akodiabo eniyan, eto ilera ati ohun elo eko ati ilaniloye. Won maa le je ogun ati eto lati di ibo. |